Awọn ará Ketu-Alapere ní ìpínlẹ̀ Èkó ti fi ẹ̀sùn kan àwọn ọlọ́pàá àgọ́ Alapere pé wọ́n ń yọ àwọn lẹ́nu wọ́n sì ń lọ́ àwọn lọ́wọ́ gbà.
Wọ́n ní àwọn ọlọ́pàá náà ó ṣàdédé wọ àdúgbò wá ní alẹ́ wọn yóò sì máa kó gbogbo àwọn tí wọ́n bá rí. Wọ́n ní owó tabua ni ẹni tí wọ́n bá mú yóò san ní owo ìtúsílẹ̀ kó tó le padà sílé.
Lára àwọn tí wọ́n kó gbẹ̀yìn ni àwọn ọmọ ilé ìwé gíga Yaba, wọ́n ní àwọn ń ti ilé ìjọsìn bọ̀ ni àwọn ọlọ́pàá náà he àwọn bíi ìgbín tí wọ́n sì kó wọn lọ sí àgọ́ wọn.
Solomon Adelumola; ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe àlàyé pé àwọn ṣe ìdámọ̀ ara wọn pẹ̀lú káàdì ìdánimọ̀ ilé ìwé àmọ́ níṣe ni àwọn ọlọ́pàá gba ilé sí agbójú, wọn kò tilẹ̀ wò ó rárá tí wọ́n fi tari wọn sínú ọkọ̀.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó wí pé àwọn lọ sí ilé ìjọsìn ní Alapere àwọn sì jáde ní aago mẹ́wàá àbọ̀ alẹ́, wọ́n yà nílé ọ̀rẹ́ wọn kan tó ń gbé nítòsí ibẹ̀ wọ́n sì ń darí lọ ilé tiwọn.
Aago mọ́kànlá ń lọ lù ni wọ́n rí àwọn ọkùnrin méjì kan tó ń sún mọ́ wọn lójú ọ̀nà ẹlẹ́sẹ̀ Ketu, wọn kò sá nígbà tí wọn kò lẹ́bọ lẹ́rù àmọ́ àwọn ọkùnrin náà rá wọn mú ní ṣòkòtò ló bá di ọlọ́pàá àfi bí wọ́n ṣe wọ́ wọn bíi ọ̀daràn lọ sínú ọkọ̀ – Solomon Adelumola.
Ẹlòmíràn náà ṣe àlàyé ohun tí ojú rẹ̀ rí lọ́wọ́ àwọn ọlọ́pàá Alapẹ̀rẹ̀, David Owolabi ní wọ́n gba ẹ̀rọ̀ ìbánisọ̀rọ̀ òun wọ́n sì bà á jẹ́ níbi tí wọ́n ti ń wọ́ ọ ní ìwọ́kúwọ̀ọ́, àwọn mẹ́wàá mìíràn ni wọ́n kó pẹ̀lú rẹ̀.
Nígbà tí wọ́n dé àgọ́, wọn kò bèèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ wọn, ogún ẹgbẹ̀rún náìrà ni wọ́n bèèrè lọ́wọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan tó bá fẹ́ padà sílé. David ní òun takú pé òun yóò rí ọ̀gá nítorí akẹ́kọ̀ọ́ lòun àmọ́ ìyàlẹ́nu ló jẹ́ nígbà tí ọ̀gá ní kí òun ó san owó náà.
Àlàyé David tẹ̀síwájú pé òun àti ọ̀rẹ́ òun tí wọ́n jọ kó bẹ̀ wọ́n pé akẹ́kọ̀ọ́ láwọn wọn kò ní irú owó bẹ́ẹ̀ àmọ́ wọ́n ní kò kan àwọn. Nígbà tó yá, wọ́n gbà láti gba ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá náírà lọ́wọ́ òun àti ọ̀rẹ́ rẹ̀.
Wọ́n tẹ̀lé ọ̀rẹ́ rẹ̀ náà lọ sí òde láti gba owó náà lọ́wọ́ àwọn tó ń ṣe POS àmọ́ gbogbo wọn ti lọ ilé, wọ́n wá pe èèyàn kan fi àkáńtì rẹ̀ ránṣẹ́, ogún ẹgbẹ̀rún náírà ni wọ́n san sínú àkáńtì náà fún ìdásílẹ̀ òun àti ọ̀rẹ́ rẹ̀. Aago méjì òru ni wọ́n dá David àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ sílẹ̀.
Bákan náà ni ó wí pé àwọn ọlọ́pàá náà kò fi orúkọ wọn pe ara wọn bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò wọṣọ, ìnagijẹ ni wọ́n ń pe ara wọn, ọ̀kan nínú wọn ń jẹ́ Agba.
Ọ̀rọ̀ yìí ti dé etí ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó, alukoro wọn; Abimbola Adebisi wí pé àwọn ti gbọ́ nípa ẹ̀sùn náà wọ́n sì ti tari rẹ̀ lọ sí ẹ̀ka tí yóò wádìí rẹ̀. Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé àwọn ọmọ náà yóò yọjú sí ìgbìmọ̀ náà.
Ìròyìn mìíràn tó jẹ mọ́ ti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ìpínlẹ̀ Èkó ni ti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé gíga LASUSTECH tí wọ́n pàdánù ẹ̀mí wọn ní ojú ọ̀nà ikorodu:
Ilé ìwé gíga LASU ní Èkó pàdánù àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọn méjì nínú ìjàm̀bá ọkọ̀ tó wáyé ní oríta Powerline, Ikorodu lọ́jọ́ àbámẹ́ta.
Nínú àtẹ̀jáde tí alukoro fún ilé ìwé náà; Olanrewaju Kuye bu ọwọ́ lù lọ́jọ́ àìkú la ti rí i kà pé nínú àwọn mẹ́ta tó kú nínú ìjàm̀bá náà, méjì ni ó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé náà.
Orúkọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó bá ikú òjijì pàdé náà ni Oluwaseyi Afolabi Emmanuel àti Ayomide Jagun, ìpele kejì àti kẹta ni wọ́n wà ní ẹ̀ka ẹ̀kọ́ ilé ìfowópamọ́ àti ètò ìṣ̀ùná àti ẹ̀ka ìmọ̀ ẹ̀rọ ní tẹ̀létẹ̀lé.
Àlàyé tí ilé iṣẹ́ LASTMA ṣe nípa ìjàm̀bá náà ni pé ọkọ̀ akóyanrìn kan tí kò ní ìwé ìforúkọsílẹ̀ ló pàdánù ìjánu rẹ̀ tó sì kọlu ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkọ̀ kó tó dúró.
Ọ̀gá ilé ìwé náà; Ọ̀jọ̀gbọ́n Olumuyiwa Odusanya wí pé àwọn ti mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ náà àwọn sì ti kàn sí gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kàn. Ó wí pé òun ti kàn sí ilé ìwòsàn ìjọba ìkòròdú, ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá, ẹ̀ka tó ń gbọ́ ti akẹ́kọ̀ọ́ àti ọ̀gá ẹ̀ka àwọn ọmọ náà láti ṣètò ìrànwọ́ fún àwọn òbí àwọn ọmọ náà.
Bákan náà ni àwọn aṣojú akẹ́kọ̀ọ́ ń sa ipá wọn lọ́rí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Ilé ìwé LASUSTECH wí pé àwọn ti fi ọ̀rọ̀ ìbánikẹ́dùn ránṣẹ́ sí àwọn òbí àwọn ọmọ náà àwọn sì ń ṣètò bí wọn yóò ṣe fi ilẹ̀ bo àṣírí wọn.
Ọ̀jọ́gbọ́n Olumuyiwa kẹ́dùn ikú àwọn ọmọ náà, ó ṣe àpèjúwe rẹ̀ bíi ọ̀fọ̀ ńlá tí kò ṣe é rọ́pò. Ó wí pé àwọn ọmọ tí ọjọ́ ọ̀la wọn kún fún ìmọ́lẹ̀ ni ikú àìtọ́jọ́ sọ di òkùnkùn lójijì. Ó bá àwọn òbí wọn kẹ́dùn ó sì ṣe àdúrà fún àwọn òkú òrun kí ẹ̀mí wọn ó ní ìsinmi.
Kí a fi ìròyìn mìíràn tó wáyé ní Ikorodu ṣèlọ:
Àwọn kan tí wọ́n fura sí pé wọ́n jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ni wọ́n ti ṣá arákùnrin kan tí wọ́n ń pè ní Benjamin pa ní Ikorodu báyìí o. Ohun tí a gbọ́ ni pé Benji ni ìnàgijẹ ọkùnrin náà ó sì jẹ́ gbajúmọ̀ oníṣàwámà tí ilé iṣẹ́ rẹ̀ ń jẹ́ Chibest. Agbègbè Ebutte-Ipakodo ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ṣẹlẹ̀.
Nǹkan bíi aago mẹ́jọ ààbọ̀ alẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun tó kọjá ni àwọn ọkùnrin méjì kan dé sí ìsọ̀ rẹ̀ nígbà tí ó ń dá àwọn oníbàárà lóhùn lọ́wọ́, wọ́n sún mọ́ ọn dáadáa kí wọ́n tó yin ìbọn fún un láìmọye ìgbà. Kò sí ẹni tó le sún mọ́ Benji títí wọ́n fi lọ pátápátá. Nígbà tí wọn yóò fi gbé e dé ilé ìwòsàn, Benji ti dágbére fáyé.
Àwọn ará àdúgbò wí pé ìkọlù àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà, wọ́n ní oró ọ̀kan lára wọn tí wọ́n pa ni wọ́n fi ikú Benji rán.




