Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ti tẹ àwọn afurasí mọ́kànlá tí wọ́n jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé girama ti ìjọba tó wà ní Bichi, ìpínlẹ̀ Kano.
Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kano; Abdullahi Haruna fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn ti mú àwọn afurasí akẹ́kọ̀ọ́ mọ́kànlá náà lórí ikú tó pa akẹgbẹ́ wọn méjì.
Ó wí pé àwọn ti kó wọn sí àhámọ́ láti fi ọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò lórí ipa tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn kó nínú ikú àwọn akẹgbẹ́ wọn méjì náà.
Hamza Idris Tofawa àti Umar Idris Dungurawa ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ méjì náà tí wọ́n ṣekú pa. ìròyìn fi yé wa pé lẹ́yìn tí wọ́n jáde ilé ìwé ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹgbẹ́ wọn ṣe ìkọlù sí wọn tí wọ́n sì fi irin ìbílẹ̀ kan tí wọ́n ń pè ní ‘Gwale gwale’ ṣekú pa wọ́n.
Kọmíṣọ́nà fún ètò ẹ̀kọ́ ìpínlẹ̀ Kano; Dọ́kítà Ali Haruna Makoda ti pàṣẹ kí àwọn ọlọ́pàá ó ṣe ìwádìí fínní lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Abdullahi Haruna ti wá fi àwọn aráàlú lọ́kàn balẹ̀ pé àwọn yóò ṣe ìwádìí ìjìnlẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ náà tí àwọn yóò sì mú àwọn tó pa àwọn ọmọ náà.
Adarí ètò ẹ̀kọ́ girama ìpínlẹ̀ Kano; Abbas Abdullahi náà dá sí ọ̀rọ̀ náà. Ó rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ pé kí wọn ó má ṣe ìdájọ́ lọ́wọ́ ara wọn ó sì rọ àwọn ọlọ́pàá láti ṣe ìwádìí ìjìnlẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
ỌKỌ̀ ÀWỌN AKẸ́KỌ̀Ọ́ ILÉ ÌWÉ GÍGA KWARA GBANÁ LÓRÍ ÌRÌN.
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé gíga ìpínlẹ̀ Kwara méjìdínlógún ni orí kó yọ lọ́wọ́ ikú òjijì nígbà tí ọkọ̀ wọn gbaná lójijì lórí ìrìn.
A gbọ́ pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà gbéra láti Ilorin, wọ́n ń lọ fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ní Malete ni ọkọ̀ wọn gbaná lórí ìrìn. Òpópónà Shao nítòsí ibùdó àwọn ológun tó wà ní Sobi ni ọkọ̀ náà ti gbaná ní nǹkan bíi aago mẹ́jọ òwúrọ̀ ń lọ lù.
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ráàyè sá jáde nínú ọkọ̀ náà àmọ́ ọkọ̀ náà jóná kan éérú. Àwọn panápaná náà sa ipá wọn lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Adarí ẹ̀ka àtẹ̀jáde fún ilé iṣẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ Kwara; Hassan Adekunle fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ pé àwọn ta mọ́ra láti dóòlà ẹ̀mí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ inú ọkọ̀ náà àmọ́ ọkọ̀ náà jóná kanlẹ̀ ní tirẹ̀.
ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ TI MÚ ỌKÙNRIN KAN TÓ GBÌYÀNJÚ ÀTI FÚN WỌN NÍ OWÓ Ẹ̀YÌN.
Arákùnrin kan ni àwọn ọlọ́pàá ti mú sọ sí gbaga látàrí pé ó gbìyànjú àti fún àwọn ọlọ́pàá ní àbẹ̀tẹ́lẹ̀ mílíọ̀nù kan àbọ̀ náírà.
A gbọ́ pé àwọn ọlọ́pàá mú ajínigbé kan sí àhámọ́, ọkùnrin yìí tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Yahaya Saleh wá fi owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ mílíọ̀nù kan àbọ̀ náírà lọ àwọn ọlọ́pàá pé kí wọn ó dá ajínigbé náà sílẹ̀.
Ọlọ́pàá tí ó ń ṣe ìwádìí ọ̀rọ̀ náà kọ̀ láti gba owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ náà ó sì ṣètò bí wọ́n ṣe fi òfin gbé Saleh.
Kọ́míṣọ́nà ọlọ́pàá Abuja kí ọlọ́pàá náà kú ìfọmọnìyànṣe àti ìwà òdodo rẹ̀, ó wá kàn án nípá fún àwọn ọlọ́pàá láti wá àwọn yòókù tí wọ́n jọ ń ṣe ìjínigbé náà jáde.
ỌKỌ̀ ÀJÀGBÉ AGBÉPO GBANÁ NÍ ÌBÀDÀN.
Ọkọ̀ àjàgbé agbépo kan tó gbé epo bẹntiróòlù tó lé ní jálá ẹgbẹ̀rún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33,000 lt) ti gbaná ní Ìbàdàn tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
A gbọ́ pé ọkọ̀ náà gbaná lánàá, Ọjọ́bọ, ọjọ́ kẹtàdínlógún, oṣù Agẹmọ ní oríta Celica tó wà ní New life, Ìbàdàn.
Ọkọ̀ yìí kọ́kó pàdánù ìjánu rẹ̀ lórí eré ó sì kọlu ọkọ̀ Prado kan kó tó di pé ó ṣubú lulẹ̀ tó sì gbaná, kò sí ẹni tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ yìí lọ àmọ́ ọkọ̀ Prado náà jóná kanlẹ̀.
Maoof Akinwande; ẹni tó jẹ́ alága ilé iṣẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ pé àwọn gba ìpè pàjáwìrì náà ní nǹkan bíi aago mẹ́fà àbọ̀ ìrọ̀lẹ́ ní Ọjọ́bọ àwọn sì ta mọ́ra dé ibẹ̀.
Akinwande wí pé àwọn panápaná ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ fi afẹ́fẹ́ ìpaná kojú iná náà wọ́n sì dáàbò bo ilé epo NNPC tó wà ní ìtòsí àti àwọn ilé agbègbè náà. Àwọn panápaná ìjọba àpapọ̀ náà rìn sí àsìkò wọ́n sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti pa iná náà tán yányán.
ÀÀRẸ BOLA AHMED TINUBU ṢE ÀYÍPADÀ ORÚKỌ ILÉ ÌWÉ GÍGA MAIDUGURI SÍ ORÚKỌ MUHAMMADU BUHARI.
Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti ṣe àyípadà orúkọ ilé ìwé gíga Maiduguri UNIMAID sí orúkọ ààrẹ àná tó dágbére fáyé; Muhammadu Buhari.
Orúkọ ilé ìwé náà titun ni Muhammadu Buhari University MBU.
Níbi àpéjọ àwọn àgbààgbà olóṣèlu tó wáyé ní Abuja lánàá, Ọjọ́bọ, ọjọ́ kẹtàdínlógún ni Ààrẹ Tinubu ṣe ìkéde yìí. Ó wí pé Buhari jẹ́ adarí tó nífẹ̀ẹ́ orílẹ̀-èdè yìí dénúdénú tó sì fi ìgbé ayé rẹ̀ sìn ín.
Ààrẹ oní ṣe àpèjúwe ààrẹ àná bíi èèyàn jẹ́jẹ́, onísùúrù, ẹni tó ṣe é fi ọkàn tán. Ó gbé ìgbé ayé ọmọlúàbí ó sì fi ayé rẹ̀ fún Ọlọ́run.
Nípa báyìí, ó pọn dandan láti ṣe àpónlé àti ìṣelọ́jọ̀ orúkọ Buhari kó má baà parun.
DELE MOMODU YAPA KÚRÒ NÍNÚ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ PDP.
Dele Momodu; ẹni tó ti fìgbà kan du ipò ààrẹ ilẹ̀ yìí ti kéde ìyapa rẹ̀ kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP.
Nínú ìwé tó kọ ránṣẹ́ sí alága ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ni a ti ríi kà pé ó di dandan kí n kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP nítorí pé àwọn àgbà ẹgbẹ́ náà ń ṣorò bí èwe.
Kò sí ohun tó tọ́ sí mi lásìkò yìí ju kí n lọ darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú tó ní àfojúsùn ìyẹn ẹgbẹ́ òṣèlú ADC.
Mi ò ní gbàgbé àtìlẹyìn tí ẹ ṣe fún mi lásìkò tí ko jẹ́ ọ̀kan lára yín. Èyí ji àwọn ohun tí Dele Momodu kọ sínú ìwé náà.
YÍYAPA ATIKU Ò LE TU IRUN KAN LÁRA ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ PDP – LAJA ADEOYE.
Ọmọba Laja Adeoye; ẹni tó jẹ́ èèkà nínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ní ìpínlẹ̀ Èkó ti sọ̀rọ̀ sókè pé ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ò le è yindin bí Atiku ṣe yapa kúrò lọ darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú ADC.
Ọmọba Adeoye ni ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣójúṣòfin tó ń ṣojú ẹ̀kun Oshodi-Isolo. Ó ṣe àlàyé nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan tó ṣe pẹ̀lú ilé iṣẹ́ ìròyìn News Agency of Nigeria ní òwúrọ̀ òní; ọjọ́ Ẹtì, ọjọ́ kejìdínlógún.
Ohun tó sọ náà ni pé yípapa Abubakar Atiku kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP yóò mú kí àlàáfíà ó jọba nínú ẹgbẹ́ náà ni nítorí pé Atiku gan-an jẹ́ ọ̀kan lára àwọn igi wọ́rọ́kọ́ tíí da iná ẹgbẹ́ òṣèlú PDP rú.
Èyí kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí Atiku yóò yapa kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣelú PDP tó sì máa ń padà wá darapọ̀ padà, gbogbo bí ó ṣe ń lọ tó ń bọ̀ nínú ẹgbẹ́ náà, digbí ni ẹgbẹ́ náà wà.
Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ti fi ọ̀rọ̀ ìdìbò ọdún 2027 ṣe àkòtúnramú ìjà ẹ̀kùn, wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ ìgbaradì tó nípọn fún ètò ìdìbò ọdún 2027 – èyí ji àwọn ọ̀rọ̀ tí Ọmọba Adeoye sọ.




