Àwọn ará abulé Kwaple ní ìjọba ìbílẹ̀ Chibok ìpínlẹ̀ Borno pé jọ láti sin òkú àwọn èèyàn tí àwọn agbésùnmọ̀mí pa, ibẹ̀ ni wọ́n wà tí wọ́n tún fi y abò wọ́n, èèyàn mẹ́ẹ̀dógún ni wọ́n pa nígbà tí wọ́n jí ọ̀pọ̀lọpọ̀ gbé sá lọ.
Alága ìjọba ìbílẹ̀ Chibok; Modu Mustapha fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí múlẹ̀ fún àwọn akọ̀ròyìn pé èèyàn mẹ́ẹ̀dógún mìíràn ni wọ́n pa níbi tí wọ́n ti ń sin òkú àwọn ti wọ́n ti pa tẹ́lẹ̀.
Lẹ́yìn náà ni wọ́n dáná sun ilé ìjọsìn EYN àti ilé márùn-ún.
Gbogbo akotiyan láti bá agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Borno; Nahum Daso sọ̀rọ̀ kò yọrí sí rere lásìkò tí a kọ ìròyìn yìí.
Bí a kò bá gbàgbé, ìjọba ìbílẹ̀ Chibok yìí ni àwọn agbésùnmọ̀mí ti kó ogúnlọ́gọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin lọ́dún 2014 tí kò sì sí àbọ̀ kankan lórí wọn di àsìkò yìí.
Kò fẹ́rẹ̀ sí ibi tó fara rọ lásìkò yìí ní àríwá ilẹ̀ wa, ojoojumọ́ ni àwọn agbésùnmọ̀mí ń ṣe ìkọlù sí wọn.
Ọ̀sẹ̀ yìí náà ni wọ́n ṣe ìkọlù sí ìpínlẹ̀ Adamawa.
Àwọn èèyàn mẹ́tàdínlógún ni wọ́n rán lọ̀run ọ̀sán gangan nínú ìkọlù náà.
Alága ìjọba ìbílẹ̀ Hong ní ìpínlẹ̀ Adamawa; Usman Wa’anganda bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìkọlù tó ti wáyé ní agbègbè rẹ̀ láàrin ọ̀sẹ̀ méjì síra. Ó wí pé àwọn èèyàn mẹ́tàdínlógun ni àwọn agbésùnmọ̀mí ti pa lápapọ̀ láàrín ọ̀sẹ̀ méjì síra.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Usman wí pé àwọn ọdẹ mẹ́wàá ni wọ́n pa lọ́jọ́ Àbámẹ́ta ní abúlé Kopre. Nǹkan bí aago mẹ́rin ìrọ̀lẹ́ ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kẹrìnlélọgún, oṣù Igbe yìí ni ìkọlù náà wáyé.
Yàtọ̀ sí àwọn tí wọ́n pa yìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé ni wọ́n dáná sun tí àwọn èèyàn sì wà nínú ìbẹ̀rùbojo. Usman ní òun gan-an ò le fi ojú ba oorun láti ìgbà yìí.
Ó wí pé àwọn agbésùnmọ̀mí máa ń wọ abúlé Kopre lóòrèkóòrè nítorí pé ó pààlà pẹ̀lú igbó Sambisa ní èyí tó mú un rọrùn fún wọn láti wọlé jáde.
Usman tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé àwọn ọdẹ ìbílẹ̀ nìkan ni àwọn ní ní aláàbò, kò sí ológun kankan ní ìtòsí abúlé náà, àwọn ọlọ́pàá tó súnmọ́ àwọn kìí dáhùn bí àwọn bá ránṣẹ́ pè wọ́n. Ó ní ó bani lọ́kàn jẹ́ gidi. Usman rọ ìjọba ìpínlẹ̀ Adamawa láti da àwọn ọmọ ológun sí abúlé náà kí àwọn ó le padà sí oko.
Abúlé Kopre ni ìlú akọ̀wé ìjọba àpapọ̀ tẹ́lẹ̀rí; Mustapha. Àwọn ológun a máa dáàbò bo abúlé náà láti ibùdó Garaha tí kò jìnnà sí Kopre àmọ́ lọ́gán tí Mustapha kúrò nípò ni wọ́n kó gbogbo àwọn ọmọ ológun náà kúrò tí ibùdó náà sì ṣófo.
Àwọn ará abúlé Kopre ra ọwọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ìjọba láti gbà wọ́n kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn agbésùnmọ̀mí tó ń fi ojoojúmọ́ pa wọ́n bíi adìyẹ. Wọ́n ní inú fu àyà fu ni àwọn wà nítorí pé ìgbàkúùgbà ni wọ́n le ṣe ìkọlù sí àwọn.
Àti abúlé Kopre àti abúlé Kwaple ló gbóná janjan lásìkò yìí. Ẹ̀bẹ̀ ni wọ́n bẹ ìjọba kó gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn afẹ̀míṣòfò.
Ti àwọn afẹ̀míṣòfò lẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, ìròyìn mìíràn tí ọwọ́ wa tún tẹ̀ ni ìròyìn tó gbòde kan lónìí pé àjọ EFCC ti palẹ̀ E-money mọ́
A gbọ́ pé Àjọ tó ń gbógun ti ìṣowówóòlú mọ́kumọ̀ku EFCC ti gbé Emeka Okonkwo tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí E-money fún ẹ̀sùn ìṣowó náírà mọ́kumọ̀ku.
Òru ọjọ́ Ajé mọ́jú ọjọ́ Ìṣẹ́gun ni àwọn òṣìṣẹ́ EFCC ya wọ ilé rẹ̀ tó wà ní Omole tí wọ́n sì kó o ní pápámọ́ra.
Ohun tí a gbọ́ ni pé nítorí pé E-money ná owó ilẹ̀ òkèrè níbi ayẹyẹ tó ṣe lọ yìí ni wọ́n ṣe gbé e. Bákan náà la gbọ́ pé wọ́n ti gbé e lọ sí Abuja fún ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò.
Agbẹnusọ̀ fún àjọ EFCC; Dele Oyawale kọ̀ láti sọ ohunkóhun nípa ọ̀rọ̀ yìí.
Ní èsì sí gbígbé tí wọ́n gbé E-money yìí, ọ̀rẹ́ rẹ̀; Cubana priest bu ẹnu àtẹ́ lu èyí, ó wí pé ìwà ẹlẹ́yàmẹyà ni ìjọba hù yìí, ó ní torí pé ó jẹ́ ọmọ igbo ni wọ́n ṣe gbé e.
Kìí wá ṣe E-money nìkan ni àjọ EFCC gbé o, wọ́n gbé gbajúmọ̀ arábìnrin Aisha Achimugu náà. A gbọ́ pé Àjọ tó ń gbógun ti ìwà àjẹbánu EFCC ti gbé gbajúgbajà arábìnrin Aisha Achimugu ní pápákọ̀ òfurufú Nnamdi Axikwe tó wà ní Abuja.
Ní kété tí Aisha balẹ̀ láti inú ọ̀kọ̀ bàlúù tó gbée dé láti ìlú London ni wọ́n gbé e.
Láti inú oṣù Ẹrẹ́nà ni àjọ EFCC ti kéde pé àwọn ń wá Aisha lórí ẹ̀sùn jìbìtì. Ọjọ́ Ajé ọ̀sẹ̀ yìí ni ilé ẹjọ́ gíga Abuja pàṣẹ pé kí Aisha ó farahàn níwájú ilé ẹjọ́ lónìí ọjọ́ iṣẹ́gun àti ọ̀la ọjọ́rú.
Agbẹjọ́rò Aisha; Olóyè Chikaosolu Ojokwu wí pé àwọn gba ìwé ìpè láti ilé ẹjọ́ lóòótọ́ wọ́n sì ti gbé e bó ṣe dé.
Èyí tí a ó fi kádìí ẹ̀ nílẹ̀ náà ni ti ìjàmbá tó wáyé lórí afárá Otedola lónìí. Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ kà báyìí pé Ọkọ̀ àjàgbé eléjò kan gbókìtì lórí afárá Ọ̀tẹdọlá lónìí tí ó sì dá súnkẹrẹ fàkẹrẹ ọkọ̀ tó nípọn sílẹ̀.
Nǹkan bíi aago kan ọ̀sán òní ni ọkọ̀ náà dànù tó sì dùbú ọ̀nà.
Àwọn oṣìṣẹ́ LASTMA ti wà níbẹ̀ láti mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Inú ọdún yìí náà ni ìjàmbá burúkú kan wáyé lórí afárá Otedola yìí kan náà níbi tí ọkọ̀ àjàgbé tó gbé epo bẹntiróòlù ti gbaná lojijì. Ìjàmbá yìí pọ̀ débi pé àwọn èèyàn jóná gúrúgúrú nínú rẹ̀ ni, kódà tọkọtaya kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ìgbéyàwó bá ìjàmbá náà lọ.
Discussion about this post