Ọjọ́ àìkú, ọjọ́ kọkànlélógún tó kọjá yìí ni àwọn agbébọn mẹ́wàá ṣàdédé ya wọ ibùdókọ̀ Ilesa Baruba tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Baruten, ìpínlẹ̀ Kwara. Ilé ìgbafẹ́ kan tó wà ní ibùdókọ̀ yìí ni wọ́n ṣínà ìbọn bò tí wọ́n sì pa àwọn èèyàn mẹ́fà nígbà tí àwọn èèyàn méjì mìíràn farapa.
Ilé ìgbókùúsí Baruba ni wọ́n kó àwọn tó kú náà lọ nígbà tí wọ́n kó àwọn tó farapa náà lọ sí ilé ìwòsàn.
Aago mẹ́sàn-án àbọ̀ alẹ́ ni wọ́n ṣe ìkọlù ti ibùdókọ̀ Baruba yìí, nígbà tó di aago mọ́kànlá àbọ̀ alẹ́ ọjọ́ kannáà, àwọn ikọ̀ agbésùnmọ̀mí mìíràn tún ṣe ìkọlù sí Kemanji ní ìjọba ìbílẹ̀ Kaiama. Àwọn ọdẹ ìbílẹ̀ kojú wọn wọ́n sì mú mẹ́ta balẹ̀ nínú wọn àmọ́ àwọn náà yin ọdẹ kan níbọn ó sì padà kú sí ilé ìwòsàn.
Yusuf Samba ni orúkọ ọdẹ tí wọ́n yìnbọn pa náà, òun àti ikọ̀ rẹ̀ ni wọ́n dá àwọn agbésùnmọ̀mí náà lọ́wọ́ kọ́ tí wọ́n sì fi ìbọn ṣe mẹ́ta léṣe nínú wọn.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara sọ̀rọ̀ láti ẹnu agbẹnusọ wọn; Toun Ejire-Adeyemi pé àwọn gba ìfisùn méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nípa ìkọlù tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Kwara, wọ́n ní ọwọ́ ti tẹ èèyàn kan tó ń fún àwọn agbésùnmọ̀mí lọ́wọ́. Toun wí pé ẹni náà ti jẹ́wọ́ pé òun ló ń fún àwọn agbésùnmọ̀mí lọ́wọ́ tí wọ́n fi wá ṣe àwọn ìkọlù náà.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá sọ nínú ọ̀rọ̀ wọn pé àwọn ti ṣe àlékún àwọn ọlọ́pàá agbègbè náà, àwọn sì ti dá àlàáfíà padà sípò. Wọ́n ní ẹni tọ́wọ́ bà náà yóò wúlò púpọ̀ fụ́n ìwádìí ìkọlù yìí wọ́n sì ṣe ìlérí pé àwọn yóò mú àwọn tó ṣe ìkọlù náà.
Ìkọlù yìí wáyé lẹ́yìn èyí tó wáyé léraléra ní ìpínlẹ̀ Plateau lọ́sẹ̀ tó kọjá sẹ́yìn.
Àwọn èèyàn ò le gbàgbé àwọn ìkọlù ìpínlẹ̀ Plateau náà bọ̀rọ̀ nítorí pé ẹ̀mí sọnù.
Ìkọlù tó wáyé lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun náà gba ẹ̀mí àwọn èèyàn mọ́kànléláàdọ́ta nígbà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ wà ní ilé ìwòsàn. Ará abúlé kan fi ẹ̀sùn kan àwọn ológun ibùdó náà pé wọ́n mọ̀ọ́nmọ̀ má wá ni nítorí pé ibùdó náà ko ju ohun tí wọ́n le fi ẹsẹ̀ rìn lọ.
Gbogbo akitiyan àwọn oníròyìn láti kàn sí Ọ̀gágun ibùdó yìí kí ó le tan ìmọ̀lẹ̀ sí ọ̀rọ̀ yìí kò yọrí sí rere látàrí pé kò gbé ìpè rẹ̀ kò sì tún fèsì sí àtẹ̀jíṣẹ́.
BÍ ÌKỌLÙ NÁÀ ṢE WÁYÉ.
Abúlé Zikke gbóná janjan lóru ọjọ́ Ajé mọ́jú ọjọ́ Ìṣẹ́gun ọ̀sẹ̀ tó kọjá nígbà tí àwọn agbébọn bá wọn lálejò. Ìjọba ìbílẹ̀ Bassa ni abúlé Zikke wà ní Jos tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Plateau.
Òru ní nǹkan bíi aago méjìlá kọjá ni àwọn agbébọn náà dé sí abúlé Zikke lógúnlógún lọ́gbọ̀nlọ́gbọ̀n. Wọ́n yìnbọn lákọlákọ, wọ́n dáná sun ọ̀pọ̀ ilé, wọ́n pa àwọn èèyàn bíi àádọ́ta wọ́n sì tún ṣe ogúnlọ́gọ̀ báṣubàṣu.
Ó lé ní wákàtí kan tí wọ́n fi ṣe ọṣẹ́ yìí láìsí ìdíwọ́ kankan.
Olórí ọ̀dọ́ abúlé Zikke, ẹni tó jẹ́ akọ̀wé ẹgbẹ́ Irigwe; Joseph Chudu bá ikọ̀ àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Ó wí pé wọ́n ti kó àwọn tó farapa lọ sí ilé ìwòsàn ìjọba Jos, ipò wọn burú wọ́n sì nílò ẹ̀jẹ̀.
Chudu rọ ìjọba láti ṣe àtúnṣe sí ètò ààbò tó mẹ́hẹ yìí. Gbogbo akitiyan láti kàn sí ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Plateau kò so èso rere nípa pé agbẹnusọ wọn; Alabo Alfred kò gbé ìpè àwọn oníròyìn.
Ìkọlù yìí jẹ́ ọ̀tun lẹ́yìn gbogbo àwọn ìkọlù tó ti wáyé ní ìpínlẹ̀ Plateau lẹ́nu lọ́lọ́ yìí. Ọ̀sẹ̀ tó lọ lọ́hùn-ún ni wọ́n fẹ́rẹ̀ run gbogbo ìjọba ìbílẹ̀ Bokko. Àádọ́ta èèyàn ni wọ́n pa lọ́sẹ̀ náà nìkan tí ọ̀pọ̀ dúkìá sì tún ṣòfò dànù.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Plateau bu ẹnu àtẹ́ lu ìkọlù tó ń wáyé sásá yìí ó sì rọ àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò láti wá àwọn agbésùnmọ̀mí náà jáde.
Kọmíṣọ́nà fún ìfitónilétí; Joyce Renmap wí pé ìkọlù tó gba ìpínlẹ̀ Plateau kan yìí jẹ́ ohun tó bani lọ́kàn jẹ́. Joyce wí pé ogúnlọ́gọ̀ àwọn èèyàn ni wọ́n pa ní ìjọba ìbílẹ̀ Bokko àti Bassa láàrín ọ̀sẹ̀ méjì yìí.
Ọ̀rọ̀ Joyce tẹ̀síwájú pé ìlú tó kún fún ìfẹ́ àti àdùn tẹ́lẹ̀ ti paradà di ibi tó kún fún ìkorò àti ìbànújẹ́ látàrí ìkọlù ojoojúmọ́ yìí. Ó gúnlẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú pé kí àwọn èèyàn ó fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ìjọba láti borí àdojúkọ yìí.
Wàyí o, àwọn ará abúlé bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lórí ibi tí iná gbà jó wọn. Lancaster Akpa; ẹni ọdún mọ́kàndínláàdọ́ta wí pé ẹbí òun mẹ́sàn-án ló bá ìkọlù náà lọ. Akpa wí pé Jos ni òun wà nígbà tí àbúrò òun pe òunp pé àwọn agbésùnmọ̀mí ti bẹ̀rẹ̀ ìkọlù, ó ní òun kò le sùn mọ́ lóru ọjọ́ náà, ìgbà tí òun pe aago rẹ̀ tí kò lọ mọ́ ni ara ti ń fu òun kó tó wá di pé òun dé bá òkú rẹ̀, ẹ̀gbọ́n òun àti àwọn ọmọ wọn méje.
Akpa wí pé àwọn tí wọ́n wá ṣe ìkọlù náà wọ aṣọ ológun àmọ́ Fulani ni wọ́n gẹ́gẹ́ bí ohun tí òun gbọ́.
Jerry Muwa náà sọ tirẹ̀, ó ní àwọn ọmọọmọ òun mẹ́fẹ́ẹ̀fà ni wọ́n dáná sun mọ́lé nígbà tí wọn kò rí ìlẹ̀kùn já. Ó ní òun rápálá jáde lóru ọjọ́ náà ni pẹ̀lú ọmọ òun tó jẹ́ bàbá àwọn ọmọ náà. Muwa wí pé àwọn ọmọ náà jóná di éérú débi pé kò sí ẹran tàbí eegun tí àwọn le sin, àwọn kan kó éérú wọn jọ sínú sàárè kan ni.
Ìpínlẹ̀ Plateau lọ́sẹ̀ tó lọ, ìpínlẹ̀ Kwara lọ́sẹ̀ yìí, ìpínlẹ̀ wo la mọ̀ tó kàn? Àfi kí ìjọba tètè wá wọ̀rọ̀kọ̀ fi ṣàdá.
Discussion about this post