ADVERTISEMENT
  • About
  • Contact
Monday, June 1, 2026
  • Login
  • Register
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
No Result
View All Result
Home Ààyè Olóòtú

ÀWỌN AGBÉBỌN ṢEKÚ PA ÈÈYÀN MẸ́RIN, WỌ́N JÍ ÈÈYÀN MÉJÌ GBÉ SÁLỌ.

Ìkọlù àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn.

by Adeola Olanrewaju
June 20, 2025
in Ààyè Olóòtú, Ìgbé-Ayé, Ìròyìn, Ìròyìn Agbègbè, Ìròyìn Tó Gbòde, Ọ̀rọ̀ Ààbò
0
Àwọn agbébọn ya wọ ààfin ní Kwara.
0
SHARES
11
VIEWS
Pín Lórí FacebookPín Lórí ThreadsPín Lórí TwitterPín Lórí Bluesky
ADVERTISEMENT

Àwọn agbébọn ṣe ìkọlù sí agbègbè Oko ní ìjọba ìbílẹ̀ Orumba ní ìpínlẹ̀ Anambra níbi tí wọ́n ti ṣekú pa àwọn èèyàn mẹ́rin tí wọ́n sì tún ṣe ìpalára fún àwọn èèyàn méje mìíràn, bákan náà ni wọ́n gbé àwọn èèyàn méjì sá lọ.
A kò le sọ pàtó okùnfà ìkọlù yìí àmọ́ ohun tí a ń gbọ́ bíi àhesọ ni pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ni ó ṣe ìkọlù náà nítorí pé àwọn mẹ́rin tí wọ́n pa àti àwọn méje tí wọ́n farapa náà jẹ́ ọmọ ilé ìwé gíga ìjọba tó wà ní Oko.
Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn ṣe àlàyé wí pé àwọn agbébọn náà yaw ọ ìlú lójijì, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní yin ìbọn, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé gíga Oko mẹ́rin ni wọ́n yìnbọn pa tí wọ́n sì ṣe àwọn méje mìíràn léṣe kí wọ́n ó tó ṣẹ̀ṣẹ̀ wá gbé àwọn tí wọ́n wá wa gan-an.
A rí fọ́nrán kan tí akẹ́kọ̀ọ́bìnrin kan àti akẹ́kọ̀ọ́kùnrin kan tí wọ́n wà nínú àgbàrá ẹ̀jẹ̀ tí wọn kò sì le mí dáadáa.
Tochukwu Ikenga; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Anambra fìdí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí múlẹ̀ àmọ́ ó wí pé àwọn méjì ni wọ́n pa dípò èèyàn mẹ́rin tí àwọn aráàlú sọ.
Ikenga wí pé ìkọlù náà súnmọ́ iṣẹ́ àwọn ẹgbẹ́ òkùnkùn àwọn sì ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí.
Ní ìpínlẹ̀ Anambra yìí kan náà ni àwọn ọlọ́pàá ti lọ kó wọn níbi orò ìgbaniwọlé sínú ẹgbẹ́ òkùnkùn lọ́sẹ̀ tó kọjá. Ìròyìn náà kà báyìí pé:
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Anambra ṣe àlàyé ọ̀rọ̀ láti ẹnu agbẹnusọ wọn; Tochukwu Ikenga pé àwọn ọlọ́pàá yabò wọ́n níbi tí wọ́n ti ń ṣe orò ìgbaniwọlé sínú ẹgbẹ́ òkùnkùn kan ní agbègbè Nawfia, Njikoka ní ìpínlẹ̀ Anambra.
A gbọ́ pé àwọn afurasí mẹ́fà ni ọwọ́ tẹ̀, wọ́n bá ìbọn ìléwọ́ kan, ìbọn gígùn méjì, àdá méjì, amuga méjì àti ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan ní sàkánì wọn.
Orúkọ àwọn afurasí náà ni Nwadike Chibuike, Anierobi Precious, Rapheal Ebube, Ezechi Benjamin, Okafor Chidera àti Chiema Okoye. Ọjọ́ orí wọn wà láàrín ogún ọdún sí ọgbọ̀n ọdún. Gbogbo wọn ti wà ní àhámọ́ títí ìwádìí yóò fi parí tí wọn yóò sì fi ojú ba ilé ẹjọ́.
Lára ìgbésẹ̀ àti kojú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn gẹ́gẹ́ bí ìjọba ṣe ṣe ìlérí rẹ̀ ni èyí jẹ́. Wọ́n ní àsìkò ti tó láti fi imú àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn dánrin kí wọn yé da ìlú láàmú.
Mélòó la fẹ́ kà nínú àwọn ọṣẹ́ tí wọ́n ti ṣe sẹ́yìn. Ọ̀kan ni ti àwọn akẹ́kọ̀ọ́jáde ilé ìwé gíga Niger tí wọ́n ṣá láṣàápa. Ìròyìn náà kà báyìí pé:
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́jáde méjì ti ilé ìwé gíga Niger Delta tó wà ní Amassoma ni àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ti ṣá láṣàápa báyìí.
Àlàyé tí a rí gbà ni pé àwọn méjì yìí wà ní Gbarantoru ní Yenogoa, ìpínlẹ̀ Bayelsa, ìwé ìpè sí àgùnbánirọ̀ ni wọ́n ń retí kí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn náà tó ṣá wọn pa.
Orúkọ èkíní ń jẹ́ Ayaokpe Sinclair nígbà tí a kò tíì mọ orúkọ èkejì. Ìrọ̀lẹ́ àná; Ọjọ́bọ, ọjọ́ kẹjọ, oṣù Èbìbí ni wọ́n ṣá wọn pa.
Aláṣẹ ẹ̀ṣọ́ aláàbò ìbílẹ̀ ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Bayelsa; Tolummbofa Johnathan ṣe àlàyé pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́jáde méjì yìí ń rìn lọ ní òpópónà ni àwọn kan pariwo láti inú ọkọ̀ pé “àwọn nìyẹn” wọ́n bọ́ sílẹ̀ tì àwọn méjì náà wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní pariwo “Aye, Aye” kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí ṣá wọn ládàá.
Ayaokpe kú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ àmọ́ èkejì rẹ̀ gbìyànjú àti sálọ, awakọ̀ tó gbé wọn wá ríi pé àbúrò òun ni ó sì gbé e lọ sínú ọkọ̀ kó le gbé é sálọ àmọ́ wọ́n ká wọn mọ́ inú ọkọ̀ náà wọ́n sì ṣá a pa.
Johnathan wí pé àwọn rí awakọ̀ náà mú àwọn sì ti fàá lé àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́.
Nígbà tí èyí ṣì ń jà ràìnràìn nílẹ̀, a tún gbọ́ nípa bí wọ́n ṣe sẹkú pa Benji ní Ìkòròdú, ìròyìn bí wọ́n ṣe pa Benji tí a rí gbà ni pé:
Àwọn kan tí wọ́n fura sí pé wọ́n jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn ni wọ́n ti ṣá arákùnrin kan tí wọ́n ń pè ní Benjamin pa ní Ikorodu báyìí o. Ohun tí a gbọ́ ni pé Benji ni ìnàgijẹ ọkùnrin náà ó sì jẹ́ gbajúmọ̀ oníṣàwámà tí ilé iṣẹ́ rẹ̀ ń jẹ́ Chibest. Agbègbè Ebutte-Ipakodo ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ṣẹlẹ̀.
Nǹkan bíi aago mẹ́jọ ààbọ̀ alẹ́ ọjọ́ Ìṣẹ́gun tó kọjá lọ́hùn-ún ni àwọn ọkùnrin méjì kan dé sí ìsọ̀ rẹ̀ nígbà tí ó ń dá àwọn oníbàárà lóhùn lọ́wọ́, wọ́n sún mọ́ ọn dáadáa kí wọ́n tó yin ìbọn fún un láìmọye ìgbà. Kò sí ẹni tó le sún mọ́ Benji títí wọ́n fi lọ pátápátá. Nígbà tí wọn yóò fi gbé e dé ilé ìwòsàn, Benji ti dágbére fáyé.
Ìkọlù àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn yìí kò mọ níbẹ̀, a gbọ́ nípa ìdúnkokò tí wọ́n dún mọ́ àwọn ará abúlé Ifa Ikot pé:
Àwọn ará abúlé Ifa Ikot Akpan ní ìpínlẹ̀ Akwa Ibom ti ké gbájarè sí àwọn ọlọ́pàá láti gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn tó ń dún mọhurumọ̀ruru mọ́ àwọn.
Àlàyé tí a rí gbà ni pé ẹgbẹ́ òkùnkùn KKK kọ ìwé pélébé há fún àwọn ará ìlú, ohun tí wọ́n kọ sínú ìwé náà ni pé kí àwọn aráàlú náà ó máa múra ìkọlù tó lágbára tí àwọn yóò ṣe sí wọn.
Wọ́n ní àwọn yóò ṣe ìkọlù sí àwọn aráàlú náà nítorí pé wọ́n màá ń yọ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àwọn lẹ́nu ní gbogbo ìgbà.
Ẹgbẹ́ òkùnkùn KKK fi ẹ̀sùn kan àwọn ará ìlú Ifa pé wọ́n ń fi àwọn ọlọ́pàá halẹ̀ mọ́ àwọn wọ́n sì ń yọ àwọn lẹ́nu. Wọ́n ní ọjọ́ tí àwọn ọlọ́pàá bá tún wá kó àwọn tàbí yọ àwọn lẹ́nu, àwọn èèyàn tí àwọn yóò pa díi ni:
Ọ̀gbẹ́ni Abasiama Eti Eyo, Ọ̀gbẹ́ni Itoro Offiong Essien, Ọ̀gbẹ́ni Itoro Etim Ben, Ọ̀gbẹ́ni Eddiong Efiong àti Ọ̀gbẹ́ni Victor Edet Asuquo.
Wọ́n ní àwọn wọ̀nyìí ni wọ́n ń ta àwọn ọlọ́pàá lólobó nípa àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àwọn.
Wọ́n wá fi ìkìlọ̀ kún un pé ọjọ́ tí àwọn ọlọ́pàá bá tún halẹ̀ mọ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ àwọn, gbogbo àwọn tí àwọn dárúkọ náà ni wọn yóò lọ síi nítorí pé ọmọ ìlú Ifa náà ni olórí àwọn, àwọn kò tún gbodò máa bẹ̀rù láàárín ìlú.
Baálẹ̀ abúlé Ifa Ikot Akpan; Ọ̀gbẹ́ni Eteidung Ebong fi ọ̀rọ̀ náà tó kọ́míṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Akwa Ibom àti Gómìnà Umo Eno láti gba àwọn kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn yìí.
Ó rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Gómìnà láti ṣe àlékún àwọn ọlọ́pàá àtí àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ní ìlú náà. Ó wí pé òun mọ àwọn méjì tí wọ́n jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn náà.
Bákan náà ni a gbọ́ pé àwọn tí wọ́n dárúkọ sínú ìwé náà ti fẹsẹ̀ fẹ́ẹ.

ADVERTISEMENT
Facebook Comments Box
ADVERTISEMENT

Related

Tags: #iweiroyinyoruba#ìwéròyìnyorùbá #NewsOnline#newsfeed#newsupdatesAfojúsùn Iwe Iroyin YorubaIwe Iroyin Yorubanewsinyorubatrending
ADVERTISEMENT
Adeola Olanrewaju

Adeola Olanrewaju

Next Post
MO KÁBÀÁMỌ̀ PÉ MO ṢE ÌPOLONGO ÌBÒ FÚN TINUBU – AMINATU PAPAPA.

MO KÁBÀÁMỌ̀ PÉ MO ṢE ÌPOLONGO ÌBÒ FÚN TINUBU – AMINATU PAPAPA.

Recommended

ILÉ ÌWÉ GÍGA USMAN DAN FODIYO FI ỌWỌ́ ÒSÌ JÚWE ILÉ FÚN ÀWỌN OLÙKỌ́ MẸ́TA.

ILÉ ÌWÉ GÍGA USMAN DAN FODIYO FI ỌWỌ́ ÒSÌ JÚWE ILÉ FÚN ÀWỌN OLÙKỌ́ MẸ́TA.

1 year ago
Ìròyìn Jákèjádò.

Ìròyìn Jákèjádò.

1 year ago

Popular News

  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ TI MÚ IKỌ̀ ONE-CHANCE NÍ IDIMU, ÈKÓ.

    Ọwọ́ tẹ ikọ̀ one-chance ní kebbi.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • OLÓLÙFẸ́ DA ÁSÍÌDÌ SÍ ỌMỌṢẸ́ Ọ̀RẸ́BÌNRIN RẸ̀ LÁRA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ILÉ ẸJỌ́ PÀṢẸ KÍ GBOGBO DÚKÌÁ SYLVA Ó DI TI ÌJỌBA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • AYÉ LÓ ṢE ỌLỌ́PÀÁ TÓ YÌNBỌN PA ÈÈYÀN.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ ṢE ÀWÁRÍ AYÉDÈRÚ ILÉ ỌMỌ ALÁÌNÍYÀÁ.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0

Connect with us

ADVERTISEMENT

Newsletter

Lorem ipsum dolor sit amet, consectetuer adipiscing elit. Aenean commodo ligula eget dolor.
SUBSCRIBE

Category

Site Links

  • Register
  • Log in
  • Entries feed
  • Comments feed
  • WordPress.org

About Us

We bring you the best Premium WordPress Themes that perfect for news, magazine, personal blog, etc. Check our landing page for details.

  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
  • Àṣà Yorùbá
  • Ìgbé-Ayé
  • Ìdánilárayá
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

Welcome Back!

Login to your account below

Forgotten Password? Sign Up

Create New Account!

Fill the forms below to register

All fields are required. Log In

Retrieve your password

Please enter your username or email address to reset your password.

Log In
No Result
View All Result
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

This website uses cookies. By continuing to use this website you are giving consent to cookies being used. Visit our Privacy and Cookie Policy.