Lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́ àti ọ̀sẹ̀ tó kún fún rògbòdìyàn àti ẹ̀șíkanrín wàhálà òṣèlú ní ilé ìgbìmọ̀ Așòfin Èkó, àwọn àgbààgbà àti àwọn aṣáájú ẹgbẹ́ òṣèlú APC ti pòbìrìkòtò lórí ọ̀rọ̀ náà, wọ́n sì ti fẹnu kò lórí kókó mẹ́rin tí ó ṣe gbòógì :
Ọbasá ti lọ pátápátá, éégún rẹ̀ ò tún sẹ́ mọ́ nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin gege bí Abẹnugan ilé. Àti pé ìyọnípò rẹ̀ ni yóò gbé àwọ̀n mìíràn wọ̀, tí wọn yóò yí sí ìkọ̀wé-fipò-sílẹ̀ fún un.
Meranda tó jẹ́ Abẹnugan tí wọ́n yàn dípò Ọbasá yóò lọ rọ ọ́ kún, kí ipò agbára ní Ìpínlẹ̀ Èkó lè wà ní dọ́gbañdọ́gba.
Abẹnugan titun láti Ìwọ̀ Oòrùn Èkó tí í ṣe agbègbè tó pọ̀ jù yóò gba ipò lọ́wọ́ Meranda.
Kì í ṣe pé Ààrẹ wà lẹ́hìn abẹnugan tó kúrò níbẹ̀, àmọ́ bí wọ́n ṣe fojú Ọbasá gbolẹ̀ lórí Ọ̀nà tí wọ́n gbà yẹ àga mọ́ ọn nídìí ni Ààrẹ gbójú agan sí.
Ìròyìn fi tóni létí pé Ààrẹ Tinubu ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn èèkàn kànkànràn ní ìlú Èkó lórí ọ̀rọ̀ náà, tí gbogbo wọn sì sọ ewu tó wà nínú ọ̀rọ̀ yìí tọ́wọ́ ò bá le ká a mọ́. Nínú àwọn àgbààgbà òṣèlú APC tó wà nípàdé náà ni a ti rí Olóyè Bísí Akande; Olúṣẹ́gun Ọ̀șọbà; Délé Aláké àti àwọn mìíràn bẹ́ẹ̀.
Inú ìpàdé yìí ni wón ti fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé omi kì í ṣàn kó bojú wẹ̀yìn, pé Ọbasá ò tún lè padà wá mọ́ sórí ìjókòó Abẹnugan ilé. Èyí wà bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àgbékalè òfin ilé ìgbìmọ̀ Așòfin. Gbogbo àwọn ọmẹẹgbẹ́ tó ní àǹfààní láti sọ̀rọ̀ ni wọ́n fẹ̀hónú wọn hàn lórí itu burúkú tí Ọbasá ń pa nígbà tí kùkùudà wà lọ́wọ́ rẹ̀ nígbà náà.
Gbogbo rògbòdìyàn yìí bẹ̀rẹ̀ ní òpin ọdún tó kọjá nígbà tí wọ́n yọ Mudashiru Obasa ní ipò agbẹnusọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Èkó tí wọ́n sì fi ìgbákejì rẹ̀; arábìnrin Meranda sí ipò agbẹnusọ náà.
Láti ìgbà náà ni ọ̀rọ̀ ti di ègbìnrìn ọ̀tẹ̀ tó ṣe pé bí wọ́n ṣe ń pàkan ni ọ̀kan ń rú. Ọ̀rọ̀ wá dàbí ti adìyẹ tó bà lé okùn, ara ò rọ Obasa tí wọ́n yọ, ara ò rọ àwọn tó yọ ọ́ nípò náà.
Lára àwọn rògbòdìyàn tó dá sílẹ̀ ni ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó; Babajide Sanwoolu pé ó kó owó rọ̀gùnrọ́gùn nínú àkàṣù owó ìjọba Èkó fún iná ọba tí kò lábọ̀.
Ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni mẹ́fà ni Ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Èkó gbé dìde láti wádìí àwọn owó kan tí Gómìnà Sanwoolu fi ṣe akanṣe iṣẹ́ iná ọba.
Ẹni tí kò bá ní ẹ́fídẹ́ńsì, àlàyé rẹ̀ yóò pọ̀ gan-an ni, Gómìnà Babajide Sanwoolu gbọdọ̀ ní àwọn ẹ́fídẹ́ńsì rẹpẹtẹ nítorí pé ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Èkó ti gbé ìgbìmọ̀ ẹlẹ́ni mẹ́fà dìde nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin Èkó láti ṣèwádìí owó rọ̀gùn-rọ́gún tí Sanwó-olú tí í ṣe gómìnà Ìpínlẹ̀ Èkó ná lórí àkànṣe iṣẹ́ iná.
Àkànṣe iṣẹ́ iná náà tó wà ní abẹ́ ìdarí ilé-iṣẹ́ Agbára àti Àlùmọ́nì ilẹ̀ ní in lọ́kàn láti pèsè agbára iná tó ṣeé simi lé fáwọn olùgbé ìpínlẹ̀ Èkó.
Níbi ìjókòó àwọn aṣòfin m tó kọjá, olórí-ilé tí í ṣe Mojísọ́lá Meranda, yan àwọn ọmọ ìgbìmọ̀ kan èyí tí Abíọ́dún Tobun, Desmond Elliot, Stephen Ògúndipẹ̀, Abíọ́dún Ọ̀rẹ́kọ̀yà, Fẹ́mi Saheed àti Sabur wà lára wọn.
Meranda tẹnu mọ́ ọn bó ṣe ṣe pàtàkì láti lo àgbájọ ọwọ́ fún pípèsè ìmọ́lẹ̀ fún Èkó ; ó sì sọ bí iṣẹ̀ náà ṣe jẹ́ pàtàkì sí. Ó tún sọ ọ́ nínú ìjíròrò náà bí àwọn ṣe gbọ́dọ̀ pèsè iná ìgboro fún àwọn olùgbé Èkó, èyí yóò mú ààbò tó péye àti ìdáàbò bò ẹ̀mí àti dúkìá jákè-jádò ipinle Èkó.
“ Èyí nìkan ni ọ̀nà tá a fi lè yanjú ìṣòro àìsí ààbò ; nígbà tí gbogbo àyíká bá mọ́lẹ̀ rokoso, a ó lè dá ẹni tó ń bọ̀ mọ̀; a ó mọ̀ bóyá elewu ènìyàn ni àbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Èyí ni àfojúsùn Èròǹgbà wa lórí àkànṣe iṣẹ́ náà”
Ó tún sọ ọ́ síwájú sí i pé “ ó yẹ kí a la àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ lọ́yẹ̀ pé iná ìgboro gbọ́dọ̀ jẹ́ ara àkànṣe iṣẹ́ tá a bá gbé fún agbaṣẹ́ṣe lórí ọ̀nà.
Lákòótán, ó rọ ìpínlè àti ìjọba ìbílẹ̀ láti fi kún ìsapá wọn fún àbójútó ọlọ́kan-ò-jọ̀kan.
Bí a bá fi owó ra òòyì, ó ṣáà yẹ kó kọ́ni lójú, àìrí iná ọba lò déédéé ní ìpínlẹ̀ Èkó lẹ́yìn owó ribiribi tí Gómìnà ná lé orí rẹ̀ ni ìgbìmọ̀ yìí fẹ́ ṣe ìwádìí rẹ̀.
Gbogbo bí èyí ṣe ń lọ lábẹ́lẹ̀ ni Obasa náà ń ké tantan pé òun ṣì ni agbẹnusọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin Èkó o pé àwàdà lásán ni gbogbo ọ̀tẹ̀ tí wọ́n dì mọ́ òun.
Ó ṣe àlàyé pé lábẹ́ òfin, dandan ni kí òun ó wà lórí ìjokòó bí wọ́n bá fẹ́ yọ òun nípò àbí ojú àwo ṣá ni àwo fi ń gba ọbẹ̀, ẹnìkan kìí sì fárí lẹ́yìn olórí, ó ṣe jẹ́ ìgbà tí òun lọ ìrìn àjò ni wọ́n yọ òun? Kò le ṣe é ṣe o.
Àlàyé rẹ̀ tẹ̀síwájú pé àwọn ẹ̀sùn tí ilé aṣòfin fi kan òun kò fẹsẹ̀ múlẹ̀ rárá, òfûtùfẹ́tẹ̀ ásà tí ò ní káún nínú ni. Wọ́n ní òun fi bílíọ̀nù mérìndínlógún ṣe géètì, Obasa wí pé ṣé géètì Jẹ́ríkò ni géètì náà ni?
Wọ́n tún ní òun fi ogójì bílíọ̀nù ra ọkọ̀ bọ̀gìnnì, Obasa wí pé kí ẹ má dá wọn lóhùn o, àwáwí ni wọ́n ń wá kiri.
Àgbà kò ní wà lọ́jà kí orí ọmọ titun ó wọ́, àwọn àgbààgbà ilé ti ṣe ìpàdé pẹ̀lú ààrẹ Bola Ahmed Tinubu, wọ́n fẹnu kò síbi pé odò kìí ṣàn kó bojú wẹ̀yìn, ìgbà Obasa gẹ́gẹ́ bí agbẹnusọ ti dópin nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin Èkó. Bákan náà ni wọ́n yọ Meranda ní ipò náà, ní báyìí, wọn yóò ṣẹ̀ṣẹ̀ yan agbẹnusọ titun ni.