Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá Abuja ti fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé àwọn afurasí mọ́kàndínlógún ló ti wà ní àhámọ́ àwọn lórí ìkọlù tó wáyé ní Abuja níbi tí wọ́n ti pa ọmọ ogun ilẹ̀ wa kan tí wọ́n sì tún ṣe àwọn méjì mìíràn léṣe.
Agbègbè ilé ìtajà Banex tó wà ní Wuse 2, Abuja ni ìwọ́de náà ti fẹjú toto ní nǹkan bíi aago méjì àbọ̀ ọ̀san ń lọ lù. Ohun tí wọ́n ń ṣe ìwọ́de lé lórí náà ni ogun tó ń ṣẹlẹ̀ láàrin ilẹ̀ Palestine níbi tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀mí ti ṣòfò pàápàá ní Gaza.
Ọ̀rọ̀ yìí jé mímọ̀ láti ẹnu agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá Abuja; Josephine Adeh pé àwọn ẹgbẹ́ ẹlẹ́sìn Mùsùlùmí Shi’ites ṣe ìwọ́de ní agbègbè Wuse ní Abuja, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni àwọn ọlógun àti àwọn ọlọ́pàá ti gbéra lọ sí ibẹ̀ láti ríi dájú pé kò mú rògbòdìyàn dání.
Kín ni wọ́n fojú gánní àwọn agbófinró sí ni? Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní lẹ̀ wọ́n lókò, onírúuurú àwọn ohun ìjà olóró bíi àdá, òkuta, àdó olóró kéékèèkèé, ọfà, igi àti awọn ohun ìjà olóró mìíràn ni àwọn olùwọ́de náà kó dání.
Wọ́n ṣe ìkọlù sí àwọn ológun ilẹ̀ wa, mẹ́ta nínú wọn ni wọ́n ṣe yánkanyànkan, ilé ìwòsàn ni ọ̀kan dákẹ́ sí nígbà tí àwọn méjì yòókù ṣì ń gba ìtọ́jú.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ti fìdí ẹ̀ múlẹ̀ báyìí pé àwọn mọ́kàndínlógún ni ọwọ́ ti tẹ̀ báyìí, ìwádìí sì ti bẹ̀rẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Bí ìròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀ ṣe lọ rèé:
Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Mùsùlùmí kan tí a mọ̀ sí Shi’ites ni wọ́n wà á kò pẹ̀lú àwọn ọmọ ológun ilẹ̀ yìí ní àkókò tí wọ́n ń ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn tako ìwà aitọ́ tí àwọn ọmọ ilẹ̀ Palestine kojú látọwọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní agbègbè Gaza.
Nínú fọ́nrán tó lùgboro pa ni a ti rí ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Shi’ites yìí ní àdúgbò ilé ìtajà Banex, Adémọ́lá Adétòkunbọ̀, Wuse 2 ní Abuja tíí ṣe olú ìlú wa tí wọ́n ń fi ẹ̀hónú hàn lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní Gaza.
Rògbòdìyàn ìlú Abuja wáyé ní kété tí ilé-iṣẹ́ aṣojú ìjọba ilẹ̀ Amẹ́ríkà ní Nigeria ṣèkìlọ̀ fáwọn èèyàn rẹ̀ pé ojú ni kí alákàn wọn fi máa ṣọ́ orí o; kí wọ́n sì fetí léde nípa ìwọ́de táwọn ẹgbẹ́ ẹlẹ́sìn náà ń gbèrò láti ṣe nílùú Abuja àti àwọn ìlú ńlá mìíràn nílẹ̀ Nàìjíríà. Ìkìlọ̀ ìfura aláàbò náà dárúkọ àwọn ìlú bíi Banex plaza, oríta Berger, Unity Fountain àwọn mìíràn bẹ́ẹ̀bẹ́ẹ̀ tí ó ṣeé ṣe kí ìwọ́de náà napá-nàyẹ́ dé. Ogun àwítẹ́lẹ̀ ni o, tí kì í pa arọ tó bá gbọ́n.
Wàhálà náà kúrò ní ohun tí a pè é nígbà tí àwọn olùwọ́de fojú gán-ánní àwọn agbófinró, tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ òkò àti nǹkan olóró gbogbo lu àwọn agbófinró náà tí wọ́n fẹ́ láti pèsè ààbò. Àfi bí ìgbà tí iná àti ẹ̀tù bá pàdé ni, àwọn agbófinró náà ò bèṣù-bẹ̀gbà táwọn náà fi dáhùn pẹ̀lú ìró ìbọn. Bẹ́ẹ̀ ni ìró ìbọ́n ń dún kẹ̀ù-kẹ̀kẹ̀ù-kẹ̀ù bí ti ogun kírìjí ìgbà náà. Kí wón tóó ṣẹ́jú pẹ́ẹ́, àwọn bíi márùn-ún ti ń pọ̀kà ikú, tí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn mìíràn ti fara pa yánnayànna.
Nígbà tí ẹgbẹ́ Shi’ites ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn lórí ogun tó ń ṣẹlẹ̀ ní ìlú mìíràn, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ìpínlẹ̀ ̀ǹdó fara ya lórí bí ètò ààbò ṣe mẹ́hẹ ní ìpínlẹ̀ náà.
Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni pé ìfẹ̀honú ńlá kan ti bẹ́ sílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Oǹdó látọ̀dọ̀ àwọn Ẹgbẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ ilẹ̀ yìí ( NANS) ẹka ìpínlẹ̀ Oǹdó.
Ìfẹ̀honú-hàn àti ìwọ́de náà wáyé ní ìlú Àkúré tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Òǹdó níbi tí ogụ́nlọ́gọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti fọ́n dà sí ojú pópó pẹ̀lú ọ̀kẹ́ àìmọye onírúurú àwọn àkọlé lọ́wọ́.
Ohun tó sì mú ú láyà wọn, tí gbogbo wọ́n ń tẹnu mọ́ náà ni àìsí ètò ààbò tó nípọn ní ìpínlẹ̀ náà. Nínú fọ́nrán tó gba orí afẹ́fẹ́ kan náà ni a ti rí àwọn afẹ́hónú-hàn tí wọ́n fọ́n ká ojú pópó, tí wọ́n sì ń fi àìdùnnú àti ẹ̀dùn ọkàn wọn hàn lórí bí ìwà ọ̀daràn ṣe lu ìgboro àwọn ìlú àti ìletò tó wà ní ìpínlẹ̀ Oǹdó pa. Èyí tó sì ṣe wọ́n ní kàyéfì ni àìrí nǹkan ṣe sí i látọ̀dọ̀ ìjọba láti pinwọ́ rẹ̀.
Èyí lápá kan, ká tún fẹsẹ̀ kan dé ìpínlẹ̀ Plateau níbi tí àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP náà ti ṣe tiwọn.
Ohun tí a gbọ́ ni pé ìjọba ìbílẹ̀ Wase ní ìpínlẹ̀ Plateau gbóná janjan nígbà tí àwọn alátìlẹyìn ẹgbẹ́ òṣèlú PDP dáná sun pátákó ìpolongo ẹgbẹ́ náà àti ohun ètò sọ̀lú-dẹ̀rọ̀ tí wọ́n gbé fún wọn ní iná.
Kókó ohun tí wọ́n ń jà fún ni ohun tí wọ́n pè ní “gbà – jẹ́-ń-simi ètò sọ̀lú-dẹ̀rọ̀ tí wọ́n ṣe fún wọn ní àkókò ààwẹ̀ Ramadan yìí.
Àwọn ọmẹẹgbẹ́ tó ń wọ́de fi igbe àtariwo “ a ò fẹ́, gbé sọ̀lú-dẹ̀rọ̀ yín lọ sílé alága.” A rí i tí wọ́n tú sójú pópó, tí wọ́n ń dáná sun ìwé ìpolongo ìbò, pátákó ìpolongo ìbò àti oúnjẹ sọ̀lú-dẹ̀rọ̀ tí wọ́n pin fún wọn. Gbogbo wọn ni iná ń sọ kẹ̀ù lára wọn lójú pópó ibi tí wọ́n dáná sun wón sí.
Kóńgò ráìsì méji àti agolo kan ni Dsyyabu Ibrahim sọ wí pé wọ́n fún gbogbo àwọn tó wà lẹ́kùn ìdìbò Ja’oji. Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n ṣe pín in fún àwọn ará ẹkùn ìdìbò Runji. “Kín ni ká fi ṣe?” ni ìbéèrè tó ń jáde lẹ́nu wọn.
Rògbòdìyàn lọ́tùn-ún, wàhálà lósì, ìlú kò fara rọ àfi kí Elédùmarè ó ṣàánú.
Discussion about this post