Gómìnà ìpínlẹ̀ Osun ìjẹta; ọ̀gbẹ́ni Rauf Aregbesola ṣe ìpàdé ìkọ̀kọ̀ pẹ̀lú Olùdásílẹ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú New Nigeria People’s party; Rabiu Musa Kwankwaso.
Ohun tí wọ́n jọ sọ níbi ìpàdé náà kò hàn síta, àwọn èèyàn fura pé bóyá Aregbesola fẹ́ dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú New Nigeria ni.
Ilé Aregbesola tó wà ní Èkó ni ìpàdé náà ti wáyé, wọn kò gba oníròyìn láàyè nílé náà.
Ẹnìkan nínú ẹgbẹ́ òṣèlú New Nigeria ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Osun wí pé ọ̀rọ̀ òṣèlú àti ìdàgbàsókè náà ni wọ́n jọ sọ.
Ohun tó fàá tí àwọn èèyàn fi ń lẹtí mọ́ ìgànná lórí ìpàdé náà ni pé Aregbesola ti kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú APC, àwọn ikọ̀ rẹ̀ náà bíi Ọmọlúàbí Progressive group ti yapa kúrò lára ẹgbẹ́ òṣèlú APC. Àwọn èèyàn fẹ́ mọ ohun tí ó fẹ́ ṣe báyìí.
Ohun tí ó fàá tí Aregbesola fi kúrò nínú ẹgbẹ́ òṣèlú náà gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ sẹ́yìn ni ìdúkokòmọ́ni, ìjẹgàba àti ìfìyàjẹni tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ẹgbẹ́ náà.
Alága ẹgbẹ́ òṣèlú New Nigeria ẹ̀ka ìpínlẹ̀ Osun; Dọ́kítà Tosin Odeyemi fún àwọn akọ̀rọ̀yìn ní àwọn àwòrán ìpàdé náà níbi tí Aregbesola àti Kwankwaso ti jókòó pọ̀. Odeyemi wí pé kí Nàìjíría ó le dára náà ni wọ́n sọ̀rọ̀ lé lórí.