Arábìnrin Kemi Akinbobola ti kú pẹ̀lú oyún nínú látàrí pé kò ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta náírà owó àsan-án-lẹ̀ tí ilé ìwòsàn bèèrè fún.
Ọjọ́ burúkú èṣù gbomi mu ni ọjọ́ náà jẹ́ fún ìdílé Akinbobola nígbà tí Kemi ń rọbí, ipò rẹ̀ burú díẹ̀ ó sì nílò ìtọ́jú pàjáwìrí àmọ́ ilé ìwòsàn aládàáni kan tí wọ́n gbé e lọ kọ̀ láti tọ́jú rẹ̀ nítorí pé ọkọ rẹ̀; Folajimi Akinbobola kò ní owó àkọ́san ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta náírà tí wọ́n ní kó san.
Dọ́kítà ilé ìwòsàn náà wí pé kí wọn ó máa gbé Kemi lọ sí ilé ìwòsàn ìjọba tó wà ní Epe láti Lekki, Kemi kò dé Epe tó fi dákẹ́.
Ọkọ rẹ̀ ló ká fọ́nrán bí Kemi ṣe wà nínú ìrora tó sì ń rọ́ ọ lójú. Folajimi fi ẹ̀sùn kan ilé ìwòsàn yìí pé àwọn ló ṣekú pa ìyàwó rẹ̀ nítorí pé wọ́n kọ̀ láti tọ́jú rẹ̀ nítorí owó.
Ilé ìwòsàn As Salam Convalescent tó wà ní Iwerekun, Ibeju-Lekki ní ìpínlẹ̀ Èkó náà fèsì sí ẹ̀sùn tí Akinbobola Folajimi fi kàn wọ́n lórí ìyàwó rẹ̀ tó kú.
Ẹ̀sùn tí Folajimi fi kan ilé ìwòsàn As Salam ni pé wọ́n kọ̀ láti tọ́jú ìyàwó rẹ̀; Kemi nígbà tí ó ń rọbí, ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta náírà ni Folajimi ní wọ́n bèèrè fún kí wọ́n tó tọ́jú rẹ̀, ojú ọ̀nà ilé ìwòsàn ìjọba Epe ni Kemi dákẹ́ sí.
Ẹni tó ni ilé ìwòsàn náà gangan; Ọ̀gbẹ́ni Rauf Salami ló bá àwọn akọ̀ròyìin sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà láàárọ̀ àná. Àlàyé tí Ọ̀gbẹ́ni Rauf ṣe tako ohun tí a gbọ́ láti ẹnu Akinbobola. Àlàyé náà lọ báyìí pé;
‘Lóòótọ́ ni wọ́n gbé Kemi wá sílé ìwòsàn wa lọ́jọ́ náà. Ipò tó wà burú jáì tó fi jẹ́ pé a kò le gbà á sọ́dọ̀ nítorí pé ó nílò kí ó gba ẹ̀jẹ̀ kó sì tún ṣe iṣẹ́ abẹ. A kò ní àwọn irin iṣẹ́ tí a le fi kojú irú ipò báyìí ni a fi ní kí ọkọ rẹ̀ ó máa gbé e lọ sí ilé ìwòsàn ìjọba Epe níbi tí wọn yóò ti le ṣe ìtọ́jú rẹ̀.
Gbogbo ohun tí wọ́n lò ní ọ̀dọ wa kò tó ìṣẹ́jú mẹ́rin, a kò tilẹ̀ gbé e sọ̀ kalẹ̀ gan-an lórí kẹ̀kẹ́ tí wọ́n fi gbé e wá tí a fi ní kí wọ́n máa lọ sí Epe. Bí ba bá ní ká fún lómi, ó le kú sí ọ̀dọ wa nítorí pé kò sí ẹ̀jẹ̀ kankan lára rẹ̀ mọ́, bẹ́ẹ̀ sì ni ẹ̀jẹ̀ kìí ṣẹ ohun tí a le rí lórí igbá bẹ́ẹ̀ yẹn, ìlànà wà tí a gbọdọ̀ tẹ̀lé.
ó ṣe pàtàkì láti fi kún un pé Kemi kò gba ìtọ́jú lọ́dọ̀ wa rí, ìgbà àkọ́kọ́ tí a ó ríi náà nìyẹn, a kò mọ nǹkan kan nípa ìlera rẹ̀ ṣaájú ọjọ́ náà ní èyí tí kò le jẹ́ kí a mọ bí a ṣe le tọ́jú rẹ̀ yàtọ̀ sí pé kò sí ẹ̀jẹ́ lára rẹ̀ mọ́. Mi ò lérò pé Kemi gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn kankan nínú oyún náà nítorí pé kò sí àpẹẹrẹ pé ó gba ìtọ́jú aláboyún àti pé kò bá má burú tó bẹ́ẹ̀ yẹn bí ó bá ṣe pé àwọn ìtọ́jú kan ti wà lára rẹ̀ tẹ́lẹ̀.
Lórí ẹ̀sùn owó tí Folajimi ọkọ rẹ̀ fi kàn wá, irọ́ pátápátá ni, a kò tilẹ̀ sọ nǹkan kan nípa owó rárá, mi ò bá ní kí n fi ọlọ́pàá gbé e àmọ́ ó ṣẹ̀ṣẹ̀ pàdánù ìyàwò rẹ̀ ni àti pé Mùsùlùmí ni mí, mo fi gbogbo rẹ̀ lé Ọlọ́run lọ́wọ́’
Ẹ̀yin èèyàn wa, àlàyé tí Ọ̀gbẹ́ni Rauf ṣe rèé o, ó wí pé àwọn tí wọ́n ń lo ilé ìwòsàn náà déédéé le jẹ́ríì sí bí àwọn ṣe máa ń ṣe ìtọ́jú wọn tó.
Ta ni ká gbàgbọ́ nínú ẹni tó ni ilé ìwòsàn àti ẹni tó fi ẹ̀sùn àìbìkítà kan ilé ìwòsàn?
Ìròyìn mìíràn tó tún ń jà ràìnràìn lórí ìtàkùn ayélujára ni ti ìdájọ́ tí ilé ẹjọ́ gbé kalẹ̀ lórí aáwọ̀ tó wà láàrin Natasha àti Akpabio.
Ohun tí a gbọ́ ni pé Ilé ẹjọ́ gíga tó fìkàlẹ̀ sí Abuja ti pàṣẹ lónìí fún ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà nnì; Natasha àti olórí ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin àgbà ilẹ̀ yìí; Goodwill Akpabio pé wọn kò tún gbọdọ̀ bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ mọ́ lórí aáwọ̀ àárín wọn.
Akpabio ló pe ẹjọ́ tako Natasha, Ó fi ẹsùn kan Natasha pé níṣe ló ń kà bòròbòrò kiri lórí àwọn ìkànnì ayélujára àti àwọn ilé iṣẹ́ amóhùnmáwòrán nípa ẹjọ́ wọn tó ṣì wà nílé ẹjọ́.
Adájọ́ Binta Fatimo Nyako ti ilé ẹjọ́ gíga Abuja ti pàṣẹ báyìí pé àwọn méjéèjì kò tún gbọdọ̀ wí nǹkan kan síta lórí ìgbẹ́jọ́ tó ń lọ lọ́wọ́ náà. Bákan náà ló pàṣẹ pé àwọn agbẹjọ́rò wọn kò tún gbọdọ̀ fi nǹkan kan léde nípa ẹjọ́ náà mọ́.
Ṣaájú ìgbẹ́jọ́ òní ni Natasha ti sọ pé òun ní àwọn fọ́nrán ìbálòpọ̀ Akpabio lọ́wọ́ pé òun yóò fi léde, bóyá yóò sì tún fi léde lẹ́yìn ìdájọ́ yìí, a kò le sọ.
Gbogbo aáwọ̀ yìí bẹ̀rẹ̀ nígbà tí Natasha fi ẹ̀sùn kan Akpabio pé ó fẹ́ máa bá òun lò pọ̀. Lẹ́yìn náà ni Akpabio dá a dúró fún oṣù mẹ́fà gbáko nílé ìgbìmọ̀ asòfin, ó pàṣẹ kí owó oṣù rẹ̀ ó dúró ó sì tún kó àwọn ẹ̀ṣọ́ kúrò lẹ́yìn rẹ̀.
Gbogbo èyí ni Natasha torí ẹ̀ gbé Akpabio lọ sí ilé ẹjọ́, ó fi ẹ̀sùn kàn án pé ìyà àìtọ́ ló fi jẹ òun nítorí pé òun kọ̀ láti bá a lò pọ̀.
Discussion about this post