ÀKÀGBÁDÙN……. :
IJÓ ÒJÓ..
Iná ń jó ilé Òjó,
Òjó ń jó níbi tílé ti ń jó,
Iná ń jó ilé,
Ilé ń jóná,
Òjó ń jó bíi kòkòrò,
Ayé Òjó ń jò pòròpòrò,
Òjó ń jó bí òrèbé.
Òjó ò ṣojo nítorí ilé tó ń jó,
Bàbá Òjó ń ṣojo
Ìyá Òjó ń ṣòjòjò.
Ilé ń jó,
Òjó ń jó bí ìgunnu,
Ará àdúgbò ń jòwèrè
Nítorí Òjó tó ń jó.
Ijó lÒjó ń jó,
Òjó ò jò dànù lórí ijó,
Òjò ń pa ilé tó ń jó,
Òjó ń jó,
Ilé ń jó,
Òjó ń rọ̀.
Ilé tó ń jó tÓjòó ń jó,
LÓ di ohun àrà létí ọba.
Ọbá dá Òjó Lọ́lá,,
Nítorí Òjó tí ò ṣojo,
Kábíèsí fÒjó joyè,
Nítori Òjó tí ò ṣòjòjò.
Ọjọ́ lọjọ́ náà,
TÓjòó ò ṣojo,
TÓjòó ò ṣòjòjò,
Ijó Òjó gbayì,
Òjó náà jó gbẹ̀yẹẹ !