Àjò kò ní dùn títí kónílé má relé. Ìjọba CANADA júwe ilé fún ìdílé Akinlade
Ìdílé Lola Akinlade ni ìjọba orílẹ̀-èdè CANADA ti wí fún pé kí wọn ó kúrò ní ilẹ̀ CANADA padà sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà lórí ẹ̀sùn pé ayédèrú ni ìwé igbaniwọlé rẹ̀.
Arábìnrin Lola jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè wa Nàìjíríà tí ó sì jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́jáde ilé ìwé gíga fáfitì. Ìmọ̀ ìṣègùn òyìnbó ni ó kọ́ tí ó sì lọ tẹ̀ síwájú lókè òkun.
Ilé ìwé gíga Regina tó wà ní CANADA ni abániṣọ́nà rẹ̀; Babatunde Adegoke báa ṣètò ìwé kíkà rẹ̀ sí. Lola gbéra kúrò ní nàìjíría ní oṣù Kejìlá ọdún 2016 pẹ̀lú èrò àti bẹ̀rẹ̀ ilé ìwé ní oṣù kìíní ọdún 2017. Ó wí pé Adegoke ṣe àlàyé nígbà tí òun dé CANADA tán pé kò sí ààyè ní ilé ìwé Regina lásìkò náà kí òun ó dúró de ìgbà tí ààyè yóò wà tàbí wá ilé ìwé mìíràn.
Oṣù kẹsàn-án ọdún 2017 ni wọ́n gbàá sí ilé ìwé gíga Nova Scotia. Ọkọ ati ọmọ rẹ̀ sì lọ dara pọ̀ mọ́ ọn lọ́hùn-ún. Lẹ́yìn náà ló bí ọmọkùnrin kan ní ọdún 2021
Ǹjẹ́ kó tún tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ lẹ́yìn tó jáde ní Nova Scotia tán ní ọdún 2023, ibi tí wọ́n ti ń yẹ àwọn ìwé rẹ̀ wò ni wọ́n ti ríi pé ìwé igbaniwọlé sí ilé ìwé Regina tí wọ́n torí rẹ̀ fún un ní ìwé ìgbélùú kìí ṣe ojúlówó. Ìjọba CANADA yẹ àwọn ìwé náà wò wọ́n sì fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé ayédèrú ni ìwé náà. Ní báyìí, wọ́n ti wí fún arábìnrin Lola àti ìdílé rẹ̀ pé kí wọn ó kúrò ní ìlú wọn. Ọmọ rẹ̀ Kejì tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè CANADA kò ní anfààní sí ètò ìlera mọ́ nítorí ọ̀rọ̀ náà
Arábìnrin Lola ti wá ké gbàjarè sí ìjọba ilẹ̀ yìí àti ti CANADA pé kí wọn ó bá òun yanjú rẹ̀ nítorí òun kò mọ̀ rárá pé ayédèrú ni ìwé tí wọ́n ṣe fún òun.
#iweiroyinyoruba #news #canada #deportation #fakedocuments