Àjọ àwọn agbẹjọ́rò àti adájọ́ ilẹ̀ yìí NBA ti dá sí ọ̀rọ̀ tó ń jà ràìràìn lórí ìkànnì ayélujára nípa ẹ̀sùn tí àwọn òṣìṣẹ́ Patience Johnathan fi kàn án.
Àjọ NBA wí pé àwọn ti kàn sí Patience Johnathan, àwọn agbẹjọ́rò àti àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ọgbà ẹ̀wọ̀n lórí ọ̀rọ̀ náà. Àgbà àjọ NBA kan tí kò fẹ́ kí a dárúkọ rẹ̀ wí pé àwọn ti kàn sí Patience Johnathan, àwọn agbẹjọ́rò rẹ̀ àti ọ̀gá ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Bayelsa lórí bí ọ̀rọ̀ náà yóò ṣe yanjú ní kíákíá nítorí pé ó ti ń pe àkìyésí àwọn èèyàn láì nídìí.
Ó wí pé ọ̀gá ọlọ́pàá ti wí pé òun yóò gbé ọ̀rọ̀ náà yẹ̀wò, alága àjọ NBA náà sì ti wí pé òun yóò sa ipá òun lórí rẹ̀.
Bákan náà ló wí pé àwọn tí wọ́n fi ẹ̀sùn kàn náà ló ń dá ìgbẹ́jọ́ náà dúró, ó wí pé agbẹjọ́rò ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n lò ní èyí tó mú kí ẹjọ́ ó gùn sí, ọ̀kan nínú wọn tún bímọ ní èyí tó fa ìdádúró.
Olórí ẹ̀sọ́ aláàbò ọgbà ẹwọ̀n ṣe ìkìlọ̀
Ohun tí a gbọ́ ni pé ní òwúrọ̀ kùtù òní, olórí ẹ̀ṣọ́ aláàbò Okaka níbi tí àwọn èèyàn náà wà pè wọ́n jọ ó sì ṣe ìkìlọ̀ fún wọn. Ó wí pé wọn kò tún gbọdọ̀ bá àwọn oníròyin sọ̀rọ̀ mọ́. Ó ní òun kàá pé òun máa ń kó wọn lọ bá Patience Johnathan, ó ní òun kò rí Patience Johnathan sójú kòró rí o. Bákan náà ló wí pé àwọn kò já wọn léèkánná rí láti ìgbà tí wọ́n ti wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n náà.
Ohun tí ọ̀kan nínú wọn tún padà sọ fún wa láàárọ̀ yìí kan náà lòdì sí ohun tí àwọn èèyàn wọ̀nyìí sọ, ó ní irọ́ ni olórí ẹ̀ṣọ́ aláàbò náà pa pé àlùbami ni wọ́n ń lu àwọn. Bákan náà ló wí pé àkàndá ni obìnrin tó lóyún náà ni wọ́n ṣe gba onídùúró rẹ̀ pé kìí ṣe òun ló dá ìgbẹ́jọ́ náà dúró.
Bákan náà ló wí pé ẹbí Patience Johnathan tó wà nílé lọ́jọ́ náà tí wọ́n jọ kó àwọn ni wọ́n ti fi sílẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àwọn ọlọ́pàá tó ń ṣọ́ ilé náà tí wọ́n kọ́kọ́ kó ni wọ́n ti fi sílẹ̀, àwọn òṣìṣẹ́ nìkan ni wọ́n ń fìyà jẹ.
Ní báyìí, àjọ NBA ti wí pé àwọn yóò ríi pé ọ̀rọ̀ náà yanjú láì figbá kan bọ̀kan.
Èyí ni èsì tí àjọ NBA fọ̀ lórí ẹ̀sùn tí àwọn òṣìṣẹ́ Patience Johnathan fi kàn án. A mú ìròyìn náà wá pé:
‘Àwọn òṣìṣẹ́ tí aya ààrẹ orílẹ̀-èdè wa tẹ́lẹ̀rí; Patience Johnathan fi ẹ̀sùn olè kàn ti rí òbìrí ayé ní ọgbà ẹ̀wọ̀n tí wọ́n dà wọ́n sí láti ọdún 2019. Bí wọ́n ṣe ń fi ojú wọn rí màbo lu sí àwọn akọ̀ròyìn lọ́wọ́, wọ́n bá àwọn ẹbí wọn sọ̀rọ̀, ilẹ̀ kún.
Ọdún 2019 ni Patience Johnathan fi ẹ̀sùn kan àwọn òṣìṣẹ́ rẹ̀ pé wọ́n jí àwọn ọ̀ṣọ́ òun tí iye rẹ̀ tó igba mílíọ́nù náírà. Gbogbo wọn sì ni àwọn ọlọ́pàá kó sí ọgbà ẹ̀wọ̀n Okaka ní ìpínlẹ̀ Bayelsa lati ìgbà náà láísí ìgbẹ́jọ́ kankan tó wáyé.
Àwọn èèyàn náà ni Williams Alami, Vincent Olabiyi, Ebuka Cosmos, John Dashe, Tamunokuro Abaku, Emmanuel Aginwa, Erema Deborah, Precious Kingsley, Tamunosiki Achese, Sunday Reginald, Vivian Golden, Emeka Benson, Boma Oba, Salomi Wareboka àti Sahabi Lima.
Ẹ̀sùn tí Patience Johnathan fi kàn wọ́n náà ni pé wọ́n jí àwọn ọ̀ṣọ́ méje, ẹ̀rọ amúlétutù márùn-ún, àga ilé méjì àti ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán mẹ́fà tí gbogbo rẹ̀ jẹ́ igba mílíọ́nù náírà. Bákan náà ló tún fi ẹ̀sùn ìpètepèrò láti pa òun àti àwọn ẹ̀sùn ajẹmọ́ ìpànìyàn mìíràn kàn wọ́n.
Òkan nínú àwọn tí ó fẹ̀sùn kàn náà ṣe àlàyé pé ‘Àwọn olè wọ igun kan nínú ilé ààrẹ, àwa òṣìṣẹ́ kìí dé igun ilé yìí nítorí pé iṣẹ́ wa kò dé ibẹ̀. Ìyàwó ààrẹ fi ọlọ́pàá kó gbogbo àwa òṣìṣẹ́, títí di àsìkò yìí, kò tíì sí ẹ̀rí kankan pé àwa la jí àwọn nǹkan náà, ẹ gbà wá kalẹ̀, ìyà yìí pọ̀’.
Òmíràn nínú wọn wí pé ‘Wọ́n máa ń nà wá nínàkunà, wọn yóò so wá kọ́ sókè wọn yóò sì máa lù wá. Ìyàwó ààrẹ yóò máa sọ lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ pé wọn kò nà wá dáadáa. Wọn yóò tún kó wa lọ sí ilé ìtura lọ nà níwájú aya ààrẹ’
Àwọn ẹbí àwọn afurasí.
Ipò ti àwọn oniròyìn bá àwọn ẹbí àwọn èèyàn yìí kò sunwọ̀n, wọ́n ti dààmú lórí ọ̀rọ̀ náà àmọ́ kò sí ọ̀nà àbáyọ kankan. Wọ́n rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ọ̀gá ọlọ́pàá ilẹ̀ yìí láti dá sí ọ̀rọ̀ náà.
Ẹ̀gbọ́n Tamunosiki tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Gladys ṣe àlàyé ipò tí ó máa ń bá àbúrò rẹ̀ bó bá ti lọ wò ó, ó ní ẹkún lòun máa ń sun nítorí pé ìyà ti sọ ọ́ di ìdàkudà. Gladys tẹ̀síwájú pé àwọn òbí àwọn ti lọ bẹ Patience Johnathan àmọ́ kò gba ẹ̀bẹ̀ wọn, láti ìgbà náà ni wọ́n ti ń pààrà Portharcourt sí Bayelsa. Ó wí pé kí wọn ó jẹ́ kí ìgbẹ́jọ́ ó wáyé lórí ẹ̀sùn náà, wọ́n ti lo ọdún mẹ́fà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n láìsí ìgbẹ́jọ́ kankan.
Steve Ibiene; ẹni tó jẹ́ ẹ̀gbọ́n fún Williams náà sọ̀rọ̀, ó wí pé àṣẹ aya ààrẹ ni wọ́n fi kó wọn sí ẹ̀wọ̀n láì gbọ́ ẹjọ́. Wọ́n ti kó wọn lọ sí ilé ẹjọ́ nígbà ogójì tó sì jẹ́ pé olùpẹjọ́ kò fìgbà kankan yọjú, adájọ́ kàn ń sún ìgbẹ́jọ́ síwájú tí wọ́n sì ń kó wọn padà lọ fìyà jẹ wọ́n. Steve bèèrè fún ìrànwọ́ láti gba àbúrò rẹ̀ kalẹ̀.
Boma Hubert tí ó jẹ́ ẹbí Reginald wí pé ilé ìtura aya ààrẹ tó wà ní Otuoke ni Reginald ti ń ṣiṣẹ́, ó ní kò sí ohun tí Reginald ń wá lọ sí ilé ààrẹ tí Patience fi tìí mọ́lé láti ọdún mẹ́fà sẹ́yìn lórí ohun tó sọnù ní ilé rẹ̀. Boma wí pé Patience kàn ń fìyà àìtọ́ jẹ Reginald ni. Wọn kò tún wá kó wọn sí àtìmọ́lé lágọ̀ọ́ ọlọ́pàá, ọgbà ẹ̀wọn ni wọ́n kó wọn lọ gbogbo ìgbà tí wọ́n bá sì kó wọn lọ ilé ẹjọ́ ni Patience tó pe ẹjọ́ kò ní yọjú, ó ní wọ́n tilẹ̀ wí pé wọn yóò fagi lé ẹjọ́ náà nígbà kan àmọ́ Patience ń lo agbára rẹ̀. Bákan náà ni àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n so mọ́ wọn lẹ́sẹ̀ pé wọ́n gbìyànjú láti pa Patience Johanthan jẹ́ kó nira láti gba onídùúró wọn.
Baba Cosmos náà sọ̀rọ̀ lórí ipò tí ọmọ rẹ̀ wà ní ọgbà ẹ̀wọn náà, ó wí pé ó ti di ìdàkudà. Ìgbà tí ìyá rẹ̀ fẹ́ kú lòun kò jẹ́ kó lọ wò ó mọ́ tí òun nìkan sì ń dá lọ. Ó ní Cosmos ti ní àwọn àìsàn lágọ̀ọ́ ara tí wọn kò sì tọ́jú rẹ̀, ó rọ ìjọba láti yọ̀ǹda Cosmos fún òun kí ó le rí ìtọ́jú.
Ipa àwọn ajàfẹ́tọ̀ọ́monìyàn
Àjọ ajàfẹ́tọ̀ọ́monìyàn Tech4Justice wí pé wọ́n fòró àwọn lórí ẹjọ́ àwọn èèyàn yìí, gbogbo akitiyan láti gba onídùúró wọn kò yọrí sí rere, ọ̀kan nínú àwọn agbẹjórò wọn tị́ orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Funmi Adedoyin ṣe àlàyé pé àwọn agbófinró kò tilẹ̀ ṣe àkọsílẹ̀ ẹ̀sùn náà ní èyí tó mú kí gbogbo àwọn ìgbésẹ̀ yòókù ó nira. Funmi tẹ̀síwájú pé gbogbo bí àwọn ṣe ń fi ẹsẹ̀ òfin tọ̀ ọ́ ni wọ́n ń pàṣẹ láti òkè. Ó wí pé ìyà ti sọ wọ́n di aláàárẹ̀ lọ́gbà ẹ̀wọn, kódà, ọ̀kan ń wà báyìí tí ikọ́ àhúgbẹ ń bá fínra lọ́wọ́. Ọ̀kan pàdánù ọmọ rẹ̀ wọn kò sì tún jẹ́ kí wọn ó gba onídùúró rẹ̀. Ó fẹnu kò síbi pé Patience Johnathan fẹ́ kí wọn ó gbàgbé àwọn èèyàn náà sí ẹ̀wọ̀n ni’
Àwọn òṣịsẹ́ ní wọ́n ń fìyà jẹ àwọn, àjọ ajàfẹ́tọ̀ọ́monìyàn wí pé wọ́n fìyà jẹ àwọn ẹni náà, àjọ NBA wí pé irọ́ ni, olórí ẹ̀sọ́ aláàbò wí pé irọ́ ni. Ta ló ń pa irọ́?
Discussion about this post