Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ ọ̀ṣun ti bẹ̀́rẹ̀ iṣẹ́ lórí AbdulMalik Oladosun tó di àwátì láti ọjọ́ kẹfà, oṣù Bélú.
Àtẹ̀jáde náà fi hàn pé lọ́jọ́ náà, AbdulMalik kúrò nílé rẹ̀ tó wà ní agbègbè Ilo ní Ilobu, ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun tí kò sì darí sílé láti ọjọ́ náà.
Ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún ni AbdulMalik, ó ga ní ìwọn ẹsẹ̀ bàtà márùn-ún, ó dúdú láwọ̀, sọ̀bọ̀rọ́ ni ó sì gbọ́ ède Yorùbá dáadáa. Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá bèèrè fún ìrànwọ́ lórí wíwá ọmọ náà rí.
Abiodun Ojelabi; ẹni tó jẹ́ alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun ló gbé ìkéde náà jáde, ó wí pé ẹni tó bá kófìrí rẹ̀ kó ta àwọn lólobó.
Àwọn tó ń ja ọ̀kadà gbà ní Kano ti ń gba atégùn lágọ̀ọ́ ọlọ́pàá báyìí
Àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò NSCDC ti mú afurasí kan tó jí ọ̀kadà gbé àti ẹnìkan tó ń ta òògùn olóró.
Alukoro fún ẹ̀ka NSCDC ìpínlẹ̀ Kano; Ibrahim Abdullahi ló fi ọ̀rọ̀ yìí léde lọ́jọ́ ìṣẹ́gun. Ó ṣe àlàyé pé àwọn mú Yan Kusa ní agbègbè Sabuwar, ìjọba ìbílẹ̀ Kumbotso.
Usman Abdulhamid; ẹni ọdún mọ́kàndínlógún ni afurasí olè tó jí ọ̀kadà náà, agbègbè Yandanko ni ó ń gbé.
Abdulhamid jẹ́wọ́ pé òun jẹ́ ọ̀kan nínú ikọ̀ tó máa ń já ọ̀kadà gbà lágbégbé náà. Ọ̀kadà mẹ́ta mìíràn ni wọ́n rí gbà padà lọ́wọ́ rẹ̀ nígbà tí àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ méjì yòókù tin a pápá bora.
Bákan náà ni wọ́n mú Salisu Abdullahi; ẹni ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n lórí ẹ̀sùn pé ó ń ṣe òwò òògùn olóró. Agbègbè Sabon titin ni wọ́n ti mú Abdullahi pẹ̀lú àwọn oríṣìí ìyẹ̀fun òògùn olóró.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé àwọn afurasí yìí yóò fi ojú ba ilé ẹjọ́ ní kété tí ìwádìí bá parí.
Ilé ìwé LASUSTECH ń ṣe ìdárò àwọn akékòó tó kú.
Ilé ìwé gíga LASU ní Èkó pàdánù àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọn méjì nínú ìjàm̀bá ọkọ̀ tó wáyé ní oríta Powerline, Ikorodu lọ́jọ́ àbámẹ́ta.
Nínú àtẹ̀jáde tí alukoro fún ilé ìwé náà; Olanrewaju Kuye bu ọwọ́ lù lọ́jọ́ àìkú la ti rí i kà pé nínú àwọn mẹ́ta tó kú nínú ìjàm̀bá náà, méjì ni ó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé náà.
Orúkọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó bá ikú òjijì pàdé náà ni Oluwaseyi Afolabi Emmanuel àti Ayomide Jagun, ìpele kejì àti kẹta ni wọ́n wà ní ẹ̀ka ẹ̀kọ́ ilé ìfowópamọ́ àti ètò ìṣ̀ùná àti ẹ̀ka ìmọ̀ ẹ̀rọ ní tẹ̀létẹ̀lé.
Àlàyé tí ilé iṣẹ́ LASTMA ṣe nípa ìjàm̀bá náà ni pé ọkọ̀ akóyanrìn kan tí kò ní ìwé ìforúkọsílẹ̀ ló pàdánù ìjánu rẹ̀ tó sì kọlu ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkọ̀ kó tó dúró.
Ọ̀gá ilé ìwé náà; Ọ̀jọ̀gbọ́n Olumuyiwa Odusanya wí pé àwọn ti mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ náà àwọn sì ti kàn sí gbogbo àwọn tí ọ̀rọ̀ náà kàn. Ó wí pé òun ti kàn sí ilé ìwòsàn ìjọba ìkòròdú, ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá, ẹ̀ka tó ń gbọ́ ti akẹ́kọ̀ọ́ àti ọ̀gá ẹ̀ka àwọn ọmọ náà láti ṣètò ìrànwọ́ fún àwọn òbí àwọn ọmọ náà.
Bákan náà ni àwọn aṣojú akẹ́kọ̀ọ́ ń sa ipá wọn lọ́rí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Ilé ìwé LASUSTECH wí pé àwọn ti fi ọ̀rọ̀ ìbánikẹ́dùn ránṣẹ́ sí àwọn òbí àwọn ọmọ náà àwọn sì ń ṣètò bí wọn yóò ṣe fi ilẹ̀ bo àṣírí wọn.
Ọ̀jọ́gbọ́n Olumuyiwa kẹ́dùn ikú àwọn ọmọ náà, ó ṣe àpèjúwe rẹ̀ bíi ọ̀fọ̀ ńlá tí kò ṣe é rọ́pò. Ó wí pé àwọn ọmọ tí ọjọ́ ọ̀la wọn kún fún ìmọ́lẹ̀ ni ikú àìtọ́jọ́ sọ di òkùnkùn lójijì. Ó bá àwọn òbí wọn kẹ́dùn ó sì ṣe àdúrà fún àwọn òkú òrun kí ẹ̀mí wọn ó ní ìsinmi.
Ẹ̀ya ara èèyàn ni wọ́n bá lọ́wọ́ àwọn méjì yìí
Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Benue ti tẹ àwọn èèyàn méjì kan tí wọ́n bá orí, itan àti ọkàn èèyàn lọ́wọ́ wọn.
Ọ̀gbẹ́ni Emenari Ifeanyi; ẹni tó jẹ́ kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Benue ṣe àlàyé pé àwọn kò le ṣe ìdámọ̀ àwọn èèyàn méjì náà pé wọn kò mọ́ wọ́n àmọ́ wọ́n mú wọn lọ́jọ́ kejìlélógún, oṣù Ọ̀wàrà ní agbègbè Okpoku. Orí, itan àti ọkàn èèyàn wọ́n bá nínú ẹrù wọn àwọn sì ti kó wọn lọ sílé ẹjọ́.
Ètò ìlera,
Ọwọ́ tẹ ayédèrú dọ́kítà ní Ìpínlẹ̀ Enugu
Ẹ̀ka ètò ìlera ìjọba ìpínlẹ̀ Enugu ti gbé ilé ìwòsàn aládàáni kan tí wọ́n pè ní ayédèrú tì pa ní agbègbè Obollo-Etiti ní ìjọba ìbílẹ̀ Udenu ìpínlẹ̀ náà.
Orúkọ dọ́kítà tó ni ilé ìwósàn náà ni Kenneth Mamah nígbà tí orúkọ ilé ìwòsàn náà jẹ́ St Joseph Memorial Hospital.
Nínú àgbéjáde ẹ̀ka ìlera ìpínlẹ̀ Enugu ní èyí tí alukoro wọn; Ugodu Avemaria bu ọwọ́ lù ni a ti rí i kà pé kọmíṣọ́nà fún ètò ìlera ìpínlẹ̀ náà; George Ugwu ló ṣáájú àbẹ̀wò tí wọ́n ṣe kiri ìlú ní èyí tí wọ́n fi rí ilé ìwòsàn náà.
Àbẹ̀wò náà ló tú ìdí rẹ̀ síta bí ó ṣe ń ṣe iṣẹ́ abẹ fún àwọn èèyàn nínú yàrá kótópó kan tí gbogbo ibẹ̀ sì dọ̀tí. Dọ́kítà Ugodu kò ní ìwé ẹ̀rí ẹ̀kọ́ṣẹ́ òògùn òyìnbó bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní ìwé àṣẹ láti ọ̀dọ ìjọba, níṣe ni ó ń fi ẹ̀mí àwọn èèyàn wéwu pẹ̀lú iṣẹ́ abẹ tó ń ṣe àti ayédèrú ìtọ́jú tó ń ṣe fún wọn.
Ó ya àwọn ará àdúgbò náà lẹ́nu pé dọ́kítà Ugodu kò ní ìwé ẹ̀rí lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún tó ti ń ṣe ìtọ́jú fún wọn.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Enugu ṣe àlàyé pé ó di dandan kí àwọn ó ti ilé ìwòsàn náà pa nítorí pé ààyè ilé ìwòsàn gbọ́dọ̀ mọ́ tónítóní pẹ̀lú àwọn irin iṣẹ́ ìgbàlódé àti àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́.
Wọ́n ti fa dọ́kítà Ugodu lé àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́ títí di ìgbà tí yóò fi ojú ba ilé ẹjọ́.




