Adájọ́ ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Kwara ti pàṣẹ kí wọn ó lọ yẹgi fún AbdulRahman títí ẹ̀mí yóò fi bọ́ lára rẹ̀.
Àná, ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n, oṣù Agẹmọ ni ìdájọ́ náà wáyé.
Lẹ́yìn gbogbo atótónu àti àwíjare, adájọ́ wí pé AbdulRahman jẹ̀bi ẹ̀sùn ìpànìyàn àmọ́ kò jẹ̀bi ẹ̀sùn ìfipábánilò.
Bákan náà ni ó jẹ̀bí ẹ̀sùn ìfiniṣowó.
Adájọ́ wá pàṣẹ pé kí ó lo ọdún mẹ́wàá lọ́gbá ẹ̀wọ̀n fún ẹ̀sùn ìfiniṣowó kí wọn ó sì yẹgi fún un fún ẹ̀sùn ìpànìyàn.
Ta ni AbdulRahman sẹkú pa?
AbdulRahman ni arákùnrin ọ̀dọ́ Alfa tó ṣekú pa ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Hafsoh.
Lórí ìbálòpọ̀ ni AbdulRahman ti fún Hafsoh lọ́rùn pa tó sì kun ún wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ sínú ike ọ̀dà.
Ó ta orí rẹ̀ fún oníbàárà rẹ̀ kan ó sì tọ́jú àwọn ẹ̀yà ara yòókù ní oríkèéríkèé sínú àwọn ike.
Hafsoh kìí ṣe àkọ́pa AbdulRahman nitori bàtà àwọn ọmọbìnrin tó ti pa báyìí bíi mẹ́fà ni wọ́n bá nínú ilé rẹ̀.
Àwọn ará ilé rẹ̀ ṣe àlàyé pé AbdulRahman yóò kọ́ pa ẹran níwájú ìta lọ́jọ́ tó bá fẹ́ pa èèyàn, èyí ni kìí jẹ́ kí àwọn èèyàn ó fura síi bí wọ́n bá ń gbọ́ ìró àdá nínú ilé.
Ikú Hafsoh:
AbdulRahman ni orúkọ afurasí alápatà yìí, ìlú Ilorin ló tẹ̀dó sí, inú ilé rẹ̀ náà ló sọ di odò ẹran tó ti ń pa á kun ún. Èyí tó bu ú lọ́wọ́ yìí ni ti ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ tó pa; Hafsoh.
Hafsoh lọ kí AbdulRahman nílé ni kò dé mọ́. Ìtọpipin àwọn ọlọ́pàá ni wọ́n fi mú AbdulRahman, ó ti pa ọmọ náà ó sì ti gé e níkèéníkèé sínú ike ọ̀dà ọlọ́mọrí.
Ó ti fojú ba ilé ẹjọ́ lẹ́ẹ̀kan níbi tó ti sọ pé òun kò jẹ̀bi, adájọ́ sì sún ìgbẹ́jọ́ rẹ̀ síwájú.
Gbogbo bí ìgbẹ́jọ́ ṣe ń lọ ni AbdulRahman ń sọ pé òun kò jẹ̀bi.
Nígbà tó dé àárín kan, Adájọ́ pàṣẹ kí wọn ó lọ sin òkú Hafsoh gẹ́gẹ́ bí ohun tí agbẹjọ́rò rẹ̀ bèèrè fún.
A gbọ́ pé:
Ilé ẹjọ́ gíga ìpínlẹ̀ Kwara tó fìkàlẹ̀ sí Ilorin ti pàṣẹ kí wọn ó yọ̀ǹda ìyókù Hafsoh fún àwọn òbí rẹ̀ láti lọ sin.
Adájọ́ Hannah Ajayi ló pàṣẹ yìí nìgbà tí agbẹjọ́rò ẹbí Hafsoh bèèrè fún ìyọ̀ǹda ìyókù Hafsoh kí wọn ó sin ín kí ẹ̀mí rẹ̀ ó le sinmi.
Adájọ́ Hannah wí pé òun kò ní àtakò sí ìbéèrè yií, ó wí pé òun bá àwọn ẹbí Hafsoh kẹ́dùn ó sì pàṣẹ kí àwọn ọlọ́pàá ó yọ̀ǹda ìyókù ọmọ náà fún àwọn òbí rẹ̀.
Ní báyìí, ìgbẹ́jọ́ ti pari, adájọ́ sì ti gbé ìdájọ́ rẹ̀ kalẹ̀. A rí fọ́nrán bí àwọn ọlọ́pàá ṣe ń mú AbdulRahman lọ sínú ọkọ̀ lẹ́yìn tí ìgbẹ́jọ́ parí.
Ìhà lórí ìtàkùn ayélujára:
Kò sí ẹni tó káàámú AbdulRahman, bí èpè bí èpè ni àwọn àríwísí tí a ń rí kà lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀.
AbdulRahman kọ́ ni ẹni àkọ́kọ́ tí yóò ṣe irú nǹkan báyìí, ó sì ti dájú pé kìí ṣe òun ni ẹni ìgbẹ̀yìn nítorí pé ọwọ́ àwọn agbófinró ti tẹ ọ̀pọ̀lọpọ̀ lẹ́yìn ti AbdulRahman yìí.
Èyí tó tún ń gbóná lọ́wọ́ báyìí ni ti nọ́ọ̀sì kan tó lóyún sínú tí Chiemere sẹkú pa tó sì tún kun ún wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́.
Ìròyìn náà kà báyìí pé:
Arábìnrin kan tó jẹ́ nọ́ọ̀sì tó sì tún lóyún sínú ni àwọn méjì kan ti sẹkú pa báyìí tí wọ́n sì tún kun ún wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́.
Chiemere Elobisi; ọ̀dọ́mọkùnrin kan ló tan nọ́ọ̀sì náà wá sí ilé rẹ̀ pé kí ó wá tọ́jú òun, nígbà tí nọ́ọ̀sì yìí dé ilé rẹ̀, Chiemere pa á ó sì kun ún wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́ sínú àwọn ọ̀rá dúdú.
Lẹ́yìn náà ni ó ta àwọn ẹ̀yà ara náà fún àwọn oníṣègùn káàkiri. Ìyókù rẹ̀ tó dà sí inú kòtò ìdaminù ni ó mú kí àwọn ọ̀dọ́ ó faraya tí wọ́n sì tọpinpin dé ilé rẹ̀.
Chiemere ti fẹsẹ̀ fẹ́ẹ àmọ́ ọwọ́ tẹ ọ̀rẹ́bìnrin rẹ; Somtochukwu Nwafor.
Ẹni ọdún mẹ́rìnlélógún ni Somtochukwu, ó ṣe àlàyé pé òun kò lọ́wọ́ sí pípa àti kíkun nọ́ọ̀sì náà, òun kàn nu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ nígbà tí Chiemere pa á tán ni.
Somtochukwu ló mú àwọn ọlọ́pàá dé ọ̀dọ àwọn oníṣègùn tí Chiemere ta àwọn ẹ̀yà ara náà fún ọwọ́ sì ti tẹ ọ̀kan nínú wọn.
Tochukwu Ikenga; ẹni tó jẹ́ alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Anambra ṣe àlàyé pé ọjọ́ kẹẹ̀dọ́gbọ̀n, oṣù yìí ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹ̀ ní agbègbè Ogbunike ní ìjọba ìbílẹ̀ Oyi.
Ó ṣe àlàyé pé àwọn ti mú Somtochukwu tó jẹ́ ọ̀rẹ́bìnrin Chiemere nígbà tí Chiemere gan-an ti sá lọ.
Somtochukwu júwe àwọn oníṣègùn tí Chiemere máa ń ta àwọn ẹ̀yà ara náà fún. Èyí ni wọ́n fi mú Nwafor Chibunna tí wọ́n sì bá ẹ̀yà ara nọ́ọ̀sì yìí àti àwọn mìíràn lákàtà rẹ̀.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé àwọn ṣì ń wá àwọn oníbàárà ẹ̀yà ara yòókù àti Chiemere.
Lórí ìpànìyàn yìí kan náà, Augustina ṣekú pa ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ àmọ́ òun kò kun ún wẹ́lẹ́wẹ́lẹ́.
A gbọ́ pé:
Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ti tẹ Augustina Mowan ní ìpínlẹ̀ Òndó lórí ẹ̀sùn pé ó sẹkú pa ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀.
Okitipupa ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ṣẹ̀ lẹ́yìn tí Augustina kojú ọ̀rẹ́kùnrin rẹ̀ nípa ọmọbìnrin mìíràn tó ń yàn lọ́rẹ̀ẹ́, ọ̀rọ̀ náà dìjà láàrin wọn ní èyí tí Augustina sì fi emuga gún Michael ní ẹsẹ̀.
Alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Òndó; Ọ̀gbẹ́ni Olayinka Ayanlade wí pé àwọn ti mú Augustina sí àhámọ́ lórí ikú tó pa ọ̀rẹ́kùnrin é; Michael.
Ẹnìkan tí kò fẹ́ kí a dárúkọ rẹ̀ ṣe àlàyé pé Michael àti Augustina jọ ń gbé nínú yàrá kan aládàáni, wọn kò tíì ṣe ìgbéyàwó.
Ó wí pé gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń jà tí Augustina máa ń fi ẹ̀sùn àlè yíyàn kan Michael.
Lọ́jọ́ náà, wọ́n tún bẹ̀rẹ̀ ìjà yìí, Augustina bá mú emuga ló bá fi gún Michael ní ẹsẹ̀. Wọ́n gbé é lọ sí ilé ìwòsàn ó sì gba ìtọ́jú.
Lẹ́yìn tó dé ilé ni ẹsẹ̀ náà bẹ̀rẹ̀ sí ní wú, ìgbà tí yóò fi padà sí ilé ìwòsàn, ẹlẹ́mìí ti gbà á, Michael dágbére fáyé.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé àwọn yóò parí ìwádìí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.





