Ààrẹ orile-ede wa Naijiria; Bola Ahmed Tinubu yóò pé ọmọ ọdún mẹ́tàléláàdọ́rin ní ọ̀la ọjọ́ àbámẹ́ta. Adúrà ọjọ́ ìbí yóò wáyé ní mosalasi ìlú tó wà ní Àbújá.
Bayo Onanuga; Olùbádámọ̀ràn ààrẹ lórí ìfitónilétí ló sọ ọ̀rọ̀ yìí di mímọ̀ lánàá. Ó wí pé ojo ìbí ààrẹ tọdún yìí bọ́ sínú oṣù mímọ́; oṣù Ramadan, bó tilẹ jẹ pé ojú wa ti rí to, ààrẹ yóò béèrè fún ìrànlọ́wọ́ Olórun níbi adúrà náà láti tún le tukọ̀ orílẹ̀ èdè yìí dé èbúté ògo.
Bákan náà ló wí pé ààrẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún ìṣejọba orílẹ̀-ède Nàìjíríà. Bayo kò ṣàì má mẹ́nu ba pé ṣíṣetò àdúrà ọjọ́ ìbí fi hàn pé ẹni tó ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run lọ́kàn ni ààrẹ wa tó sì ń fi ìlànà Ọlọ́run to ètò ìlú yìí.
Nígbà tí ààrẹ ń yọ ayọ̀ ọjọ́ ìbí rẹ̀ lápá kan, ìbànújẹ́ ikú ọmọ Ajimobi sọ orí àgbà rẹ̀ kodò lápá kejì. Ọwọ́ wa tẹ ìròyìn kan tó sọ pé ‘ààrẹ orílẹ̀-ède wa Nàìjíríà ti bá aya Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ àná; Abiola Ajimobi kẹ́dùn lórí ikú àkọ́bí rẹ̀ lóbìnrin.
Nínú àtẹ̀jáde ti Bayo Onanuga; ẹni tó jẹ́ olùbádámọ̀ràn ààrẹ lórí ìfitónilétí gbé jáde la ti ríi kà pé inú ààrẹ Bola Ahmed Tinubu bàjẹ́ gidi lórí ikú Bisola Ajimobi, ó bá Florence tíí ṣe ìyá Bisola kẹ́dùn ikú ọmọ náà. Ó ṣe àpèjúwe Bisola bíi ọmọlójú àwọn òbí rẹ̀, aya rere lọ́ọ̀dẹ̀ ọkọ àti abiyamọ fún àwọn ọmọ mẹ́ta tó bí.
Bákan náà ló nawọ́ ìkẹ́dùn náà dé ọ̀dọ àwọn ẹbí ọkọ Bisola; ìyẹn ìdílé Kola-Daisi pé wọ́n kú àtẹ̀mọ́ra.
Ààrẹ kò ṣàì má tọrọ àforíjì fún ẹ̀mí Bisola lọ́dọ Ọlọ́run, ó wí pé kí Ọlọ́run ó pa àwọn àṣìṣe rẹ̀ rẹ́ kó sì tẹ́ ẹ sí afẹ́fẹ́ rere.
Bí ààrẹ ṣe ń ṣe èyí ni àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin ilẹ̀ wa àti àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú ń forí gbarí lórí gbèdéke ọjọ́ orí. A gbọ́ pé ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin ilẹ̀ wa ti jẹ ìkó lórí lọ́wọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú PDP àti SDP lórí àbá gbèdéke ọjọ́ orí titun tí wọ́n dá.
Àbá náà ni pé ẹni tí yóò jẹ Gómìnà àti ààrẹ kò gbọdọ̀ ju ọmọ ọgọ́ta ọdún lọ. Àbá yìí fẹsẹ̀ múlẹ̀ láàrin àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ àṣojúṣòfin wọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀ igbésẹ̀ àti sọ ọ́ di òfin ó sì ti dé ìpele kejì.
Èyí gbòdì lára ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, UPP àti SDP wọ́n sì bu ẹnu àtẹ́ lu àbá náà. Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP wí pé bí àbá yìí bá fi le di ofin, Atiku Abubakar tó jẹ́ olùdíje sípò ààrẹ lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ náà kò ní le díje mọ́. Bákan náà ni ẹgbẹ́ òṣèlú Labour wí pé Peter Obi kò ní le díje dupò ààrẹ nítorí ó ti lé lọ́mọ ọgọ́ta ọdún.
Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP wí pé àwọn aṣòfin yìí kò mọ ohun tí wọ́n ń ṣe rárá, wọ́n ní ọ̀rọ̀ náà dàbí ìgbà tí wọ́n bá fi ẹ̀tẹ̀ sílẹ̀ pa làpálàpá lásán ni. Wọ́n ni ìsoro Nàìjíríà dá lé ìwà àjẹbánu kìí ṣe ọjọ́ orí.
Ẹgbẹ́ òṣèlú SDP fara mọ́ àbá yìí lápá kan, wọ́n ní ọjọ́ orí ṣe pàtàkì lóòótọ́ àmọ́ wọn kò sọ bí àwọn fara mọ́ ọn kó di òfin.
Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP ni ọ̀rọ̀ yìí ká lára jù, igbákejì adarí ọ̀dọ́ ẹgbẹ́ náà; Timothy Osadolor wí pé àwọn aṣòfin ọ̀tẹ̀ yìí kò wúlò rárá. Ó wí pé kí lo kan ọjọ́ orí pẹ̀lú ipò ààrẹ àti Gómìnà? Kódà, Timothy dìídì bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ ni pé ó dá òun lójú ni pé àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin ìsìn yìí kò mọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe lórí ìlọsíwájú Nàìjíríà rárá, ó ní àbá yìí fi hàn pé iṣẹ́ kò yé wọn.
Timothy tẹ̀ síwájú pé ìwà ìbàjẹ́ àti àjẹbánu ni olúborí ìṣoro wa ní Nàìjíríà kìí ṣe ti ọjọ́ orí tí wọ́n mú ní kankan. Ó ṣe àpẹẹrẹ orílẹ̀-ède Singapore pé gbogbo àwọn adarí wọn kò dín ní ọmọ ọgọ́ta ọdún wọ́n sì ń ṣe dáadáa, ó tún ní ká wo ilẹ̀ Amẹ́ríkà náà pé ìdójútì ni ká wá fi ọjọ́ orí ṣe gbèdéke ìṣejọba.
Timothy gúnlẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú àmọ̀ràn fún àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣojúṣòfin pé kí wọn ó gbájúmọ́ ojúlówó ìṣòro Nàìjírìà.
Bákan náà lọmọ ṣorí lọ́dọ̀ akọ̀wé ẹgbẹ́ òṣèlú CUPP; Mark Adebayo. Ó wí pé ìwà ìkà ni láti ṣe ìdènà fún ẹni tó tó ìjọba ṣe pẹ̀lú ọjọ́ orí. Mark ṣe àlàyé pé ìwà àjẹbánu ni ìṣòro Nàìjíríà kìí ṣe ọjọ́ orí.
Mark ṣe àpẹẹrẹ orílẹ̀-ède Singapore tó ṣe pé àgbàlagbà ni adarí wọn, ó tún ní ká wo Joe Biden; ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kúrò lórí àpèrè ààrẹ orílẹ̀-ède Amẹ́ríkà.
Àlàyé Mark tẹ̀wíwájú pé a kò nílò àtúṣe ìwé òfin ilẹ̀ wa láti gbé gbèdéke ọjọ́ orí sí ọgọ́ta ọdún, ó ní a kò nílò rẹ̀ rárá. Mark kò ṣàì má rán wa létí pé a ti fìgbà kan ní àwọn ọ̀dọ́ nípò adarí, kín ni wón gbé ṣe? Ìwà ìbàjẹ́ náà ló wọ̀ wọ́n lẹ́wù.
Ojú mìíràn ni akọ̀wé gbogbobò ẹgbẹ́ òṣèlú SDP fi wo ọ̀rọ̀ náà. Ọ̀gbẹ́ni Rufus Aiyenigba wí pé àwọn ọ̀dọ́ ṣe pàtàkì nínú ìṣejọba lóòótọ́ àmọ́ ìrírí àgbà náà kò ṣe é fọ́wọ́ rọ́ sẹ́yìn. Ó wí pé ọjọ́ orí ṣe kókó láwọn apá ibikan àmọ́ ọjọ́ orí nìkan kò tó láti fi ṣe òdiwọ̀n.
Rufus wí pé ohun tó yẹ kí a ṣe ni àtúnyẹ̀wò àwọn ètò ìṣèjọba wa. Ó dábàá pé ká pọn ìjíròrò orí afẹ́fẹ́ ní dandan fún ẹni tó bá fẹ́ díje dupò, nípa báyìí, àwọn aráàlú ó le ṣe ìgbéléwọn ọgbọ́n, òye àti ìrírí àwọn olùdíje kí wọ́n tó yàn wọ́n sípò.
Discussion about this post