Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti kéde ìpínlẹ̀ Rivers ní ìpínlẹ̀ pàjáwìrì lọ́jọ́ Ìṣẹ́gun. Oṣù mẹ́fà ni ààrẹ wí pé kí Gómìnà Similayi Fubara ó lọ lò nílé pẹ̀lú igbákejì rẹ̀; Ngozi Odu àti gbogbo àwọn tí wọ́n dìbò yàn nílé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ náà.
Ààrẹ sọ nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé ìgbésẹ̀ yìí pọn dandan láti mú kí gbogbo hílàhílo tó ń ṣẹlẹ̀ ní láàrin Gómìnà àti àwọn aṣòfin ìpínlẹ̀ náà ó rodò lọ mumi.
Ìlú kò le wa kò má ní olórí, nígbà tí Siminalayi Fubara ó máa fitan ewúrẹ́ jiyan jẹkà pẹ̀lú àwọn ebi rẹ̀ lágbàlá rẹ̀, Ibot-Ette Ibas ni ààrẹ yàn láti máa delé dè é. Ajagunfẹ̀yìntì ni Ibas, òun ni yóò máa ṣe àkóso ìpínlẹ̀ Rivers fún oṣù mẹ́fà náà.
Ní kété tí Ààrẹ Tinubú kéde ìjọba pàjáwìrì ní ìpínlẹ̀ Rivers ni Gómìnà ìpínlẹ̀ náà gbé e bẹ́, tó sì di àwátì àfi ìgbà tí a ríi lọ́jọ́ Àìkù tó lọ yìí nílé ìjọsìn Salvation tó wà ní Portharcourt.
Ṣé gẹ́rẹ́ tí ìjọba Gómìnà Siminalayi Fubara bẹ̀rẹ̀ ní Rivers ni òun pẹ̀lú Nyesom Wike Ọ̀gá rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ ìforí-gbárí, tí nǹkan ò sì fara rọ nítorí fànfà tó wà láàárín Fubara àti Wike tó jẹ́ Mínístà fún Olú ìlú ilẹ̀ yìí tó wà ní Àbújá. Fànfà náà tí ń lọ sí ibi tí àgbá tí fẹ́ẹ́ bú; tí kugú fẹ́ẹ́ bẹ́ ní ìpínlẹ̀ náà láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀.
Ìgbésẹ̀ ìjọba pàjáwìrì yìí ni Tinubú kéde, èyí tí ó ti fòpin sí ìṣèjọba gómìnà Fubara; ìjókòó àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ Așòfin àti àwọn alákòóso ijoba rẹ̀ gbogbo. Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ fi yé wa pé ìpàdé ni gomina Fubara ń ṣe lọ́wọ́ pẹ̀lú àwọn àlejò kan nígbà tí ìkéde náà dé bá a. Kíá náà ni Fubara ṣe páá-pàà-páá, tó fòpin sí ìpàdé náà, tó sì fi ilé ijoba sílẹ̀ láìsọ pàtó ibi tó forí lé. Òun àti àwọn abẹ́sinkáwọ́ rẹ̀ ló sì jọ kọ́wọ̀ọ́ rìn jáde.
Ní kété tí wọ́n kéde ètò ìṣèjọba pàjáwìrì náà ni a rí í tí wọ́n yára pààrọ̀ gbogbo àwọn Ẹ̀ṣọ́ aláàbò tó wà nílè ìjọba ; a ò sì tí ì mọ awọn tó pàṣẹ irú ìgbésẹ̀ bẹ́ẹ̀. A sì tún gbọ́ ọ pé àwọn òṣìṣẹ́ EFCC tí bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwádìí lọ́dọ̀ àwọn òṣìṣẹ́ ijoba kọ̀ọ̀kan lórí gbogbo fànfà tó gba ètò ìjọba Fubara náà. Gbogbo nǹkan ló gbóná janjan báyìí ní Ìpínlẹ̀ Rivers kò fara rọ rárá.
Àwọn ológun gba ìjọba.
Bíṣẹ́ ò bá pẹ́ni, ẹnìkan kìí pẹ́ṣẹ́ ni ajagubfẹ̀yìntì Ibas fi ọ̀rọ̀ náà ṣe. Nǹkan bíi aago mẹ́sàn-án alẹ́ àná ni àwọn ológun dé sí ilé iṣẹ́ ìjọba tó wà ní Portharcourt. Siminalayi Fubara ti kúrò níbẹ̀ ṣaájú dídé wọn.
Àwọn ológun náà dé tẹrùtẹrú ni, àwọn ọkọ̀ ojú ogun ni wọ́n ṣí wọlé bìbà wọ́n sì gbé ọ̀kan sí iwájú ilé iṣẹ́ ìjọba náà.
Ilé ìgbé gómínà ni a gbúròó Fubara sí lálẹ́ àná àmọ́ a kò le sọ bóyá ó ń múra àti kúrò níbẹ̀ ni nítorí pé àwọn ọkọ̀ akẹ́rù wà níwájú ilé náà.
Ìlú ò fara rọ —
Ní kéte tí àwọn ọmọ ológun ya wọ ìpínlẹ̀ Rivers ni gbogbo rẹ̀ pa lọ́lọ́, kẹ́kẹ́ pa mọ́ àtíòro lẹ́nu níbi gbogbo. Àwọn ọlọ́jà ti ìsọ wọn, oníkalukú kọrí sí ilé rẹ̀. Ìbẹ̀rùbojo gba gbogbo ìlú kan, àwọn èèyàn dúró ní méjì mẹ́ta síwájú ilé wọn, wọ́n wara ro, kò sí ẹni tó mọ ohun tí yóò ṣẹlè.
Ìhà tí àwọn èèyàn kọ sí èyí —
Àwọn èèyàn pàápàá àwọn olóṣèlú àti àgbẹjọ́rò ló bu ẹnu àtẹ́ lu ìgbésẹ́ yìí. Ọ̀gá ẹ̀sọ́ aláàbò ilẹ̀ wa; Bello Matawalle nìkan ló ti kín ààrẹ Bola Ahmed Tinubu lẹ́yìn lórí ìgbésẹ̀ yìí.
Àwọn agbẹjọ́rò dìde sí ìgbésẹ̀ tí ààrẹ Bola Ahmed Tinubu gbé lórí ìpínlẹ̀ Rivers nípa dídá Fubara dúró lórí ipò rẹ̀ fún odidi oṣù mẹ́fà. Àwọn agbẹjọ́rò yìí tẹ́ pẹpẹ ọ̀rọ̀ lórí ìkànnì ayélujára, wọ́n ní kó yẹ kí ààrẹ ó sọ ìpínlẹ̀ Rivers sí abẹ́ ìṣèjọba pàjáwìrì rárá débi tí yóò tún wá ní kí Gómìnà ó lọ rọ́kún nílé fún oṣù mẹ́fà tán.
Àwọn agbẹjọ́rò yìí fi àwọn àyọlò láti inú ìwé òfin ilẹ̀ wa gbe ọ̀rọ̀ wọn lẹ́sẹ̀.
Ẹgbẹ́ òṣèlú PDP náà bu ẹnu àtẹ lu ìgbésẹ̀ tí Tinubu gbé lórí ìjọba pàjáwìrì tó kéde ní Ìpínlẹ̀ Rivers yìí. Wọ́n ní kò bá òfin mu rárá ni ; pé agbára ló ń pa Bola Ahmed Tinubu bí ọtí ; pé ó fẹ́ bi ìjọba tiwa-n-tiwa ṣubú ni. Débọ̀ Ológúnàgbà; ẹni tó jẹ́ akọ̀wé ìpoloñgo fún ẹgbẹ́ PDP ló fi eléyìí lédè. Ó ní òún lòdì sí pátápátá sí ìgbésẹ́ Ààrẹ náà., àti pé ìgbésẹ̀ náà tako àgbékalè òfin ọdún 1999 pé ààrẹ́ kàn mọ̀-ọ́nmọ̀ gbé ìjọba tí a ò dìbò yàn lé àwọn ará ìlú lórí ni.
Ẹgbẹ́ PDP àti gbogbo àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè yìí ló fi ìbànújẹ́ ọkàn gbọ́ ohun tí ààrẹ́ wí lórí ẹ̀rọ rédíò nígbà tó ń fi gbogbo ipá àti agbára rẹ̀ kọlu òfin ọdún 1999, tó sì gbé ìjọba pàjáwìrì sọ̀kalẹ̀ kàà lórí àwọn ènìyàn Ìpínlẹ̀ Rivers. Wọ́n ṣàpèjúwe ìpinnu Ààrẹ Tinubu pé ó fẹ́ fi Ìpínlẹ̀ náà sínú ìgbèkùn àti ìjẹgàba ni. Èyí sì jẹ́ àtakò sí ìjọba ti wà-tiwa àti ẹ̀tọ́ tí àwọn ará Ìpínlẹ̀ Rivers ní láti yan aṣáájú wọn lábẹ́ òfin.
Wọ́n sì tún ṣàlàyé ní ọ̀rínkinniwín pé ẹgbẹ́ òṣèlú APC kàn mọ̀-ọ́nmọ̀ ń fíná wàhálà àti rògbòdìyàn òun rúkè-rúdò ní Ìpínlẹ̀ Rivers ni, wọ́n ń ṣe èyí gẹ́gẹ́ bí ète láti bàa lè fi tìpá-tìkúùkù gba ìṣàkóso agbára ìjọba; kí wón sì sọ gbogbo ẹgbẹ́ alátakò di akúrẹtẹ̀ kalẹ̀.
Discussion about this post