Ilé iṣẹ́ ológun ojú òfurufú ilẹ̀ wa Nàìjíríà wí pé bí ẹ bá mọ iye àwọn agbésùnmọ̀mí tí àwọn ti pa, ẹ ó gbà pé akọ iṣẹ́ làwọn ṣe.
Alukoro fún ilé iṣẹ́ ológun náà; Ọ̀gágun Ehimen Ejodame ló fi ọ̀rọ̀ yìí léde pé ní òwúrọ̀ ọjọ́ ẹtì, ọgbọ̀njọ́, oṣù Èbìbí, àwọn ológun ojú òfurufú ta mọ́ra wọ́n sì ṣe ìkọlù sí Bita ní ìpínlẹ̀ Borno. Wọ́n ní Bita ni àwọn agbésùnmọ̀mí tí wọ́n sá ní ibùdó wọn máa ń lọ fi ara pamọ́ sí.
Ọ̀gágun Ehimen wí pé láti òkè ni àwọn ológun náà ti kọlu àwọn agbésùnmọ̀mí tí wọ́n sì pa pálapàla sí wọn lára, wọ́n ní àwọn pa tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ tí àwọn kò le sọ pé iye báyìí ni àwọn pa.
Ilé iṣẹ́ ológun wí pé àṣeyọrí ńlá kan rèé nínú ìgbìyànjú àti rẹ́yìn àwọn agbésùnmọ̀mí. Wọ́n ní kò sí ààyè fún afẹ̀míṣòfó mọ́ nílẹ̀ yìí, ìjà náà ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni.
Ọ̀rọ̀ yìí dàbí ìmúṣẹ ìlérí tí míníśtà fún ètò ààbò ilẹ̀ wa ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù yìí pé àwọn ti ṣetán àti wọ̀yá ìjà pẹ̀lú àwọn agbésùnmọ̀mí. Bello Matawalle ní agbésùnmọ̀mí tó bá ta félefèle lásìkò yìí yóò dá ara rẹ̀ lẹ́bi.
Ìròyìn náà kà báyìí pé:
Mínísítà fún ètò ààbò ilẹ̀ yìí, Bello Matawalle ti ṣe àlàyé bí ìjọba Tinubu kò ṣe fi ààyè gba àwọn agbésùnmọ̀mí lásìkò tirẹ̀ tó ṣe pé ó dojú ìjà gidi kọ wọ́n ni, Matawalle wí pé igba mẹ́rin ni àwọn agbésùnmọ̀mí tí àwọn ti pa lásìkò ìṣejọba Tinubu yìí.
Ó ṣe àlàyé pé àwọn agbékalẹ̀ titun tí ìṣejọba Tinubu gbé kalẹ̀ ni àwọn fi ń kojú àwọn agbésùnmọ̀mí tí àwọn sì ń mú wọn balẹ̀. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tẹ̀síwájú pé ìṣọwọ́ gbógun ti àwọn agbésùnmọ̀mí yìí tó ìdí tí a fi gbọdọ̀ dìbò yan ààrẹ Tinubu nínú ìdìbò ọdún 2027 kí ó le bá àwọn agbésùnmọ̀mí náà kanlẹ̀ pátápátá.
Mínísítà fún ètò ààbò wa wí pé àwọn ti ṣe àgbékalẹ̀ ikọ̀ tí ó ń gbógun ti àwọn ajínigbé tí wọ́n ń fi imú wọn danrin ní èyí tó mú kí ìjínigbé ó di ohun ìgbàgbé báyìí. Bákan náà ni ó wí pé àwọn àlàkalẹ̀ ààrẹ Tinubu lórí ètò ààbò yẹ ní ohun tí ó yẹ kó gba oríyìn fún nítorí pé yàtọ̀ sí àwọn agbésùnmọ̀mí ẹgbẹ̀rin tí àwọn ti pa, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun ìjà olóró ni àwọn ti rí gbà padà lọ́wọ́ wọn.
Matawalle gúnlẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú pé kí ẹ̀yin ọmọ Nàìjíríà ó dìbò yan Tinubu nínú ìdìbò ọdún 2027 kí ó le tẹ̀síwájú nínú iṣẹ́ rere.
Lórí akitiyan àti ṣẹ́gun àwọn agbésùnmọ̀mí yìí náà ni àwọn ológun ti ṣekú pa ọlọ́wọ́ ọ̀tún Bello Turji.
Bello Turji jẹ́ ògbólògbó agbésùnmọ̀mí tí ó ń da ìpínlẹ̀ Sokoto àti agbègbè láàmú.
Ìròyìn náà kà báyìí pé:
Ilé iṣẹ́ ológun ilẹ̀ yìí, ẹ̀ka àwọn jagunjagun ojú òfurufú ti kéde pé àwọn ti pa ọlọ́wọ́ ọ̀tún Bello Turji àti àwọn ẹmẹ̀wá rẹ̀ nínú ìkọlù tí àwọn ṣe sí ibùdó wọn.
Bello Turji ni ògbólògbó agbésùnmọ̀mí tó ń da ìpínlẹ̀ Sokoto, Zamfara àti Kastina láàmú, gbogbo àwọn ìkọlù tó nípọn tó ń wáyé ní Sokoto àti àwọn ìlú tó yíi ká kò ṣẹ̀yìn rẹ̀, ó ti pẹ́ tí àwọn ológun ti ń lépa Bello Turji tí wọn kò ríi mú.
Àmọ́ báyìí, ilé iṣẹ́ ológun wí pé àwọn ti pa ọlọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Shaudo Alku pẹ̀lú àwọn ikọ̀ rẹ̀. Ìbùdó àwọn agbésùnmọ̀mí tó wà ní ìtòsí ilé ìwé ìjọba alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Tunfa tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Sokoto ni wọ́n ti ṣe ìkọlù sí wọn.
Shaudo Alku wá sí Sokoto láti ilẹ̀ Nìjéè wá ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn lọ́gàálọ́gàá agbésùnmọ̀mí pẹ̀lú àṣe Bello Turji. Shaudo ni ó máa ń kó àwọn ohun ìjà olóró wọlé fún Bello láti ilẹ̀ òkèrè.
Ilé iṣẹ́ ológun wí pé àwọn ti bẹ̀rẹ̀ sí ní wá àwọn agbésùnmọ̀mí yòókù tó na pápá bora. Wọ́n ní Shaudo tí àwọn pa yìí yóò da ètò àwọn agbésùnmọ̀mí náà rú wọn kò sì ní le rí àwọn ohun ìjà olóró lò mọ́ nítorí pé Shaudo náà ni ó máa ń kó wọn wọlé. Àṣeyọrí ńlá ni ikú Shaudo jẹ́ àmọ́ bí wọn ó bá rí àwọn agbésùnmọ̀mí náà mú délẹ̀, dandan ni kí orílẹ̀-ède Nìjéè àti Chad ó fi ọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú Nàìjíríà.
Àwọn ará Isa ní Sokoto fèsì sí èyí, wọ́n ní àwọn yóò tilẹ̀ ní ìsinmi lọ́wọ́ àwọn agbésùnmọ̀mí yìí pẹ̀lú ikú Shaudo yìí. Ilé iṣẹ́ ológun wí pé àwọn kò ní sinmi lórí ọ̀rọ̀ àwọn agbésùnmọ̀mí yìí.
Bí éégún ẹni bá jóore, orí a máa yá atọ́kùn. Lórí gbogbo akitiyan ààrẹ Bola Ahmed Tinubu láti ṣẹ́gun àwọn agbésùnmọ̀mí yìí, àwọn olóṣèlú lù ú lọ́gọ ẹnu pé bí aṣáájú rere ṣe ń ṣe nìyìí. Ààbò àwọn èèyàn rẹ̀ ló jẹ ẹ́ lógún.
Lára àwọn tó kan sáárá sí ààrẹ wa Bola Ahmed Tinubu ni Gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi; Ahmed Ododo. Ó wí pé:
Ọlá àbàtà níí módò ó ṣàn, ọlá baba lọmọ fi ń yan; bí kò bá sí ti ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ni, ibo ni àwọn ọmọ Nàìjíríà ò bá gbé ọ̀rọ̀ wọn gbà ní orílẹ̀-èdè tó ti dẹnu kọlẹ̀ tán kí baba tó bọ́ sípò.
Ododo wí pé ààrẹ Tinubu ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn iṣẹ́ àtúntò ní èyí tó mú kí ìgbé ayé ó rọrùn fún àwọn ọmọ orílẹ̀-ède Nàìjíríà, ó ṣe àpèjúwe Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu gẹ́gẹ́ bíi aṣáájú tó ní ètò àti àlàkalẹ̀.
Ọ̀rọ̀ Ododo tẹ̀síwájú pé àsìkò tí a wà yìí ni àsìkò ìkórè, èso iṣẹ́ takuntakun tí ààrẹ fi ọdún méjì àkọ́kọ́ náà ṣe ti ń délẹ̀ báyìí, kí a máa jẹ iṣẹ́ rere tí baba ṣe fún wa ló kù báyìí.




