Ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó ti ṣe ìlérí láti ṣe ìwádìí ìjìnlẹ̀ lórí ikú arábìnrin Folajimi Akinbobola tó kú toyúntoyún. Ẹ̀sùn tí ọkọ rẹ̀ fi kan ilé ìwòsàn tí wọ́n gbé e lọ náà ni pé wọ́n kọ̀ láti tọ́jú rẹ̀ nítorí pé òun kò ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà igba náírà tí wọ́n ní kó mú wá.
Kọmíṣọ́nà fún ètò ìlera ìpínlẹ̀ Èkó; Ọ̀jọ́gbọ́n Akin Abayomi ṣe ìlérí pé ìwádìí ìjìnlẹ̀ yóò wáyé lórí ọ̀rọ̀ náà òfin yóò sì fẹsẹ̀ múlẹ̀. Ìgbìmọ̀ tí yóò ṣe ìwádìí náà ti gba àṣẹ, àwọn àgbà dọ́kítà àti oníṣègùn òyìnbó ló wà nínú ikọ̀ náà.
Wọ́n ní ìwádìí náà yóò dé ọ̀dọ eléwé ọmọ tó kọ́kọ́ tọ́jú arábìnrin náà, ilé ìwòsàn tí wọ́n gbé e lọ náà ní àwọn ìbéèrè tí yóò dáhùn. Ohun tí wọn yóò wò náà ni bí wọ́n ṣe gbámụṣé tó, àṣẹ ọwọ́ wọn àti ìwà àìlákàsí. Ìjọba wí pé ẹni tí ajere ọ̀rọ̀ náà bá ṣí mọ́ lórí yóò fi ojú winá òfin.
Dọ́kítà Abayomi rọ àwọn aráàlú láti fi ẹjọ́ ilé ìwòsàn tí kò bá ní àṣẹ sun ìjọba àti èyí tó ń ṣe ju àṣẹ ọwọ́ rẹ̀ lọ. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tèsíwájú pé ìjọba ìpínlẹ̀ Èkó kò ní fi ààyè gba ìwà àìbìkítà àti ìfẹ̀míwéwu lọ́wọ́ ilé ìwòsàn kankan, ó rọ àwọn olórí ìlú kéréje kéréje ní ìpínlẹ̀ náà láti ṣe àyẹ̀wò bí àwọn ilé ìwòsàn agbègbè wọn ṣe ń ṣiṣẹ́ kí wọ́n sì fi èyí tó bá rú òfin tó ìjọba létí.
Ó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú pé ìdájọ́ òdodo yóò wáyé lórí ikú arábìnrin Folajimi Akinbobola.
Aláboyún mìíràn náà pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Yobe. Ó lọ nájà ni kò padà sílé mọ́. Ohun tí a gbọ́ ni pé:
Aláboyún kan àti àwọn mẹ́rin mìíràn ti dèrò ọ̀run nígbà tí ọkọ̀ akérò kan pàdánù ìjánu rẹ̀ tó sì tẹ̀ wọ́n pa.
Ọjà Damagum tó wà ní Yobe ni ìjàm̀bá yìí ti wáyé ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Àìkú. Ọkọ̀ akérò náà pàdánu ìjánu rẹ̀ lórí eré, nítorí kó má baà kọlu àwọn tó ń sọdá ló ṣe yà bàrà sínú ọjà náà. Aláboyún kan àti àwọn mẹ́rin mìíràn ló tẹ̀ pa lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ nígbà tó tún ṣe àwọn mọ́kàndínlógún mìíràn léṣe.
Adarí ẹ̀ṣọ́ aláàbò ojú pópó ẹ̀ka ìpínlẹ Yobe; Livinus Yilzoom ló sọ ọ̀rọ̀ yìí di mímọ̀ fún àwọn akọ̀ròyìn láàárọ̀ yìí. Àwọn tó kú yìí dúró ní ẹ̀gbẹ́ títì, wọ́n ń wá ọkọ̀ tí yóò gbé wọn lọlé ni ṣáájú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí.
Livinus wí pé ní kíá tí àwọn gba ìpè náà ni àwọn ta mọ́ra dé ibẹ̀, wọ́n ṣe aájò àwọn èèyàn náà dé ilé ìwòsàn ìjọba Damagum.
Àwọn tí ọ̀rọ̀ náà ṣojú wọn wí pé àwọn ọjà tó súnmọ́ títì márosẹ̀ léwu púpọ̀ nítorí irú àwọn nǹkan báyìí.
Lórí ikú yìí kan náà, ìròyìn tó tún tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni ikú Olùdásílẹ̀ ilé ìfowópamọ́ Diamond. Ohun tí a gbọ́ ni pé:
Pascal Dozie; ẹni tó jẹ́ olùdásílẹ̀ ilé ìfowópamọ́ Diamond ti rèwàlẹ̀ àṣà. Ẹni ọdún márùndínláàdọ́rùn-ún ni Pascal lásìkò ikú rẹ̀.
Àwọn ẹbí rẹ̀ ló túfọ̀ ikú rẹ̀ ní òwúrọ̀ òní, ọmọ Pascal tí orúkọ rẹ̀ jẹ́ Uzoma Dozie ló bu ọwọ́ lu ìwé ìtúfọ̀ náà. Ó kà báyìí pé ‘Pẹ̀lú ẹ̀dùn ọkàn àti ọpẹ́ fún Ọlọ́run la fi kéde ikú bàbá wa; Pascal Gabriel Dozie tó di olóògbé lọ́jọ́ kẹjọ, oṣù Igbe, ọdún 2025.
Bàbá dáadáa ni bàbá wa, ó jẹ́ ọkọ rere, bàbá rere àti bàbá àgbà rere tí ìgbàgbọ́ rẹ̀ jinlẹ̀ nínú Ọlọ́run, aya, àwọn ọmọ àti àwọn ọmọọmọ ló gbẹ̀yìn olóògbé’
Ó ṣe pàtàkì láti fi kún un pé Pascal ti fìgbà kan jẹ́ Alága ilé iṣẹ́ MTN.
Ìgbé ayé Pascal Dozie
Ọdún 1939 ni a bí Pascal ní abúlé Egbu, Owerri ní ìpínlẹ̀ Imo. Ìdílé ìjọ Àgùdà ni a bí Alùfáà Pascal sí, bàbá rẹ̀; Charles Dozie jẹ́ Àlùfáà ìjọ Àgùdà.
Ilé ìwé Our Ladies tó wà ní Emekuku ni Pascal ti kàwé, ọpọlọ rẹ̀ tó jí pépé ló jẹ́ kó ní àǹfààní àti lọ kẹ́kọ̀ọ́ ní London.
Àti London ló ti lọ sí UK lọ tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀, kò tán síbẹ̀ o, Pascal gba àwọn ìwé ẹ̀rí ní àwọn ilé ìwé gíga káàkiri.
Ìròyìn mìíràn tó tún fara pẹ́ èyí ni ti arábìnrin kan tí wọ́n pa ní ìpínlẹ̀ Anambra. Àwọn afurasí méjì ni ọwọ́ ti tẹ̀ báyìí. Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ náà kà báyìí pé:
Arábìnrin ẹni àádọ́rin ọdún kan ni àwọn kan pa nípakúpa sórí oko rẹ̀ ní abúlé Ihiala, ìpínlẹ̀ Anambra.
Afurasí méjì ló ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá báyìí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Ọjọ́ kejì, oṣù Igbe ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹlẹ̀, gẹ́gẹ́ bíi àlàyé tí a rí gbà, àwọn ọ̀daràn náà so ìyá yìí lọ́wọ́ àti ẹ̀sẹ̀, wọ́n fi aṣọ díi lẹ́nu kí wọ́n tó pa á, lẹ́yìn náà ni wọ́n gbé ọ̀kadà rẹ̀ lọ.
Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá Anambra; Tochukwu Ikenga ló sọ ọ̀rọ̀ yìí di mímọ̀ pé ọmọ ìyá yìí rí ọ̀kan nínú àwọn ọ̀daràn náà pẹ̀lú ọ̀kadà ìyá rẹ̀ tó gùn ún kọjá lọ lọ́jọ́ náà gan-an, nígbà tó wá ríi pé wọ́n ti pa ìyá rẹ̀ ló fi dárúkọ ẹni tó rí náà bíi afurasí.
Ọmọ abulé Ihiala kan náà ni àwọn afurasí méjéèjì náà. Ọ̀kan ń jẹ́ Chidiebere Igboanugo nígbà tí èkejì ń jẹ́ Umunwaji Ogboro. Ọ̀kadà náà ṣì wà ní àkàtà Chidiebere tó ń gùn kiri. Nínú ìwádìí ni wọ́n ti dárúkọ Emmanuel Ibeabuchi, Alla àti Emeka pé àwọn jọ ń ṣiṣẹ́ pọ̀ ni. Alla àti Emeka ti fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ nígbà tí Emmanuel náà ti wà nínú àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá.
Ikenga wí pé àwọn afurasí náà yóò fojú ba ilé ẹjọ́ láìpẹ́.
Discussion about this post