Ìjọba ìpínlẹ̀ Ondo ti ṣe ìfanilétí fún àwọn òṣìṣẹ́ ìlera káàkiri àwọn ìjọba ìbílẹ̀ méjéèjìdínlógún tó wà ní ìpínlẹ̀ náà. Ó wí pé iṣẹ́ wọn ni yóò sọ bí wọn yóò ṣe pẹ́ nídìí iṣẹ́ náà sí.
Àjọ tó ń mójútó ilé ìwòsàn ìjọba ló kéde èyí láti ẹnu akọ̀wé wọn; Dọ́kítà Francis Akanbiemu pé òun korò ojú sí ìwà ìmẹ́lẹ́ tí àwọn èèyàn náà ń hù lẹ́nu iṣẹ́ pàápàá ní ẹ̀ka abẹ́rẹ́ àjẹsára, ó rọ̀ wọ́n láti múra síṣẹ́ wọn tàbí gba ilé lọ.
Ọ̀rọ̀ dọ́kítà Akanbiemu tẹ̀síwájú pé ìṣèjọba gómìnà Aiyedatiwa kò ní fi ààyè gba ìwà kòkànmí lẹ́yìn gbogbo owó tó ná sí ẹ̀̀ka ìlera. Bí ẹ bá ṣe mú iṣẹ́ yín lọ́kùnkúndùn tó ni yóò sọ bóyá ẹ ṣì máa wà lẹ́nu iṣẹ́ àbí kí a ó júwe ilé fún yín, ètò ti ń lọ́ lábẹ́lẹ̀ láti gba àwọn dọ́kítà àti àwọn oníṣẹ́ ìlera yòókù kí iṣẹ́ le máa tẹ̀síwájú.
Ó rọ̀ wọ́n láti jáde ṣe ìpolongo abẹ́rẹ́ àjẹsára kí àwọn ìyá ó jáde gba abẹ́rẹ́ àjẹsára fún àwọn ọmọ wọn.
Bákan náà ló wí pé iṣẹ́ ń lọ lábẹ́lẹ̀ láti kojú àwọn ìṣòro tí wọ́n le máa kojú lẹ́nu iṣẹ́ wọn pàápàá àwọn tó wà ní abúlé láti gba òṣìṣẹ́ kún wọn kí ètò ìlera ó le gbéra láwọn ìgbèríkò gbogbo.
Kò tán síbẹ̀ o, Dọ́kítà Akanbiemu rọ àwọn òṣìṣẹ́ ìlera láti jẹ́ kí àwọn owó tí Gómìnà Aiyedatiwa ná sí ẹ̀ka ìlera ó yọ nípa ṣíṣe iṣẹ́ wọn bí iṣẹ́. Ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Gómìnà tí kò fi owó jẹ wọ́n níyà ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá gbé àkànṣe iṣẹ́ tọ̀ ọ́ lọ.
Dọ́kítà Victor Adefesoye; ẹni tó jẹ́ adarí ẹ̀ka àjàkálẹ̀ ààrùn àti abẹ́rẹ́ àjẹsára náà wà níbi a-péjọ náà, ó rọ àwọn adarí ìjọba ìbílẹ̀ kọ̀ọ̀kan láti mú iṣẹ́ wọn lọ́kùnkúndùn kí wọn ó gbájú mọ́ṣẹ́ kí wọn ó sì ṣe àṣeyọrí ìdá ọgọ́rùn-ún nínú ọgọ́rùn-ún.
Ipò ìlera ìpínlẹ̀ Ondo yìí farapẹ́ ohun tí mínísítà fún ètò ìlera ilẹ̀ wa; Iziaq Salako sọ lọ́sẹ̀ tó kọjá, ìyàtọ̀ tó wà níbẹ̀ ni pé ìpínlẹ̀ Ondo ń náwó sí ẹ̀ka ìlera ju àwọn yòókù lọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ náà ṣe lọ.
Mínísítà fún ètò ìlera ilẹ̀ wa; Iziaq Salako kọminú lórí ipò tí ètò ìlera ilẹ̀ wa wà báyìí nípa pé gbogbo àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ dọ́kítà ló ti jápa tán lọ sí òkè òkun.
Ó wí pé ní ilé ìwòsàn nísìn yìí, dọ́kítà kan ṣoṣo ni ó ń tọ́jú aláìsàn tí iye wọn lé ní ọ́dúnrún.
Salako sọ ọ̀rọ̀ yìí níbi àpérò kan tó wáyé ní Abuja lọ́jọ́ Ajé, ó wí pé àdójúkọ ńlá ti dé bá ètò ìlera nípa pé gbogbo àwọn dọ́kítà ló ti sá lọ sí òkè òkun tán látàrí pé iṣẹ́ náà tà lọ́hùn-ún.
Àpérò yìí wáyé lẹ́yìn tí Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu pàṣẹ kí àwọn dọ́kítà ó padà sí ẹnu iṣẹ́ kíá.
Àwọn dọ́kítà gùn lé ìyanṣẹ́lódì láti ọjọ́ Àbámẹ́ta lórí pé ìjọba ń fi ẹ̀tọ́ wọn dùn wọ́n, wọ́n wí pé àwọn kò rí owọ́ oṣù gbà lásìkò tó yẹ, àjẹmọ́nú kò jáde, wọn kò rí irin iṣẹ́ lò bẹ́ẹ̀ sì ni gbogbo ilé ìwòsàn kò ṣeé rí.
Salako wí pé bí àwọn dọ́kítà ti jápa yìí kò tilẹ̀ burú tó pé àwọn kò rí àwọn mìíràn gbà sí iṣẹ́, lọ́gán tí wọ́n bá ti kẹ́kọ̀ọ́jáde báyìí, òkè òkun ni wọ́n ń lọ, èyí gan-an ló fà á tí àwọn ilé ìwòsàn kò fi ní dọ́kítà.
Ó fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé kìí ṣe orílẹ̀-ède Nàìjíríà nìkan ló ní àdojúkọ yìí, ó kàn jẹ́ pé ọrọ̀ ajé tó dẹnukọlẹ̀ ló jẹ́ kí ó burú ní Nàìjíríà àmọ́ ìjọba ti bẹ̀rẹ̀ gbogbo ètò láti dá ohun gbogbo padà sípò.
Lára ohun tí ìjọba ń ṣe ni kíkọ́ àwọn ilé ẹ̀kọ́ ẹ̀kọ́ṣẹ́ òògùn òyìnbó kún èyí tó ti wà nílẹ̀ wọn yóò sì rọ àwọn ọ̀dọ́ láti wá kẹ́kọ̀ọ́ ìṣègùn òyìnbó bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé yóò gba àkókò díẹ̀ kó tó le so èso rere nítorí pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà yóò kẹ́kọ̀ọ́gboyè ná kí wọ́n tó le dí àlàfo yií.
Àwọn orílẹ̀́-èdè kan tilẹ̀ ti fi òfin de àwọn dọ́kítà àti oníṣẹ́ ìlera tí wọn kò ní le kúrò ní orílẹ̀-ède wọn , àwa náà yóò ṣe bẹ́ẹ̀ láìpẹ́ kí a le tọ́jú àwọn yòókù sílùú.
Bákan náà ni Salako ṣe àlàyé ìdí tí àwọn ilé ìwòsàn ìjọba fi ń gba àwọn dọ́kítà fìdí-hẹ́ lásìkò yìí, ó wí pé ojoojúmọ́ ni àwọn ojúlówọ́ dọ́kítà ń fìṣẹ́ sílẹ̀, ètò ìgbanisíṣẹ́ ìjọba sì gùn, láti orí ìdánwò dé orí àyẹ̀wò àti ìfọwọ́sí, èyí kò ṣe é ṣe lásìkò yìí ni àwón ṣe fún àwọn dọ́kítà àgbà láṣẹ́ àtigba dọ́kítà fìdí-hẹ́ ná kí gbogo nǹkan ó fi bọ́ sípò.
Níbi àpérò yìí náà ni àjọ àwọn òṣìṣẹ́ ìlera ti sọ̀rọ̀ fún gbogbo àwọn òṣìṣẹ́ ìlera pé ìyà ni ìjọba fi ń jẹ wọ́n lójú méjéèjì, láti ibi owó oṣù, àjẹmọ́nú tó fi dé orí ọrọ̀ ajé tó dẹnu kọlẹ̀, ìyà ló bá dé fún wọn.
Níbi àpérò kan tó wáyé ní Abuja ni àjọ yìí ti sọ̀rọ̀. Alága àjọ náà; Kabiru Sani àti akọ̀wé gbobogbò; Auwalu Kiwaya ló tẹ́ pẹpẹ ọ̀rọ̀ náà.
Wọ́n wí pé gbogbo àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ dọ́kítà, nọ́ọ̀sì tó fi dé orí àwọn amojúẹ̀rọ àyẹ̀wò ló ti bá kó le dáa lọ sí òkè òkun.
Ètò ìlera yìí ti burú ju ohun tó yẹ lọ, ó jìnnà réré sí ètò ìlera fún èèyàn, gbogbo ilé ìwòsàn ti dẹnukọlẹ̀, kò sí ibùsùn fún aláìsàn, kò sí owó oṣù gidi fún òṣìṣẹ́, kò sí òògùn, gbogbo rẹ̀ ló polúkúrúmusu.
Àsìkò ti tó fún ìjọba láti gbé ìgbésẹ̀ lórí èyí ní kíákíá láti dá ohun gbogbo padà sípò.




