Ilé ìwé gíga Babcock tó wà ní Ilishan ti fèsì sí ọ̀rọ̀ Oladipupo Sijuola ọmọ arábìnrin Fijabi Omotayo tó pòórá àmọ́ tí wọ́n ti rí padà báyìí pé àwọn yóò fi ṣìkún òfin gbé e nítorí pé ó jáde kúrò nínú ọgbà ilé ìwé náà lọ́nà àìtọ́.
Wọ́n ní ìwà tó hù yìí ta àbùkù bá orúkọ ilé ìwé náà àti bí ìyá rẹ̀ ṣe fi ẹ̀sùn kan àwọn nígbà tí wọ́n ń wá a.
Ilé ìwé Babcock wí pé Oladipupo jáde kúrò nínú ọgbà ilé ìwé náà láìgba ìwé àṣẹ. Akute ni wọ́n ti padà rí i ní ìpínlẹ̀ Ogun.
Wọ́n ní ṣaájú àkókò yìí ni àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀ tí wọ́n jọ wà ní yàrá ti fi ẹjọ́ rẹ̀ sùn pé ó ń wẹ ọṣẹ dúdú àti kàìnkàìn ibílè. Ní ìdáhùn sí ẹ̀sùn yìí, ìyá rẹ̀ wí pé òun ló gbé àwọn ọṣẹ dúdú kan fún un tí ó jẹ́ amárádán. Ilé ìwé Babcock wí pé àwọn kò faramọ́ àwíjàré ìyá Oladipupo nítorí pé ó ń kàn ń wá àwíjàre fún ọmọ rẹ̀ ni.
Bákan náà ni wọ́n wí pé lílo ọṣẹ dúdú tàbí àwọn ohun ìbílẹ̀ mìíràn lòdì sí òfin ilé ìwé.
Ilé ìwé Babcock tẹ̀ síwájú pé àwọn ti gbé ọ̀rọ̀ náà lé àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́ báyìí.
Ìyá Oladipupo ló figbe ta lórí ìkànnì ayélujára nígbà tí kò rí ọmọ rẹ̀, ọ̀rọ̀ náà pe àkíyèsí àwọn èèyàn wọ́n sì kojú ilé ìwé Babcock lórí bí ọmọ náà ṣe rìn.
A mú ìròyìn náà wá pé:
Arábìnrin Fijabi Oyindamola Omotayo ti ké gbàjarè síta lórí ọmọ rẹ̀ tó di àwátì lẹ́yìn tó gbé e lọ sí ilé ìwé.
Ilé ìwé gíga Babcock tó wà ní Ilishan-Remo, ìpínlẹ̀ Ogun ni ọmọ náà ń lọ, Oladipupo Sijuola sì ni orúkọ rẹ̀.
Ìyá rẹ̀ wí pé fúnra òun lòun gbé e lọ sí ilé ìwé náà ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n, oṣù Igbe tó lọ yìí. Ó ní ojú òun ló ṣe wọ inú ọgbà ilé ìwé náà lọ tí òun sì padà sílé.
Arábìnrin Fijabi ní òun pe ọmọ òun lẹ́yìn wákàtí mẹ́ta àmọ́ kò gbé aago, láti ìgbà náà ni òun kò ti ríi bá sọ̀rọ̀ tí òun kò sì gbúrǒ rẹ̀ títí di àsìkò yìí.
Ìyá Oladipupo ní òun wá a lọ sí ilé ìwé ní àná, ọjọ́ kejì, oṣù Èbìbí àmọ́ wọ́n sọ fún òun pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ a máa farasin sínú ọgbà ilé ìwé nígbà mìíràn pé kò sí ohun tó le ṣe ọmọ náà.
Ìyá Oladipupo kò fara mọ́ ohun tí Babcock sọ yìí, ó ní kí wọn ó wá ọmọ òun jáde ni. Bákan náà ló bèèrè pé kín ni ìdí tí wọ́n fi gbé àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ méjì tó ríi gbẹ̀yìn; Lampard àti Tobi pamọ́?
Ní èsì sí ọ̀rọ̀ yìí, olùbádámọ̀ràn pàtàkì fún Gómìnà Dapo Abiodun lórí àtẹ̀jáde; Ọ̀gbẹ́ni Emmanuel Ojo wí pé òun ti kàn sí kọmíṣọ́nà fún ètò ẹ̀kọ́, kọmíṣọ́nà sì ti kàn sí ọ̀gá ilé ìwé náà láti wá bí ọmọ náà ṣe rìn.
Ọ̀gá àgbà ilé ìwé Babcock wí pé òun ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọ́ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni òun sì ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lé e lórí.
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun; Lanre Ogunlowo náà wí pé àwọn ti gba ìfisùn náà, ìwádìí sì ti bẹ̀rẹ̀ lórí bí wọn yóò ṣe wá ọmọ náà rí.
Lẹ́yìn ọjọ́ díẹ̀ ni wọ́n rí Oladipupo tí wọ́n sì fà á lé ìyá rẹ̀ lọ́wọ́.
A gbọ́ pé Oladipupo Sijuola, akẹ́kọ̀ọ́ ilé iwé Babcock tó wà ní Ilishan ti padà dé o lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ariwo lórí ìtàkùn ayélujára.
Bí ẹ bá ń fi ọkàn bá wa lọ, orí ìtàkùn ayélujára fẹ́rẹ̀ gbiná lọ́sẹ̀ tó lọ yìí nígbà tí gbogbo ojú òpó ń bèèrè fún àwárí Oladipupo. Ìyá rẹ̀; arábìnrin Fijabi Oyindamola Omotayo ló fi omijé wẹ gbogbo ojú ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ nígbà tí ó ń wá ọmọ rẹ̀, ọ̀rọ̀ náà ṣeni láàánú àwọn èèyàn sì ṣúgbà rẹ̀ láti kojú àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn.
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá, kọmíṣọ́nà fún ètò ẹ̀kọ́, olùbádámọ̀ràn Gómìnà Dapo Abiodun, gbogbo wọn ló ṣe ìlérí àtiṣe àwárí ọmọ náà.
Ní báyìí, Oladipupo ti padà dé, ìyá rẹ̀ ti kọ ọ́ sí ojú òpó rẹ̀ pé ó ti dé bẹ́ẹ̀ sì ni a rí fọ́nrán bí wọ́n ṣe fà á lé ìyá rẹ̀ lọ́wọ́.
Ní báyìí, ilé ìwé Babcock ti fèsì sí gbogbo awuyewuye náà pé àwọn yóò pe Oladipupo lẹ́jọ́ nítorí pé ó jáde kúrò nínú ọgbá ilé ìwé náà láìgba àṣẹ.
Ìròyìn mìíràn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ní yàjóyàjó ni ti ọmọ tó ṣá bàbá rẹ̀ ládàá pa ní ìpínlẹ̀ Jigawa.
Ọmọ inú ọká la mọ̀ tó ń sẹkú pa ọká, ọmọ inú erè ní Yorùbá sọ pé ó ń sẹkú pa erè, kín ni ká ti gbọ́ pé ọmọ èèyàn sẹkú pa bàbá rẹ̀?
Ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ kà báyìí pé Muhammad Salisu; ẹni ogún ọdún ti ṣá bàbá rẹ̀; Salisu Abubakar ládàá pa ní ìpínlẹ̀ Jigawa. Àlàyé tí a rí gbà ni pé nǹkan bíi aago mẹ́wàá àárọ̀ ni èyí ṣẹlẹ̀ ní agbègbè Bakin Kasuwa, Sara, ìpínlẹ̀ Jigawa.
Lóòórọ̀ ọjọ́ Àìkú tó lọ yìí, Muhammad he àdá tó mú ṣáṣá ó sì fi ṣá bàbá rẹ̀ lápá, lọ́rùn àti léjìká. Ilé ìwòsàn ìjọba tó wà jí Birnin Kudu ni wọ́n gbé Salisu lọ àmọ́ ó dágbére fáyé.
Àwọn ọlọ́pàá ti gbé Muhammad àmọ́ kò rí nǹkankan pàtó sọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà ju pé inú bíi lọ.
Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ mímọ̀ láti ẹnu alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá Jigawa; Shi’isu Adam pé ọwọ́ tó Muhammad Salisu tó ṣá bàbá rẹ̀ pa nítorí pé inú bíi, ìwádìí ti bẹ̀rẹ̀ yóò sì fi ojú ba ilé ẹjọ́ láìpẹ́.
Discussion about this post