Ààrẹ orílẹ̀-ède wa Nàìjíríà; Aṣíwájú Bola Ahmed Tinubu ti sọ̀rọ̀ nípa ipò tí orílẹ̀-ède Nàìjíríà wà báyìí àti àlàkalẹ̀ ọjọ́ iwájú.
Ààrẹ Tinubu sọ èyí lónìí ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Èbìbí tó jẹ́ àyájọ́ ọdún kejì tó dé ipò ààrẹ. Ó wí pé ohun tí òun fi gbogbo ọdún méjì náà ṣe ni láti ṣètò ìpìlẹ̀ rere, ìpìlẹ̀ tó níkìmí fún ọjọ́ iwájú Nàìjíríà.
Ààrẹ wí pé ìjọba òun ti ṣètò ìgbé ayé ìrọ̀rùn, ètò ọrọ̀ ajé tó yè koro àti àtìlẹ́yìn fún àwọn ọmọ orílẹ̀-ède Nàìjíríà. Iṣẹ́ ìdàgbàsókè àti ìpìlẹ̀ rere náà ń tẹ̀síwájú.
Tẹrú tọmọ ti gbogbo mùtúmùwà ni yóò máa gbádùn bíi èèrà inú ṣúgà nígbà tí gbogbo rẹ̀ bá délẹ̀ tán.
Ẹ̀yin náà ṣá mọ̀ pé ìkòko tí yóò bá játa, dandan ni kí ìdí rẹ̀ ó gbóná, ààrẹ ò sùn bẹ́ẹ̀ sì ni kò wo lórí bí orílẹ̀-ède Nàìjíríà ó ṣe dùn yùngbà yùngbà. Èyí ni àwọn ọ̀rọ̀ tí ààrẹ sọ.
Bákan náà ni ààrẹ dúpẹ́ lọ́wọ́ gbogbo àwọn ọmọ orílẹ̀-ède Nàìíríà fún ìfọwọ́sowọ́pọ̀ àti àtìlẹ́yìn wọn, ó wí pé kò sí ohun tí òun le dá ṣe bí ẹ kò bá ṣe àtìlẹ́yìn fún òun. Ààrẹ wí pé kí ẹ dúró ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́, kí ẹ má ṣe mikàn tàbí ṣiyè méjì nípa ìṣejọba òun, ìrọ̀rùn igi ni ìrọ̀rùn ẹyẹ, ìgbàgbọ́ yín ni ó le mú kí òun ó ṣe àṣeyọrí.
Ọ̀rọ̀ ààrẹ tẹ̀síwájú pé òun mọ rírí sùúrù àti ẹ̀mí ìfaradà tí ẹ ní lásìkò yìí, ó wí pé kí ẹ mọ̀ dájú pé gbogbo rẹ̀ ni yóò dẹ̀rọ̀ pẹ̀sẹ̀ pẹ̀sẹ̀ láìpẹ́ jọjọ. Ààrẹ wí pé orílẹ̀-ède Nàìjíríà tí kò ní jẹ gbèsè sí ilé ìfowópamọ́ àgbáyé tàbí jẹ orílẹ̀-èdè kankan lówó tí yóò sì le dá gbọ́ bùkátà ara rẹ̀, pàápàá tí owó Náírà yóò gbera sọ tí yóò sì níyì ju owó òkè òkun lọ ni òun ń kọ́ lọ́wọ́ báyìí, nígbà tí òun bá sì ṣetán, gbogbo yín lẹ ó máa jó mùkúlú mùkẹ.
Ààrẹ àná náà kí ààrẹ Tinubu kú iṣẹ́ takuntakun.
Ààrẹ àná; Muhammadu Buhari kí ààrẹ òní; Aṣíwájú Bola Ahmed Tinubu kú oríire ọdún kejì lórí ipò ààrẹ ilẹ̀ yìí. Ó kan sáárá síi ó sì lù ú lọ́gọ ẹnu.
Buhari wí pé kí ẹ má fi ti ọ̀rọ̀ àwọn olóṣèlú alátakò ṣe, ẹ má sì retí kí gbogbo rẹ̀ ó dẹ̀rọ̀ lẹ́kan náà nítorí pé ọjọ́ tí a bá gbin iṣu kọ́ ni yóò ta.
Ọ̀rọ̀ Buhari tẹ̀síwájú pé ààrẹ Tinubu gbé ogun ti ìṣẹ́ àti òṣì ó sì ti ń nípa rere, ẹ fún un ní àǹfààní àti parí iṣẹ́ rere tó dáwọ́lé yìí kí ẹ le jọrọ̀ ibẹ̀.
Àsìkò yìí ni ẹgbẹ́ òṣèlú APC nílò àtìlẹyìn yín jùlọ, láti gbé ààrẹ Bola Ahmed Tinubu wọlé lẹ́ẹ̀kejì kí ó le máa bá iṣẹ́ rere lọ. Buhari ló sọ bẹ́ẹ̀.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi náà kò gbẹ́yìn.
Gómìnà ìpinlẹ̀ Kogi; Ahmed Ododo kí ààrẹ Bola Ahmed Tinubu kú oríire àyájọ́ ọdún kejì lórí ipò. Ó wí pé ọlá àbàtà níí módò ó ṣàn, ọlá baba lọmọ fi ń yan; bí kò bá sí ti ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ni, ibo ni àwọn ọmọ Nàìjíríà ò bá gbé ọ̀rọ̀ wọn gbà ní orílẹ̀-èdè tó ti dẹnu kọlẹ̀ tán kí baba tó bọ́ sípò.
Ododo wí pé ààrẹ Tinubu ti ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn iṣẹ́ àtúntò ní èyí tó mú kí ìgbé ayé ó rọrùn fún àwọn ọmọ orílẹ̀-ède Nàìjíríà, ó ṣe àpèjúwe Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu gẹ́gẹ́ bíi aṣáájú tó ní ètò àti àlàkalẹ̀.
Ọ̀rọ̀ Ododo tẹ̀síwájú pé àsìkò tí a wà yìí ni àsìkò ìkórè, èso iṣẹ́ takuntakun tí ààrẹ fi ọdún méjì àkọ́kọ́ náà ṣe ti ń délẹ̀ báyìí, kí a máa jẹ iṣẹ́ rere tí baba ṣe fún wa ló kù báyìí.
Ọ̀rọ̀ ìwúrí tí wọ́n sọ nípa iṣẹ́ rere ààrẹ Bola Ahmed Tinubu yìí kò ṣàì má fìdí múlẹ̀ ní gbogbo ẹ̀ka pàápàá ẹ̀ka ètò ẹ̀kọ́.
Bí èèyàn bá ń fi ọkàn bá ìdánwò àṣekágbá ilé iwe girama WAEC ọdún yìí lọ, èèyàn ó ríi pé tẹ̀gàn ni hẹ̀. Kódà a gbọ́ pé gbọ̀gán tún wó pa àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ń ṣe ìdánwò náà lánàá ní ìpínlẹ̀ Taraba.
Ìròyìn náà kà báyìí pé:
Gbọ̀gán ìdánwò ilé ìwé girama ìjọba tó wà ní Namnai ní ìjọba ìbílẹ̀ Gassol ní ìpínlẹ̀ Taraba ti wó lé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ tó ń ṣe ìdánwò àṣekágbá ilé ìwé girama WAEC lórí lẹ́yìn àrọ̀ọ̀rọ̀dá òjó.
Kò sí ẹni tó gbé ẹ̀mí mì nínú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí àmọ́ wọ́n fi ara pa yánnayàna, Kódà, àwọn kan dá lápa nígbá tí àwọn mìíràn dá lẹ́sẹ̀. Gbogbo àwọn akẹ́kọ̀ọ́, olùkọ́, agùnbánirọ̀ àti alámòójútó ti balẹ̀ sí ilé ìwòsàn lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Alhaji DanAzumi Lauris; ẹni tó jẹ́ ará àdúgbò náà ṣe àlàyé pé gbọ̀gán náà dà wó ní nǹkan bíi aago mẹ́fà ìrọ̀lẹ́ nígbà tí àwọn ikọ̀ kejì ń ṣe ìdánwò lọ́wọ́. Àwọn ikọ̀ kìíní ti parí wọ́n sì ti lọ sí ilé wọn ṣáájú ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Alhaji Lauris wí pé òjò náà fẹ́ atẹ́gùn tó le púpọ̀ ló mú kí gbọ̀gán náà ó dà wó.
Ó wí pé kìí ṣe gbọ̀gán ìdánwò náà nìkan ló dà wó, àwọn ilé kan náà ní àdúgbò náà fara gbá nínú àtẹ́gun òjò náà.
Òjò yìí kò bá má bá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ní ilé ìwé àmọ́ àwọn adarí ìdánwò náà kò tètè dé, ó tó nǹkan bíi aago kan ọ̀sán kí wọ́n tó kó àwọn ìwé ìdánwò dé, èyí ló fà á tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà fi pẹ́ nílé ìwé lánàá.
Gbogbo akitiyan láti bá kọmíṣọ́nà fún ètò ẹ̀kọ́ ìpínlẹ̀ Taraba; Dọ́kítà Augustina Godwin sọ̀rọ̀ kò so èso rere lásìkò yìí.
Discussion about this post