Ọmọkùnrin ọmọ ọdún méjìlá kan ni àṣìta ìbọn ti ṣekú pa báyìí ní agbègbè Mushin ní ìpínlẹ̀ Èkó.
A gbọ́ pé àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn méjì ji wọ́n ń gbéná wojú ara wọn ní nǹkan bíi aago mẹjọ alẹ́ lọ́jọ́bọ, ọjọ́ kẹta, oṣù Agẹmọ.
Wasiu; ìyẹn ọmọdékùnrin yìí lọ ra oúnjẹ lọ́dọ̀ olóúnjẹ kan tí wọ́n ń pè ní ìyá ìbejì ní ìsàlẹ̀ ilé rẹ̀ tó wà ní Olosha kí ó tó di pé ìbọn àwọn ọmọ ẹgbẹ́ òkùnkùn náà bà á tó sì pa á lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
Tale Amoo; ọ̀kan lára àwọn ará àdúgbò náà ṣe àlàyé fún àwọn akọ̀ròyìn pé nǹkan bíi aago mẹ́jọ alẹ́ ni àwọn ṣàdédé bẹ̀rẹ̀ sí ní gbọ́ ìró ìbọn, Wasiu sá sí abẹ́ isọ̀ kan nítorí ìpayà, ibẹ̀ náà ni ìbọn ti lọ bá a.
Amoo wí pé àwọn ọkọ ẹgbẹ́ òkùnkùn náà gbìyànjú àti sá lọ àmọ́ wọ́n rí mú nínú wọn.
Àwọn èèyàn tilẹ̀ ṣe aájò Wasiu dé ilé ìwòsàn ẹ̀kọ́ṣẹ́ òògùn òyìnbó LUTH àmọ́ títì ni ilẹ̀kùn ilé ìwòsàn náà wà kó tó di pé ọmọ náà padà kú.
Àwọn ará àdúgbò wí pé èyí kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí àwọn ọmọ ẹgbẹ òkùnkùn máa yìnbọn pa èèyàn báyìí, wọ́n ké sí ìjọba láti wá nǹkan ṣe sí i.
Irú ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí ṣẹlẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Anambra nínú oṣù Okúdù tó lọ yìí. A gbọ́ pé:
Ọmọdékùnrin kan tí ọjọ́ orí rẹ̀ kò ju ọdún mẹ́wàá lọ ti yìnbọn pa bàbá rẹ̀ tó jẹ́ rìpẹ́tọ̀ ọlọ́pàá.
Ìpínlẹ̀ Anambra ni èyí ti ṣẹlẹ̀, ìròyìn tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni pé ọmọ náà ń fi ìbọn bàbá rẹ̀ ṣeré ni ìbọn náà bá yìn mọ́ ọn lọ́wọ́, ó ba bàbá rẹ̀ lẹ́yìn ó sì tún ba àbúrò ọmọ yìí ní ọrùn ọwọ́.
Okolie Amechi ni orúkọ ọlọ́pàá yìí, nígbà tí wọn yóò fi gbé e dé ilé ìwòsàn, ó ti dágbére fáyé àmọ́ ọmọ kejì ṣì ń gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn.
Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ mímọ̀ láti ẹnu alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Anambra; Tochukwu Ikenga. Ó ṣe àlàyé pé ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Anambra àti Nàìjíríà lápapọ̀ ń ṣe ìdárò ẹni ire tó lọ, ìyẹn Rìpẹ́tọ̀ Okolie Amechi tí ọmọ rẹ̀ ṣèèṣì yìnbọn pa nínú ilé rẹ̀.
Wọ́n ti gbé òkú rẹ̀ lọ sí ilé ìgbókùúsí wọ́n sì ti gba ìbọn náà pamọ́ fún àyẹ̀wò.
Ó tún ṣẹlẹ̀ ní Onitsha náà:
Ọ̀dọ́mọkùnrin kan ẹni ọdún mẹ́tàdínlógún ti gba èkuru jẹ lọ́wọ́ ẹbọra lẹ́yìn tí ìbọn bà á.
Òpópọnà Ifejike ní Gúùsù Onitsha ni èyí ti ṣẹlẹ̀. A gbọ́ pé ọmọkùnrin náà jókòó sí iwájú ilé àwọn òbí rẹ̀ nígbà tí àwọn ikọ̀ ẹ̀ṣọ́ aláàbò Agunechemba ń lé afurasí ọ̀daràn kan lọ, ọ̀kan nínú wọn yin ìbọn sókè àmọ́ ọmọ náà ló bà tó sì pa á lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn ṣe àlàyé pé àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò náà fẹ́ sá lọ àmọ́ àwọn èrò àti àwọn ọlọ́jà ló dá wọn dúró tí wọ́n sì ní kí wọn ó gbé òkú ọmọ náà dandan. Wọ́n ní èyí kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí wọn ó yin ìbọn pa aráàlú.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé àwọn ti mú àwọn afurasí méjì sí àhámọ́ báyìí.
Bákan náà ni a gbọ́ pé akẹ́kọ̀ọ́ UNIPORT kan dáná sun olólùfẹ́ rẹ̀ nítorí pé kò gba oyún tó ní fún un pé;
Cynthia Chukwundah; akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé UNIPORT kan ló ti dáná sun olólùfẹ́ rẹ̀ nítorí aáwọ̀ gboyún-mi-ò-gboyún tó ṣẹlẹ̀ láàrín wọn.
Ẹni ọdún méjìlélọ́gbọ̀n ni Sunny Amadi tó je.́ olólùfẹ́ Cynthia, Sunny àti Cynthia ń jiyàn lórí ọ̀rọ̀ oyún ní àṣálẹ́ ọjọ́ náà ni kí ó tó di pé ọ̀rọ̀ náà burẹ́kẹ tí Cynthia sì lọ gbé epo bẹntiróòlù, ó túu lé Sunny lórí ó sì ṣá iná síi mọ́ orí ìbùsùn rẹ̀.
Grace Iringe-Koko; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ipínlẹ̀ Rivers ló fi ọ̀rọ̀ yìí léde, ó wí pé Sunny kú látàrí iná tí Cynthia dáa síi lára, Cynthia fúnra rẹ̀ fi ara kó nínú iná náà ó sì wà ní ilé ìwòsàn níbi tí àwọn ọlọ́pàá ti ń ṣọ́ ọ.
Ìròyìn mìíràn tí a kò gbọdọ̀ má fi tóo yín létí ni ti obìnrin kan tí ó ń fi àwọn èèyàn ṣe òwò. A gbọ́ pé;
Arábìnrin kan tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Goodness Daniel, ẹni ọdún mẹ́rìnlélógójì ni ilé ẹjọ́ ti pàṣẹ kó lọ lo ọdún márùn-ún lọ́gbà ẹ̀wọ̀n lórí èsùn pé ó ń fi àwọn ọmọ ṣe òwò.
Ìpínlẹ̀ Anambra ni ìgbẹ́jọ́ náà ti wáyé níwájú Adájọ́ Peace Otti. Lẹ́yìn gbogbo atótónu àti àwíjarè, adájọ́ Otti pàṣẹ kí Goodness ó lọ lo ọdún márùn-ún lọ́gbà ẹ̀wọ̀n tàbí san mííọ́nù méjì náírà owó ìtanràn.
Ẹ̀sùn tí ìjọba fi kan Goodness pé ó ń ṣe òwò káràkátà èèyàn. Wọ́n ní Goodness ń ra èèyàn lọ́wọ́ àwọn ajínigbé yóò sì tà wọ́n fún àwọ oníbàárà rẹ̀ tí wọn yóò máa fi wọ́n ṣe iṣẹ́ àṣekára àti àwọn ohun mìíràn.
Ẹni tí Goodness tà gbẹ̀yìn ni ọwọ́ ọlọ́pàá fi tẹ̀ẹ́. Adájọ́ pàṣẹ kí Goodness ó san mílíọ́nù méjì àti ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀ta náírà owó gbà-má-bínú fún ẹni náà.
Iroyin iku Peter Rufai ka bayii pe:
Peter Rufai; ọlọ́wọ́ ẹ̀mú bọ́ọ̀lù àfẹ̀sẹ̀gbá ti dágbére fáyé lẹ́ni ọdún mọ́kànlélọ́gọ́ta.
Ọmọ bíbí orílẹ̀-ède Nàìjíríà ni Peter, ikọ̀ Super Eagles náà ni ó ti jẹ́ ọlọ́wọ́ idán lórí pápá.
Gbogbo ẹbí àti ikọ̀ Super Eagles lápapọ̀ ń dárò ikú rẹ̀ lásìkò yìí.
Dodo Mayana ni ìnagijẹ Peter Rufai, ọjọ́ kẹta, oṣù Agẹmọ ló dágbére fáyé lẹ́yìn àìsàn ránńpẹ́.



