Oko ẹ̀gẹ́ tó tó mílíọ̀nù mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n náírà ni àwọn kan tí wọ́n fura sí pé wọ́n jẹ́ darandaran dáná sun ní ìpínlẹ̀ Ogun.
Eni tó ni oko náà ṣe àlàyé ohun tí ojú rẹ̀ rí lọ́jọ́ náà pé nígbà tí òun dé orí oko, òun bá àwọn màálù tí wọ́n ń jẹ oko tí òun sì tún rí iná tí wọ́n ti dá sínú oko náà káàkiri, ó wí pé bí àwọn darandaran náà ṣe rí òun ni wọ́n kó àwọn màálù wọn sá lọ àmọ́ òun rí ọ̀kan mú nínú àwọn màálù náà, ó mú màálù yìí lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá gẹ́gẹ́ bíi ẹ̀rí.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ pé àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí tó nípọn lórí ẹ̀sùn tí àgbẹ̀ náà fi kan àwọn darandaran, wọ́n ní màálù tó mú wá náà làwọn ó fi ṣe àwárí ẹni tó ni í kí ìwádìí náà ó le so èso rere.
Abúlé Adao tó wà ní Alabata ní Abẹ́òkúta, ìpínlẹ̀ Ogun ni èyí ti ṣẹ̀.
Àgbẹ̀ náà bara jẹ́ gidi, ó ṣe àlàyé pé oko ẹ̀gẹ́ òun wọ̀n tó mílíọ̀nù mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n náírà.
Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun; Omolola Odutola ló sọ ọ̀rọ̀ yìí di mímọ̀ pé àwọn gba ìfisùn láti ọ̀dọ àgbẹ̀ kan ní ìpínlẹ̀ Ogun pé àwọn darandaran sọ iná sí oko òun tí ìwọ̀n rẹ̀ tó mílíọ̀nù mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n náírà.
Ọjọ́ kọkàndínlógún, oṣù Ebìbí yìí ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹ̀. Àgbẹ̀ náà wí pé àwọn ẹ̀gẹ́ tí iná kò jó ni wọ́n tún hú tìdí tìdí kúrò nílẹ̀.
Omolola wí pé àwọn ti lọ pẹ̀tù sí àdúgbó náà kí ogun ó má baà ṣẹlẹ̀. Ó wí pé àwọn ti fi ọ̀rọ̀ náà ṣọwọ́ sí ẹ̀ka tí yóò ṣe ìwádìí rẹ̀ jinlẹ̀.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá fi àwọn ará ìlú lọ́kàn balẹ̀ pé ààbò àti déédé ni àwọn wà fún.