Ẹ gbọ́ kí la mí ṣe lónìí o?
Ìyàwó la mí gbé o!
Ó kàn jẹ́ pé orílẹ̀-èdè Tanzania ni wọ́n ti ṣe ìgbéyàwó náà ni kò jẹ́ kí àṣà yorúbá ó rinlẹ̀ níbi ayẹyẹ náà, àmọ̀ o, tẹ̀gàn ni hẹ̀.
Àfẹ́sọ́nà Priscilla ìyẹn ọlórin tàkasúfě tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Juma Nkambala ti gbé ìyàwó rè lódidi báyìí.
Ilẹ̀ Tanzania ni ayẹyẹ ìgbéyàwó náà ti wáyé, àwọn èèyàn tí wọ́n pè nìkan ló péjúpésẹ̀ sí ibẹ̀, àlọọ́lẹ̀ ni àwọn àlejò náà lọ.
Priscilla fúnra rẹ̀ fi àwọn àwòrán oríṣiríṣi sí orí àwọn ojú òpó ayélujára rẹ̀, àwọn àwòrán òun àti olólùfẹ́ àti àwọn àwọn ẹbí bí wọ́n ṣe ń dé sí Tanzania.
Aṣọ aláwọ̀ òféfèé àti olómi góòlù ni ìyàwó wọ̀ tí gbogbo rẹ̀ sì ń kán tó tó, ọkọ náà kò bàjẹ́ nínú aṣọ funfun àti ṣòkòtò rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àṣà rẹ̀.
Níbi ayẹyẹ náà la ti rí Enioluwa; ọ̀rẹ́ ìyàwó láti ọjọ́ tó ti pẹ́. Kò sí oúnjẹ tí Enioluwa kò jẹ tán níbi ìgbéyàwó náà, lẹ́yìn náà ló fi ijó dábírà, ijó yìí kọjá bẹ́ẹ̀, òun gan-an là bá pè ní abólóde-fẹ̀ẹ́lójú.
Ẹ̀yìn náà ti mọ ìyá ìyàwó lánàá kó tó dòní. Queen mother fúnra rẹ̀, bí èèyàn kò bá dá a mọ̀ dáadáa tẹ́lẹ̀, ẹ ó ṣe bí òun gan-an ni ìyàwó ni, ọmọ dára ó dẹjọ́. Òun àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ kòríkòsùn ni wọ́n jọ dáwọ̀ọ́ ìdùnú.
Ṣáájú kí ìgbéyàwó yìí tó wáyé, Jux ti wá sí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà láti wá mọ ìyá ìyàwó rẹ̀ ìyun nnì Iyabo Ojo.
Tìlútìfọn ni wọ́n fi pàdé rẹ̀ ní pápákọ̀ òfurufú. Àwọn oníjó, onílù náà kò gbẹ́yìn.
Wọ́n fi tẹ̀ríntọ̀yàyà kíi káàbọ̀ sí ilẹ̀ Nàìjíría.
Lẹ́yìn náà ni Jux padà sí ìlú rẹ̀ pẹ̀lú Priscilla. Tọ̀yàyàtọ̀yàyà náà ni wọ́n fi pàdé rẹ̀ ní Tanzania lọ́hǔn.
Olórin tàkasúfě ni Juma, ìbáṣepọ̀ láàrin òun àti Priscilla ti mú kí òkìkí rẹ̀ ó kàn síi, awon ọmọ Nàìjíría di olólùfẹ́ rẹ̀, orin rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ tó pè ní Olólùfẹ́ mi ń gbóná lọ́wọ́ lórí ìkànnì YouTube.