ADVERTISEMENT
  • About
  • Contact
Monday, June 1, 2026
  • Login
  • Register
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
No Result
View All Result
Home Ààyè Olóòtú

ÀWỌN AGBÉBỌN TÚN TI PUTÚ BURÚKÚ…

Wọ́n jí èèyàn mẹ́ta gbé nínú mọ̀lẹ́bí kannáà.

by Adeola Olanrewaju
February 4, 2025
in Ààyè Olóòtú, Ìrìn Àjò, Ìròyìn, Ìròyìn Agbègbè, Ìròyìn Tó Gbòde, Ọ̀rọ̀ Ààbò, Ọrọ̀-Ajé, Òṣèlú
0
Àwọn agbébọn ya wọ ààfin ní Kwara.
0
SHARES
27
VIEWS
Pín Lórí FacebookPín Lórí ThreadsPín Lórí TwitterPín Lórí Bluesky
ADVERTISEMENT

Àwọn agbébọn palẹ̀ èèyàn mẹ́ta mọ́ nínú mọ̀lẹ́bí kan ṣoṣo. Ojú ọ̀nà Òró sí Àgbàmú, ní ìjọba ìbílẹ̀ Ìrẹ́pọ̀ọ́dùn ní Ìpínlẹ̀ Kwara ni èyí ti ṣẹlẹ̀, àwọn ọlọ́pàá lọ fi lédè pé àwọn agbébọn túj gbé ìṣe wọn dé o, àwọn èèyàn mẹ́ta tánntán ni wọ́n tún jí gbé lọ nínú ẹbí kan náà.
Lónìí lọ́la, bí ẹkún apọkọjẹ. Ẹnu kìí sì lára afọ́kéèmù ni ọ̀rọ̀ àwọn ajinigbe yìí, nígbà tí àwọn ọlọ́pàá kò tíì rí gbogbo àwọn tí wọ́n ti jí gbé gbà tán, wọ́n tún lọ kó àwọn mìíràn, láìṣe adìyẹ, ó mà wá ga báyìí o.
Nínú àlàyé ọ̀rọ̀ tí ọ̀gá Ọlọ́pàá DSP TÒUN Èjìrẹ́-Adéyẹmí fọwọ́ sí ní ìlú Ìlọrin, ọjọ́ ÀÌKÚ tó kọjá yìí ló fìdìí ọ̀rọ̀ náà múlẹ̀ pé àwọ́n ẹni ibi tíí pọn ọmọ re baluwẹ̀ yìí ya wọ ìletò Owóyalé lojú Ọ̀nà Òró-Agbamu wọ́n sì fi tipátipá kó àwọn mẹ́ta ní pápá mọ́ra tí wọ́n sì gbé wọn lọ tèfètèfè.
Ìgbẹ́ làá féwé, oko làá wá nǹkan ọbẹ̀, bí àárín ìlú ni wọ́n kó wọn lọ ni bí igbó ni kò sí ẹni tó le sọ.
Àwọn tí wọ́n jí gbé náà ni Alhaji Abdulkazeem Owóyalé àti ìyàwó rẹ̀ pẹ̀lú Alhaji Moshood.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ti da àwọn ọlọ́pàá síta, wọn yóò ṣiṣẹ́ ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọdẹ láti wá àwọn ẹni yìí jáde.
Ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé mìíràn tó wáyé ni ti ìyàwó Ọ̀gá Ọlọ́pàá m Ìpínlẹ̀ Ògùn, tí àwọn ajínigbé palẹ̀ wọ́n gbé àmọ́ tó rí ìtúsílẹ̀.
Ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kìn-ínní ọdún yìí ( 2025) ni ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé yìí wáyé, tí arábìnrin náà sì gba ìtúsílẹ̀ lẹ́hìn tó ti lo ọjọ́ mẹ́jọ gbáko ní kàtà wọn.
Gẹ́gẹ́ bí ohun tí alukoro àwọn Ọlọ́pàá Ìpínlẹ̀ Ògún sọ, ìyẹn ACP Múyiiwá Adejọbí, àwọn kan lára àwọn ajínigbé náà fara gbọgbẹ́ nígbà tí àwọn ọlọ́pàá ya bò wọ́n.
Oríṣìí irin-iṣẹ́ ni wọ́n rí gbà lọ́wọ́ wọn. Yàtọ̀ sí èyí, wọ́n gba owó tó tó ẹgbẹẹgbẹ̀ lọ́wọ́ wọn, bí irú èyí tí wọ́n fi tọ́dẹ pàkúté fún wọn tí ọwọ́ fi tẹ̀ wọ́n.
Wọ́n ní yinniyinni, kẹ́ni ó ṣèmíì, èyí ló mú kí Ọ̀gá Ọlọ́pàá yán-ányán-án ní orílẹ̀ èdè yìí, IGP Káyọ̀dé Ẹgbẹ́tókun gbé òṣùbà ràbàǹdẹ̀ fún ikọ̀ àwọn Ọlọ́pàá tó ṣe iṣẹ́ ribiribi náà.
Ní báyìí, arábìnrin aya Odùúmósù ti wà pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀.
Ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé yìí kò mọ láàrin àwọn àgbà nìkan, kódà kò yọ ọmọ ọwọ́ sílẹ̀. Àbí kín ni ká ti pe ẹni tó jí ọmọ ẹ̀gbọ́n rẹ̀ gbé?
Agbègbè Kwamba, Suleja ní ìpínlẹ̀ Niger ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ṣẹ̀. Ọjọ́ kẹẹ̀dọ́gbọ̀n oṣù Ọ̀pẹ ọdún tó kọjá ni ìyá ọmọ oṣù mẹ́fà yìí fi ọmọ rẹ̀ ti Joy; ẹni tó jẹ́ ọmọ àbúrò bàbá rẹ̀ pé òun fẹ́ jáde.
Dídé tí yóò dé lálẹ́, kò bá ọmọ rẹ̀ bẹ́ẹ̀ sì ni kò bá Joy tó fi ti ọmọ náà. Kò kọ́kọ́ bìkítà pé bóyá ó sáré jáié rẹ̀ méjì tí wọn kò sí nílé láti ọjọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ náà, bí ọ̀kan nínú wọn ṣe dé ni àwọn ọlọ́pàá he é bíi ìgbín, òun ló júwe ibi tí Joy àti àwọn méjì yòókù wà.
Agbègbè Kubwa ní Abuja ni wọ́n gbé ọmọ oṣù mẹ́fà náà lọ láti tàá, Emmanuel Ezekiel jẹ́wọ́ pé àwọn ti ń gbìmọ̀pọ̀ tipẹ́ láti jí ọmọ náà gbé pẹ̀lú Joy, nígbà tí àwọn sì rí anfààní láti gbé e ni àwọn ṣe jọ jí ọmọ náà gbé lọ tà.
Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá tẹ Joy àti Favour, wọ́n mú àwọn ọlọ́pàá lọ sí ilé Patience Obana tí yóò bá wọn ta ọmọ náà, kò tíì rí ọmọ náà tà tí àwọn ọlọ́pàá fi mú un. Àlàáfíà sì ni ọmọ yìí wà.
Wasiu Abiodun; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Niger bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ pé àwọn mú Joy Nuwa; ẹni ogún ọdún tó jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Nasarawa, Emmanuel Ezekiel; ẹni ọgbọ̀n ọdún tó sì jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Niger, Favour James; ẹni ọdún márùndínlọ́gbọ̀n tó sì jẹ́ ọmọ ìlú Niger bákan náà àti Patience Obana; ẹni ọdún mẹ́tàlélógún tí òun sì jẹ́ ọmọ bíbí ìlú Abuja lórí ẹ̀sùn ìjọ́mọgbé.
Kìí wá ṣe pé ẹ̀sùn ìjọ́mọgbé nìkan o, ọmọ títà ni iṣẹ́ Patience, Kubwa ní Abuja ló tẹ̀dó sí.
Àwọn ọlọ́pàá ti gba ọmọ náà padà lọ́wọ́ wọn, wọ́n sì ti gbé e fún ìyá rẹ̀.
Ọ̀gbẹ́ni Abiodun wí pé àwọn ti kó àwọn afurasí mẹ́rin yìí sí àtìmọ́lé, wọn yóò fi ojú ba ilé-ẹjọ́ láìpẹ́.
Ọ̀rọ̀ àwọn ajínigbé àti ajọ́mọgbé yìí ti gba àpérò nílǔ yìí, lónìí lọ́la bí ẹkún apọkọjẹ. Àwọn èèyàn kò le sùn fi orí lé òṣùká, bí ilẹ̀ ṣúni síta, inú fu àyà fu ni.
Ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn tó fara pẹ́ èyí ni ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Kaduna ní oṣù Ògún ọdún tó kọjá yìí kan náà nígbà tí àwọn ajinigbe palẹ̀ àwọn èèyàn mẹ́sàn-án mọ́ ní ìpínlẹ̀ Kaduna.
Orin ‘káàbọ̀, ṣé dáadáa ló dé’ ni àwọn ajínigbé kọ pàdé ìyá àti àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin méjì tí wọ́n gbéra kúrò ní Èkó lọ sí Kaduna láàárọ̀ ọjọ́ náà tí wọ́n sì jí wọn gbé ní ìrọ̀lẹ̀ ọjọ́ kan náà.
Èèyàn mẹ́sàn-án ni wọ́n gbé lọ lápapọ̀, nínú wọn ni aya akọ̀ròyìn Muhammed Bashir àti àwọn ọmọ rẹ̀ obìnrin méjì wà.
Bashir fún ra rẹ̀ ló kéde lójú òpó ìbánisọ̀rọ̀ àjọ akẹgbẹ́ rẹ̀ pé kí wọn ó gba òun ra òun kalẹ̀ o, ìsinmi ni ìyàwó àti àwọn ọmọ òun fẹ́ lọ lò lọ́dọ̀ ìyá àgbà ní Kaduna, wọ́n dé sí Kaduna láàárọ̀, àwọn ajínigbé sì gbé wọn lọ ní àsálẹ́.
Àwọn ọlọ́pàá àtí àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn ti ta mọ́ra láti wá àwọn èèyàn náà.
Mélòó la ó kà nínú eyín adìpèlé? Tinú ọrún, tòde ẹ̀jọ.
Bí ojumọ́ ṣe ń mọ́ tí ọ̀yẹ̀ ń là ni àwọn èèyàn ń ké gbàjarè àwọn èèyàn wọn tí wọ́n jí gbé. Àbí ẹ̀yin ò gbọ́ nípa èyí tó ṣẹlẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ogun nígbà tí wọ́n gbé odidi ìyàwó ọlọ́pàá?
Ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kìn-ínní ọdún yìí ( 2025) ni ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé yìí wáyé, tí arábìnrin náà sì gba ìtúsílẹ̀ lẹ́hìn tó ti lo ọjọ́ mẹ́jọ gbáko ní kàtà wọn.
Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ACP ìpínlẹ̀ Ogun; Múyiiwá Adejọbí sọ , àwọn kan lára àwọn ajínigbé náà fara gbọgbẹ́. Wọ́n sì rí onírúurú irin-iṣẹ́ gbà lọ́wọ́ wọn. Yàtọ̀ sí èyí, wọ́n gba owó tó tó ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ lọ́wọ́ wọn, bí irú èyí tí wọ́n fi tọ́dẹ pàkúté fún wọn tí ọwọ́ fi tẹ̀ wọ́n.
Wọ́n ní yinniyinni, kẹ́ni ó ṣèmíì, èyí ló mú kí Ọ̀gá Ọlọ́pàá yán-ányán-án ní orílẹ̀ èdè yìí, IGP Káyọ̀dé Ẹgbẹ́tókun gbé òṣùbà ràbàǹdẹ̀ fún ikọ̀ àwọn Ọlọ́pàá tó ṣe iṣẹ́ ribiribi náà.
Ní báyìí, arábìnrin aya Odumosu ti wà pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀.
Òmíràn mà tún ṣẹlẹ̀ o, àbí ẹ̀yin ò ríi gbọ́ pé àwọn agbanipa ya wọ inú ilé ìjọsìn ìjọ mímọ́ Christ Hebrew tó wà ní òdo ẹran, ìdíròkó, ìpínlẹ̀ Ogun tí wọ́n sì ṣekú pa Yomi Adetula, ẹni ọdún mẹ́rìnléláàdọ́ta ni pásítọ̀ ìjọ náà.
Pásítọ̀ Yomi Adetula ni àwọn agbanipa yìí bá lọ́rọ̀, orí pẹpẹ ìwàásù ni pásítọ̀ Yomi wà tí àwọn aráabí fi wọlé sínú ilé ìjọsìn náà, wọ́n rọ̀jò ìbọn fún Pásítọ̀ Yomi, gbogbo ara rẹ̀ ni ọta ìbọn dálu. Lẹ́yìn tí wọ́n yìnbọn mọ́ ọn tán ni wọ́n tún fi ààké fọ́ orí rẹ̀ kí wọ́n le ní ìdánilójú pé ó ti kú.
Omolola Odutola; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun ṣe àlàyé pé àwọn ọlọ́pàá tara ṣàṣà dé ilé ìjọsìn náà nígbà tí wọ́n gba ìpè pàjáwìrì. Inú àgbàrá ẹ̀jẹ̀ ni wọ́n bá pásítọ̀ Yomi, gbogbo ara rẹ̀ ló lu fún ọta ìbọn tí wọ́n sì tún fi ààké fọ́ orí rẹ̀ kalẹ̀.
Àwọn ọlọ́pàá lé àwọn afurasí yìí àmọ́ ẹnu ìloro ni wọ́n gbà sá lọ.
Wọn kò ṣe àwọn ọmọ ìjọ tàbí ẹlòmíràn léṣe, pásítọ̀ Yomi nìkan náà ni wọ́n wá pa. Èyí ló kọ àwọn èèyàn lóminú pé kín ni pásítọ̀ le ṣe fún àwọn ẹni ibi yìí?
Ìwádìí ìjìnlẹ̀ fi hàn pé ọ̀gá ni pásítọ̀ Yomi nínú iṣẹ́ ìwádìí àti ìdáàbòbò. Wọ́n ní ó ń ṣe ìwádìí ẹ̀sùn kan tó níí ṣe pẹ̀lú olóṣèlú kan pàtàkì.
Kò sí ẹni tó le sọ pàtó bóyá ìwádìí tó ń ṣe yìí ló fa ikú rẹ̀ tàbí nǹkan mìíràn.
Àwọn ọlọ́pàá ti gbé òkú Yomi lọ sí ilé ìgbókùúsí Ilaro.
Ìjínigbé lọ́tùn-ún, ìpànìyàn lósì, orílẹ̀-èdè wa ń ṣàn fún ẹ̀jẹ̀. Kí Olódùmarè bojú àánú wo Nàìjíría.

Facebook Comments Box
ADVERTISEMENT
ADVERTISEMENT

Related

ADVERTISEMENT
Adeola Olanrewaju

Adeola Olanrewaju

Next Post
Baálẹ̀ Areola àti ọba AbdulSemiu Ogunjobi

GÓMÌNÀ DAPO ABIODUN JÁWĚ JÓKÒÓJẸ́ FÚN ỌBA OGUNJOBI.

Recommended

TUFACE ṢE ÌGBÉYÀWÓ ÌBÍLẸ̀ PẸ̀LÚ OLÓLÙFẸ́ RẸ̀ TITUN; NATASHA OSAWURU.

TUFACE ṢE ÌGBÉYÀWÓ ÌBÍLẸ̀ PẸ̀LÚ OLÓLÙFẸ́ RẸ̀ TITUN; NATASHA OSAWURU.

10 months ago
A KÒ FI ÀÀYÈ GBA NÍNA AKẸ́KỌ̀Ọ́ – ÌJỌBA ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ.

A KÒ FI ÀÀYÈ GBA NÍNA AKẸ́KỌ̀Ọ́ – ÌJỌBA ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ.

1 year ago

Popular News

  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ TI MÚ IKỌ̀ ONE-CHANCE NÍ IDIMU, ÈKÓ.

    Ọwọ́ tẹ ikọ̀ one-chance ní kebbi.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • OLÓLÙFẸ́ DA ÁSÍÌDÌ SÍ ỌMỌṢẸ́ Ọ̀RẸ́BÌNRIN RẸ̀ LÁRA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ILÉ ẸJỌ́ PÀṢẸ KÍ GBOGBO DÚKÌÁ SYLVA Ó DI TI ÌJỌBA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • AYÉ LÓ ṢE ỌLỌ́PÀÁ TÓ YÌNBỌN PA ÈÈYÀN.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ ṢE ÀWÁRÍ AYÉDÈRÚ ILÉ ỌMỌ ALÁÌNÍYÀÁ.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0

Connect with us

ADVERTISEMENT

Newsletter

Lorem ipsum dolor sit amet, consectetuer adipiscing elit. Aenean commodo ligula eget dolor.
SUBSCRIBE

Category

Site Links

  • Register
  • Log in
  • Entries feed
  • Comments feed
  • WordPress.org

About Us

We bring you the best Premium WordPress Themes that perfect for news, magazine, personal blog, etc. Check our landing page for details.

  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
  • Àṣà Yorùbá
  • Ìgbé-Ayé
  • Ìdánilárayá
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

Welcome Back!

Login to your account below

Forgotten Password? Sign Up

Create New Account!

Fill the forms below to register

All fields are required. Log In

Retrieve your password

Please enter your username or email address to reset your password.

Log In
No Result
View All Result
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

This website uses cookies. By continuing to use this website you are giving consent to cookies being used. Visit our Privacy and Cookie Policy.