Ọmọ oṣù méje jóná ní Èkó – Ọmọ oṣù méje kan tó ṣì ń rá kòrò ti jóná kú nínú ijàm̀bá iná tó ṣẹlẹ̀ ní Èkó.
Ìsọ̀ kékéré kan tí wọ́n ti ń ta afẹ́fẹ́ gáàsì ìdáná ni ó dédé gbaná, ọmọ yìí wà nínú ìsọ̀ yìí lásìkò ìṣẹ̀lẹ̀ náà wọn kò sì rí I gbé jáde títí tó fi jóná kú nítorí iná náà tó pọ̀. – Ọmọ oṣù méje jóná ní Èkó.
Agbègbè Egan ní Igando, Èkó ni ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ti ṣẹ̀. Ìsọ̀ onídìrí kan wà ní ẹ̀gbẹ́ ìsọ̀ gáàsì yìí, ẹni tó ń ta gáàsì náà ni ọmọbìnrin kan tó ti jẹ́ ọ̀dọ́langba, òun náà wà nínú ìsọ̀ náà lásìkò tí iná náà gbà.
Ọmọ ẹ̀kọ́ṣẹ́ onídìrí yìí ni ìyá ọmọ oṣù méje tó kú náà, ọmọ ẹni tó ni ìsọ̀ gáàsì ni ó lọ bá ṣéré nínú ìsọ̀ náà ṣáájú ìṣẹ̀lẹ̀ náà. – Ọmọ oṣù méje jóná ní Èkó.
Bí iná ṣe sọ ni ọ̀dọ́bìnrin náà sá jáde tó sì fi ọmọ ìrákòrò náà sílẹ̀, òun náà fi ẹsẹ̀ jóná díẹ̀.
Ìyá ọmọ yìí kọ́ dákú kí àwọn èèyàn tó jí i sáyé padà. Wọn kò rí ọmọ náà gbé jáde kò sí ẹni tó le sún mọ́ iná náà. Iná yìì jó ìsọ̀ gáàsì náà àti ìsọ̀ onídìrí náà gúrúgúrú.- Ọmọ oṣù méje jóná ní Èkó.
N ó wọ Akwete bí ọkọ mi bá wọlé ẹlẹ́ẹ̀kejì – Oluremi Tinubu.
Aya ààrẹ wa; Oluremi Tinubu ti so pé aṣọ akwete ni òun yóò bẹ̀rẹ̀ sí ní wọ̀ gbàrà tí ọkọ rẹ̀ bá wọlé sípò ààrẹ fún sáà kejì lọ́dún 2027.
Oluremi sọ èyí nígbà tó ṣe àbẹ̀wò sí ìlú tí wọ́n ti ń hun aṣọ akwete ní ìpínlẹ̀ Abia, bílíọ́nù méjì náírà ni ó fi ṣe ìrànwọ́ fún wọn kí láti fi gbé híhun akwete lárúgẹ.
Ó wí pé òun nífẹ̀ẹ́ sí aṣọ akwete nítorí pé ó fúyẹ́ lára ó sì rọrùn láti wọ̀. Òun ni n o fi máa rán ìró àti bùbá lọ́gán tí ọkọ mi bá wọlé sáà kejì.
Aya ààrẹ gbé oríyìn fún àwọn obìnrin tó ń hun aṣọ náà níbẹ̀ pé wọ́n kú iṣẹ́ takuntakun tí wọn kò jẹ́ kí iṣẹ́ àtìrandírán ó parun tí wọ́n sì tún ń fi lé ọmọ lọ́wọ́. Ó rọ àwọn ọmọ Nàìjíríà láti máa wọ akwete kí ọrọ̀ ajẹ́ ó tún le gbèrú síi.
Bákan náà ló dúpẹ́ lọ́wọ́ Gómìnà ìpínlẹ̀ Abia; Alex Otti, ó ṣe àpèjúwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi èèyàn ire. Ìyàwó Alex náà ṣèèyàn, mo ti pè é ṣaájú pé mo fẹ́ mọ̀ nípa aṣọ akwete yìí mo sì fẹ́ rí àwọn tó wà nídìí rẹ̀.
Inú mi dùn láti wà níbi lónìi, èyí ni ara ìtàn tí a ó sọ lọ́la – Oluremi Tinubu.

Ayédèrú ilé ìwé gíga ní Èkó.
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́tàdínláàdọ́fà (107) ni wọ́n gbà kalẹ̀ ní ayédèrú ilé ìwé gíga tó fìkàlẹ̀ sí Èkó.
Àjọ ẹ̀ṣọ́ aláàbò abẹ́lé NSCDC ló ṣe àwárí ilé ìwé gíga yìí tí wọ́n ń fi ẹkọ fọnná fún àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n sì ń fi wọ́n ṣe sogún dogójì.
Imeke ní Olorunda, ìpínlẹ̀ Èkó ni ilé ìwé yìí gúnwà sí, wọn kò ní ìwé ìforúkọsílẹ̀ wọn kò sì í ìwé àṣẹ. Ìlérí àti lọ kàwé lókè òkun ni wọ́n ń ṣe fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wọn tí wọ́n sì ń fi wọ́n ṣe ètò sogún dogójì.
Alukoro fún àjọ NSCDC; Oluwaseun Abolurin ló fi ọ̀rọ̀ yìí tó àwọn akọ̀ròyìn létí. Abolurin wí pé ọjọ́ Ajé ni àwọn ẹ̀ṣọ́ NSCDC j́de láti ṣiṣẹ́ wọn kí wọ́n tó kan ilé ìwé yìí.
Wọ́n bá àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́tàdínláàdọ́fà níbẹ̀ wọ́ sì gbà wọ́n kalẹ̀. Àwọn afurasí mẹ́fà tí ọjọ́ orí wọn wà láàrin ọdún mẹ́rinlélógún sí ọgbọ̀n ni ọwọ́ wọn tẹ̀.
Adarí àjọ NSCDC ìpínlẹ̀ Èkó; Adedotun Keshinro ti pàṣẹ kí wọn ó kó àwọn afurasí mẹ́fà àti ẹ̀rí tí wọ́n bá fún àjọ ICPC àti àwọn tọ́rọ̀ kàn fún ìwádìí.
Keshiro ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn ọmọ tí wọ́n fẹ́ wọ ilé ẹ̀kọ́ láti ṣe ìwádìí fínní kí wọ́n sì fi ojú balẹ̀ dáadáa kí wọ́n má kó sí ọwọ́ àwọn ọ̀daràn báyìí.

Ìsìnkú Toba wáyé ní Èkó.
Wọ́n ti sin òkú akọ̀wé àjọ NURTW tó kú náà; Toba Ajiboye tí àwọn èèyàn mọ̀ sí Toba ìjayà sí ilé rẹ̀ tó wà ní Ketu, Èkó.
Ọmọ, ẹbí, ará, ọ̀rẹ́, ojúlùmọ̀ àti àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ ni wọ́n pé jọ láti ṣe ẹ̀yẹ ìkẹyìn fún Toba, ẹsẹ̀ kò gbèrò níbi ìsìnkú rẹ̀.
Ikú Toba:
Àwọn agbébọn ni wọ́n dá ọkọ̀ Toba lọ́nà nígbà tí ó ń darí lọlé tí wọ́n sì yin ìbọn mọ́ ọkọ̀ rẹ̀, ìbọn náà pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ó dá gbogbo ara ọkọ̀ rẹ̀ lu. Toba àti àwọn ẹmẹ̀wàá rẹ̀ farapa àmọ́ kò kú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
Àdúgbò rẹ̀ ní Fadeyi ni Toba Ajiboye ti ń bọ̀ lálẹ́ ọjọ́ Àìkú kí wọ́n tó dá a lọ́nà. Ijaya ni ìnagijẹ Toba, òun ni akọ̀wé fún àjọ NURTW, ìyẹn àjọ àwọn tó ń ṣètò ibùdókọ̀ gbogbo.
Toba àti àwọn ẹmẹ̀wàá rẹ̀ kò kú lójú ẹsẹ̀ àmọ́ Toba padà kú sí ilé ìwòsàn lọ́jọ́ kẹta.
Alága àjọ NURTW; Mustapha Adewale tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí Sego banújẹ́ lórí ikú Toba, ó wí pé òfò ńlá ni ikú rẹ̀ jẹ́ fún àjọ náà nítorí ipa ribiribi tó ń kó nínú àjọ náà.
Ìhà tí àwọn èèyàn kọ sí ikú Toba:
Ọ̀pọ̀ lo gbàgbọ́ pé ikú Toba lọ́wọ́ kan ejò nínú, wọ́n tilẹ̀ wí pé níṣe ni wọ́n padà lọ pa á sílé ìwòsàn àmọ́ a kò le fi ìdí èyí múlẹ̀.
Lójú òpo ayélujára, oríṣìí àríwísí ni àwọn èèyàn kọ, ẹnìkan kọ ọ́ pé ẹni tó pa Toba wà láàrín wọn níbi ìsìnkú náà bẹ́ẹ̀ sì ni ọ̀pọ̀ ń gbé àwọn tó pa á ṣépè.

