ADVERTISEMENT
  • About
  • Contact
Monday, June 1, 2026
  • Login
  • Register
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
No Result
View All Result
Home Ààyè Olóòtú

Àwọn agbébọn ya wọ ààfin ní Kwara.

Wọ́n kó àwọn ìyàwó àti ọmọ lọ.

by Adeola Olanrewaju
June 1, 2026
in Ààyè Olóòtú, Ìgbé-Ayé, Ìrìn Àjò, Ìròyìn, Ìròyìn Agbègbè, Ọ̀rọ̀ Ààbò, Ọ̀rọ̀ ìdílé, Òṣèlú
0
Àwọn agbébọn ya wọ ààfin ní Kwara.
0
SHARES
0
VIEWS
Pín Lórí FacebookPín Lórí ThreadsPín Lórí TwitterPín Lórí Bluesky
ADVERTISEMENT
ADVERTISEMENT

Àwọn agbébọn ya wọ ààfin ní Kwara: Àwọn agbébọn ti ṣe ìkọlù sí ààfin emir ìlú Yashikira tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Baruten, ìpínlẹ̀ Kwara.
Òru gànjọ́ ni wọ́n ya wọ ààfin Alhaji Umar Seriki, wọ́n dáná sun abala kan nínú ààfin náà, wọ́n kó àwọn ìyàwó rẹ̀ mẹ́ta, àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́rin pẹ̀lú àwọn aráàlú wọgbó lọ.
Aago méjìlá òru ni àwọn agbébọn náà ya wọ ìlú Yashikira lógúnlógún lọ́gbọ̀nlọ́gbọ̀n, wọ́n yìnbọn lákọlákọ wọ́n sì mórí lé ààfin àti àgọ́ ọlọ́pàá kan tó wà nítòsí ibẹ̀.
Wọ́n ṣe ìkọlù sí àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ìbílẹ̀ tó ń ṣọ́ ààfin náà wọ́n sì wọ inú ààfin lọ pitú ọwọ́ wọn.
Àwọn aráàlú sá kíjokíjo nígbà ìkọlù náà, àwọn mìíràn tilẹ̀ farapa níbi tí wọ́n ti ń du ẹ̀mí wọn. A kò tíì le sọ pàtó iye aráàlú tí wọ́n kó lọ.
Ọ̀kadà ni àwọn agbébọn náà ṣí wọlé, lẹ́yìn tí wọ́n kó àwọn èèyàn tán ni wọ́n sọ iná sí ààfin, wọ́n dáná sun gbogbo ọkọ̀ pẹ̀lú.
Bákan náà ni wọ́n ṣe ìkọlù sí àgọ́ ọlọ́pàá tó wà nílùú náà, wọ́n ṣe àwọn ọlọ́pàá náà bí ọṣe ṣe ń ṣojú. – Àwọn agbébọn ya wọ ààfin ní Kwara.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara fèsì láti ẹnu agbẹnusọ wọn; Adetoun Ejire-Adeyemi, ó bu ẹnu àtẹ́ lu ìkọlù náà. Ó wí pé èèyàn mẹ́wàá ni wọ́n kó lọ mọ́ àwọn ìyàwó àti ọmọ Emir Seriki.
Adeyemi wí pé àwọn ọlọ́pàá àgọ́ tí wọ́n kọlù náà ṣe akin, wọ́n kojú àwọn agbébọn náà wọ́n sì dáàbò bo àgọ́ náà.
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà ti pàṣẹ kí àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò abẹ́lé, ti ìbílẹ̀, àwọn ológun àti àwọn ọlọ́pàá ó kán lu igbó kí wọ́n sì gba àwọn ẹni náà kalẹ̀.
Emir Seriki kọ́ ni ọba àkọ́kọ́ tí wọn yóò ṣe ìkọlù sí ní Kwara, Aniwo ti Aaafin náà lo oṣù kan gbáko ní àkàtà wọn kí wọ́n tó dá a sílẹ̀:
Ọba Aniwo ti ìlú Aaafin ní ìjọba ìbílẹ̀ Ifelodun, ìpínlẹ̀ Kwara ti wà ní àkàtà àwọn ajínigbé àti àrẹ̀mọ rẹ̀.
Oba Simeon Olaonipekun àti ọmọ rẹ̀ Olaolu tó jẹ́ Agùnbánirọ̀ ni àwọn ajínigbé náà gbé lọ nígbà tí wọ́n ṣe ìkọlù sí ààfin rẹ̀.
Nǹkan bíi aago mẹ́jọ alẹ́ àìsùn ọdún ni àwọn agbébọn náà ya wọ ààfin Aniwo tí wọ́n sì ṣíná ìbọn bolẹ̀
Ìbọn ni wọ́n fi já ilẹ̀kùn ààfin wọlé, wọ́n kó jìnnìjìnnì bo gbogbo ààfin, ariwo ọba ni wọ́n ń ké tantan ó sì jáde sí wọn.
Wọ́n bèèrè olorì rẹ̀ náà àmọ́ ìbọn ti bà á lápá lásìkò tí wọ́n ń fi ìbọn já ilẹ̀kùn, ọmọ rẹ̀ Olaolu ni wọ́n nawọ́ gán nígbà tí wọn kò le mú olorì mọ́.
Òṣìṣẹ́ inú ààfin kan ló ṣe àlàyé pé òun rí wọn dáadáa níbi tí òun sá pamọ́ sí, wọ́n tó mẹ́wàá níye, èdè Gẹ̀ẹ́sì ẹnu wọn sì já geere. Kábíèsí àti aya rẹ̀ ni wọ́n bá wá wọn kò rí ti ẹlòmíràn rò. – Àwọn agbébọn ya wọ ààfin ní Kwara:
Àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ìbílẹ̀ kò le kojú wọn nítorí wọn kò ju méjì lọ lálẹ́ ọjọ́ náà àti pé ìbọn ọwọ́ àwọn ajínigbé náà le ju tiwọn lọ. – Àwọn agbébọn ya wọ ààfin ní Kwara.
Alẹ́ ọjọ́ náà ni wọ́n gbé olorì lọ sí ilé ìwòsàn nígbà tí wọ́n lọ tán, láti ìgbà tí wọ́n sì ti gbé ọba àti ọmọ rẹ̀, wọn kò kàn sí ẹnikẹ́ni.
Wọ́n ti fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn ẹ̀ṣọ́ alààbò ìbílẹ̀ ní agbègbè létí àwọn ọlọ́pàá náà sì ti gbọ́ síi.
Alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara; Adetoun Ejire-Adeyemi wí pé àwọn ti gba ìfisùn lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà àwọn sì ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lórí rẹ̀.
Odidi oṣù kan ni Aniwo lò ní àkàtà wọn kí ó tó gba ìtúsílẹ̀ lẹ́yìn òbítíbitì owó ìtúsílẹ̀.
Lára àwọn ìkọlù tó ti wáyé ní ìpínlẹ̀ Kwara ni:
Ọjọ́ àìkú, ọjọ́ kọkànlélógún, osu Erena ni àwọn agbébọn mẹ́wàá ṣàdédé ya wọ ibùdókọ̀ Ilesa Baruba tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Baruten, ìpínlẹ̀ Kwara. Ilé ìgbafẹ́ kan tó wà ní ibùdókọ̀ yìí ni wọ́n ṣínà ìbọn bò tí wọ́n sì pa àwọn èèyàn mẹ́fà nígbà tí àwọn èèyàn méjì mìíràn farapa.
Ilé ìgbókùúsí Baruba ni wọ́n kó àwọn tó kú náà lọ nígbà tí wọ́n kó àwọn tó farapa náà lọ sí ilé ìwòsàn.
Aago mẹ́sàn-án àbọ̀ alẹ́ ni wọ́n ṣe ìkọlù ti ibùdókọ̀ Baruba yìí, nígbà tó di aago mọ́kànlá àbọ̀ alẹ́ ọjọ́ kannáà, àwọn ikọ̀ agbésùnmọ̀mí mìíràn tún ṣe ìkọlù sí Kemanji ní ìjọba ìbílẹ̀ Kaiama. Àwọn ọdẹ ìbílẹ̀ kojú wọn wọ́n sì mú mẹ́ta balẹ̀ nínú wọn àmọ́ àwọn náà yin ọdẹ kan níbọn ó sì padà kú sí ilé ìwòsàn.
Yusuf Samba ni orúkọ ọdẹ tí wọ́n yìnbọn pa náà, òun àti ikọ̀ rẹ̀ ni wọ́n dá àwọn agbésùnmọ̀mí náà lọ́wọ́ kọ́ tí wọ́n sì fi ìbọn ṣe mẹ́ta léṣe nínú wọn.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara sọ̀rọ̀ láti ẹnu agbẹnusọ wọn; Toun Ejire-Adeyemi pé àwọn gba ìfisùn méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nípa ìkọlù tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Kwara, wọ́n ní ọwọ́ ti tẹ èèyàn kan tó ń fún àwọn agbésùnmọ̀mí lọ́wọ́. Toun wí pé ẹni náà ti jẹ́wọ́ pé òun ló ń fún àwọn agbésùnmọ̀mí lọ́wọ́ tí wọ́n fi wá ṣe àwọn ìkọlù náà.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá sọ nínú ọ̀rọ̀ wọn pé àwọn ti ṣe àlékún àwọn ọlọ́pàá agbègbè náà, àwọn sì ti dá àlàáfíà padà sípò. Wọ́n ní ẹni tọ́wọ́ bà náà yóò wúlò púpọ̀ fụ́n ìwádìí ìkọlù yìí wọ́n sì ṣe ìlérí pé àwọn yóò mú àwọn tó ṣe ìkọlù náà.
Ìpínlẹ̀ Kwara ti di ìpínlẹ̀ ikú-wá-rà báyìí, bíi àkàrà àti ẹ̀kọ ni wọ́n ń fọ́n ikú kiri ìpínlẹ̀ náà.

Facebook Comments Box
ADVERTISEMENT

Related

Tags: #iweiroyinyoruba#ìwéròyìnyorùbá #NewsOnline#newsfeed#newstoday#newstodaysnews#TRENDINGNEWSTODAYbanditattackbanditsÌròyìnkwaraattackkwarapalaceattackkwarastatemurdertrending
ADVERTISEMENT
Adeola Olanrewaju

Adeola Olanrewaju

Leave a Reply Cancel reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Recommended

ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ Logo

ÌYÀWÓ DÁNÁ SUN ỌKỌ RẸ̀ TÓ JẸ́ OLÓGUN.

8 months ago
Ìròyìn Jákèjádò.

Ìròyìn Jákèjádò.

1 year ago

Popular News

  • Àwọn agbébọn ya wọ ààfin ní Kwara.

    Àwọn agbébọn ya wọ ààfin ní Kwara.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • Ọwọ́ tẹ ikọ̀ one-chance ní kebbi.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • OLÓLÙFẸ́ DA ÁSÍÌDÌ SÍ ỌMỌṢẸ́ Ọ̀RẸ́BÌNRIN RẸ̀ LÁRA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ILÉ ẸJỌ́ PÀṢẸ KÍ GBOGBO DÚKÌÁ SYLVA Ó DI TI ÌJỌBA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • AYÉ LÓ ṢE ỌLỌ́PÀÁ TÓ YÌNBỌN PA ÈÈYÀN.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0

Connect with us

ADVERTISEMENT

Newsletter

Lorem ipsum dolor sit amet, consectetuer adipiscing elit. Aenean commodo ligula eget dolor.
SUBSCRIBE

Category

Site Links

  • Register
  • Log in
  • Entries feed
  • Comments feed
  • WordPress.org

About Us

We bring you the best Premium WordPress Themes that perfect for news, magazine, personal blog, etc. Check our landing page for details.

  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
  • Àṣà Yorùbá
  • Ìgbé-Ayé
  • Ìdánilárayá
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

Welcome Back!

Login to your account below

Forgotten Password? Sign Up

Create New Account!

Fill the forms below to register

All fields are required. Log In

Retrieve your password

Please enter your username or email address to reset your password.

Log In
No Result
View All Result
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

This website uses cookies. By continuing to use this website you are giving consent to cookies being used. Visit our Privacy and Cookie Policy.