ADVERTISEMENT
  • About
  • Contact
Sunday, May 31, 2026
  • Login
  • Register
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
No Result
View All Result
Home Ìròyìn Tó Gbòde Ìròyìn Jákèjádò

ILÉ ẸJỌ́ PÀṢẸ KÍ GBOGBO DÚKÌÁ SYLVA Ó DI TI ÌJỌBA.

Àti àwọn ìròyìn mìíran tó gbòde.

by Adeola Olanrewaju
May 6, 2026
in Ìròyìn Jákèjádò, Ìròyìn Tó Gbòde
0
ILÉ ẸJỌ́ PÀṢẸ KÍ GBOGBO DÚKÌÁ SYLVA Ó DI TI ÌJỌBA.
0
SHARES
4
VIEWS
Pín Lórí FacebookPín Lórí ThreadsPín Lórí TwitterPín Lórí Bluesky
ADVERTISEMENT

Ilé ẹjọ́ pàṣẹ kí gbogbo dúkìá sylva ó di ti ìjọba – Ilé ẹjọ́ gíga Abuja ti pàṣẹ kí gbogbo dúkìá tó wà lábẹ́ orúkọ Timipre Sylva ó di ti ìjọba. Sylva ni mínísítà tẹ́lẹ̀rí fún epo rọ̀bì, àjọ tó ń gbógun ti ìwà àjẹbánu EFCC ni ó wọ́ ọ tuurutu lọ sí ilé ẹjọ́, lẹ́yìn gbogbo atótónu àti àwíjàre, adájọ́ Obiora Egwuatu pàṣẹ kí gbogbo ogún rẹ̀ ó di ti ìjọba àpapọ̀.
Adájọ́ fún Obiora lọ́jọ́ mẹ́rìnlá gbáko láti gbé ẹ̀rí àti àwíjàre wá sí iwájú adájọ́ ìdí tí kò fi yẹ kí wọn ó gbé ẹsẹ̀ lé ohun ìní rẹ̀, lẹ́yìn èyí ni àṣẹ yóò jáde láti ilé ẹjọ́.
Ẹ̀sùn tí àjọ EFCC fi kan Obiora ni pé ó kó owó jẹ nígbà tó wà ní ipò náà àti pé gbogbo àwọn ohun ìní rẹ̀ ni ó fi ọ̀nà àlùmọ̀kọ́rọ́yí kó jọ- Ilé ẹjọ́ pàṣẹ kí gbogbo dúkìá sylva ó di ti ìjọba

TONY ELUMELU FI ỌLỌ́PÀÁ GBÉ AKẸ́KỌ̀Ọ́ JAMB KAN.

Olówó pọ̀rọ̀kú nnì; Toni Elumelu ti fi ọlọ́pàá gbé ọ̀dọ́mọkùnrin kan lórí ohun tó kọ sí ojú òpó X rẹ̀. Ọmọ ọdún méjìdínlógún ni ọmọ náà, ó ṣẹ̀ṣẹ̀ kọ ìdánwò àṣewọ ilé ìwé gíga JAMB ni.
Kingsley Akunemeihe ni orúkọ ọmọ náà, ó ń bọ̀ láti ibi tó ti lọ kọ ìdánwò rẹ̀ ni àwọn ọlọ́pàá hè é bíi ìgbín, ọjọ́ kẹwàá rèé tó ti wà ní àtìmọ́lé.
Ohun tí ọmọ náà ṣe ni pé ó kọ ọ́ sí ojú òpó X rẹ̀ pé Tony Elumelu àti ìyàwó rẹ̀ Awele ti túká. Ẹ̀gbọ́n Kingsley rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Tony pé ọmọdé ni Kingsley ó ṣẹ̀ṣẹ̀ pé ọdún méjìdínlógún ni. Ó ṣe àlàyé pé Kingsley kọ́ ni ó gbé ìkéde náà jáde, ó dàá kọ lójú òpó ẹlòmíràn ni. Lẹ́yìn náà ni ó mú ìkéde náà kúrò tó sì tọrọ àforíjìn pé ìròyìn òfegèé ni ìròyìn náà.
Ẹ̀gbọ́n rawọ́ ẹ̀bẹ̀ pé kí wọn ó dákun dá Kingsley sílẹ̀ láti ọjọ́ mẹ́wàá sẹ́yìn, ó tọrọ àforíjìn lọ́wọ́ Tony Elumelu.

SISI ALAGBO TỌRỌ ÀFORÍJÌN LỌ́WỌ́ GBOGBO YÍN.

Arábìnrin Eniola Fagbemi tí gbogbo àwọn èèyàn mọ̀ sí Sisi alagbo ti tọrọ àforíjìn lọ́wọ́ ẹgbẹ́ alágbo àti ẹ̀yin ọmọ orílẹ-ède Nàìjíríà lápapọ̀. Sisi bèèrè fún ìdáríjìn ẹ̀ṣẹ̀ lórí fọ́nrán ìbálòpọ̀ òun, ọkọ rẹ̀ àti obìnrin kan tó gbòde.
Ọjọ́ Ajé ni fọ́nrán náà lu síta tó sì ti dá họ́wùhọ́wù sílẹ̀ lórí ìtàkùn ayélujára. Láti ìgbà náà ni ìtàkùn ti gbaná tí ọ̀pọ̀ sì ń ṣe fọ́nrán náà ní àtagbà.
Àbùkù náà pọ̀ fún sísí tó bẹ́ẹ̀ gẹ́, òun àti ọkọ rẹ̀ tọrọ ìdáríjìn, ó ní òun kò le sùn láti ìgbà tí fọ́nrán náà ti lu síta. Eniola ṣe fọ́nrán ìtọrọ ìdáríjìn, ó kúnlẹ̀ ó sì rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí àwọn ẹgbẹ́ alágbo, àwọn ẹbí rẹ̀ àti gbogbo àwọn ọmọ Nàìjíríà lápapọ̀.
Eniola ní òun kábàámọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ó ní òun kò ní àwíjàre kankan lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà rárá. Ó tọrọ àforíjìn lọ́wọ́ gbogbo abiyamọ ayé kí wọn ó jèbùrẹ́. Ó wí pé ‘ọmọ yín ni mo jẹ́ ẹ̀yin ọmọ Nàìjíríà, àṣìṣe ńlá ni mo ṣe mo sì kábàámọ̀ rẹ̀. Mi ò ní àwíjàre kankan fún àṣemáṣe mi yìí, àṣìṣe ni, ẹ dáríjìn mí, mo bẹ̀ yín lórúkọ Ọlọ́run’

CARTER EFE LU PORTABLE LÁLÙBOLẸ̀.

Níbi ìdíje ẹ̀ṣẹ́ kíkù láàrín àwọn gbájumọ̀ tó wáyé lálẹ́ ọjọ́ Àbámẹ́ta ni Carter Efe ti fi yé Portable ọmọ Ọlálọmí pé ẹgbẹ́ baba kọ́ ni ọmọ. Ipele mẹ́ta ni ìdíje náà tí ó sì nà án ní ẹ̀ẹ̀mẹtẹ̀ẹ̀ta. Èyí ló mú kí Portable ó pàdánù ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi ààrẹ abẹ̀ṣẹ́-kù-bí-òjò láàrín àwọn gbajúmọ̀ tí Carter Efe sì jẹ́ ààrẹ titun báyìí.
Ṣaájú àsìkò yìí ni Portable ti na Charles Okocha àti Speed Darlington tó sì ti lé fùrùkọkọ pé òun yóò na Carter Efe náà.
Carter Efe náà ti fèsì nígbà náà pé òun kìí ṣe Charles tàbí Speed tí ó lù nínú àwọn ìdíje àtẹ̀yìnwá, ó ní òun yóò fi ẹ̀yìn rẹ̀ gbolẹ̀ ó sì ṣe bẹ́ẹ̀. Ó borí Portable ní ìpele mẹ́ta tó wà nínú ìdíje náà ó sì gba adé orí rẹ̀.

AKẸ́KỌ̀Ọ́ MẸ́TA ÀTI OLÙKỌ́ KAN BÁ ÌJÀM̀BÁ ỌKỌ̀ LỌ.

ADVERTISEMENT

Akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé gíga Calabar àti olùkọ́ wọn kan ti pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàm̀bá ọkọ̀. Ìjàm̀bá náà wáyé nígbà tí ọkọ̀ gbọọrọ tó kó àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà fi orígbárí pẹ̀lú ọkọ̀ àjàgbé eléjò.
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ mẹ́rìnlélógún ló wà nínú ọkọ̀ náà àti olùkọ́ kan, wọ́n ń darí bọ̀ láti ibi ètò kan ní Uyo ni wọ́n ṣe àgbákò ìjàm̀bá náà. Mẹ́ta ló kú nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà àti olùkọ́ wọn nígbà tí àwọn yòókù wà ní ilé ìwòsàn.
Kété tí ìjàm̀bá náà wáyé ni awakọ̀ àjàgbé náà ti fi ẹsẹ̀ fẹ́ẹ, àwọn ọlọ́pàá ti ń wá a báyìí.
Ọ̀gá iléèwé náà banújẹ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ó bá àwọn mọ̀lẹ́bí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ náà kẹ́dùn.

AFÁRÁ MORO TI JÁ LULẸ̀ NÍ KWARA.

Afárá Moro tó wà ní ojú ọ̀na márosẹ̀ Ilorin sí Igbeti já lulẹ̀ ní ìdájí yìí. Afárá yìí já mọ́ ọkọ̀ àjàgbé kan lábẹ́ ó sì gbé e mìn.
Àwọn alájàpá tí wọ́n lọ ra ọjà kò rí ọ̀nà gbà kọjá, wọ́n fi ẹ̀dùn ọkàn wọn hàn pé ọjà àwọn yóò bàjẹ́ mójú ọ̀nà ni látàrí pé wọn kò le gbé e dé ìlú.
Kọmíṣọ́nà fún àkànṣe iṣẹ́; Abdulquawiy Olododo fèsì pé kí àwọn ọkọ tó bá ń bọ̀ ó ṣẹ́rí gba ọ̀na ibòmíràn.
Bákan náà ni wọ́n ti rán àwọn amójú ẹ̀rọ lọ sí ibẹ̀ láti bẹ̀rẹ̀ àtúnṣe afárá náà.

OBÌNRIN KAN FẸ́ PA ỌMỌ RẸ̀ NÍ ÈKÓ.

ADVERTISEMENT

Fọ́nrán kan ti gbòde nínú èyí tí a ti rí obìnrin kan tó yọ ọ̀bẹ sí ọmọ rẹ̀ tó sì fẹ́ pa á. Obìnrin yìí lu ọmọ rẹ̀ títí, ó fún un lọ́rùn ó sì tún yọ ọ̀bẹ tìí.
Ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbòn ni ọmọ yìí, ìyá rẹ̀ kìí mọ́lẹ̀ ó sì lù ú bíi kí ó kú. Lẹ́yìn náà ló gbìyànjú àtigún un lọ́bẹ pa.
Aráalé wọn ló ká fọ́nrán náà tó sì fi léde. Kò tíì sí àlàyé kan pàtó lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ láàrín ìyá àti ọmọ. Bàbá kan ló gba ọ̀bẹ náà lọ́wọ́ rẹ̀ tí kò fi gún un pa.
Àwọn èèyàn ti ké sí ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá láti wádìí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí.

Facebook Comments Box

Related

Tags: #iweiroyinyoruba#ìwéròyìnyorùbá #NewsOnline#newsfeed#newsupdates#trendingpostAfojúsùn Iwe Iroyin YorubaÌròyìn Tó GbòdeIwe Iroyin Yorubanewsinyorubanewsonlinetrending
ADVERTISEMENT
Adeola Olanrewaju

Adeola Olanrewaju

Next Post
Olólùfẹ́ da ásíìdì sí ọmọṣẹ́ ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ lára nítorí ó kọ̀ ọ́ sílẹ̀.

OLÓLÙFẸ́ DA ÁSÍÌDÌ SÍ ỌMỌṢẸ́ Ọ̀RẸ́BÌNRIN RẸ̀ LÁRA.

Leave a Reply Cancel reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Recommended

Walimah

7 months ago
ÀWỌN OLỌṢÈLÚ LÓ Ń FÚN ÀWỌN AGBÉSÙNMỌ̀MÍ LỌ́WỌ́ – GÓMÌNÀ ÌPÍNLẸ̀ BORNO.

ÀWỌN OLỌṢÈLÚ LÓ Ń FÚN ÀWỌN AGBÉSÙNMỌ̀MÍ LỌ́WỌ́ – GÓMÌNÀ ÌPÍNLẸ̀ BORNO.

1 year ago

Popular News

  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ TI MÚ IKỌ̀ ONE-CHANCE NÍ IDIMU, ÈKÓ.

    Ọwọ́ tẹ ikọ̀ one-chance ní kebbi.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • OLÓLÙFẸ́ DA ÁSÍÌDÌ SÍ ỌMỌṢẸ́ Ọ̀RẸ́BÌNRIN RẸ̀ LÁRA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ILÉ ẸJỌ́ PÀṢẸ KÍ GBOGBO DÚKÌÁ SYLVA Ó DI TI ÌJỌBA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • AYÉ LÓ ṢE ỌLỌ́PÀÁ TÓ YÌNBỌN PA ÈÈYÀN.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ ṢE ÀWÁRÍ AYÉDÈRÚ ILÉ ỌMỌ ALÁÌNÍYÀÁ.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0

Connect with us

ADVERTISEMENT

Newsletter

Lorem ipsum dolor sit amet, consectetuer adipiscing elit. Aenean commodo ligula eget dolor.
SUBSCRIBE

Category

Site Links

  • Register
  • Log in
  • Entries feed
  • Comments feed
  • WordPress.org

About Us

We bring you the best Premium WordPress Themes that perfect for news, magazine, personal blog, etc. Check our landing page for details.

  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
  • Àṣà Yorùbá
  • Ìgbé-Ayé
  • Ìdánilárayá
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

Welcome Back!

Login to your account below

Forgotten Password? Sign Up

Create New Account!

Fill the forms below to register

All fields are required. Log In

Retrieve your password

Please enter your username or email address to reset your password.

Log In
No Result
View All Result
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

This website uses cookies. By continuing to use this website you are giving consent to cookies being used. Visit our Privacy and Cookie Policy.