ADVERTISEMENT
  • About
  • Contact
Sunday, May 31, 2026
  • Login
  • Register
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
No Result
View All Result
Home Ààyè Olóòtú

NÍTORÍ IGBA NÁÍRÀ NI WỌ́N ṢE PA AYOMIDE NÍ OGUN.

Aboy gún Ayomide pa nítorí igba náírà ní ogun.

by Adeola Olanrewaju
April 18, 2026
in Ààyè Olóòtú, Ìgbé-Ayé, Ìròyìn, Ìròyìn Agbègbè, Ọ̀rọ̀ Ààbò, Ọ̀rọ̀ ìdílé
0
ÌJỌBA ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ TI DÁ ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ NÁÀ SÍLẸ̀. - Asia ile ise olopaa
0
SHARES
2
VIEWS
Pín Lórí FacebookPín Lórí ThreadsPín Lórí TwitterPín Lórí Bluesky
ADVERTISEMENT

Nítorí igba náírà ni wọ́n ṣe pa ayomide ní ogun: Ayomide àti ẹnìkan tí wọ́n ń pè ní Aboy jọ ní gbólóhùn asọ̀ lórí igba náírà, Aboy ò ṣe méní ṣe méjì, ó fa ọ̀bẹ yọ ó sì fi gún Ayomide pa.Àlàyé ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó tẹ̀ wá lọ́wọ́ ni pé lọ́jọ́ kìíní, oṣù Igbe ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹ̀ ní ilé iṣẹ́ búlọ́kù Ori Ade, ojú ọ̀nà Alaka ní Ewupe ni ó wà.
Lọ́jọ́ náà, Ayomide dé ibi iṣẹ́ rẹ̀ tó wà ní ẹgbẹ́ ilé iṣẹ́ búlọ́kù náà, Aboy wá bá a níbẹ̀ ọ̀rọ̀ wọn sì dìjà tó fi di pé ó gún un pa.
Moyo; ẹnikàn tó wà ní agbègbè náà ṣe àlàyé pé láàrín ìṣẹ̀jú kan tí ìjà náà bẹ̀rẹ̀ ni Aboy ti gún Ayomide pa, kí àwọn ará àdúgbò tó ṣètò bí wọn yóò ṣe gbé e lọ sílé ìwòsàn, Ayomide ti kú nígbà tí Aboy fi ẹsẹ̀ fẹ́ ẹ.
Daniel náà ṣe àlàyé pé àwọn ọlọ́pàá àgọ́ Onipaanu tí wọ́n mú ẹjọ́ lọ kò gbé ìgbésẹ̀ kankan lórí bí wọn yóò ṣe mú Aboy, àwọn tí wọ́n lọ fi ẹjọ́ sùn ni wọ́n tìmọ́lé tí wọ́n sì gba owó ribiribi kí wọ́n tó dá wọn sílẹ̀ lọ́jọ́ kejì; Nítorí igba náírà ni wọ́n ṣe pa ayomide ní ogun.
Daniel wí pé Aboy ò ṣẹ̀ṣẹ̀ máa gún àwọn èèyàn nígò àti lọ́bẹ ní àdúgbò náà tí àwọn ọlọ́pàá sì máa ń dá a sílẹ̀ ní gbogbo ìgbà, ìdí ni pé ìyá rẹ̀ ti fìgbà kan jẹ́ ọlọ́pàá.
Àwọn tí wọ́n lọ fi ẹjọ́ sùn ni àwọn ọlọ́pàá mú mọ́lẹ̀, wọn kò wá sí àdúgbò wá mú Aboy títí tó fi sá lọ kí ilẹ̀ ọjọ́ kejì tó mọ́. Daniel ní àwọn ọlọ́pàá ló fún Aboy láyè àtisá lọ.
Bàbá Ayomide; Ọ̀gbẹ́ni Israel bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, ó ṣe àlàyé pé ilé iṣẹ́ Ayomide níbi tó ti ń tún ọkọ̀ ṣe wà ní ẹ̀gbẹ́ ilé iṣẹ́ búlọ́kù tirẹ̀, Aboy jẹ́ òṣìṣẹ́ bàbá Ayomide nílé iṣẹ́ búlọ́kù náà. Ó wí pé òun ti fẹ́ dá Aboy dúró kí ó tó di pé ó pa ọmọ rẹ̀ yìí.
Ọgbẹ́ni Israel ṣe àlàyé pé lọ́jọ́ ìṣẹ̀lẹ̀ náà, Aboy ti ṣaájú Ayomide dé ibi iṣẹ́, ó sùn kalẹ̀, Ayomide sì ṣe ìtọ́jú àyíká nígbà tí òun dé. Bí ó ṣe ṣetán ni ó lọ ra oúnjẹ ni Aboy bá ní kí ó fún òun ní igba náírà. Ayomide takú pé òun kò fún un ni ó bá sọ ọ́ dìjà, ó gbé Ayomide ṣubú ó sì gún un pa.
Àlàyé bàbá Ayomide tẹ̀síwájú pé àwọn ọlọ́pàá kó gbogbo àwọn tì ìsọ̀ wọn wà ní òpópónà náà wọ́n sì tì wọ́n mọ́lé nígbà tí wọn kò tilẹ̀ ya ilé Aboy rárá. Owó gidi ni wọ́n gbà kí wọ́n tó dá àwọn ẹni náà sílẹ̀.
Nígbà tó di ọjọ́ kejì, àwọn ẹbí àti ará ilé Aboy wá bá òun nílé pé kí òun ó sìnkú Ayomide pé àwọn yóò wá Aboy jáde. Àwọn ará àdúgbò náà wá bẹ̀bẹ̀ pé kí ó sìnkú ọmọ náà kí ó má fi ráre nílé ìgbókùúsí.
Ó wí pé òun tún lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá Sango nígbà tí àgọ́ Onipaanu kò ṣe nǹkankan, ibẹ̀ ni wọ́n ti sọ fún òun pé Aboy kò ṣẹ̀ṣẹ̀ máa pa èèyàn, òun ló pa ọkọ ìyá rẹ̀ tó sì tún ti gún àwọn mẹ́rin mìíràn nígò.
Bákan náà ni àwọn ọlọ́pàá kó àwọn ayálegbé bàbá Ayomide mẹ́fà, alága àdúgbò náà tí wọ́n sì tún gba òbítíbitì owó lọ́wọ́ wọn, ó di pé àwọn ẹni náà kò le sọ̀rọ̀ nítorí wọ́n ti kó wọn láyà jẹ látìmọ́lé.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun ti fèsì, wọ́n ní ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé lóòótọ́ àmọ́ irọ́ ni pé àwọn kò ṣe nǹkankan. Wọ́n ní Aboy ti sá lọ àwọn kò sì le mú ìyá rẹ̀ nítorí àgbàlagbà ni. Bákan náà ni pé Aboy kò mú ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀ kúrò nílé léyìí tó jẹ́ kọ́ nira láti wá a àmọ́ àwọn ṣì ń wá a – Nítorí igba náírà ni wọ́n ṣe pa ayomide ní ogun.

ADVERTISEMENT

Kìí ṣe òní ni àwọn èèyàn ti ń gún ara wọn pa, ní ìpínlẹ̀ Kwara níjọ́sí, àwọn ọ̀rẹ́ méjì kan gún ara wọn pa.

Ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ni Gafar àti Hammed kó tó di pé abo dá ìjà sílẹ̀ láàrin wọ́n. A gbọ́ pé àwọn méjéèjì nífẹ̀ẹ́ obìnrin kan náà wọn kò sì ṣetán àti yọ̀ǹda rẹ̀.
Ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ni Hammed Usman Tunde nígbà tí Gafar jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlélógún. Ọmọ ìlú Ilorin ni àwọn méjéèjì.
Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà, àwọn méjéèjì pàdé ní ìsọ̀ onírèké lọ́jà Gboro, Ilorin. Èdè àìyedè ni wọ́n kọ́ fi bẹ̀rẹ̀ àgi bó ṣe di ìjàkadì, ẹ̀ẹ̀kan náà ni Gafar fa ọ̀bẹ yó tó sì fi gún Hammed láyà, lẹ́yìn náà ló sá lọ.
Àwọn èèyàn ṣe aájò Hammed dé ilé ìwòsàn aládàáni kan ní Gboro àmọ́ ó ti kú kí wọ́n tó dé ibẹ̀.
Títí di àsìkò yìí, kò sí ẹni tó mọ ibi tí Gafar wà bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ ti sá kúrò nílé.
Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ mímọ̀ láti ẹnu agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara; Adetoun Ejire-Aderemi. Ó wí pé àwọn gba ìpè pàjáwìrì náà ní aago méjì ọ̀sán lọ́jọ́rú, nígbà tí wọn dé ibẹ̀, ẹ̀jẹ Hammed ni wọ́n bá nílẹ̀ tí àwọn èèyàn sì ti gbé e lọ sí ilé ìwòsàn. Àwọn ọlọ́pàá ta mọ́ra lọ sílé Gafar àmọ́ wọn kò bá ẹyẹ, tọdé tàgbà ilé náà tin a pápá bora kódà wọn kò dúró kó ẹrù.
Kọmiṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà; Adekimi Ojo bá àwọn ẹbí Hammed kẹ́dùn ó sì kí àwọn ará ọjà Gboro kú ìbọ̀wọ̀ fún òfin tí wọn kò dáná sun Gafar náà.

ADVERTISEMENT
Facebook Comments Box

Related

Tags: #CrimeNews #NEWS#iweiroyinyoruba#ìwéròyìnyorùbá #NewsOnline#newsfeed#TRENDINGNEWSTODAYbreaking newsbreakingnewsdeathIwe Iroyin Yorubanewsnews onlinenewsinyoruba
ADVERTISEMENT
Adeola Olanrewaju

Adeola Olanrewaju

Next Post
ÌJỌBA ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ TI DÁ ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ NÁÀ SÍLẸ̀. - Asia ile ise olopaa

ÌJỌBA ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ TI DÁ ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ NÁÀ SÍLẸ̀.

Recommended

WỌ́N TI DÁ ÒṢÌṢẸ́FẸ̀YÌNYÌ Ẹ̀ṢỌ́ AṢỌ́BODÈ ILẸ̀ WA SÍLẸ̀ LẸ́YÌN OWÓ ÌTÚSÍLẸ̀.

5 months ago
Ìròyìn Jákèjádò.

OJORA TI IJORA RỌ ÀWỌN OLÓYÈ MẸ́FÀ LÓYÈ NÍTORÍ PÉ WỌ́N LỌ SÍ IBI ÌPOLONGO ÌBÒ ẸGBẸ́ ÒṢÈLÚ LABOUR.

11 months ago

Popular News

  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ TI MÚ IKỌ̀ ONE-CHANCE NÍ IDIMU, ÈKÓ.

    Ọwọ́ tẹ ikọ̀ one-chance ní kebbi.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • OLÓLÙFẸ́ DA ÁSÍÌDÌ SÍ ỌMỌṢẸ́ Ọ̀RẸ́BÌNRIN RẸ̀ LÁRA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ILÉ ẸJỌ́ PÀṢẸ KÍ GBOGBO DÚKÌÁ SYLVA Ó DI TI ÌJỌBA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • AYÉ LÓ ṢE ỌLỌ́PÀÁ TÓ YÌNBỌN PA ÈÈYÀN.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ ṢE ÀWÁRÍ AYÉDÈRÚ ILÉ ỌMỌ ALÁÌNÍYÀÁ.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0

Connect with us

ADVERTISEMENT

Newsletter

Lorem ipsum dolor sit amet, consectetuer adipiscing elit. Aenean commodo ligula eget dolor.
SUBSCRIBE

Category

Site Links

  • Register
  • Log in
  • Entries feed
  • Comments feed
  • WordPress.org

About Us

We bring you the best Premium WordPress Themes that perfect for news, magazine, personal blog, etc. Check our landing page for details.

  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
  • Àṣà Yorùbá
  • Ìgbé-Ayé
  • Ìdánilárayá
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

Welcome Back!

Login to your account below

Forgotten Password? Sign Up

Create New Account!

Fill the forms below to register

All fields are required. Log In

Retrieve your password

Please enter your username or email address to reset your password.

Log In
No Result
View All Result
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

This website uses cookies. By continuing to use this website you are giving consent to cookies being used. Visit our Privacy and Cookie Policy.