OBÌNRIN ALÁGÀNNÁ KAN BÍ ỌMỌ SÍ ẸGBẸ́ TÍTÌ NÍ ABUJA.
Obìnrin alágànná kan bí ọmọ sí ẹgbẹ́ títì ní abuja. ọmọbìnrin làǹtìlanti ni o bi sí ẹgbẹ́ títì ní ojú ọ̀nà Kwaita ní Abuja. Àwọn ará àdúgbò ni wọ́n ránṣẹ́ pe àwọn ọlọ́pàá tí wọ́n wà nítòsí láti wá ṣe ìrànwọ́ fún obìnrin yìí àti ọmọ rẹ̀.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ọkùnrin ni àwọn ọlọ́pàá náà, wọ́n gbìyànjú láti ran obìnrin yìí lọ́wọ́ àti ọmọ titun tó bí náà, ó fi ojú wọn rí màbo kí wọ́n tó rí ọmọ náà gbà lọ́wọ́ rẹ̀. Ilé ìwòsàn ìjọba Kwali ni wọ́n gbé obìnrin yìí àti ọmọ rẹ̀ ló fún ìtọ́jú.
Àwọn dọ́kítà ṣe gbogbo ìtọ́jú tó yẹ fún ọmọ àti ìyá rẹ̀ wọ́n sì dá wọn sílẹ̀ lọ́jọ́ kẹta, ìyẹn àná.
Lẹ́yìn náà ni ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá fa ìyá àti ọmọ lé ọlọ́pàá tó darí ẹ̀ka ìtọ́jú ará ìlú; Ọ̀gbẹ́ni Sadiq Kwali lọ́wọ́ kí ó máa tọ́jú rẹ̀ lọ.
Ilé àwọn ọmọdé tí ìjọba kọ́ sí Wako ní Gwagwalada ni wọ́n kó wọn lọ, ibẹ̀ ni ọmọ náà yóò dàgbà sí títí yó fi tójú bọ́.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá kan sárá sí àwọn ọlọ́pàá náà lórí akitiyan wọn láti dóòlà ọmọ titun náà.
ÌYÁ ỌMỌ TITUN GBÉ ỌMỌ SÍLẸ̀ SÁ LỌ.
Ìyá ọmọ titun gbé ọmọ sílẹ̀ sá lọ ní Ìlọrin. Ọjọ́bọ ni obìnrin yìí bí ọmọ náà tó sì gbé e sílẹ̀ sílé ìwòsàn sá lọ.
Ilé ìwòsàn Apalara ní Ilorin ni ó bí ọmọ náà sí tó sì sá lọ, nígbà tí wọn ko ríi di ọjọ́ kejì ni wọ́n pe àwọn ọlọ́pàá tí wọ́n sì gbé ọmọ náà lọ sí ẹ̀ka tó ń ṣe ìtọ́jú ará ìlú.
Adarí ọ̀rọ̀ àwọn obìnrin ló tẹ́wọ́ gba ọmọ náà fúnra rẹ̀. Ó wí pé gbogbo ọmọ tí wọ́n bá bí ní ìpínlẹ̀ náà ló ṣe pàtàkì. Ìwádìí fi hàn pé akẹ́kọ̀ọ́ ni obìnrin tó gbé ọmọ rẹ̀ sílẹ̀ náà.
NǸKAN YAN NÍ ORÍTA SOKA NÍGBÀ TÍ TÍRÉLÀ JÁ.
Nǹkan yan ní oríta soka nígbà tí tírélà já lórí eré tó sì wọ́ ọ̀pọ̀ ọ̀kọ̀ tó há sínú súnkẹ́rẹ-fakẹrẹ. Àwọn èèyàn méjì ló gbé ẹ̀mí mì lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ nígbà tí ọ̀pọ̀ fi ara pa yánnayàna. Alẹ́ ọjọ́ àbámẹ́ta àjíǹde ku ọ̀la ni ìjàm̀bá náà wáyé.
Alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́; Ayanlade Olayinka ló fi ìròyìn tó àwọn akọ̀ròyìn létí ní Ìbàdàn.
Ayanlade ṣe àlàyé pé ọkọ̀ àjàgbé eléjò Howo kan tí òǹkà ìdámọ̀ rẹ̀ jẹ́ GEM696XE ni ó fa ìjàm̀bá náà. Abdullahi Bashiru ni ó wa ọkọ̀ náà.
Eré àsápajúdé ni Abdullahi sá ló fà á tí ó fi pàdánù ìjánu ọkọ̀ náà. Ọ̀pọ̀ ọkọ̀ ni ó tẹ̀ nínú èyí tó ti tẹ Venza kan, BMW àti àwọn mìíràn.
Abimbola Olugbenga; ẹni tó jẹ́ kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ bá mọ̀lẹ́bí àwọn tó pàdánù ẹ̀mí wọn kẹ́dùn, ó sì gbàdúrà ìlera fún àwọn tó farapa. Bákan náà ló ṣe ìlérí pé ìwádìí ìjìnlẹ̀ yóò wáyé lórí ìjàm̀bá náà.
ỌWỌ́ TẸ ÀWỌN MÉJÌ TÍ WỌ́N JÍ ỌMỌ ỌJỌ́ MẸ́TA GBÉ.
Àwọn afurasí méjì kan ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá báyìí lórí ẹ̀sùn pé wọ́n jí ọmọ ọjọ́ mẹ́ta gbé lábẹ́ ìyá rẹ̀.
Agbègbè Unguwan Bako ní Mararaba, ìpínlẹ̀ Nasarawa ni èyí ti ṣẹ̀, Aisha Bada ni orúkọ ìyá ọmọ ìkókó yìí, ẹni ọdún mọ́kàndínlógún ni.
Ọkọ Aisha ti wà ní Èkó láti oṣù márùn-ún sẹ́yìn níbi tó ti ń ṣiṣẹ́ ọ̀kadà. Inú ilé akọ́kù kan nínú ọjà ọsàn ni Aisha ń sùn kò sì sí ààbò tó péye fún un.
Alẹ́ ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n ni àwọn ọkùnrin méjì kan lọ kó Aisha ní pápámọ́ra níbi tó ń sùn tí wọ́n sì gbé ọmọ rẹ̀ ọkùnrin náà lọ.
Ọjọ́ kejì ni Aisha lọ fi ẹjọ́ sùn ní àgọ́ ọlọ́pàá pé wọ́n jí ọmọ rẹ̀ gbé lọ ni wọ́n bá kò síṣẹ́. Inú ọjà ọsàn tí ó ń sùn náà ni wọ́n ti rí ọmọ náà lọ́sàn-án ọjọ́ kejì lọ́wọ́ àwọn afurasí méjì náà. Orúkọ wọn ni Furera Abdulrahman àti Sadiya Abdullahi.
Wọ́n jẹ́wọ́ pé ẹnìkan ló wá sínú ọjà pé kí wọn ó bá òun gba ọmọ náà lọ́wọ́ Aisha pé òun yóò wá gbà á. Ẹni náà kò wá gbé ọmọ náà bíi àdéhùn tí wọ́n ṣe ni ó ṣì ṣe wà lọ́wọ́ wọn di ọjọ́ kejì.
Àwọn méjéèjì yìí ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá nígbà tí ìwádìí ṣì ń lọ láti mú ẹni tó bẹ̀ wọ́n lọ́wẹ̀ náà.




