Àwọn agbébọn bá àwọn ará Angwa Rukuba lálejò lọ́jọ́ Àìkú, ọ̀pọ̀ ẹmí ló bọ́ láìrò tẹ́lẹ̀.
Ìpínlẹ̀ Plateau ni Angwa Rukuba wà, ìgboro ni ìlú náà kìí ṣe abúlé ó sì kún fọ́fọ́. Ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n ni àwọn agbébọn náà ya wọ ìlú náà pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀kadà, wọ́n ṣíná ìbọn bolẹ̀ wọ́n sì kó àwọn èèyàn náà ní pápámọ́ra. Gbogbo ẹni tí wọ́n rí ni wọ́n yìnbọn mọ́, wọn kò mọ ọmọdé tàbí àgbà, kòsàkòsà ni ìbọn ń dáhùn lára gbogbo ẹni tí wọ́n ká mọ́.
Ọ̀kan nínú àwọn olùgbé Angwa tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Caleb bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀, ó ṣe àlàyé pé ìkọlù náà kọjá bẹ́ẹ̀, èèyàn mẹ́fà ni wọ́n kọ́ mú balẹ̀ ní fọnná-fọnṣu tí ọ̀pọ̀ sì tún wà ní ilé ìwòsàn Luna ní ẹsẹ̀ kan ayé ẹsẹ̀ kan ọ̀run.
Janet Pam náà ṣe àlàyé pé inú ilé ni òun wà nígbà tí ó bẹ̀rẹ̀ sí ní gbọ́ ìró ìbọn, nígbà tó yọjú síta, àwọn agbébọn ló rí tí wọ́n ń yìnbọn lákọlákọ lórí ọ̀kadà.
Àwọn tí wọ́n ń lọ ní títì àti àwọn tó ń tajà ló fi ara gbọta jù, Janet ní wọ́n pa ará ilé òun kan tó ń ti ilé ìjọsìn bọ̀. Ìyàlẹ́nu ni èyí jẹ́, a kò rí irú èyí rí ní àdúgbò wa, wọ́n sá lọ kí àwọn ọlọ́pàá tó dé – Janet Pam.
Ìkọlù náà ti kó ìpayà bá àwọn ará ìlú, àwọn ọ̀dọ́ tú jáde láti ṣe ìwọ́de tako ìṣẹ̀lẹ̀ náà, wọ́n bèèrè fún kí ìjọba ó fi òfin de alùpùpù ní gbogbo agbègbè náà, lẹ́yìn náà ni wọ́n gbégi dí ọ̀nà tó wọ ìlú náà àmọ́ àwọn ọlọ́pàá tú wọn ká.
Gómìnà Mutfwang ṣe àbẹ̀wò:
Gómìnà ìpínlẹ̀ Jos; Caleb Mutfwang ṣe àbẹ̀wò sí ìlú Angwan Rubuka níbi tí àwọn agbébọn ti ṣe ìkọlù ní àná tí ọ̀pọ̀ ẹ̀mí sì ṣòfò.
Gómìnà Caleb Mutfwang bá àwọn ará agbègbè náà kẹ́dùn, ó ní òun mọ bí iná náà ṣe ń jó wọn lára tó nítorí pé ẹlẹ́ran ara ni òun náà.
Ó ṣe ìlérí pé ìṣèjọba òun yóò ṣe àwárí àwọn agbébọn náà wọn yóò sì fi imú wọn dánrin.
Bákan náà ni ìṣèjọba Mutfwang yóò san owó ìtọ́jú àwọn tó wà nílé ìwòsàn wọn yóò sì tún ṣe ètò ìsìnkú àwọn tó kú náà.
Caleb ní òun yóò ṣètò ìsìnkú ẹ̀yẹ fún àwọn tó kú náà láti fi ṣe àpọ́nlé ẹ̀mí wọn tó bọ́ láìtọ́jọ́.
Gómìnà Caleb rọ àwọn lọ́balọ́ba láti mú ètò ààbọ̀ lọ́kúnkúndùn kí wọn ó ṣètò ààbò tó péye fún agbègbè wọn.
Ọ̀tun ni ìkọlù èyí nínú àwọn ìkọlù tó ti ń wáyé ní ìpínlẹ̀ Jos.
Ọdún tó kọjá ni wọ́n run abúlé Zikke tí a mú ìròyìn rẹ̀ wá pé:
Òru ní nǹkan bíi aago méjìlá kọjá ni àwọn agbébọn náà dé sí abúlé Zikke lógúnlógún lọ́gbọ̀nlọ́gbọ̀n. Wọ́n yìnbọn lákọlákọ, wọ́n dáná sun ọ̀pọ̀ ilé, wọ́n pa àwọn èèyàn bíi àádọ́ta wọ́n sì tún ṣe ogúnlọ́gọ̀ báṣubàṣu.
Ó lé ní wákàtí kan tí wọ́n fi ṣe ọṣẹ́ yìí láìsí ìdíwọ́ kankan.
Olórí ọ̀dọ́ abúlé Zikke, ẹni tó jẹ́ akọ̀wé ẹgbẹ́ Irigwe; Joseph Chudu bá ikọ̀ àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Ó wí pé wọ́n ti kó àwọn tó farapa lọ sí ilé ìwòsàn ìjọba Jos, ipò wọn burú wọ́n sì nílò ẹ̀jẹ̀.
Chudu rọ ìjọba láti ṣe àtúnṣe sí ètò ààbò tó mẹ́hẹ yìí. Gbogbo akitiyan láti kàn sí ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Plateau kò so èso rere nípa pé agbẹnusọ wọn; Alabo Alfred kò gbé ìpè àwọn oníròyìn.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Plateau bu ẹnu àtẹ́ lu ìkọlù tó ń wáyé sásá yìí ó sì rọ àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò láti wá àwọn agbésùnmọ̀mí náà jáde.
Kọmíṣọ́nà fún ìfitónilétí; Joyce Renmap wí pé ìkọlù tó gba ìpínlẹ̀ Plateau kan yìí jẹ́ ohun tó bani lọ́kàn jẹ́. Joyce wí pé ogúnlọ́gọ̀ àwọn èèyàn ni wọ́n pa ní ìjọba ìbílẹ̀ Bokko àti Bassa láàrín ọ̀sẹ̀ méjì.
Ọ̀rọ̀ Joyce tẹ̀síwájú pé ìlú tó kún fún ìfẹ́ àti àdùn tẹ́lẹ̀ ti parade di ibi tó kún fún ìkorò àti ìbànújẹ́ látàrí ìkọlù ojoojúmọ́ yìí. Ó gúnlẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú pé kí àwọn èèyàn ó fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ìjọba láti borí àdojúkọ yìí.
Wàyí o, àwọn ará abúlé bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lórí ibi tí iná gbà jó wọn. Lancaster Akpa; ẹni ọdún mọ́kàndínláàdọ́ta wí pé ẹbí òun mẹ́sàn-án ló bá ìkọlù náà lọ. Akpa wí pé Jos ni òun wà nígbà tí àbúrò òun pe òunp pé àwọn agbésùnmọ̀mí ti bẹ̀rẹ̀ ìkọlù, ó ní òun kò le sùn mọ́ lóru ọjọ́ náà, ìgbà tí òun pe aago rẹ̀ tí kò lọ mọ́ ni ara ti ń fu òun kó tó wá di pé òun dé bá òkú rẹ̀, ẹ̀gbọ́n òun àti àwọn ọmọ wọn méje.
Akpa wí pé àwọn tí wọ́n wá ṣe ìkọlù náà wọ aṣọ ológun àmọ́ Fulani ni wọ́n gẹ́gẹ́ bí ohun tí òun gbọ́.
Jerry Muwa náà sọ tirẹ̀, ó ní àwọn ọmọọmọ òun mẹ́fẹ́ẹ̀fà ni wọ́n dáná sun mọ́lé nígbà tí wọn kò rí ìlẹ̀kùn já. Ó ní òun rápálá jáde lóru ọjọ́ náà ni pẹ̀lú ọmọ òun tó jẹ́ bàbá àwọn ọmọ náà. Muwa wí pé àwọn ọmọ náà jóná di éérú débi pé kò sí ẹran tàbí eegun tí àwọn le sin, àwọn kan kó éérú wọn jọ sínú sàárè kan ni.
Ààrẹ ti sọ̀rọ̀:
Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ti fèsì sí ìkọlù tó wáyé ní Rukuba lọ́jọ́ ọjọ́ ìbí rẹ̀ náà, ó bá àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn kẹ́dùn ó sì ṣe ìlérí pé ètò ààbò yóò nípọn síi ní gbogbo agbègbè náà.




