Gómìnà ìpínlẹ̀ Ondo; Lucky Aiyedatiwa ti pàṣẹ kí àwọn ẹ̀ṣọ́ ológun ó dáná ogun yá àwọn ajínigbé ní ìpínlẹ̀ náà. Ó sọ èyí láti ẹnu kọmíṣọ́nà fún ìfitónilétí; Idowu Ajanku pé àsìkò ti tó láti gbógun ti àwọn ajínigbé tí wọ́n ń da ìlú náà láàmú, ojoojúmọ́ ni wọ́n fi ń ṣọṣẹ́ lágbègbè náà.
Ó wí pé àwọn aráàlú náà ni wọ́n ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn ajínigbé máa ṣe àwọn ọṣẹ́ yìí, ìdí ni pé wọ́n fẹ́ kí àwọn ará òkèèrè ó máa rí ìpínlẹ̀ Òǹdó bíi ìpínlẹ̀ tí kò fi ara rọ. gómìnà ti wá pàṣẹ báyìí kí àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ó dojú ìjà kọ àwọn aráàlú tó ń ṣe irú èyí, kí wọn ó fi imú wọn dán irin, ó ní òun kò ní fi ààyè gba ìjínigbé gbogbo ìgbà yìí mọ́.
Àṣẹ ni Gómìnà Aiyedatiwa pa kìí ṣe àbá rárá, ó kàn án nípá fún àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò láti wá àwọn aráàlú tí wọ́n ń jí àwọn èèyàn gbé láti ba orúkọ ìpínlẹ̀ Ondo jẹ́ kàn kí wọn ó sì fà wọ́n lé ìjọba lọ́wọ́, ó ṣe ìlérí pé àwọn tí ọwọ́ bá tẹ̀ yóò fi ojú winá òfin tààrà kò ní sí ààyè fún ìpẹ̀ tàbí ìdáríjì.
Lára àwọn ìgbésẹ̀ tí Gómìnà ti gbé kí èyí le jẹ́ mímúṣẹ ni ríra ọkọ̀ fún àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò, ìdásílẹ̀ ẹ̀ṣọ́ àbọ̀ Àmọ̀tẹ́kùn àti gbígba àwọn èèyàn ẹgbẹ̀rún márùn-ún síṣẹ́ ààbò.
Ọ̀rọ̀ yìí kan àwọn baálẹ̀ náà o, Gómìnà pàṣẹ kí wọn ó mójútó ìlú wọn dáadáa, kí wọn ó mọ gbogbo ohun tó bá ń ṣẹlẹ̀ ní agbègbè wọn kí wọn ó sì mú ọ̀rọ̀ ààbò ní ọ̀kúnkúndùn.
Bákan náà ni ó rọ àwọn aráàlú láti dẹjú sílẹ̀ kí wọn ó sì fi ìrìn tí kò bá mọ́ tó àwọn agbófinró létí.
Gómìnà Aiyedatiwa gúnlẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pẹ̀lú pé ètò ààbò ló jẹ òun lógún, ẹ̀mí àti dúkíà àwọn ará ìpínlẹ̀ Ondo ṣe iyebíye sí òun, òun kò sì ní fi ààyè gba gbogbo ohun tó bá le da àlàáfíà ìlú náà rú.
Ìjínigbé tó ń wáyé ní ìpínlẹ̀ Ondo ti kọjá ohun tí èèyàn fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú, nínú oṣù Ṣẹẹrẹ ni àwọn aráàlú tú síta láti ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn lórí ìjínigbé ojoojúmọ́ tó ń wáyé.
Àwọn ará ìlú Ilu Abo ní ìjọba ìbílẹ̀ àríwá Àkúrẹ́ ní ìpínlẹ̀ Òǹdò tú yáyá tú yàyà jáde láti ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn tako ìjínigbé tó ń wáyé lemọ́lemọ́ ní ìlú náà. Oríṣìí akọlé ni wọ́n gbé lọ́wọ́ láti fi ẹ̀dùn ọkan wọn hàn, wọ́n ní àwọn ajínigbé ti fẹ́rẹ̀ jí gbogbo àwọn gbé tán, àrẹ́sẹ̀pa ni ìlú náà dà fún àwọn agbébọn yìí, bíi adìyẹ òkòkò ni wọ́n ṣe ń kó wọn ní ìlú náà wọ igbó lọ.
Kò sí ẹni tó lọ síbi iṣẹ́ tàbí ṣí ìsọ̀, wọ́n ní kò sí ìdánilójú pé àwọn yóò délé bí àwọn bá lọ ni wọ́n ṣe kúkú takú síbi ìwọ́de náà.
Èyí tó ṣẹlẹ̀ gbẹ̀yìn tí wọ́n fi ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn yìí ni obìnrin kan tí wọ́n jí gbé ní iwájú ilé rẹ̀ gan-an nígbà tó ti òde dé. Obìnrin yìí wa ọkọ̀ rẹ̀ dé iwájú ilé rẹ̀ ni àwọn agbébọn náà yìnbọn mọ́ ilé epo ọkọ̀ rẹ̀ àti àwọn táyà ẹsẹ̀ ọkọ̀ náà. Wọ́n kó o ní pápámọ́ra wọ́n sì gbé e lọ tèfètèfè.
Tomilola Oladehinde ni orúkọ obìnrin yìí, alábàágbé rẹ̀ tó rí àwọn ajínigbé náà pariwo láti pe àwọn èèyàn jáde àmọ́ wọ́n wọ inú ọgbà ilé rẹ̀, wọ́n yìnbọn fún obìnrin yìí, ọkọ rẹ̀ àti ọmọ rẹ̀ kékeré. Ilé ìwòsàn kan tó wà nítòsí ni wọ́n kó wọn lọ láti du ẹ̀mí wọn.
Àwọn akọ̀ròyìn bá àwọn olùwọ́de yìí sọ̀rọ̀, wọ́n ṣe àlàyé ẹ̀dùn ọkàn wọn, wọ́n ké sí Gómìnà Aiyedatiwa láti wá nǹkan ṣe sí ètò ààbò tó mẹ́hẹ ní agbègbè náà. Ọ̀kan nínú wọn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Alàgbà Johnson Adajah ṣe àlàyé pé ọ̀pọ̀ àwọn aráàlú náà ló ti fi ara gbọta nínú ìkọlù àwọn agbébọn yìí, àwọn mẹ́ta ló tún wà ní ilé ìwòsàn báyìí, wọn kò le máa bá báyìí lọ.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Òǹdó kò jiyàn ohun tí àwọn èèyàn yìí sọ rárá, wọ́n fèsì láti ẹnu agbẹnusọ wọn; Abayomi Jimoh pé ọ̀pọ̀ àwọn aráàlú náà ni wọ́n ti lọ lo họlidé ní àhámọ́ àwọn ajínigbé tí ọ̀pọ̀ kò sì tíì padà, púpọ̀ nínú wọn ló ní ojú ọta ìbọn lára, ọ̀pọ̀ ni kò padà ye ìkọlù náà.
Jimoh ṣe àlàyé pé nínú ìkọlù kan, wọ́n yìnbọn pa àwọn mẹ́ta kan tí wọ́n rékọjá lásìkò náà, wọ́n sì tún jí ẹlòmíràn gbé lọ.
Èyí tó tún burú bẹ́ẹ̀ ni ti ọba aládé tí wọ́n pa sí ààfin rẹ̀ ní Ondo yìí kan náà:
Àwọn agbésùnmọ̀mí bíi mẹ́wàá ni wọ́n ya wọ ààfin ọba Agamọ ní Akure láti jíi gbé. Ọba yìí kojú wọn ó sì kọ̀ láti tẹ̀lé wọn. Wọ́n yìn ín níbọn àmọ́ kò wọlé ni wọ́n bá fọ́ nǹkan mọ́ ọn lórí kí wọ́n tó sá lọ.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ondo ló fi ọ̀rọ̀ yìí léde láti ẹnu agbẹnusọ wọn; Abayomi Jimoh pé àwọn gba ìfisùn ìṣẹ̀lẹ̀ náà. Wọ́n fẹ́ jí ọba náà gbé ni àmọ́ nígbà tó kọ̀ ni wọ́n ṣe pa á. Nǹkan tó wúwo gan-an ni wọ́n fọ́ mọ́ ọn lórí nígbà tí ìbọn kò ràn-án.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ní àwọn ti da àwọn ẹṣọ́ síta wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ nífọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀sọ́ aláàbò Àmọ̀tẹ́kùn láti wá àwọn tó ṣiṣẹ́ láabi yìí jáde. Wọn yóò fọ́ gbogbo inú igbó àti agbègbè bákan náà.
Wọ́n ṣe ìlérí pé àwọn yóò hú wọn jáde níbikíbi tí wọ́n bá farasin si.




