ADVERTISEMENT
  • About
  • Contact
Monday, June 1, 2026
  • Login
  • Register
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
No Result
View All Result
Home Ìròyìn

ÀWỌN ARÁÀLÚ TÚ SÍTA LÁTI TAKO ÌJÍNIGBÉ TÓ Ń WÁYÉ NÍ LEMỌ́LEMỌ́.

Bí ẹni kó adìyẹ òkòkó ni wọ́n ṣe ń kó wọn ní Ilu Abo.

by Adeola Olanrewaju
January 26, 2026
in Ìròyìn, Ìròyìn Agbègbè, Ọ̀rọ̀ Ààbò
0
ÀWỌN ARÁÀLÚ TÚ SÍTA LÁTI TAKO ÌJÍNIGBÉ TÓ Ń WÁYÉ NÍ LEMỌ́LEMỌ́.
0
SHARES
7
VIEWS
Pín Lórí FacebookPín Lórí ThreadsPín Lórí TwitterPín Lórí Bluesky
ADVERTISEMENT

Àwọn ará ìlú Ilu Abo ní ìjọba ìbílẹ̀ àríwá Àkúrẹ́ ní ìpínlẹ̀ Òǹdò tú yáyá tú yàyà jáde láti ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn tako ìjínigbé tó ń wáyé lemọ́lemọ́ ní ìlú náà. Oríṣìí akọlé ni wọ́n gbé lọ́wọ́ láti fi ẹ̀dùn ọkan wọn hàn, wọ́n ní àwọn ajínigbé ti fẹ́rẹ̀ jí gbogbo àwọn gbé tán, àrẹ́sẹ̀pa ni ìlú náà dà fún àwọn agbébọn yìí, bíi adìyẹ òkòkò ni wọ́n ṣe ń kó wọn ní ìlú náà wọ igbó lọ.
Kò sí ẹni tó lọ síbi iṣẹ́ tàbí ṣí ìsọ̀ lónìí, wọ́n ní kò sí ìdánilójú pé àwọn yóò délé bí àwọn bá lọ ni wọ́n ṣe kúkú takú síbi ìwọ́de náà.
Èyí tó ṣẹlẹ̀ gbẹ̀yìn tí wọ́n fi ṣe ìwọ́de ìfẹ̀hónúhàn yìí ni obìnrin kan tí wọ́n jí gbé ní iwájú ilé rẹ̀ gan-an nígbà tó ti òde dé. Obìnrin yìí wa ọkọ̀ rẹ̀ dé iwájú ilé rẹ̀ ni àwọn agbébọn náà yìnbọn mọ́ ilé epo ọkọ̀ rẹ̀ àti àwọn táyà ẹsẹ̀ ọkọ̀ náà. Wọ́n kó o ní pápámọ́ra wọ́n sì gbé e lọ tèfètèfè.
Tomilola Oladehinde ni orúkọ obìnrin yìí, alábàágbé rẹ̀ tó rí àwọn ajínigbé náà pariwo láti pe àwọn èèyàn jáde àmọ́ wọ́n wọ inú ọgbà ilé rẹ̀, wọ́n yìnbọn fún obìnrin yìí, ọkọ rẹ̀ àti ọmọ rẹ̀ kékeré. Ilé ìwòsàn kan tó wà nítòsí ni wọ́n kó wọn lọ láti du ẹ̀mí wọn.
Àwọn akọ̀ròyìn bá àwọn olùwọ́de yìí sọ̀rọ̀, wọ́n ṣe àlàyé ẹ̀dùn ọkàn wọn, wọ́n ké sí Gómìnà Aiyedatiwa láti wá nǹkan ṣe sí ètò ààbò tó mẹ́hẹ ní agbègbè náà. Ọ̀kan nínú wọn tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Alàgbà Johnson Adajah ṣe àlàyé pé ọ̀pọ̀ àwọn aráàlú náà ló ti fi ara gbọta nínú ìkọlù àwọn agbébọn yìí, àwọn mẹ́ta ló tún wà ní ilé ìwòsàn báyìí, wọn kò le máa bá báyìí lọ.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Òǹdó kò jiyàn ohun tí àwọn èèyàn yìí sọ rárá, wọ́n fèsì láti ẹnu agbẹnusọ wọn; Abayomi Jimoh pé ọ̀pọ̀ àwọn aráàlú náà ni wọ́n ti ṣe lọ lo họlidé ní àhámọ́ àwọn ajínigbé tí ọ̀pọ̀ kò sì tíì padà, púpọ̀ nínú wọn ló ní ojú ọta ìbọn lára, ọ̀pọ̀ ni kò padà ye ìkọlù náà.
Jimoh ṣe àlàyé pé nínú ìkọlù kan, wọ́n yìnbọn pa àwọn mẹ́ta kan tí wọ́n rékọjá lásìkò náà, wọ́n sì tún jí ẹlòmíràn gbé lọ.
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà; Adebowale Lawal ṣe àbẹ̀wò sí Ilu Abo ní òwúrọ̀ yìí, ó bu ẹnu àtẹ́ lu ìṣẹ̀lẹ̀ náà ó sì ṣe ìlérí pé àtúnṣe yóò wa.

Ìjínigbé kìí ṣe ìròyìn mọ́ ní ìlú yìí, bí ẹni lọ họlidé ni àwọn èèyàn ṣe ń lọ sí àhámọ́ àwọn ajínigbé, ó ti fẹ́rẹ̀ di ilé kejì àwọn aráàlú tí wọ́n bá dójú lé.
Lára àwọn tí wọ́n ti jí gbé ni ọba Aniwo ti ìlú Aafin ní ìpínlẹ̀ Kwara, tọmọtọmọ ni wọ́n gbé kábíyèsí lọ:

Ọba Aniwo ti ìlú Aaafin ní ìjọba ìbílẹ̀ Ifelodun, ìpínlẹ̀ Kwara ti wà ní àkàtà àwọn ajínigbé àti àrẹ̀mọ rẹ̀.
Oba Simeon Olaonipekun àti ọmọ rẹ̀ Olaolu tó jẹ́ Agùnbánirọ̀ ni àwọn ajínigbé náà gbé lọ nígbà tí wọ́n ṣe ìkọlù sí ààfin rẹ̀.
Nǹkan bíi aago mẹ́jọ alẹ́ àìsùn ọdún ni àwọn agbébọn náà ya wọ ààfin Aniwo tí wọ́n sì ṣíná ìbọn bolẹ̀
Ìbọn ni wọ́n fi já ilẹ̀kùn ààfin wọlé, wọ́n kó jìnnìjìnnì bo gbogbo ààfin, ariwo ọba ni wọ́n ń ké tantan ó sì jáde sí wọn.
Wọ́n bèèrè olorì rẹ̀ náà àmọ́ ìbọn ti bà á lápá lásìkò tí wọ́n ń fi ìbọn já ilẹ̀kùn, ọmọ rẹ̀ Olaolu ni wọ́n nawọ́ gán nígbà tí wọn kò le mú olorì mọ́.
Òṣìṣẹ́ inú ààfin kan ló ṣe àlàyé pé òun rí wọn dáadáa níbi tí òun sá pamọ́ sí, wọ́n tó mẹ́wàá níye, èdè Gẹ̀ẹ́sì ẹnu wọn sì já geere. Kábíèsí àti aya rẹ̀ ni wọ́n bá wá wọn kò rí ti ẹlòmíràn rò.
Àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò ìbílẹ̀ kò le kojú wọn nítorí wọn kò ju méjì lọ lálẹ́ ọjọ́ náà àti pé ìbọn ọwọ́ àwọn ajínigbé náà le ju tiwọn lọ.
Alẹ́ ọjọ́ náà ni wọ́n gbé olorì lọ sí ilé ìwòsàn nígbà tí wọ́n lọ tán, láti ìgbà tí wọ́n sì ti gbé ọba àti ọmọ rẹ̀, wọn kò kàn sí ẹnikẹ́ni.
Wọ́n ti fi ọ̀rọ̀ náà tó àwọn ẹ̀ṣọ́ alààbò ìbílẹ̀ ní agbègbè létí àwọn ọlọ́pàá náà sì ti gbọ́ síi.
Alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara; Adetoun Ejire-Adeyemi wí pé àwọn ti gba ìfisùn lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà àwọn sì ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ lórí rẹ̀.

ADVERTISEMENT
ADVERTISEMENT

Kábíyèsí kò tíì dé o àmọ́ orí ti kó òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì ẹ̀ṣọ́ aláàbò kan sílẹ̀.
Àwọn ajínigbé ti dá Emmanuel Owolabi sílẹ̀ lẹ́yìn tí àwọn ẹbí rẹ̀ san ẹgbẹ̀lẹ́gbẹ̀ mílíọ́nù owó ìtúsilẹ̀ rẹ̀.
Inú ogbó Oro Ago ní ìpínlẹ̀ Kwara ni wọ́n ní àwọn ẹbí rẹ̀ ó ti lọ pàdé rẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n san owó ìtúsílẹ̀ rẹ̀, wọ́n dé inú igbó náà wọ́n sì ríi lóòótọ́ tó ń gbìyànjú àtirìn jágboro.
Ọjọ́ kẹẹ̀dógún, oṣù Ọ̀pẹ ni wọ́n lọ gbé Owolabi ní iwájú ilé rẹ̀, òun nìkan ni wọ́n gbé lọ́jọ́ náà àmọ́ wọ́n yìnbọn pa olóyè kan tó pàdé wọn lọ́nà.
Ìròyìn bí wọ́n ṣe jí Owolabi gbé:
Àwọn agbébọn ya wọ́ Ora ní ibodè ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun àti ìpínlẹ̀ Kwara wọ́n sì gbé bàbá kan tó jẹ́ òṣìṣẹ́fẹ̀yìnyì ní ẹ̀ka aṣọ́bode lọ.
A gbọ́ pé ilé ọ̀gbẹ́ni Emmanuel Owolabi gan-an ni wọ́n ti kó o ní pápá mọ́ra tí wọ́n sì gbé e wọ igbó lọ.
Ìyàwó Emmanuel tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Titilayọ ṣe àlàyé pé ní ọjọ́ Ajé, ìyẹn ọjọ́ kẹẹdógún, oṣù Ọ̀pẹ ni ọkọ òun wá bá òun ní ìsọ̀, ó ní kí òun máa lọ sí ilé lọ dáná pé òun ṣì ń jáde lọ nítòun.
Titilayo ti ìsọ̀ ní aago mẹ́fà àbọ̀ ìrọ̀lẹ́ ó sì lọ ilé láti dáná oúnjẹ alẹ́. Nígbà tó di aago méje ni àwọn agbébọn ya wọ ìlú, ilé rẹ̀ gan-an ni wọ́n mórí lé tààrà. Àlàyé rẹ̀ tẹ̀síwájú pé òun kò kọbi ara sí ìró ìbọn náà nítorí àwọn ọdẹ a máa wọ ìlú wá àmọ́ nígbà tó ń ró lemọ́lemọ́, òun bọ́ sínú àgbàlá láti wo ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ó rí àwọn agbébọn náà tí wọ́n fo ìgànná wọlé, ó sọ ède Hausa sí wọn àmọ́ wọ́n lù ú lálùbami wọ́n sì ń bèèrè owó. Ẹ̀kannáà ló gbọ́ ìró ọ̀kadà láti ìta tí wọ́n gbé ọkọ rẹ̀ lọ. Titilayọ̀ rawọ́ ẹ̀bẹ̀ pé kí wọn ó dákun gba ọkọ rẹ̀ kalẹ̀.
Nínú ìkọlù yìí ni àwọn agbébọn náà ti yìnbọn pa olóyè ìlú nígbà tó ń bọ̀ láti oko. Olóyè Dennis ń ti oko bọ̀ ló pàdé àwọn agbébọn yìí, ó fẹ́ sá ni wọ́n bá ta á níbọn tó sì kú.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ láti ẹnu agbẹnusọ wọn; Abiodun Ojelabi.
Ojelabi ní lọ́gán tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹ̀ ni àwọn ti kán lu ìgbẹ́ láti gba ọkùnrin náà kalẹ̀, ó ní àwọn ń ṣiṣẹ́ kárakára láti ríi pé Emmanuel padà wálé. Bákan náà ló wí pé ibi tí wọ́n pa olóyè Dennis sí ti kọjá ìpínlẹ̀ Ọ̀ṣun, ìpínlẹ̀ Kwara ni yóò ṣe ìwádìí ikú rẹ̀.
Ní báyìí, Owolabi ti padà dé o, àwọn ẹbí rẹ̀ yọ ayọ̀ pé orí kó o yọ.

Facebook Comments Box

Related

Tags: #iweiroyinyoruba#ìwéròyìnyorùbá #NewsOnline#newsfeed#TRENDINGNEWSTODAY#trendingpostbreaking newsinsecuritykidnapper'skidnappingkidnappingsnewsnews onlinenewsinyorubaondo poliveondostatesecurity
ADVERTISEMENT
Adeola Olanrewaju

Adeola Olanrewaju

Next Post
ÀWỌN AJÀFẸ́TỌ̀Ọ́MỌNÌYÀN BU ẸNU ÀTẸ́ LU ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ LÓRÍ OHUN TÍ WỌ́N ṢE FÚN ÀWỌN AFẸ̀HÓNÚHÀN.

ÀWỌN AJÀFẸ́TỌ̀Ọ́MỌNÌYÀN BU ẸNU ÀTẸ́ LU ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ ÌPÍNLẸ̀ ÈKÓ LÓRÍ OHUN TÍ WỌ́N ṢE FÚN ÀWỌN AFẸ̀HÓNÚHÀN.

Recommended

ỌWỌ́ ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ ABẸ́LÉ TẸ ÀWỌN MẸ́FÀ TÓ LỌ HÚ ÒKÚ NÍ ÌPÍNLẸ̀ GOMBE.

ỌWỌ́ ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ ABẸ́LÉ TẸ ÀWỌN MẸ́FÀ TÓ LỌ HÚ ÒKÚ NÍ ÌPÍNLẸ̀ GOMBE.

8 months ago
ÈÈYÀN MẸ́TA PÀDÁNÙ Ẹ̀MÍ WỌN NÍNÚ ÌJÀM̀BÁ INÁ TÓ WÁYÉ NÍ KANO.

ÈÈYÀN MẸ́TA PÀDÁNÙ Ẹ̀MÍ WỌN NÍNÚ ÌJÀM̀BÁ INÁ TÓ WÁYÉ NÍ KANO.

6 months ago

Popular News

  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ TI MÚ IKỌ̀ ONE-CHANCE NÍ IDIMU, ÈKÓ.

    Ọwọ́ tẹ ikọ̀ one-chance ní kebbi.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • OLÓLÙFẸ́ DA ÁSÍÌDÌ SÍ ỌMỌṢẸ́ Ọ̀RẸ́BÌNRIN RẸ̀ LÁRA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ILÉ ẸJỌ́ PÀṢẸ KÍ GBOGBO DÚKÌÁ SYLVA Ó DI TI ÌJỌBA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • AYÉ LÓ ṢE ỌLỌ́PÀÁ TÓ YÌNBỌN PA ÈÈYÀN.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ ṢE ÀWÁRÍ AYÉDÈRÚ ILÉ ỌMỌ ALÁÌNÍYÀÁ.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0

Connect with us

ADVERTISEMENT

Newsletter

Lorem ipsum dolor sit amet, consectetuer adipiscing elit. Aenean commodo ligula eget dolor.
SUBSCRIBE

Category

Site Links

  • Register
  • Log in
  • Entries feed
  • Comments feed
  • WordPress.org

About Us

We bring you the best Premium WordPress Themes that perfect for news, magazine, personal blog, etc. Check our landing page for details.

  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
  • Àṣà Yorùbá
  • Ìgbé-Ayé
  • Ìdánilárayá
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

Welcome Back!

Login to your account below

Forgotten Password? Sign Up

Create New Account!

Fill the forms below to register

All fields are required. Log In

Retrieve your password

Please enter your username or email address to reset your password.

Log In
No Result
View All Result
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

This website uses cookies. By continuing to use this website you are giving consent to cookies being used. Visit our Privacy and Cookie Policy.