ADVERTISEMENT
  • About
  • Contact
Monday, June 1, 2026
  • Login
  • Register
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
No Result
View All Result
Home Ìròyìn Tó Gbòde

ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ TI MÚ AFUARSÍ KAN LÓRÍ IKÚ DESTINY BOY.

Àti àwọn ìròyìn mìíran tó gbòde.

by Adeola Olanrewaju
January 24, 2026
in Ìròyìn Tó Gbòde
0
ILÉ ẸJỌ́ PÀṢẸ KÍ GBOGBO DÚKÌÁ SYLVA Ó DI TI ÌJỌBA.
0
SHARES
4
VIEWS
Pín Lórí FacebookPín Lórí ThreadsPín Lórí TwitterPín Lórí Bluesky
ADVERTISEMENT

Afurasí kan tó lọ́wọ́ nịnú ikú Destiny Boy tó kú láìpẹ́ yìí ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá báyìí kí ó wá sọ ti ẹnu rẹ̀ lórí ikú tó pa òǹkọrin náà.
Alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun; Oluseyi Babseyi ló sọ èyí di mímọ̀ pé àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ikú Adesina Afeez ti gbogbo àwọn èèyàn mọ̀ sí Destiny Boy.
Wọ́n ti tari ẹjọ́ náà lọ sí ẹ̀ka tí yóò ṣe ìwádìí rẹ̀ jinlẹ̀ bẹ́ẹ̀ sì ni afurasí kan ti ń gba atẹ́gùn látìmọ́lé báyìí.
Ìròyìn ikú Destiny gbàgboro kan ní ọ̀sẹ̀ yìí, fọ́nrán tó kọ́ jáde ni a ti rí Destiny ní ẹ̀yìn ọkọ̀ tí wọ́n fi òwú dí ihò imú àti etí rẹ̀. Ẹ̀yìn ìgbà náà ni wọ́n túfọ̀ rẹ̀ pé ó ti jáde láyé.
Kò sí ẹni tó sọ pàtó ohun tó ṣekú pa á, ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan ló sọ wí pé Destiny ti ń bá àìlera finrá láti ọjọ́ pípẹ́.
Ní báyìí, ìjọba ti ṣetán àti wádìí ikú Destiny Boy wọ́n sì ti mú afurasí kan sí àhámọ́.

Ìjọba ti mú awakọ̀ ìjọba BRT kan sí àhámọ́ lórí ẹ̀sùn pé ó gbá ẹnìkan tí ẹni náà sì kú.
Àlàyé tí a rí gbà láti ọ̀dọ LAMATA ni pé arábìnrin náà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Elizabeth Fresh fẹ́ sọdá títì ní ojú ọ̀nà Ikeja ní àbáwọ pápákọ̀ òfurufú ni ọkọ̀ BRT náà gbá a tó si kú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
Ọjọ́ kẹsàn-án, oṣù Ṣẹẹrẹ ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹ̀. Kíá ni awakọ̀ BRT náà ti fi ẹsẹ̀ fẹ́ ẹ àmọ́ ilé iṣẹ́ náà wá a jáde wọ́n sì fà á lé àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́ lọ́jọ́ náà gan-an.
Ilé iṣẹ́ LAMATA bá àwọn ẹbí Fresh kẹ́dùn lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, wọ́n rọ àwọn èèyàn láti máa ṣe àmúlò afárá ẹlẹ́sẹ̀.

WỌ́N DÁNÁ SUN AFURASÍ OLÈ KAN NÍ ÌPÍNLE BENUE.

Àwọn èrò tí inú bí ti dáná sun afurasí olè kan ní àdojúkọ ilé epo Prime ní Makurdi tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Benue.
A gbọ́ pé afurasí náà já ọ̀kadà náà gbà lọ́wọ́ ọlọ́kadà kan ní òpópónà Ahamdu Commisi, àwọn ọlọ́kadà yòókù tí wọ́n ríi lé e títí wọ́n sì báa ní ilé epo Prime nígbà tó fẹ́ gbé ọ̀kadà náà sọdá.
Wọn kò tilẹ̀ dúró de àwọn ọlọ́pàá, wọ́n wọ inú ìsọ̀ fọga kan tó wà nítosì, wọ́n kó àwọ àlokù táyà jọ wọ́n sì dáná sun ún lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀.
Ẹni tó ni ọ̀kadà náà ṣe àlàyé pé òun ń gùn ún bọ̀ ni afurasí náà dá òun dúró bíi èrò, ó yọ ìbọn sí òun ó sì ní kí òun ó bọ́ sílẹ̀. Bí ó ṣe ń gbé ọ̀kadà náà lọ ni òun bẹ̀rẹ̀ sí ní kigbe olè tí àwọn ará yòókù rẹ̀ fi gbá tẹ̀lé e.
Ó ní mílíọ́nù méjì náírà ni òun ṣẹ̀ṣẹ̀ fi ra ọ̀kadà náà.

ỌKỌ̀ ÀJÀGBÉ AGBÉPO WÓ LÉ ỌKỌ̀ SUV LÓRÍ NÍ ÌBÀDÀN.

Ọkọ̀ àjàgbé agbépo kan tó kún dẹ́nu bámú ti gbókìtì ní ojú ọ̀nà márosẹ̀ Akala ní Ibadan. Orí ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ SUV kan tí wọ́n gbé kalẹ̀ ni ó dà wó lé lórí tí ọkọ̀ náà sì parẹ́ mọ́lẹ̀.
Obìnrin ni ẹni tó ni ọkọ̀ yìí, nínú fọ́nrán rẹ̀ tó gbòde ni a ti rí obìnrin yìí tó bu awakọ̀ so pé yóò ra ọkọ rẹ̀ padà lódidi. Ó mú ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀ ó sì ń pe ọkọ rẹ̀.
Kò sí ẹni tó farapa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí bẹ́ẹ̀ sì ni ọkọ̀ agbépo náà kò gbaná.

HILDA BACI GBA ÀMÌ Ẹ̀YẸ ÀGBÁYÉ GÍNẸ́Ẹ̀SÌ ẸLẸ́KẸTA.

Kò wọ́pọ̀ nínú ẹni tó la fi òkò kan pa ẹyẹ méjì àmọ́ Hilda Baci ti fi hàn pé kò sí ohun tí kò ṣe é ṣe látàrí bí ó ṣe gba ìpè láti ilé iṣẹ́ àmì ẹ̀yẹ àgbáyé Gínẹ́ẹ̀sì pé ìrẹsì tó sè lọ́jọ́sí ti fún un ní àmì ẹ̀yẹ mìíràn.
Àmì ẹ̀yẹ ìkòko ìrẹsì tó tóbi jù lágbàáyé ni Hilda gbà níbi ìrẹsì tó sè náà àmọ́ ní báyìí, ilé iṣẹ́ náà wí pé oúnjẹ tó há ní ọjọ́ náà gba àmì ẹ̀yẹ oúnjẹ híhá tó gùn jù lágbàáyé.
Hilda dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn olólùfẹ́ àti alátìlẹ́yìn rẹ̀ pé wọ́n ṣeun, ó ní èyí kò bá ti ṣe é ṣe láisí àtilẹ́yìn wọn.

ADVERTISEMENT

INÁ JÓ NÍ ITẸ́ ÒKÚ KAN NÍ KANO.

ADVERTISEMENT

Iná sẹ́yọ ní itẹ́ òkú kan tó wa ní ìpínlẹ̀ Kano, ọ̀pọ̀ oórì ni ó sì jóná ráúráú. Itẹ́ òkú Abattuwa tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Fagge ní ìpínlẹ̀ Kano ni iná sẹ́yọ níbẹ̀ lóru mọ́jú.
Bashir Hassan ló pe ilé iṣẹ́ panápaná lóru náà tí àwọn náà sì ta mọ́ra dé ibẹ̀, iná náà ti mú gbogbo koríko ibẹ̀ kí wọ́n tó dé.
Wọ́n kojú iná náà wọ́n sì pa á fin-ín fin-ín àmọ́ ọ̀pọ̀ oórì ló ti jóná.
Ilé iṣẹ́ panápaná ṣe àyẹ̀wò ibi iṣẹ̀lẹ̀ náà, wọ́n ní ara kóriko ni iná náà ti bẹ̀rẹ̀ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé èèyàn kan ló ju àmukù sìgá sí ilẹ̀ tó ṣe okùnfà iná náà.

ÌYÀWÓ FI ABẸ YA OJÚ ỌMỌBÌNRIN TÍ ỌKỌ RẸ̀ FẸ́ FẸ́ LÉE NÍYAKÚYA.
Ọmọdébìnrin kan ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún kan ti wà ní ilé ìwòsàn níbi tó ti ń gba ìtọ́jú lẹ́yìn ti ìyàwó ilé kan fi abẹ ya ojú rẹ̀ níyakúya.
Àlàyé tí a rí gbà nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni pé ọkọ obìnrin yìí ń da ọmọbìnrin náà láàmú pé òun yóò fẹ́ ẹ àmọ́ ó kọ̀, ìyàwó rẹ̀ rí fìrìnfìrìn pé ọkọ rẹ̀ ń jẹ̀ sí ọ̀dọ ọmọbìnrin náà, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní halẹ̀ mọ́ ọn àti ìyá rẹ̀ pé òun yóò pa á ni bí ó bá tún dé ọ̀dọ ọkọ rẹ̀.
Kò pẹ́ kò jìnnà ni obìnrin náà ṣàdédé lọ ká ọmọbìnrin náà mọ́lé tó sì fi abẹ ya ojú rẹ̀ níyakúya. Ilé ìwòsàn ni ó wà báyìí tó ti ń gba ìtọ́jú.
Agbègbè Donga ní ìpínlẹ̀ Taraba ni èyí ti ṣẹlẹ̀. Abass ni orúkọ ọkùnrin náà nígbà tí ìyàwó rẹ̀ ń jẹ́ Ramotu.
Abass ń lé ọmọ náà kiri títí Ramotu ìyàwó ilé rẹ̀ fi mọ̀, Ramotu kò ṣe méní ṣe méjì, ó fi abẹ ba ojú ọmọ náà jẹ́.
Àlàyé náà tẹ̀síwájú pé Abass lọ sí ilé ọmọbìnrin náà ó sì kìlọ̀ fún ìyá rẹ̀ pé kò gbọdọ̀ só fún ọlọ́pàá, kí ó jẹ́ kí àwọn ó tilé yanjú rẹ̀. Bákan náà ló halẹ̀ mọ́ wọn pé òun ní owó lọ́wọ́ òun yóò sì pa àtìyá àti ọmọ bí wọ́n bá fi lé fi ẹjọ́ sun ọlọ́pàá.
Ìyá ọmọ yìí ṣe àlàyé pé ọkọ òun ṣẹ̀ṣẹ̀ kú ni òun kò sì tíì jáde opó, ó rawọ́ ẹ̀bẹ̀ pé kí wọn ó gba òun lọ́wọ́ Abass àti ìyàwó rẹ̀. ó ní ọmọ òun kọ̀ láti fẹ́ Abass ni ó fa gbogbo èyí. Abass dàgbà ju ọmọ náà ẹgbẹ́ bàbá rẹ̀ níí ṣe òun kò sì le fi ọmọ fún un.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá fèsì pé àwọn ti gba ìfisùn ọ̀rọ̀ náà, wọ́n ti rí ọmọ náà tí wọ́n ba ojú rẹ̀ jẹ́ wọ́n sì ti mú àwọn afurasí náà sí àhámọ́ títí wọn yóò fi fi ojú ba ilé ẹjọ́.

Facebook Comments Box

Related

Tags: #iweiroyinyoruba#newsfeed#newstoday#trendingpostbreakingbreaking newsclebritynewsdonotmissÌròyìnÌròyìn Tó GbòdeIwe Iroyin Yorubanewsnews onlinenewsinyourbanewsonlinenewstodayirubanews
ADVERTISEMENT
Adeola Olanrewaju

Adeola Olanrewaju

Next Post
ÀWỌN ÈÈYÀN Ń ṢE WÁ BÍI Ẹ̀GBIN – ÀWỌN AGBÁLẸ̀ LAWMA.

ÀWỌN ÈÈYÀN Ń ṢE WÁ BÍI Ẹ̀GBIN – ÀWỌN AGBÁLẸ̀ LAWMA.

Recommended

ÌṢẸ̀LẸ̀ ÌJÍNIGBÉ RẸPẸTẸ NÍ ÌPÍNLẸ̀ DELTA.

ÌṢẸ̀LẸ̀ ÌJÍNIGBÉ RẸPẸTẸ NÍ ÌPÍNLẸ̀ DELTA.

1 year ago
ILÉ ADÁHUNṢE NI WỌ́N TI RÍ ÒKÚ FUNMILAYO ÀTI ỌMỌ RẸ̀.

ILÉ ADÁHUNṢE NI WỌ́N TI RÍ ÒKÚ FUNMILAYO ÀTI ỌMỌ RẸ̀.

6 months ago

Popular News

  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ TI MÚ IKỌ̀ ONE-CHANCE NÍ IDIMU, ÈKÓ.

    Ọwọ́ tẹ ikọ̀ one-chance ní kebbi.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • OLÓLÙFẸ́ DA ÁSÍÌDÌ SÍ ỌMỌṢẸ́ Ọ̀RẸ́BÌNRIN RẸ̀ LÁRA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ILÉ ẸJỌ́ PÀṢẸ KÍ GBOGBO DÚKÌÁ SYLVA Ó DI TI ÌJỌBA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • AYÉ LÓ ṢE ỌLỌ́PÀÁ TÓ YÌNBỌN PA ÈÈYÀN.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ ṢE ÀWÁRÍ AYÉDÈRÚ ILÉ ỌMỌ ALÁÌNÍYÀÁ.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0

Connect with us

ADVERTISEMENT

Newsletter

Lorem ipsum dolor sit amet, consectetuer adipiscing elit. Aenean commodo ligula eget dolor.
SUBSCRIBE

Category

Site Links

  • Register
  • Log in
  • Entries feed
  • Comments feed
  • WordPress.org

About Us

We bring you the best Premium WordPress Themes that perfect for news, magazine, personal blog, etc. Check our landing page for details.

  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
  • Àṣà Yorùbá
  • Ìgbé-Ayé
  • Ìdánilárayá
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

Welcome Back!

Login to your account below

Forgotten Password? Sign Up

Create New Account!

Fill the forms below to register

All fields are required. Log In

Retrieve your password

Please enter your username or email address to reset your password.

Log In
No Result
View All Result
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

This website uses cookies. By continuing to use this website you are giving consent to cookies being used. Visit our Privacy and Cookie Policy.