ADVERTISEMENT
  • About
  • Contact
Monday, June 1, 2026
  • Login
  • Register
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
No Result
View All Result
Home Ìròyìn Ìròyìn Agbègbè

BUKUNMI AKINAANU ‘OMIJE OJU MI’ TI DÁGBÉRE FÁYÉ.

Àti àwọn ìròyìn mìíran tó gbòde.

by Adeola Olanrewaju
January 15, 2026
in Ìròyìn Agbègbè, Ìròyìn Tó Gbòde
0
ILÉ ẸJỌ́ PÀṢẸ KÍ GBOGBO DÚKÌÁ SYLVA Ó DI TI ÌJỌBA.
0
SHARES
4
VIEWS
Pín Lórí FacebookPín Lórí ThreadsPín Lórí TwitterPín Lórí Bluesky
ADVERTISEMENT
ADVERTISEMENT

Òǹkọrin ẹ̀mí nnì; Bukunmi Akinaanu tí gbogbo àwọn èèyàn mọ̀ sí omijé ojú mi ti dágbére fáyé lọ́jọ́ ìṣẹ́gun, ọjọ́ kejìlá, oṣù Ṣẹẹrẹ.
Ilé ìwòsàn kan ní ìpínlẹ̀ Èkó ni ó dákẹ́ sí. Ọ̀rẹ́ rẹ̀; Ayo Melody ló túfọ̀ ikú Bukunmi lójú òpó X rẹ̀ pé ó ti kí ayé pé ó dìgbóṣe.
Ohun tó ṣe okùnfà ikú rẹ̀ kò tíì jẹ́ mímọ̀ ní pàtó àmọ́ ohun tí àwọn èèyàn ń gbé pòòyì ẹnu ni pé ẹsẹ̀ kan ń bá Bukunmi fínra láti ìgbà díẹ̀ sẹ́yìn.
Nínú fọ́nrán kan tó gbòde, a rí Bukunmi tó jókòò sórí àga tí wòlíì sì ń gba àdúrà sí ẹsẹ̀ tó nà sí orí àga mìíràn. Pásítọ̀ náà ń sọ nínú fọ́nrán náà pé kí ọfà inú ẹsẹ̀ náà kó jáde.
A kò le sọ ní pàtó pé ẹsẹ̀ náà ló ṣokùnfà ikú Bukunmi àmọ́ ohun tó dájú ni pé ó ti lọ bá Ọlọ́run rẹ̀.
Ẹnìkan náà ṣe fọ́nrán bí wọ́n ṣe gbé òkú Bukunmi kúrò nínú yàrá ilé ìwòsàn náà ló sí ilé ìgbókùúsí tó sì fi orí ìtàkùn ayélujára.

ILÉ ẸJỌ́ KỌ̀ LÁTI GBA ONÍDÙÚRÓ PORTABLE.

Ilé ẹjọ́ gíga ìjọba tó wà ní Ọ̀tà, ìpínlẹ̀ Ogun ti kọ̀ láti gba onídùúró Habeeb Okikiola tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí Portable.
Portable farahàn níwájú ilé ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn ìṣenimọ́kumọ̀ku àti àwọn ẹ̀sùn mìíràn tí ìyàwó rẹ̀ Asabi fi kàn án.
Oluseyi Babaseyi; ẹni tó jẹ́ alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun ṣe àlàyé pé adájọ́ kọ̀ láti gba onídùúró rẹ̀ wọ́n sì tari rẹ̀ sí àtìmọ́lé.
Àwọn ẹ̀sùn tí ìjọba fi kan Portable ni pé ó lu ìyàwó rẹ̀ Asabi àti àwọn mìíràn ní ilé ọtí rẹ̀ tó wà ní Iyana Ilogbo, ó jí ọkọ̀ tí iye rẹ̀ ń lọ bíi mílíọ́nù méjìlá náírà, ó sì tún kojú ọlọ́pàá obìnrin kan nígbà tí ìyẹn ń ṣe iṣẹ́ ọba.
Àwọn ẹ̀sùn yìí ni ìjọba fi kan Portable, Asabi fúnra rẹ̀ kò wá sí ilé ẹjọ́ àmọ́ àwọn ẹlẹ́rìí rẹ̀ péjú, bákan náà ni ọlọ́pàá obìnrin tí wọ́n ní ó nà kò wá sí ilé ẹjọ́.
Adájọ́ ní òun kò le gba onídùúró rẹ̀ àfi tí àwọn èèyàn yìí bá yọjú ó sì pàṣẹ kí wọn ó fi sí àtìmọ́lé di ìgbẹ́jọ́ tó ń bọ̀.

ÌJỌBA ÌPÍNLẸ̀ AKWA IBOM NÍ ÀWỌN KÒ MỌ̀ NÍPA ÀBÁDÒFIN ÌBÁṢEPỌ̀ LÁÀRÍN OBÌNRIN ÀTI ỌKỌ ỌLỌ́KỌ TÓ GBÀGBORO KAN.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Akwa Ibom ti fèsì sí ọ̀rọ̀ tó ń jà ràìnràìn lórí ìtàkùn ayélujára pé àwọn kò mọ̀ nípa àbádòfin ìjìyà fún obìnrin tó bá ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin tó ti láya nílé.
Ohun tí àwọn èèyàn ń ṣe àtagbà rẹ̀ ni pé ìjọba ìpínlẹ̀ náà ti gbé àbádòfin kalẹ̀ ní èyí tó sọ pé obìnrin tó bá ní àjọṣepọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin tó ti láya nílé yóò ṣe ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́wàá nígbà tí ọkùnrin bẹ́ẹ̀ yóò san mílíọ́nù méjì owó ìtanràn.
Àwọn ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Akwa Ibom ti fèsì pé àwọn kò mọ̀ nípa àbádòfin bẹ́ẹ̀, wọ́n ní àwọn èèyàn kan ló gbé ọ̀rọ̀ náà jáde kò wá láti ọ̀dọ ìjọba.
Jerry Otu; ẹni tó jẹ́ alága ìgbìmọ̀ ìfitónilétí fún ilé náà ṣe àlàyé pé ìgbìyànjú láti yẹpẹrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ náà ni èyí jẹ́, ó ní iṣẹ́ àwọn ká àwọn lára ju irú òfinkófin báyìí lọ.
Àlàyé rẹ̀ tẹ̀síwájú síi pé àwọn tó fẹ́ ba orúkọ igbákejì Gómìnà ìpínlẹ̀ náà jẹ́ ni wọ́n gbé irọ́ bàǹtàbanta náà jáde.
Ó rọ àwọn èèyàn láti yàgò fún ìròyìn òfegèé tí kò fi ẹsẹ̀ múlẹ̀.

Facebook Comments Box
ADVERTISEMENT

Related

Tags: #iweiroyinyorubabreakingnewsgospelsingerÌròyìn Tó GbòdeIwe Iroyin Yorubanewonlinenewsnewseverywhernewsinyorubaomijeojumisharenewstodaynewstrending
ADVERTISEMENT
Adeola Olanrewaju

Adeola Olanrewaju

Next Post

WỌ́N TI DÁ ÒṢÌṢẸ́FẸ̀YÌNYÌ Ẹ̀ṢỌ́ AṢỌ́BODÈ ILẸ̀ WA SÍLẸ̀ LẸ́YÌN OWÓ ÌTÚSÍLẸ̀.

Recommended

ILÉ ẸJỌ́ SỌ OLÙKỌ́ TÓ BÁ AKẸ́KỌ̀Ọ́ LÒ PỌ̀ SÍ Ẹ̀WỌ̀N GBÉRE.

ILÉ ẸJỌ́ SỌ OLÙKỌ́ TÓ BÁ AKẸ́KỌ̀Ọ́ LÒ PỌ̀ SÍ Ẹ̀WỌ̀N GBÉRE.

1 year ago
ÀÀRẸ BOLA AHMED TINUBU YÓÒ ṢE ÌWÚRE ỌJỌ́ ÌBÍ RẸ̀ LÓNÌÍ.

ÀÀRẸ BOLA AHMED TINUBU YÓÒ ṢE ÌWÚRE ỌJỌ́ ÌBÍ RẸ̀ LÓNÌÍ.

1 year ago

Popular News

  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ TI MÚ IKỌ̀ ONE-CHANCE NÍ IDIMU, ÈKÓ.

    Ọwọ́ tẹ ikọ̀ one-chance ní kebbi.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • OLÓLÙFẸ́ DA ÁSÍÌDÌ SÍ ỌMỌṢẸ́ Ọ̀RẸ́BÌNRIN RẸ̀ LÁRA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ILÉ ẸJỌ́ PÀṢẸ KÍ GBOGBO DÚKÌÁ SYLVA Ó DI TI ÌJỌBA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • AYÉ LÓ ṢE ỌLỌ́PÀÁ TÓ YÌNBỌN PA ÈÈYÀN.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ ṢE ÀWÁRÍ AYÉDÈRÚ ILÉ ỌMỌ ALÁÌNÍYÀÁ.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0

Connect with us

ADVERTISEMENT

Newsletter

Lorem ipsum dolor sit amet, consectetuer adipiscing elit. Aenean commodo ligula eget dolor.
SUBSCRIBE

Category

Site Links

  • Register
  • Log in
  • Entries feed
  • Comments feed
  • WordPress.org

About Us

We bring you the best Premium WordPress Themes that perfect for news, magazine, personal blog, etc. Check our landing page for details.

  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
  • Àṣà Yorùbá
  • Ìgbé-Ayé
  • Ìdánilárayá
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

Welcome Back!

Login to your account below

Forgotten Password? Sign Up

Create New Account!

Fill the forms below to register

All fields are required. Log In

Retrieve your password

Please enter your username or email address to reset your password.

Log In
No Result
View All Result
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

This website uses cookies. By continuing to use this website you are giving consent to cookies being used. Visit our Privacy and Cookie Policy.