Alága ẹgbẹ́ òṣèlú APC; Ọ̀jọ̀gbọ́ Nentawe Yilwatda ti ṣe ìlérí fún ààrẹ Bola Ahmed Tinubu pé àwọn ará ìpínlẹ̀ Plateau yóò di ìbò mílíọ́nù kan ṣangiliti fún un nínú ìdìbò ọdún 2027.
Níbi ìpàdé àwọn èèkàn èèkàn ẹgbẹ́ náà tó wáyé ní Pankshin, ìpínlẹ̀ Plateau lọ́jọ́ ìṣẹ́gun ni Yilwatda ti ṣe ìlérí náà. Ó wí pé èyí yóò ṣe é ṣe látàrí pé ẹgbẹ́ òṣèlú APC ń gbèrú síi lójoojúmọ́ nígbà tí àwọn ẹgbẹ́ òṣèlú alátakò ń fi ojoojúmọ́ wà sẹ́yìn bíi ìrè.
Yilwatda fi ìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé yóò rọrùn fún ẹgbẹ́ òṣèlú APC láti jáwé olúborí ní ìpínlẹ̀ Plateau lọ́dún 2027 ju ti ọdún 2023 lọ, ìdí ni pé gbogbo àwọn tó ń ṣe àtakò fún wọn lọ́dún 2023 ni wọ́n ti dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC báyìí. Láti orí Gọmìnà Caleb Mutfwang dé orí àwọn kọmíṣọ́nà àti àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ pátá ni wọ́n ti ń ṣe àtìlẹ́yìn fún Tinubu báyìí, fún ìdí èyí, bí ẹni ká aṣọ lórí ìkọ́ ni ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ó ṣe kó gbogbo ìbò ìpínlẹ̀ náà lọ́dún 2027.
Bákan náà ni Yilwatda sọ wí pé òun yóò dẹ́kun bíbu ẹnu àtẹ́ lu Gómìnà Mutfwang ní gbàgede, ó ní àwọn ti di ọmọ ìyá báyìí, tó bá ṣe ohun tó kù díẹ̀ káàtó, òun yóò pè é lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ tàbí kí òun ó lọ bá a ní ọ́fíìsì.
Kò tán síbẹ̀ o, Yilwatda ní ojú ọ̀run ẹgbẹ́ òṣèlú APC tó ẹyẹ ẹ́ fò láì fi apá gúnra, kò sí iye ẹni tó le darapọ mọ́ ẹgbẹ́ náà tí wọ́n le já ẹgbẹ́ náà gbà bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò le du ipò mọ́ ara wọn lọ́wọ́ nítorí pé ipò pọ̀ rẹpẹtẹ, láti orí aṣòfin dé orí aṣojúṣòfin tó fi dé orí alága ìjọba ìbílẹ̀.
Ọ̀rọ̀ tí Yilwatda sọ yìí fi ara pẹ́ èyí tí Yahaya Bello sọ pé Ọlọ́run ló rán Tinubu sí wa bíi ańgẹ́lì. Bí kò bá jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, àwọn olóṣèlú ò ní máa ṣe ègbè lẹ́yìn tóyìí.
Ṣé ẹ rántí bí Bello ṣe sọ ọ́?
Gómìnà ìpínlẹ̀ Kogi tẹ́lẹ̀rí; Yahaya Bello ti ṣe àpèjúwe ààrẹ Bola Ahmed Tinubu gẹ́gẹ́ bíi áńgẹ́lì tí Ọlọ́run rán láti tún Nàìjíríà ṣe.
Yahaya sọ èyí lórí ìkànnì ẹ̀rọ amóhùmáwòrán pé bí a bá ń retí kí Ọlọ́run ó sọ áńgẹ́lì kalẹ̀ láti ojú ọ̀run kí ó sì fi ìyẹ́ fò wọ Nàìjíríà, a ó dúró pẹ́ nítorí pé Ọlọ́run ti sọ áńgẹ́lì náà kalẹ̀ fún wa tipẹ́ àwa la ò kíyèsí. Ta ni áńgẹ́́lì náà? Aṣíwájú Bola Ahmed Tinubu ni áńgẹ́lì tí Ọlọ́run sọ̀ kalẹ̀ láti tún orílẹ̀-èdè yìí ṣe.
Ó ti pẹ́ tí a ti ń retí olùgbalà tí yóò tún Naìjíríà ṣe, áńgẹ́lì wo ló tún ju Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu lọ? Ó yọ owó ìrànwọ́ orí epo bẹntiróòlù, ó ṣètò èyáwó kàwé, ó ṣe àtúntò ẹ̀sẹ́wó owó òkèrè, ó ṣe àwọn òfin tó pawó wọlé sápò ìjọba àti aráàlú, ẹni tó bá ń retí iṣẹ́ ìyanu nìkan ni yóò sọ pé Tinubu kò ṣe tó, ààrẹ kan ò tún gbọdọ̀ ṣe ju báyìí lọ.
Ṣáájú ọdún 2015 ni a ti ń bèèrè fún Nàìjíríà titun ní èyí tí ayé ó dẹ gbogbo èèyàn lọ́rùn, gbogbo ohun tí a ń fẹ́ náà ni ààrẹ ń ṣe lọ́kọ̀ọ̀kan, ẹ kò le retí kí ó ṣe gbogbo rẹ̀ tán lẹ́ẹ̀kan náà nítorí pé ìlú ti bàjẹ́ jìnnà kí Tinubu ó tó gba ìjọba.
Èmi yóò maáa ṣe àtìlẹyìn fún ààrẹ Tinubu nítèmi nítorí pé mom ọ rírì iṣẹ́ tó ń ṣe, kò ṣe é ṣe fún ààrẹ láti ṣe gbogbo rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan náà mo sì nírètí pé yóò ṣe gbogbo rẹ̀ pátá bí ọjọ́ ti ń gorí ọjọ́.
Ohun tí a ń fẹ́ lọ́jó¸iwájú ni pé nígbà tí ààrẹ ó bá fi parí ìṣejọba ẹlẹ́ẹ̀kejì, yóò fi àwọn ọmọlẹ́yìn rere lélẹ̀ tí yóò máa tọ ipasẹ̀ ààrẹ tí wọn yóò sì má atẹ̀lé ìlànà ìṣejọba ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ní èyí tí yóò jẹ́ pé irú àwọn èèyàn rere bíi èmi àti àwọn mìíràn tó nífẹ̀ẹ́ orílẹ̀-ède Nàìjíríà dénú ni yóò má abọ́ sípò ààrẹ.
Lọ́jọ́ tònìí, inú mi dùn pé mo jẹ́ ọmọlẹ́yìn Tinubu, ayọ mi kún, bí ẹ bá sì wo ìṣejọba mi nígbà tí mo wà nípò, ẹ ó ríi pé àwọn iṣẹ́ rere tí mo ṣe ń tọ̀ mí lẹ́yìn – èyí ni àwọn ọ̀rọ̀ tí Yahaya Bello sọ.
Kò yọ gómìnà ìpínlẹ̀ Imo sílẹ̀:
Gómìnà ìpínlẹ̀ Imo, ẹni tó tún jẹ́ alága àwọn gómìnà lábẹ́ àsíá ẹgbẹ́ òṣèlú APC; Hope Uzodimma ti sọ wí pé orílẹ̀-ède wa Nàìjíríà ti wà ní ọ̀nà àṣelà àti ọrọ̀ rẹpẹtẹ lábẹ́ ìṣejọ́ba ààrẹ Bola Ahmed Tinubu.
Ó sọ èyí níbi ìpàdé àwọn gómìnà tó wáyé ní ìpínlẹ̀ Kebbi pé ìṣejọba ààrẹ Bola Ahmed Tinubu jẹ́ èyí tí yóò mú àtúntò bá ọrọ̀ ajé ní èyí tí yóò mú ayé dẹrùn gẹ́gẹ́ bí a ti ń ríi báyìí.
Èyí yóò sọ Nàìjíríà di ìlú ọlọ́rọ̀ bíi tìgbà kan, ṣíṣe àyọkúrò owó ìrànwọ́ epo bẹntiróòlù mú kí owó tó ń wọlé sí àpò ìjọba ó pọ̀ síi.
Bákan náà ni ìjọba yìí ti pèsè iṣẹ́ fún àwọn ọ̀dọ́ tó lé ẹgbẹ̀rún ní èyí tó mú àdínkù bá ìṣẹ́ àti òṣì. Kí á tó rí ọdún díẹ̀ síi, àwọn tí ìjọba ṣètò ẹ̀kọ́ṣẹ́ fún yóò ti di ọ̀gá, nìṣẹ́ bá di ohun àmúpìtàn.
Ọ̀rọ̀ Uzodimma tẹ̀síwájú pé ẹgbẹ́ òṣèlú kan ló wà ní orílẹ̀-ède Nàìjíríà, APC sì ni orúkọ rẹ̀, gbogbo àwọn gómìnà àti aṣòfin ni wọ́n ń fi ojoojúmọ́ darapọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ òṣèlú APC nítorí ìlànà rere tí ààrẹ Bola Ahmed Tinubu fi lélẹ̀.




