Ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Wojuola ti jáde síta fi ẹ̀sùn kan ọ̀gá ọlọ́pàá àgọ́ GRA ní Asaba tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Delta pé ó fi ẹ̀sùn ìpànìyàn kan òun látàrí pé òun ṣe ìrànwọ́ fún ẹnìkan tí òun rí lójú pópó.
Ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2025 ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹ̀, Wojuola ní òun ń lọ nínú ọkọ̀ òun lọ́jọ́ náà ni òun rí ọkùnrin kan tí ó ń japoró ikú tí kò le mí dáadáa, àwọn èèyàn kàn ń wò ó níran wọn kò ṣe ìrànwọ́ fún un ni òun bá gbé e sínú ọkọ̀ òun, bí ó ṣe dé ilé ìwòsàn ni ọkùnrin náà kú. Ilé ìwòsàn náà pe àwọn ọlọ́pàá nítorí òun kò mọ arákùnrin náà rí, òun kàn ṣe ìrànwọ́ fún un ni.
Wojuola ṣe àlàyé pé àwọn ọlọ́pàá àgọ́ GRA tí wọ́n pè fi ẹ̀sùn ìpànìyàn kan òun, wọ́n mú òun ní tìpátìkúùkù kọ àkọsílẹ̀ pé òun ló pa ọkùnrin náà, ọ̀gá àgọ́ náà tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Joseph Udoh sọ fún òun lójúkojú pé òun á fi ìyà jẹ ẹ́, ṣe bí ìwọ ni Jésù olùgbàlà, nígbà tí mo bá ṣetán pẹ̀lú rẹ, oò ní ṣe irú ẹ̀ mọ́.
Àti ìgbà náà ni wọ́n ti ń bá Wojuola ṣe ẹjọ́, wọ́n fi ẹ̀sùn ìpànìyàn kàn án. Àwọn ẹbí ẹni tó kú náà jáde ṣe àlàyé pé ọmọ wọn ní àìlera tẹ́lẹ̀ àmọ́ àwọn ọlọ́pàá kò dá Wojuola sílẹ̀. Lẹ́yìn tí àwọn lọ́gàálọ́gàá lẹ́nu iṣẹ́ ọba dá síi tí wọ́n sì padà yọ̀ǹda rẹ̀ lẹ́yìn bíi oṣù mẹ́wàá, àwọn ọlọ́pàá wọ́ gbogbo owó inú àpò owó rẹ̀ wọ́n sì fún un ní ẹgbẹ̀rún méjì náírà kó fi wọ ọkọ̀ relé.
Wojuola ní ó wá yé òun ìdí tí àwọn èèyàn kò fi ki ń ṣe ìrànwọ́ fún ẹlòmíràn, ó ní àṣìṣe gbáà ni òun ṣe òun kò sì ní ṣe irú rẹ̀ mọ́.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ti fèsì pé àwọn ti gba ẹ̀sùn náà àwọn sì ti ké sí ọ̀gá ọlọ́pàá àgọ́ GRA, Asaba kó wá ṣe àlàyé.
Ìgbésẹ̀ tí ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá gbé:
Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Delta; Bright Edafe ti kọ ọ́ sí ojú òpó rẹ̀ pé àwọn ti pe Wojuola àwọn sì ti dá owó rẹ̀ padà fún un bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ti yọ Joseph Udoh níṣẹ́, ó parí rẹ̀ pẹ̀lú pé Nàìjíríà yóò dára lọ́jọ́ kan.
Bí wọ́n ti sọ ti Wojuola síbìkan ni ọkùnrin mìíràn ti jáde fi ẹ̀sùn kan àwọn ọlọ́pàá pé wọ́n dá òun dúró lórí afárá otedola fún àyẹ̀wò ọkọ̀ wọ́n sì fi tìpátìkúùkú gba àádọ́rin ẹgbẹ̀rún (#70,000) náírà lọ́wọ́ rẹ̀.
Nifemi Oyerinde ni orúkọ ọkùnrin yìí, iṣẹ́ gbẹ́dògbẹ́dò ló ń ṣe. Ó ṣe àlàyé pé lọ́jọ́ Àbámẹ́ta, òun ń lọ nínú ọkọ̀ òun lórí afárá Otedola nígbà tí wọ́n dá òun dúró fún àyẹ̀wò, wọ́n gba báàgì rẹ̀ wọ́n sì yẹ̀ ẹ́ wò fínnífínní, wọ́n mú un lọ sí ìdí ọkọ̀ tiwọn wọ́n sì gba ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀.
Nifemi sọ fún wọn pé iṣẹ́ agbẹ́dò ni òun ń ṣe àmọ́ wọ́n takú pé gbájúẹ̀ ni ó ń ṣe, wọ́n ní kí ó pe èèyàn kan tó le jẹ́rìí pé iṣẹ́ agbẹ́dò ni ó ń ṣe. Nifemi ní òun pe ọ̀gá òun ó sì jẹ́rìí òun síbẹ̀ àwọn ọlópàá kọ̀, wọ́n ní ọmọ yàhú ni bí kò bá sì san owó ìtúsílẹ̀ àwọn yóò mú un lọ sí àgọ́ wọn yóò sì ṣe ẹjọ́.
Àlàyé Nifemi tẹ̀síwájú síi pé wọ́n yẹ ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ òun wò wọn kò bá nǹkankan tó jẹ mọ́ ìwà ọ̀daràn, wọ́n wá sọ fún òun pé kí òun ó san mílíọ́nù kan náírà tàbí kí òun ó kálọ sí àgọ́.
Ó ní òun bẹ̀ wọ́ títí àmọ́ wọ́n ní kò ní dín ní ọ̀dúnrún ẹgbẹ̀rún (#300,000) náírà, lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bẹ̀, wọ́n padà gba àádọ́rin ẹgbẹ̀rún (#70,000) náírà lọ́wọ́ rẹ̀.
Nifemi wí pé wọ́n na ìbọn sí òun ní ọrùn ní gbogbo àsìkò yìí títí òun fi tari owó náà sí àpò owó ọ̀kan nínú wọn, lẹ́yìn náà ni wọ́n tẹ̀lé òun dé ìdí ọkọ̀ òun kí wọ́n tó gbé ìbọn náà kúrò lọ́rùn rẹ̀.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ láti ẹnu Abimbola Adebisi; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ wọn pé àwọn ti gbọ́ sí ẹ̀sùn náà àwọn sì ti bẹ̀rẹ̀ ìwádíì lórí rẹ̀.
Òní kọ́ ni àwọn aráàlú ti ń fi ẹ̀sùn kan àwọn ọlọ́pàá lórí ìlọ́nilọ́wọ́gbà. Nínú osù Ọ̀pẹ ọdún tó kọjá ni àwọn ará Ketu-Alapere figbe ta:
Awọn ará Ketu-Alapere ní ìpínlẹ̀ Èkó ti fi ẹ̀sùn kan àwọn ọlọ́pàá àgọ́ Alapere pé wọ́n ń yọ àwọn lẹ́nu wọ́n sì ń lọ́ àwọn lọ́wọ́ gbà.
Wọ́n ní àwọn ọlọ́pàá náà ó ṣàdédé wọ àdúgbò wá ní alẹ́ wọn yóò sì máa kó gbogbo àwọn tí wọ́n bá rí. Wọ́n ní owó tabua ni ẹni tí wọ́n bá mú yóò san ní owo ìtúsílẹ̀ kó tó le padà sílé.
Lára àwọn tí wọ́n kó gbẹ̀yìn ni àwọn ọmọ ilé ìwé gíga Yaba, wọ́n ní àwọn ń ti ilé ìjọsìn bọ̀ ni àwọn ọlọ́pàá náà he àwọn bíi ìgbín tí wọ́n sì kó wọn lọ sí àgọ́ wọn.
Solomon Adelumola; ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe àlàyé pé àwọn ṣe ìdámọ̀ ara wọn pẹ̀lú káàdì ìdánimọ̀ ilé ìwé àmọ́ níṣe ni àwọn ọlọ́pàá gba ilé sí agbójú, wọn kò tilẹ̀ wò ó rárá tí wọ́n fi tari wọn sínú ọkọ̀.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó wí pé àwọn lọ sí ilé ìjọsìn ní Alapere àwọn sì jáde ní aago mẹ́wàá àbọ̀ alẹ́, wọ́n yà nílé ọ̀rẹ́ wọn kan tó ń gbé nítòsí ibẹ̀ wọ́n sì ń darí lọ ilé tiwọn.
Aago mọ́kànlá ń lọ lù ni wọ́n rí àwọn ọkùnrin méjì kan tó ń sún mọ́ wọn lójú ọ̀nà ẹlẹ́sẹ̀ Ketu, wọn kò sá nígbà tí wọn kò lẹ́bọ lẹ́rù àmọ́ àwọn ọkùnrin náà rá wọn mú ní ṣòkòtò ló bá di ọlọ́pàá àfi bí wọ́n ṣe wọ́ wọn bíi ọ̀daràn lọ sínú ọkọ̀ – Solomon Adelumola.
Ẹlòmíràn náà ṣe àlàyé ohun tí ojú rẹ̀ rí lọ́wọ́ àwọn ọlọ́pàá Alapẹ̀rẹ̀, David Owolabi ní wọ́n gba ẹ̀rọ̀ ìbánisọ̀rọ̀ òun wọ́n sì bà á jẹ́ níbi tí wọ́n ti ń wọ́ ọ ní ìwọ́kúwọ̀ọ́, àwọn mẹ́wàá mìíràn ni wọ́n kó pẹ̀lú rẹ̀.
Nígbà tí wọ́n dé àgọ́, wọn kò bèèrè ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ wọn, ogún ẹgbẹ̀rún náìrà ni wọ́n bèèrè lọ́wọ́ ẹnìkọ̀ọ̀kan tó bá fẹ́ padà sílé. David ní òun takú pé òun yóò rí ọ̀gá nítorí akẹ́kọ̀ọ́ lòun àmọ́ ìyàlẹ́nu ló jẹ́ nígbà tí ọ̀gá ní kí òun ó san owó náà.
Àlàyé David tẹ̀síwájú pé òun àti ọ̀rẹ́ òun tí wọ́n jọ kó bẹ̀ wọ́n pé akẹ́kọ̀ọ́ láwọn wọn kò ní irú owó bẹ́ẹ̀ àmọ́ wọ́n ní kò kan àwọn. Nígbà tó yá, wọ́n gbà láti gba ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá náírà lọ́wọ́ òun àti ọ̀rẹ́ rẹ̀.
Wọ́n tẹ̀lé ọ̀rẹ́ rẹ̀ náà lọ sí òde láti gba owó náà lọ́wọ́ àwọn tó ń ṣe POS àmọ́ gbogbo wọn ti lọ ilé, wọ́n wá pe èèyàn kan fi àkáńtì rẹ̀ ránṣẹ́, ogún ẹgbẹ̀rún náírà ni wọ́n san sínú àkáńtì náà fún ìdásílẹ̀ òun àti ọ̀rẹ́ rẹ̀. Aago méjì òru ni wọ́n dá David àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ sílẹ̀.
Bákan náà ni ó wí pé àwọn ọlọ́pàá náà kò fi orúkọ wọn pe ara wọn bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kò wọṣọ, ìnagijẹ ni wọ́n ń pe ara wọn, ọ̀kan nínú wọn ń jẹ́ Agba.




