Ó ti di àwọn méjì tí wọ́n ti kú níbi ìjàm̀bá iná tó jó ní ilé ìdójútòfò Great Nigeria ní ọdúnkọ̀la.
Abala ilé náà tó wó làsìkò tí iná náà ń jó ló wó lu àwọn ẹni náà mọ́lẹ̀ tí wọ́n sì ṣe bẹ́ẹ̀ jóná mọ́bẹ̀.
Lásìkò tí àwọn òṣìṣẹ́ NEMA ń ṣe àyẹ̀wò èérún bíríkì níbi ìṣẹ̀lẹ̀ náà ni wọ́n kan àwọn géńdé ọkùnrin méjì náà lábẹ́ rẹ̀.
Àwọn ará ọjà náà ṣe ìdámọ̀ ọ̀kan nínú wọn, wọ́n ní òun náà ní ìsọ̀ nínú ọjà náà, níbi tó ti ń gbìyànjú àti kó àwọn ọjà jáde ni ògiri náà ti wó pa á. Wọn kò dá ẹnìkejì mọ̀, wọ́n ní bóyá oníbàárà ni.
Obum ni orúkọ ọkùnrin ará ọjà náà, aṣọ ni ó ń tà ó sì máa ń ná orílẹ̀-ède China, lásìkò ìṣẹ̀lẹ̀ náà, Obum ń kó àwọn aṣọ rẹ̀ jáde kí iná má ba à jó wọn, ó tilẹ̀ ti fẹ́rẹ̀ kó gbogbo rẹ̀ tán kí ògiri náà tó wó o mọ́lẹ̀.
Òwúrọ̀ ọjọ́bọ ni Obum pe Afolayan lórí aago pé òun ti há sí abẹ́ ògir àti pé àwọn pọ̀ níbẹ̀, ó bẹ̀bẹ̀ kí wọ́n má jẹ́ kí òun ó kú nítorí kò sí ẹni tí yóò tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀.
Obum kìí gbé ní Nàìjíríà, ó kàn máa ń kó ọjà ránṣẹ́ láti China ni, ọdún kérésì ni ó wá ṣe nílé tó fi pàdé ikú òjijì.
Nígbà tí wọn yóò fi tú èérún ògiri kan Obim, òun àti ẹnìkan ti kú nígbà tí àwọn yòókù ṣì wà láàyè.
Àbúrò rẹ̀ kan náà jí dé sí ibi ìṣẹ̀lẹ̀ náà ní àárọ̀ yìí, ó ní Obum ló pe òun lórí aago.
Àbẹ̀wò Gómìnà:
Gómìnà ìpínlẹ̀ Èkó; Babajide Sanwoolu ti ṣe àbẹ̀wò sí ilé alájà rẹpẹtẹ Great Nigeria Insurance tó jóná lánàá, ọjọ́ kẹrìnlélógún.
Àjà kẹrin ni iná náà ti bẹ̀rẹ̀ tó sì ràn mọ́ gbogbo ilé náà, ó tún nawọ́ gán ilé alájà méje ti Radio Nigeria, ọjà Oluwole àti àwọn ilé mìíràn tó yíi ká.
Nǹkan bíi aago márùn-ún ìrọ̀lẹ́ ni iná náà bẹ̀rẹ̀ tó sì jó di àárọ̀ ọjọ́ ọdún kérésì ó sì gba ilé iṣẹ́ panápaná ní wákàtí mẹ́wàá gbáko kí wọ́n tó iná náà pa.
Gboyega Akosile; ẹni tó jẹ́ olùbádámọ̀ràn Gómìnà Sanwoolu lórí àtẹ̀jáde ló fi léde pé Sanwoolu ṣe àbẹ̀wò sí ibi ìṣẹ̀lẹ̀ náà gẹ́gẹ́ bíi ohun tó tọ́ fún ìjọba tó ráyè ti ará ìlú. Ó fi fọ́nrán bí Gómìnà ṣe ń rin inú àjókù náà kọjá síta pẹ̀lú.
Àjọ tó ń gbọ́ ti ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì èka ìpínlẹ̀ Èkó LASEMA náà sọ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí láti ẹnu agbẹnusọ wọn; Nosa Okunbo pé àwọn kojú iná náà, àwọn èèyàn méje ló farapa nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Àwọn èèyàn márùn-ún ni wọ́n fa èéfín símú tí wọ́n sì tọ́jú wọn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ níbẹ̀.

Àwọn ìjàm̀bá iná mìíràn tó wáyé lọ́dún yìí.
Ilé oúnjẹ:
Ṣàdédé ni iná sẹ́yọ ní ilé oúnjẹ Kayat tó wà ní òpópónà Polo ní Maiduguri tíí ṣe olú ìlú ìpúnlẹ̀ Borno.
Nǹkan bíi aago mọ́kànlá òwúrọ̀ ọjọ́ Àìkú ni iná náà sẹ́yọ, àwọn panápaná ìpínlẹ̀ náà ló tètè kojú rẹ̀ kò bá jóná kan éérú.
Nínú àtẹ̀jáde tí alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Borno; Nahum Daso bu ọwọ́ lù la ti ríì kà pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà kò la ẹ̀mí lọ.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ṣe àlàyé pé àwọn gba ìpè pàjáwìrì náà lọ́jọ́ kẹrìndínlógún, oṣù Bélú pé ilé oúnjẹ Kayat ti ranná ní Maiduguri. Lọ́gán ni kọmíṣọ́nà ọloọ́pàá; Naziru Abdulmajid ti pàṣẹ kí àwọn ọlọ́pàá ó máa lọ sí ibẹ̀ tó sì tún ké sí ilé iṣẹ́ panápaná.
Yàtò sí pípa iná náà, àwọn ọlọ́pàá ríi dájú pé àwọn dóòlà ẹ̀mí àwọn èèyàn àti dúkíà tí kò tíì múná, àwọn aráàlú kan sáárá fún iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ṣe náà.
Alukoro fún ilé iṣe ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Borno; Nahum Daso rọ àwọn èèyàn láti máa ṣe jẹ́jẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹ̀rọ tó ń lo iná ọba
Ọkọ̀ àjàgbé:
Òpópónà Udoji ní agbègbè Ozubulu ní ìjọba ìbílẹ̀ Ekwusigo, ìpínlẹ̀ Anambra gbaná ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kọkànlélógún, oṣù Bélú. Èèyàn gbẹ́mìí mìn nígbà tí àwọn mẹ́fà mìíràn farapa tí ọ̀pọ̀ ìsọ̀ sì jóná gúrúgúrú.
Àlàyé tí a rí gbà ni pé ọkọ̀ àjàgbé agbépo kan ló forígbárí pẹ̀lú ọkọ̀ mìíràn àti kẹ̀kẹ́ maruwa kan, ọkọ̀ yìí gbaná lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí ó sì ràn mọ́ gbogbo ilé àti ìsọ̀ tó yíi ká.
Tochukwu Ikenga; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Anambra fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ pẹ̀lú ìkìlọ̀ pé kí àwọn èèyàn ó yẹra fún àhesọ ọ̀rọ̀ lórí pé ìkọlù àwọn agbébọn ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn náà ṣe àlàyé pé ọkọ̀ agbépo náà kọlu ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan àti kẹ̀kẹ́ maruwa kan ni ó ṣe gbaná, iná náà pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tó jó àwọn èèyàn méje, mẹ́fà wà nílé ìwòsàn nígbà tí ẹnìkan ti kú.
Ìsọ̀ bíi mẹ́fà ló ti jóná kan éérú kí àwọn panápaná ó tó dé, ó gbà wọ́n ní ọ̀pọ̀ wákàtí kí wọn ó tó ríi pa nítorí pé ó ti fẹjú gan-an.
Ìjàm̀bá yìí fa súnkẹ́rẹ-fàkẹrẹ ọkọ̀ ní òpópónà náà, àwọn ọkọ̀ ní láti gba ọ̀nà ibòmíràn.
Adarí ilé iṣẹ́ àtẹ̀jáde ìpínlẹ̀ Anambra; Chukwudi Chiketa náà dá sí ọ̀rọ̀ yìí, ó ṣe àlàyé pé àwọn panápaná ta mọ́ra dé ibẹ̀ nígbà tí wọ́n gba ìpè náà àmọ́ nǹkan ti yan kí wọ́n tó dé ibẹ̀.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá rọ àwọn èèyàn láti yẹra fún àwọn ọ̀rọ̀ tó le da omi àlàáfíà ìlú rú, wọ́n ní ìjàm̀bá ọkọ̀ ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà kí àwọn èèyàn ó dẹ́kun àhesọ pé ìkọlù àwọn agbébọn ni.





