ADVERTISEMENT
  • About
  • Contact
Monday, June 1, 2026
  • Login
  • Register
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú
No Result
View All Result
ÌWÉ ÌRÒYÌN YORÙBÁ
No Result
View All Result
Home Ìgbé-Ayé

ỌMỌ OṢÙ MÉJÌ NI RITA GBÉ TÀ NÍ DELTA.

Ìròyìn nípa àwọn agbọ́mọ́tà.

by Adeola Olanrewaju
December 25, 2025
in Ìgbé-Ayé, Ìròyìn, Ọ̀rọ̀ Ààbò
0
ỌWỌ́ TẸ ÀWỌN MÁRÙN-ÚN TÍ WỌ́N TA ỌMỌ ỌWỌ́.
0
SHARES
7
VIEWS
Pín Lórí FacebookPín Lórí ThreadsPín Lórí TwitterPín Lórí Bluesky
ADVERTISEMENT

Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ti tẹ obìnrin kan tó gbé ọmọ oṣù méjì tà ní ìpínlẹ̀ Delta. Rita Ughale ni orúkọ obìnrin yìí, agbègbè Kokori ní ìjọba ìbílẹ̀ Ethiope ni ilé rẹ̀ wà.
Lọ́jọ́ kẹẹdógún, oṣù ọ̀pẹ ni Rita mú ẹjọ́ lọ sí àgọ́ ọlọ́pàá pé àwọn kan já ọmọ òun ọmọ oṣù méjì náà gbà lọ́wọ́ òun nínú kẹ̀kẹ́ márúwá.
Àwọn ọlọ́pàá mú iṣẹ́ ṣe, wọ́n rí ọmọ náà gbà padà lọ́wọ́ tọkọtaya kan ní ìpínlẹ̀ Delta kan náà, àwọn ẹni yìí ní àwọn kò jí ọmọ gbé pé Rita; ìyá ọmọ náà ló tà á fún àwọn.
Rita kó àlàyé rò pé lóòótọ́ ni òun ta ọmọ náà ní mílíọ́nù kan àbọ̀ náírà.
Osas Omijie, ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n àti Judith Omijie, ẹni ọgbọ̀n ọdún ni tọkọtaya tó ra ọmọ náà.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Delta ní àwọn ti gba ọmọ náà lọ́wọ́ àwọn afurasí náà, ìwádìí ṣì ń lọ lórí àwọn afurasí yòókù tí wọ́n lọ́wọ́ nínú rírà àti títà ọmọ náà.

Nínú oṣù Èbìbí ni ọwọ́ tẹ àwọn márùn-ún kan tí wọ́n ta ọmọ ọ̀sẹ̀ méjì:

Àwọn márùn-ún ló ti wà ní agodo àwọn àwọn ọlọ́pàá báyìí lórí ẹ̀sùn pé wọ́n ta ọmọ ìkókó, ọmọ ọ̀sẹ̀ méjì.
Ìpínlẹ̀ Èkó ni ọwọ́ ti tẹ àwọn èèyàn wọ̀nyìí, ọkùnrin ni ọmọ náà. Àlàyé tí a rí gbà lẹ́nu agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó; Benjamin Hundeyin ni pé Happiness lóyún ní ẹni ọdún mẹ́rìndínlógun kò sì mọ ẹni tó loyún. Ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tó ń gbé lọ́dọ̀ rẹ̀ kò ní owó àti ohun tó le fi tọ́jú rẹ̀ ló bá mú un lọ sí ọ̀dọ obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Nonye Osi tó dúró bíi aláàánú.
Ìgbà tí Nonye gbé Happiness kúrò ní ilé tó gbà fún un lọ sí ibòmíràn ni ara ti bẹ̀rẹ̀ sí ní fu ẹ̀gbọ́n Happiness, láti ìgbà náà ni kò ti rí Happiness mọ́.
Nígbà tí yóò tún padà rí Happiness, kò sí oyún nínú rẹ̀ mọ́ bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí ọmọ lọ́wọ́ rẹ̀. Happiness gan-an ò le sọ pàtó ohun tó ṣẹlẹ̀ síi.
Ẹ̀gbọ́n rẹ̀ lọ fi ẹjọ́ sùn ní àgọ́ ọlọ́pàá wọ́n sì gbé Nonye, òun ló ka àwọn mẹ́rin yòókù tí wọ́n jọ ta ọmọ náà. Orúkọ àwọn yòókù ni Akintan Adedayo, Jimoh Bashiru, Elizabeth Bishop àti Bukola Oladapo.
Wọ́n jẹ́wọ́ pé lẹ́yìn tí Happiness bímọ́ tán ni àwọn ta ọmọ náà ní mílíọ́nù mẹ́ta náírà fún àwọn tó nílò rẹ̀ fún aájò.
Agbègbè Agemuwo ní Badagry ni àwọn ọlọ́pàá ti lọ gbé ọmọ náà. Ìwádìí ṣì ń lọ láti mú àwọn tí wọ́n ta ọmọ náà sí Badagry nítorí pé àtọwọ́dọ́wọ́ ni wọ́n fi títà rẹ̀ ṣe.

ADVERTISEMENT

Kò tán síbẹ̀ o, inú oṣù Igbe, ọdún yìí náà ni wọ́n mú Blessing àti ìyá rẹ̀; Grace tí wọ́n ta ọmọ ọjọ́ méjì. Ẹ̀yin náà ṣe hà?
Grace Walter; ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́ta àti ọmọ rẹ̀; Blessing Walter; ẹni ogún ọdún gbìmọ̀pọ̀ ta ọmọ tí Blessing bí ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ẹgbẹ̀rin náírà. Ọjọ́ kejì tí Blessing bí ọmọ náà ni òun àti ìyá rẹ̀ gbé e tà.
Agbègbè Oron ní ìpínlẹ̀ Awka Ibom ni èyí ti ṣẹlẹ̀ nígbà tí ọwọ́ tẹ àwọn tí wọ́n ta ọmọ́ náà fún.
Àwọn ọlọ́pàá ojú pópó ni wọ́n dá ọkọ̀ àwọn tó ra ọmọ náà dúró ní òpópónà Nsit Atai sí Oron, àwọn mẹ́ta ni wọ́n wà nínú ọkọ̀ náà; ọkùnrin kan tó wa ọkọ̀ náà àti àwọn obìnrin méjì. Àwọn ìdáhùn tí wọ́n fún àwọn ọlọ́pàá lórí bí ọmọ náà ṣe jẹ́ kò gún régé tó ló fàá tí wọ́n fi mú wọn lọ sí àgọ́ wọn fún ìdánilójú.
Àgọ́ ọlọ́pàá ni Naskpo Sonia Labere àti Inemesit Okin Akpan ti jẹ́wọ́ pé wọ́n rán àwọn wá ra ọmọ náà láti Portharcourt ni. Wọ́n ní Wazor Godwin àti Lilian Duru ló rán àwọn wá gba ọmọ náà lọ́wọ́ Grace Inyang ní Oron, Awka Ibom.
Ní báyìí, ọwọ́ ti tẹ Alison Eduno tó ṣọ̀nà rírà àti títa ọmọ náà.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Awka Ibom ló fi ọ̀rọ̀ yìí léde láti ẹnu alukoro wọn; Timfon John láàárọ̀ yìí pé ọwọ́ tẹ àwọn oníṣòwò ọmọ ní agbègbè Oron ní Awka Ibom. Wọ́n ti mú ìyá àti ìyá ìyá ọmọ náà tó ta ọmọ náà, bákan náà ni wọ́n ti mú Lilian tó mú ẹni tó ra ọmọ mọ ẹni tó ta ọmọ. Wọ́n ti gbé ọmọ náà lọ sí ẹ̀ka tó ń mójútó ọ̀rọ̀ obìnrin tó wà ní Uyo fún ìtọ́jú.

ADVERTISEMENT

Ṣebí àwọn eléyìí tilẹ̀ ta ọmọ wọn fún ẹlòmíràn, Maryam gbé tirẹ̀ sin láàyè ní:

Àwọn èèyàn ló rí Maryam níbi tó ti ń gbìyànjú àti sin ọmọ rẹ̀ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bí láàyè ní Kamba, ìjọba ìbílẹ̀ Dandi ní ìpínlẹ̀ Kebbi.
Ó tilẹ̀ ti ń da iyèpẹ̀ bo ọmọ naa kí wọn ó tó ríi, wọ́n wú ọmọ náà jáde wọ́n sì gbé e lọ sí ilé ìwòsàn.
Àwọn dọ́kítà fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé ọmọ náà wà ní àlàáfíà wọ́n sì fa Maryam lé àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́.
Nafiu Abubakar; ẹni tó jẹ́ alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kebbi ṣe àlàyé pé Maryam wé ọmọ náà láṣọ, ó fi aṣọ dí ẹnu rẹ̀ ó sì lọ sín ín sí inú igbó Malam Yaro tó jẹ́ inú oko Alhaji Kabiru Muhammad.
Níbi tí Kabiru ti ń roko ló ti kófìrí pé ojú ibẹ̀ jọ ilẹ̀ tí èèyàn kan ti hú, ó pe àwọn èèyàn mọ́ra wọ́n sì hú ilẹ̀ náà, ọmọ titun jòjòló ni wọ́n bá nínú ẹ̀.
Àwọn ará àdúgbò ló tọ́ka pé Maryam ni ẹni tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bímọ ní àdúgbò náà, wọ́n bá gbéra lọ bèèrè ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ rẹ̀, àìrí ọmọ náà gbé jáde ni wọ́n fi fà á lé àwọn ọlọ́pàá lọ́wọ́.
Ẹni ogún ọdún ni Maryam, ó jẹ́wọ́ lágọ̀ọ́ àwọn ọlọ́pàá pé òun sin ọmọ náà láàyè nítorí pé òun kò ní ohun tí òun yóò fi tọ́jú rẹ̀.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá wí pé àwọn yóò fa ọmọ náà lé àjọ tọ́rọ̀ kàn lọ́wọ́ nígbà tí Maryam yóò fi ojú ba ilé-ẹjọ́.

Facebook Comments Box

Related

Tags: #iweiroyinyoruba#ìwéròyìnyorùbá #NewsOnline#newsfeed#newsupdatesChild traffickingchild trafficking in Nigerianewsinyorubatrending
ADVERTISEMENT
Adeola Olanrewaju

Adeola Olanrewaju

Next Post
ILÉ ẸJỌ́ PÀṢẸ KÍ GBOGBO DÚKÌÁ SYLVA Ó DI TI ÌJỌBA.

ỌWỌ́ TẸ ÀWỌN ADIGUNJALÈ MÁRÙN-ÚN TÍ WỌ́N DÍBỌ́N BÍI Ẹ̀ṢỌ́ ALÁÀBÒ NÍ ÌPÍNLẸ̀ ANAMBRA.

Recommended

ÀNÀ-DOJÚ-DÉ NI ÀWỌN Ẹ̀ṢỌ́ ALÁÀBÒ NA ÒṢÌṢẸ́ INÁ MỌ̀NÀMỌ́NÁ

ÀNÀ-DOJÚ-DÉ NI ÀWỌN Ẹ̀ṢỌ́ ALÁÀBÒ NA ÒṢÌṢẸ́ INÁ MỌ̀NÀMỌ́NÁ

1 year ago
ERIN WÓ, ÀJÀNÀKÚ SÙN BÍ OKE.

ERIN WÓ, ÀJÀNÀKÚ SÙN BÍ OKE.

1 year ago

Popular News

  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ TI MÚ IKỌ̀ ONE-CHANCE NÍ IDIMU, ÈKÓ.

    Ọwọ́ tẹ ikọ̀ one-chance ní kebbi.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • OLÓLÙFẸ́ DA ÁSÍÌDÌ SÍ ỌMỌṢẸ́ Ọ̀RẸ́BÌNRIN RẸ̀ LÁRA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ILÉ ẸJỌ́ PÀṢẸ KÍ GBOGBO DÚKÌÁ SYLVA Ó DI TI ÌJỌBA.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • AYÉ LÓ ṢE ỌLỌ́PÀÁ TÓ YÌNBỌN PA ÈÈYÀN.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0
  • ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ ṢE ÀWÁRÍ AYÉDÈRÚ ILÉ ỌMỌ ALÁÌNÍYÀÁ.

    0 shares
    Share 0 Tweet 0

Connect with us

ADVERTISEMENT

Newsletter

Lorem ipsum dolor sit amet, consectetuer adipiscing elit. Aenean commodo ligula eget dolor.
SUBSCRIBE

Category

Site Links

  • Register
  • Log in
  • Entries feed
  • Comments feed
  • WordPress.org

About Us

We bring you the best Premium WordPress Themes that perfect for news, magazine, personal blog, etc. Check our landing page for details.

  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
  • Àṣà Yorùbá
  • Ìgbé-Ayé
  • Ìdánilárayá
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

Welcome Back!

Login to your account below

Forgotten Password? Sign Up

Create New Account!

Fill the forms below to register

All fields are required. Log In

Retrieve your password

Please enter your username or email address to reset your password.

Log In
No Result
View All Result
  • Ilé Wa
  • Ìròyìn
    • Ọ̀rọ̀ Ààbò
    • Ìròyìn Agbègbè
    • Ìròyìn òkèrè
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
    • Ìfipábánilò
  • Òṣèlú
  • Ọrọ̀-Ajé
  • Fọ́nrán
    • Ìròyìn Jákèjádò
  • Àṣà Yorùbá
    • Àjọ̀dún Yorùbá
    • Ìtàn Yorùbá
    • Oríkì
  • Ìgbé-Ayé
    • Oge Ṣiṣe
    • Ìlera
    • Ìrìn Àjò
    • Ọ̀rọ̀ ìdílé
  • Ìdánilárayá
    • Fiimu ati Nollywood
    • Orin
  • Ààyè Olóòtú

© 2024 -2026 The Morganable Media Group - Ìwé Ìròyìn Yorùbá is owned by The Morganable Media Group

This website uses cookies. By continuing to use this website you are giving consent to cookies being used. Visit our Privacy and Cookie Policy.