Òṣèrébìnrin ilẹ̀ wa; Tonto Dikeh ti ṣe ìjẹ́rìí sí ọwọ́ Ọlọ́run nínú ayé rẹ̀ nípa bí ó ṣe dẹ́kun mímu sìgá, ọtí àti ohun mìíràn bẹ́ẹ̀ lẹ́yìn ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n.
Ó ṣe àlàyé pé ọmọ ọdún mẹ́tàlá ni òun wà nígbà tí òun bẹ̀rẹ̀ mímu àwọn nǹkan wọ̀nyìí, ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n gbáko ló sì fi mu wọ́n.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Tonto Dikeh wí pé òun ní ẹ̀mí ìbínú láwọn àsìkò náà àmọ́ òun ti borí rẹ̀ báyìí.
Ilé ìjọsìn Sreams of Joy International níbi tí odásílẹ̀ ilé ìjọsìn náà; Pásítọ̀ Jerry Eze ti ṣe ètò ìsìn àsọtẹ́lẹ̀ àti ìgbé ayé titun ni Tonto Dikeh ti ṣe ìjẹ́rìí yìí níbi lọ́jọ́ Àìkú, ọjọ́ kẹrìnlá, oṣù Ọ̀pẹ.
Ó wí pé òun a máa ní àjọṣepọ̀ aládàánìkanṣe láwọn àsìkò náà àmọ́ òun ti ṣẹ́gun rẹ̀ báyìí bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé láti kékeré ni òun ti máa ń ní àjọṣepọ̀ ojú oorun. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tẹ̀síwájú pé jíjáde tí òun jáde jẹ́rìí sí iṣẹ́ Ọlọ́run yìí jẹ́ ọ̀nà tí òun gbà dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run, ohun tí àwọn èèyàn yóò sọ nípa òun nítorí pé òun ní òkìkí kọ́kọ́ fẹ́ kí òun fà sẹ́yìn àmọ́ òun ṣe ọkàn akin pé ṣebí Ọlọ́run ló fún òun ní òkìkí náà, bí ó bá gbà á ńkọ́?
Gbogbo ìrìn àjò yìí bẹ̀rẹ̀ nígbà tí mo lọ sí ìsọ̀jí ní Ghana, mo gba àdúrà ìṣẹ́gun àti ìtúsílẹ̀, bàbá tó máa ń bámi lájọṣepọ̀ lójú oorun náà sì sá lọ. Ẹ̀mí ìbínú tó ti jẹ́ kí n bàjẹ́ lọ́wọ́ àwọn èèyàn tó sì tún ti jẹ́ kí n pàdánù àwọn nǹkan mìíràn náà ti fimí sílẹ̀ nígbà tí mo gbàdúrà takò ó. Ọlọ́run mú ẹ̀mí ìbínú náà kúrò ó sì fún mi ní àlàáfíà àti ìsinmi ọkàn.
Ọmó ogójì ọdún ni mí báyìí mi ò sì mọ ìsinmi títí di àsìkò yìí. Bàbá mi máa ń u sìgá ni èmi náà ṣe mọ̀ ọ́n m, kò sí kékeré ìwà tí ọmọ kò le mú lọ́wọ́ òbí.
Lẹ́yìn tí mo gba àwọn àdúrà yìí, ara mi kò bèèrè fún ọtí àti sìgá mọ́, ìdè náà yi já báyìí – Tonto Dikeh.
Pásìtọ́ Eze náà gba àdúrà fún un pé ìdè náà ti já pátápátá.
Tontoh Dikeh fi ìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé òun ti di ọmọ Ọlọ́run báyìí òun sì ṣetán láti fi gbogbo ayé òun fún Ọlórun.

AFURASÍ JẸ́WỌ́ ÌDÍ TÓ FI PA ADÁJỌ́ FẸ̀YÌNTÌ IFEOMA OKOGWU.
Afurasí tí ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá tẹ̀ lórí ikú tó pa adájọ́ fẹ̀yìntì Ifeoma Okogwu jẹ́wọ́ pé nítorí ẹ̀rọ ìbanisọ̀rọ̀ rẹ̀ àti àwọn ohun ìní mìíràn ni àwọn ṣe pa Ifeoma.
Godwin Mngumi ṣe àlàyé pé òun pe àwọn méjì mìíràn mọ́ra láti gba ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ Ifeoma, aago ọwọ́, ohun ọ̀ṣọ́ àti ẹ̀rọ agbanápamọ́ rẹ̀. ó ní àwọn kò lérò láti pa obìnrin náà àmọ́ ó kú mọ́ àwọn lọ́wọ́ ni.
Ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ni Godwin, kò ju ọ̀sẹ̀ méjì lọ tí Ifeoma gbà á ní aṣọ́gbà ni ó pa á. Ó ṣe àlàyé pé àwọn so ọwọ́ àti ẹsẹ̀ Ifeoma méjéèjì sẹ́yìn, wọ́n kó ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀ méjéèjì. Nnaji Obalum ló gba ọ̀kan nínú rẹ̀ sọ́wọ́ nígbà tí wọ́n ta èkejì.
Obalum; ẹni ọdún mọ́kànlélógún ṣe àlàyé pé òun fi síìmù òun sínú ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ náà ni wọ́n fi mú òun. Obalum àti Godwin kábàámọ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà wọ́n sì tọrọ àforíjìn.
Bright Edafe; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Delta ló fi fọ́nrán ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò àwọn afurasí ọ̀daràn náà léde.

WỌ́N DÁNÁ SUN ALÁBOYÚN ÀTI ỌMỌ RẸ̀ NÍ ÌPÍNLẸ̀ KANO.
Aláboyún kan àti ọmọ rẹ̀ ọmọ oṣù mẹ́rìndínlógún kan ni àwọn kan ti pa sínú ilé wọn tí wọ́n sì tún dáná sun òkú wọn.
A gbọ́ pé ọkọ aláboyún yìí dé ní òwúrọ̀ ọjọ́ àbámẹ́ta ló ríi pé ilẹ̀kùn wà ní títì sí ìta. Ó já ilẹ̀kùn náà wọlé, òkú ìyàwó rẹ̀ tó lóyún sínú àti ọmọ rẹ̀ ọmọ ọdún kan àbọ̀ ni ó bá lórí ìbùsùn.
Wọ́n gún obìnrin yìí àti ọmọ rẹ̀ pa wọ́n sì tún dáná sun òkú wọn.
Ahmad Sani; ẹni tó jẹ́ adarí agbègbè náà banú jẹ́ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà, ó bu ẹnu àtẹ́ lu ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá pé wọ́n kọ̀ láti yan ọlọ́pàá sí abúlé náà. Ó ní àwọn dá owó jọ kọ́ àgọ́ ọlọ́pàá nítorí ètò ààbò tó mẹ́hẹ àmọ́ wọn kò yan ọlọ́pàá sí abúlé náà. Ọwọ́ Ọlọ́run ni gbogbo wọn wà.
Sani rọ kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kano; Ibrahim Bakori láti yan ọlọ́pàá sí abúlé náà kí irú ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí le dẹ́kun.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀, Abdullahi Haruna; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ wọn ní àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
ÀWỌN ADIGUNJALẸ̀ ṢỌṢẸ́ LỌ́SÀN-AN GAN-AN NÍ ÌPÍNLẸ̀ KWARA.
Ọ̀sán gangan ni àwọn adigunjalè dá ọkọ̀ kan dúró ní Ilorin tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Kwara. Ọkọ̀ náà wà lórí ìrìn ni àwọn adigunjalè náà bíi mẹ́rin dá a lọ́nà, wọ́n yìnbọn fún awakọ̀ náà wọ́n sì kó owó tí wọ́n dì sínú páálí mẹ́rin lọ.
Ẹnìkan tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú rẹ̀ ṣe àlàyé pé àwọn adigunjalè náà wa ọkọ̀ tiwọn dubú ọkọ̀ náà, wọ́n fi ìbọn fọ́ táyà rẹ̀ wọ́n sì tún yìnbọn fún awakọ̀ náà. Páálí bíi mẹ́rin tí wọ́n kó owó sí ni wọ́n gbé sá lọ.
Adetoun Ejire-Adeyemi; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara ṣe àlàyé pé nǹkan bíi aago mọ́kànlá àbọ̀ òwúrọ̀ ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹ̀. Wọ́n yìnbọn fún awakọ̀ náà ní ọwọ́ wọ́n sì gbé owó tí a kò tíì mọ iye rẹ̀ sá lọ. Wọ́n ti gbé awakọ̀ náà lọ sí ilé ìwòsàn ìwádìí sì ti bẹ̀rẹ̀ lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.





