Àwọn oníṣẹ́ oṣù àti àwọn oníṣòwò pẹ́ dé ibi iṣẹ́ àti ìdí ọjà wọn láàárọ̀ ọjọ́ Ajé, ọjọ́ kẹjọ, oṣù Ọ̀pẹ látàrí súnkẹrẹ-fàkẹrẹ ọkọ̀ tó wáyé lórí afárá Third mainland ní Ekó.
Ọkọ̀ agbépo bẹntiróòlù ló forígbárí pẹ̀lú ọkọ̀ àjàgbé akẹ́rù ní òru ọjọ́ Àìkú mọ́jú ọjọ́ Ajé.
Iwájú ilé ìwé gíga Waterfront, Èkó ni ìjàm̀bá náà ti wáyé ó sì fa ìdènà fún àwọn tó ń bọ̀ láti ìyànà Oworo. Àwọn ojú ọ̀nà mìíràn tó dí ni Alapere, Oṣòdì sí Apapa àti Ikorodu.
Àwọn òṣìṣẹ́ àbò ojú pópó ìpínlẹ̀ Èkó; LASTMA ti wà ní ibẹ̀ láti ṣètò wíwọ́ àwọn ọkọ̀ náà kúrò lójú ọ̀nà.
Ó ṣẹ̀lẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Ogun náà.
Àwọn èèyàn méjì ló pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàm̀bá ọkọ̀ tó wáyé ní Ososa, ojú ọ̀na márosẹ̀ Sagamu, ìpínlẹ̀ Ògùn.
Babatunde Akinbiyi; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ tó ń mójútó ìgbòkègbodò ọkọ̀ ní ìpínlẹ̀ Ogun fi ìdí ẹ̀ múlẹ̀ fún àwọn akọ̀ròyìn pé ọkọ̀ akérò Hiace náà kó àwọn èèyàn mọ́kànlélógún ó sì gba ojú ọ̀nà tí kìí ṣe tirẹ̀ tí wọ́n ń pè ní one-way.
Ọkọ̀ àjàgbé akẹ́rù ló pàdé lójijì tí ìyẹn ń bọ̀ lójú ọ̀nà tirẹ̀, wọ́n fi orí gbárí lójijì, èèyàn méjì ló gbẹ́mìí mìn lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ nígbà tí ọ̀pọ̀ farapa yánnayànna.
Ilé ìgbókùúsí ti ilé ìwòsàn ìjọba Ijebu-ode ni wọ́n kó àwọn tó kú náà lọ nígbà tí àwọn tó farapa náà ti wà nílé ìwòsàn náà.
Wọ́n ti wọ́ ọkọ̀ náà kúrò lójú pópó báyìí.
Ìjàm̀bá ọkọ̀ mánigbàgbé ní ita-oluwo, Ikorodu:
Ọkọ̀ Toyota kan tó kó èèyàn méje láti ìpínlẹ̀ Osun wá sí Èkó pàdánù ìjánu rẹ̀ ó sì kó sí abẹ́ ọkọ̀ àjàgbé eléjò kan tó ń lọ ní tirẹ̀.
Ọ̀gbẹ́ni Sanni Saifullahi ló wa ọkọ̀ àjàgbé eléjò náà, ọkọ̀ àjàgbé yìí ga tó ìwọ̀n ogójì ẹsẹ̀ bàtà, ilé iṣẹ́ Ay and Rolly’s ventures tó wà ní Magodo, ìpínlẹ̀ Èkó ló ni ọkọ̀ àjàgbé yìí.
Ọgbẹ́ni Sunday Okpe ti ilé iṣẹ́ Miracle Ultima international limited ló wa ọkọ̀ Sienna yìí.
Ìpínlẹ̀ ọ̀ṣun ni ọ̀gbẹ́ni Sunday ti gbéra pẹ̀lú èrò méje, ojú ọ̀nà márosẹ̀ Èkó sí ìbàdàn ní ìta Olúwo, Ìkòròdú ni ọkọ̀ yìí ti pàdánù ìjánu rẹ̀ tó sì kó sí abẹ́ ọkọ̀ àjàgbé eléjò náà.
Arábìnrin Miracle Chibuzor tí òun náà jẹ́ òṣìṣẹ́ ilé iṣẹ́ Miracle Ultima international limited ló jókòó níwájú, ó pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nínú ìjàmbá yìí, àwọn èèyàn márùn-ún mìíràn fara pa yánnayànna.
Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun; Omolola Odutola ló fi ọ̀rọ̀ yìí ṣọwọ́ sí àwọn akọ̀ròyìn pé arábìnrin Miracle pàdánù ẹ̀mí rẹ̀ nínú ìjàmbá ọkọ̀ tó wáyé ní ojú ọnà márosẹ̀ Èkó sí ìbàdàn.
Àwọn ọlọ́pàá ojú pópó ló kó àwọn márùn-ún tí wọ́n farapa náà lọ sí ilé ìwòsàn Falobis tó wà ní Mowe fún ìtọ́jú.
Wọ́n gbé òkú arábìnrin Miracle lọ sí ilé ìgbókùúsí Idera fún àyẹ̀wò àti ìwé ẹ̀rí.
Lẹ́yìn náà ni àwọn ọlọ́pàá wọ́ àwọn ọkọ̀ méjèèjì náà lọ sí àgọ́ wọn tó wà ní Shagamu kí àwọn òṣìṣẹ́ VIO le ṣe àyẹ̀wò rẹ̀.
Ìjàmbá ọkọ̀ mìíràn wáyé ní ìta Olúwo yìí kan náà ní nǹkan bíi aago mẹ́jọ àárọ̀.
Arábìnrin kan tí a kò tíì mọ orúkọ rẹ̀ ni ó jánà mọ́ kẹ̀kẹ́ márúwá lẹ́nu tó sì padà gbé ẹ̀mí mìn.
Usman Abdullah; ẹni ọdún mọ́kànlélógún ló wa kẹ̀kẹ́ TVS náà, obìnrin yìí fẹ́ sọdá títì ló jánà mọ́ kẹ̀kẹ́ Abdullahi lẹ́nu, orí ló fi ṣèṣe. Àwọn èèyàn ṣe aájò rẹ̀ dé ilé ìwòsàn Omowunmi tó wà ní Kusela, Ogijo àmọ́ obìnrin yìí padà jẹ́ ìpè Elédùà.
Àwọn ọlọ́pàá dé ibẹ̀, wọ́n ya àwòrán ìṣẹ̀lẹ̀ náà wọ́n sì wọ́ kẹ̀kẹ́ náà lọ sí àgọ́ wọn. Abdullahi ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá fún ìwádìí lórí bí ìjàmbá náà ṣe wáyé.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá kòrò ojú sí ìjàmbá méjèèjì yìí, wọ́n rọ àwọn awakọ̀ láti yàgò fún eré àsápajúdé ní èyí tó le mú kí ìjàmbá ọkọ̀ ó wáyé, bákan náà ni wọ́n rọ àwọn awakọ̀ láti má màa sún mọ́ ọkọ̀ àjàgbé eléjò pẹ́kípẹ́kí.
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ogun; Lanre Ogulowo gba àwọn awakọ̀ níyànjú.
Kò tán síbẹ̀ o:
Nínú ìjàmbá ọkọ̀ tó wáyé lójú ọ̀nà márosẹ̀ Èkó sí ìbàdàn, ọkùnrin kan gbé ẹ̀mí mìn nígbà tí àwọn èèyàn márùndínlógún mìíràn farapa yánnayànna. ọkọ̀ náà rún wómúwómú ni, kọjá bẹ́ẹ̀, bí èèyàn bá jẹ orí ahun gan-an yóò kérora abiyamọ.
Okọ̀ Mazda kan ló pàdánù ìjánu rẹ̀ tó sì lọ forí sọ ọkọ̀ àjàgbé eléjò kan tó jáde láti inú ọgbà ilé iṣẹ́ aládàáni kan tó wà ní ojú ọnà náà.
Èèyàn mẹ́rìndínlógún ló wà nínú ọkọ̀ Mazda yìí. Àwọn èèyàn ṣe aájò wọn dé ilé ìwòsàn àmọ́ eléérú sungi fún ẹni kan nínú wọn kí awon dọ́kítà tó tẹ́wọ́ gbà á rárá.
Ẹnìkan tí ọ̀rọ̀ náà ṣojú rẹ̀ ṣàlàyé pé ọkọ̀ àjàgbé eléjò ti ilé iṣẹ́ AIM Coy jáde láti inú ọgbà ilé iṣẹ́ náà ní tirẹ̀ kó tó di pé ọkọ̀ Mazda náà sá eré àsápajúdé pàdé rẹ̀ lójijì.
Adarí àjọ ààbò ojú pópó ìpínlẹ̀ Ogun; ọ̀gbẹ́ni Seni Ogunyemi fìdìí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí múlẹ̀ pé ó bani lọ́kàn jẹ́ gan-an ni.
Ogunyemi wí pé àwọn ti gbé òkú arákùnrin tó kú náà sí ilé ìgbókùúsí ilé ìwòsàn Livewell tó wà ní Shagamu. Ilé ìwòsàn Livewell yìí kan náà ni àwọn mẹ́ẹ̀dógún yòókù ti ń gba ìtọ́jú.
Ojoojúmọ́ ni àwọn èèyàn ń pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàmbá ọkọ̀, kò fẹ́rẹ̀ sí ọjọ́ kan tí ìròyìn ìjàmbá ọkọ̀ kò kàn nílû yìí, èyí ń fẹ́ àpérò.
Púpọ̀ nínú àwọn ìjàmbá yìí ló jẹ́ pé ìjánu àwọn ọkọ̀ náà da iṣẹ́ sílẹ̀ lórí eré ni, bákan náà ni ọ̀fintótó fi hàn pé àwọn awakọ̀ yìí kìí sá eré mọ níwọ̀n.







