Ìjọba ìpínlẹ̀ Imo ti gbé ilé ìtura àti itẹ́ òkú kan tì pa ní agbègbè Umuhu, Ngor-Okpalar, ìpínlẹ̀ Imo. Ilé ìtura àti itẹ́ òkú náà jẹ́ ti aládàáni, ẹnìkan tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Stanley Morocco Oparaugo ló ni méjéèjì.
Àwọn ọlọ́pàá ya bo ilé itẹ́ náà nígbà tí ìròyìn kàn wọ́n lára pé wọ́n ń ṣe iṣẹ́ ibi ní ilé ìtura àti itẹ́ náà. Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, ohun tí wọ́n bá kọjá àfẹnuròyìn, nígbà tí wọ́n tún lọ tú ilé àwọn afurasí tí wọ́n gbá mú, ó burú jáì.
Òkú àwọn èèyàn kún ilẹ̀ pẹ̀lú ojú àpá bi tí wọ́n ti yọ àwọn ẹ̀yà ara wọn, kò sí ìtọ́jú fún àwọn òkú náà bẹ́ẹ̀ sì ni kò sí èyí tí àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀ pé nínú àwọn òkú náà.
Bákan náà ni wọ́n fura pé yàtọ̀ sí yíyọ ẹ̀yà òkú ara tà, ó ṣe é ṣe kí wọn ó máa jí àwọn èèyàn gbé wá síbẹ̀ láàyè. Ìdí ni pé gbogbo ìgbà ni ìjínigbé ń wáyé ní ojú ọ̀nà márosẹ̀ Owerri sí Aba, èyí ló mú kí kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà; Aboki Danjuma ó ṣiṣẹ́ ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹ̀ṣọ́ aláàbò abẹ́lé láti ṣe àwárí ibi tí àwọn tí wọ́n ń jí gbé náà le máa wọlẹ̀ sí.
Okoye Henry; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Imo ṣe àlàyé pé ẹni tó ni ilé ìtura àti itẹ́ náà; Stanley Morocco Oparaugo ti na pápá bora báyìí.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ló ti sọ wí pé àwọn ọ̀dájú ọ̀daràn ni àwọn ẹni tó ń lo itẹ́ náà, òkú àwọn èèyàn kúnlẹ̀ rẹ́kẹrẹ̀kẹ ní ipò tí kò bá ojú mu, gbogbo ẹ̀yà ara wọn sì ni wọ́n ti yọ yán.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Imo ti pàṣẹ kí wọn ó gbé àti ilé ìtura àti itẹ́ náà tì pa báyìí. Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá fi àwọn aráàlú lọ́kàn balẹ̀ pé gbogbo àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ibi ní ibẹ̀ ni àwọn yóò mú, wọ́n ní ẹni bá mọ ohunkóhun nípa bí àwọn ṣe le rí Stanley Morocco mú kó kàn sí àgọ́ ọlọ́pàá tó bá sún mọ́ ọn jùlọ.
Ní báyìí, wọ́n ti ṣe àlékún àwọn ọlọ́pàá ojú ọ̀nà mároṣẹ̀ Owerri sí Aba.
Irú ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣẹ̀ ní ilé ìtura Century Home náà:
Láti ọdún 2024 ni Onoriode Bethel ti sọ̀nu tí wọ́n sì ti ń wá a, inú ilé ìtura Century Home tó wà ní Owehlogho ni wọ́n ti rí òkú rẹ̀ níbi tí wọ́n sin ín sí.
Ọ̀tọ̀ ni ẹni tí àwọn ọlọ́pàá wá lọ sí ilé ìtura náà tí wọ́n fi túlé kan òkú Bethel. Arákùnrin arìnrìnàjò kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sunday Ogofohta ni ó sun ilé ìtura Century Home tí kò sì padà jáde mọ́.
Sunday ni àwọn ọlọ́pàá tọpinpin lọ sí ibẹ̀ tí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní tú gbogbo yàrá, wọ́n kan yàrá kan tó ṣe pé òkú àwọn èèyàn ni wọ́n ń sin sínú rẹ̀, lára àwọn tó ti sin síbẹ̀ ni Bethel wà.
Iboirode ni orúkọ alámòójútó ilé ìtura yìí, ó jẹ́wọ́ pé òun ló pa Bethel ní ọdún 2024 nítorí pé ó ba òun lórúkọ jẹ́. Iṣẹ́ fi ẹ̀rọ gbowó POS ni Bethel ń ṣe, ní ọdún tó kọjá, Iboirode fi èrú gba ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá náírà lọ́wọ́ rẹ̀, nígbà tí Bethel padà ríi pé òfegèé ni àtẹ̀jíṣẹ́ owó tí Iboirode fi ránṣẹ́ sí òun, ó kò ó lójú ó sì gba owó rẹ̀.
Ẹ̀yìn ìgbà náà ni Iboirode tàn án wọ inú ilé ìtura náà pé òun fẹ́ parí ìjà náà, ó tìí wọ inụ́ yàrá náà tí ó máa ń sin àwọn èèyàn sí, ó gba píínì ẹ̀rọ POS rẹ̀ kí ó tó pa á. Lẹ́yìn náà ló wọ́ gbogbo owó tó wà nínú àpò owó náà, ó tún pe bàbá Bethel pé kí ó san owó ìtúsílẹ̀ ọmọ rẹ̀.
Ìyàwó Iboirode náà jẹ́rìí síi pé ọkọ òun máa ń pa àwọn arìnrìnàjò tó bá wá sun ilé ìtura náà, yóò wọ́ owó inú àpò owó náà yóò sì tún gba owó ìtúsílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ẹbí wọn.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Delta wí pé afurasí náà yóò fi ojú ba ilé ẹjọ́ ní kété tí ìwádìí bá parí.
Golden point hotel náà súnmọ́ odò ẹran èèyàn ó jìnnà sí ilé ìtura:
Ilé ìtura ni àwọn èèyàn ń wò lórí ilẹ̀ náà, àmọ́ abattoir èèyàn ni ó wà ní ìsàlẹ̀ rẹ̀.
Udoka Golden point hotel tí wọ́n tún dà pè sí La Cruise hotel ni àsìrí rẹ̀ lu síta lónìí.
Ó lé ní ọgbọ̀n sàrê tó wà ní ìsàlẹ̀ ilé náà, ọ̀pọlọpọ̀ àwọn ohun ìjà olóró, oògùn dúdú, igbá ẹbọ àti àwọn nǹkan bẹ́ẹ̀ ló farasin sí abẹ́ ilé ìtura yìí.
Omi gbígbóná kò gbọdọ̀ pẹ́ lẹ́nu, ọwọ́ kò gbọdọ̀ pẹ́ nísà akekě, ìjọba ti da ilé náà wó.
Ojú ọ̀nà márosẹ̀ Onitsha sí Owerri ní ìpínlẹ̀ Anambra ni ilé ìtura yìí wà, àwọn ajinigbe àti agbénipa ló tẹ̀dó sí ibẹ̀ àmọ́ tí wọ́n fi ilé ìtura ni wọ́n fi bo ojú ilé náà.
Ìjọba ìpínlẹ̀ Anambra ló fúnra rẹ̀ kéde ìṣẹ̀lẹ̀ yìí lójú òpó X rẹ̀ pé àwọn da ilé ìtura là cruise wó nítorí àwọn èèyàn ni wọ́n ń pa tà ní ibẹ̀.
Mélòó la ó sọ nípa àwọn ilé ìtura yìí? Ṣebí ilé ìtura náà ni wọ́n ti là Timothy.
Akẹ́kọ̀ọ́ ilé ìwé gíga Obafemi Awolowo ni Timothy, ilé ìtura Hilton ló dé sí fún ìdánwò tó fẹ́ ṣe nílé ìwé náà, oorun tí Timothy sùn nílé ìtura náà kò padà jí sáyé.
Ẹni tó ni ilé ìtura náà; Rahman Adedoyin ni adájọ́ ti dá ẹjọ́ ikú fún báyìí.



