Kò dín ní àwọn èèyàn mẹ́ta tí wọ́n kú nínú ìjàm̀bá ọkọ̀ agbépo tó bú gbàmù ní ìpínlẹ̀ Kano.
Ọjọ́ Ẹtì ni èyí wáyé ní ọjà Kura ní òpópónà Zaria. A gbọ́ pé ọkọ̀ agbépo tó gbé gbé epo jálá ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n kọlu ọ̀kadà kan ó sì gbaná bẹ́ẹ̀.
Danlami Muhammad; ẹni tó jẹ́ òṣìṣẹ́fẹ̀yìntì ní ẹ̀kan NSCDC ni ó pe ilé iṣẹ́ panápaná, nígbà tí wọn yóò fi dé ibẹ̀, ọkọ̀ náà ti ran iná délẹ̀, àwọn èèyàn mẹ́rin ló ti jóná nínú èyí tí àwọn mẹ́ta kú tí ọlọ́kadà náà sì yè.
Ìwádìí ṣì ń lọ lórí ohun tó ṣe okùnfà ìjàm̀bá náà.
Ní ọjọ́ kan náà ni ìjàm̀bá iná mìíràn wáyé ní ìpínlẹ̀ Kano yìí kan náà ní nǹkan bíi aago méjì ọ̀sán ń lọ lù.
Ilé ìtajà Hamisu tó wà ní òpópónà Maiduguri ní ìjọba ìbílẹ̀ Taruni ni èyí ti wáyé.
A gbọ́ pé iná náà sẹ́yọ láti inú ìsọ̀ kan nílé ìtajà náà ó sì ràn mọ́ àwọn ìsọ̀ yòókù ní kíá.
Nígbà tí àwọn panápaná ó fi dé ibẹ̀, iná náà ti dé àwọn ìsọ̀ tó wà ní àjà kẹta. Àwọn ìsọ̀ tó wà ní ìsàlẹ̀ pátápátá àti àjà kìíní ni wọ́n rí gbà kalẹ̀ nígbà tí àwọn ìsọ̀ tó wà ní àjà kejì àti ẹ̀kẹta jóná gúrúgúrú.
Ìwádìí ohun tó fa ìjàm̀bá náà ṣì ń lọ lọ́wọ́
Bákan náà ni iná tún ṣọṣẹ́ ní ìpínlẹ̀ Anambra;
Òpópónà Udoji ní agbègbè Ozubulu ní ìjọba ìbílẹ̀ Ekwusigo, ìpínlẹ̀ Anambra gbaná ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kọkànlélógún, oṣù Bélú. Èèyàn gbẹ́mìí mìn nígbà tí àwọn mẹ́fà mìíràn farapa tí ọ̀pọ̀ ìsọ̀ sì jóná gúrúgúrú.
Àlàyé tí a rí gbà ni pé ọkọ̀ àjàgbé agbépo kan ló forígbárí pẹ̀lú ọkọ̀ mìíràn àti kẹ̀kẹ́ maruwa kan, ọkọ̀ yìí gbaná lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí ó sì ràn mọ́ gbogbo ilé àti ìsọ̀ tó yíi ká.
Tochukwu Ikenga; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Anambra fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ pẹ̀lú ìkìlọ̀ pé kí àwọn èèyàn ó yẹra fún àhesọ ọ̀rọ̀ lórí pé ìkọlù àwọn agbébọn ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn náà ṣe àlàyé pé ọkọ̀ agbépo náà kọlu ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ kan àti kẹ̀kẹ́ maruwa kan ni ó ṣe gbaná, iná náà pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tó jó àwọn èèyàn méje, mẹ́fà wà nílé ìwòsàn nígbà tí ẹnìkan ti kú.
Ìsọ̀ bíi mẹ́fà ló ti jóná kan éérú kí àwọn panápaná ó tó dé, ó gbà wọ́n ní ọ̀pọ̀ wákàtí kí wọn ó tó ríi pa nítorí pé ó ti fẹjú gan-an.
Ìjàm̀bá yìí fa súnkẹ́rẹ-fàkẹrẹ ọkọ̀ ní òpópónà náà, àwọn ọkọ̀ ní láti gba ọ̀nà ibòmíràn.
Adarí ilé iṣẹ́ àtẹ̀jáde ìpínlẹ̀ Anambra; Chukwudi Chiketa náà dá sí ọ̀rọ̀ yìí, ó ṣe àlàyé pé àwọn panápaná ta mọ́ra dé ibẹ̀ nígbà tí wọ́n gba ìpè náà àmọ́ nǹkan ti yan kí wọ́n tó dé ibẹ̀.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá rọ àwọn èèyàn láti yẹra fún àwọn ọ̀rọ̀ tó le da omi àlàáfíà ìlú rú, wọ́n ní ìjàm̀bá ọkọ̀ ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà kí àwọn èèyàn ó dẹ́kun àhesọ pé ìkọlù àwọn agbébọn ni.
Kò yọ Ilorin sílẹ̀;
Ilé ìtura Ebunlomo tó wà ní Ilorin tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Kwara ti jóná kan éérú lọ́jọ́ ìṣẹ́gun.
Nǹkan bíi aago márùn-ún ìdájí ni iná náà bẹ̀rẹ̀ tó sì ràn mọ́ gbogbo yàrá mẹ́tàlélógún ilé ìtura náà. Àwọn panápaná ìpínlẹ̀ náà ló kojú iná náà.
Hassan Adekunle; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ Kwara ṣe àlàyé pé àwọn tètè kojú iná náà kó má baà ràn mọ́ àwọn ilé tó yíi ká.
Ìwádìí fi hàn pé iná náà sẹ́yọ nígbà tí àwọn wáyà iná kanra wọn ẹ̀ka ọtí mímu ilé ìtura náà tó sì ṣe bẹ́ẹ̀ ràn mọ́ gbogbo ilé náà.
Adarí ilé iṣẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ náà; Ọmọọba Falade John rọ àwọn onílé ìtura láti máa mójútó gbogbo ohun tó bá le fa ìjàm̀bá iná.
Maiduguri ní tòun ò le yàtọ̀;
Ṣàdédé ni iná sẹ́yọ ní ilé oúnjẹ Kayat tó wà ní òpópónà Polo ní Maiduguri tíí ṣe olú ìlú ìpúnlẹ̀ Borno.
Nǹkan bíi aago mọ́kànlá òwúrọ̀ ọjọ́ Àìkú ni iná náà sẹ́yọ, àwọn panápaná ìpínlẹ̀ náà ló tètè kojú rẹ̀ kò bá jóná kan éérú.
Nínú àtẹ̀jáde tí alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Borno; Nahum Daso bu ọwọ́ lù la ti ríì kà pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà kò la ẹ̀mí lọ.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ṣe àlàyé pé àwọn gba ìpè pàjáwìrì náà lọ́jọ́ kẹrìndínlógún, oṣù Bélú pé ilé oúnjẹ Kayat ti ranná ní Maiduguri. Lọ́gán ni kọmíṣọ́nà ọloọ́pàá; Naziru Abdulmajid ti pàṣẹ kí àwọn ọlọ́pàá ó máa lọ sí ibẹ̀ tó sì tún ké sí ilé iṣẹ́ panápaná.
Yàtò sí pípa iná náà, àwọn ọlọ́pàá ríi dájú pé àwọn dóòlà ẹ̀mí àwọn èèyàn àti dúkíà tí kò tíì múná, àwọn aráàlú kan sáárá fún iṣẹ́ takuntakun tí wọ́n ṣe náà.
Alukoro fún ilé iṣ̣́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Borno; Nahum Daso rọ àwọn èèyàn láti máa ṣe jẹ́jẹ́ pẹ̀lú àwọn ẹ̀rọ tó ń lo iná ọba.
Iná mọ̀nàmọ́ná rí ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ó ní òun náà yóò ṣe tòun, níbi ayẹyẹ ìwúyè ló ti dárà tirẹ̀:
Bàbá kan ní òpópónà Anjorin ni ó ń wúyè tó sì pe àwọn èèyàn jọ, nígbà tí ayẹyẹ ń lọ lọ́wọ́ ni ọkọ̀ ajáyanrìn kan fẹ́ kọjà lọ sí ilé tí wọ́n ń kọ́ lọ́wọ́ ní òpin òpópónà náà, ọ̀kan nínú àwọn agbòòrùn òde tí wọ́n ta náà dí ọ̀nà tí ọkọ̀ agbéyanrìn yìí le gbà kọjá, wọ́n gbìyànjú láti gbé agbòòrùn náà ni iná bá gbé wọn pa.
Ọmọ ẹ̀kọ́ṣẹ́ awakọ̀ náà àti àwọn mẹ́ta mìíràn tí wọ́n wá sí òde ni wọ́n jọ gbé agbòòrùn náà kúrò lọ́nà, nígbà tí wọ́n máà gbé e kalẹ̀, orí wáyà iná ni wọ́n gbé e lé, èyí ló fà á tí iná fi gbé wọn.
Àwọn èèyàn ò tètè mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ àfi ìgbà tí wọ́n ṣubú sílẹ̀.
Femi Ajiboye; ọ̀kan lára àwọn àlejò òde náà ṣe àlàyé pé ìgbìyànjú àti la ọ̀nà tí ọkọ̀ agbéyanrìn náà le gbà kọjá síbi tó ń lọ ló ṣekú pa wọ́n, kò sí ẹni tó mọ̀ pé wáyà iná wà nílẹ̀ ní ìhòòhò, orí rẹ̀ tí wọ́n gbé irin agbòòrùn òde náà lé ni iná fi gbé wọn tó sì gbé wọn pa.
Ẹ̀sẹ̀kẹsẹ̀ ni àríyá ìdùnú di òde ìbànújé́, olórin pa ìlù lójú ẹsẹ̀, ojú agbo dàrú, wọ́n ṣe aájò àwọn tó ṣe àgbákò iná náà.
Olajide náà sọ̀rọ̀, ó wí pé wọ́n kó àwọn mẹ́rin náà lọ sí ilé ìwòsàn àmọ́ ọmọ iṣẹ́ awakọ̀ náà kú nígbà tí àwọ mẹ́ta yòókù ń gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó ní àwọn kò gbọ́ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà.




