Àwọn ọlọ́pàá ti ń wá Timothy Gilbert lẹ́yìn tó fi ásíìdì wẹ ọ̀rẹ́bìnrin rẹ̀ Angela Ogah ní ìpínlẹ̀ Edo.
Àlàyé tí a rí gbà láti ẹnu alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà; Moses Yamu ni pé Timothy fi ẹsẹ̀ fẹ́ ẹ lẹ́yìn tó dá ọ̀ràn náà ní agbègbè Ihovbe, Ikpoba.
Ẹni ogójì ọdún ni Angela Ogah, lọ́jọ́ náà, èdè àìyedè wáyé láàrin Timothy àti Angela, Timothy kò ṣe méní ṣe méjì, ó da ásíìdì lé Angela lórí ó sì sálọ.
John Izegaegbe; ẹni tó jẹ́ agbẹjọ́rò Angela ṣe àlàyé pé Angela ti wà ní ilé ìwósàn níbi tó ti ń gba ìtọ́jú, ó ní àwọn ti kọ̀wé sí ọ̀gá ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Edo lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Yamu rọ àwọn èèyàn láti yàgò fún àwọn olólùfẹ́ ọ̀ràn ó sì ṣe ìlérí pé àwọn yóò mú Timothy láìpẹ́.
ỌLỌ́PÀÁ KÓ ÌBÓM̀BÓ TI KỌ̀ǸDỌ́ NÍNÚ ỌKỌ̀ RẸ̀.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó ti fèsì sí fọ́nrán tó gbòde nínú èyí tí ọlọ́pàá kan ti kó ẹ̀ṣẹ́ bo kọ̀ǹdọ́ nínú ọkọ̀ akérò tó sì tún fún un lọ́rùn mọ́lẹ̀.
Àwọn èrò inú ọkọ̀ ló ń gbìyànjú àtìlà wọ́n tí kọ̀ǹdọ́ náà sì ń pariwo ‘ẹ má pa mí, ẹ má pa mí’ lédè gẹ̀ẹ́sì.
Abimbola Adebisi; ẹni tó jẹ́ alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó fèsì pé awakọ̀ akérò náà fi ọkọ̀ rẹ̀ dí ojú ọ̀nà ní èyí tó fa súnkẹrẹ-fàkẹrẹ ọkọ̀, nítorí kí ọlọ́pàá má baà mú un ló ṣe bọ́ aṣọ sílẹ̀ àmọ́ síbẹ̀, ohun tí ọlọ́pàá náà ṣe kò dára tó.
Ó ní àwọn ti ṣe ìdámọ̀ ọlọ́pàá náà yóò sì ṣe àlàyé bí ọ̀rọ̀ ṣe jẹ́. Bákan náà ni kọ̀ǹdọ́ náà yó farahàn níwájú kọmíṣọ́nà ní ọjọ́ Ajé.
Ọkọ̀ akérò náà ti wà ní àgọ́ àwọn ọlọ́pàá títí ìwádìí ó fi parí.
olopaa miiran tun pa omo olomo:
Ọlọ́pàá kan ti yìnbọn pa ọ̀dọ́kùnrin kan ní agbègbè Alakia ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́.
A gbọ́ pé ọlọ́pàá náà àti ọ̀dọ́ náà ń ṣe fàǹfà nígbà tí ọ̀dọ́ náà kọ̀ láti jẹ́ kí ó mú òun, èyí ni wọ́n ń ṣe lọ́wọ́ tí ọloọ́pàá yìí fi yìnbọn fún un lẹ́sẹ̀, wọ́n gbé e dé ilé ìwòsàn àmọ́ kò yè é.
Ajakale aarun n kan ilekun:
Àwọn olùgbé àwọn agbègbè bíi Iyana-ipaja, Abule egba, Oṣodi, Iṣeri, Agege àti àwọn mìíràn bẹ́ẹ̀ ti ké sí ilé iṣẹ́ kólẹ̀kódọ̀tí LAWMA láti wá kó àwọn ilẹ̀ tó ti di ẹ̀rìmọ̀ sí àwọn agbègbè náà. Wọ́n wí pé èyí le fa àjàkálẹ̀ ààrùn nítorí pé ó léwu fún ìlera.
Kunle Ayeni; ẹni tó jẹ́ olùgbé Igando wí pé ó ti lé ní oṣù mẹ́ta tí wọ́n ti wá kó ilẹ̀ agbègbè náà, gbogbo rẹ̀ ni ó ń mú òórùn burúkú jáde.
Yàtọ̀ sí pé ilẹ̀ ti gba ìdajì ọ̀nà, òórùn rẹ̀ kò sùnwọ̀n bí òjò bá rọ̀. Àwọn ará Igando kò le ṣí fèrèsé wọn, eeṣin ọdẹ ni yóò bá wọn lálejò. A ti sọ fún ọ̀gá LAWMA agbègbè wa àmọ́ wọn kò ṣe nǹkankan síi.
Deola Davies tí òun náà ń gbé ní Ìṣẹri ṣe àlàyé pé àwọn LAWMA kò wá gbé ilẹ̀ àwọn èèyàn ò sì yé da ilẹ̀ jọ síbẹ̀, àwọn tó ń gbé níbẹ̀ ni yóò máa jẹ òórùn.
Funmi Adagba náà fi ẹjọ́ sùn pé ilẹ̀ ń bá ọkọ̀ du títì ni lágbègbè tirẹ̀ pẹ̀lú òórùn burúkú.
Àwọn èèyàn yìí wí pé oṣooṣù ni àwọn ń san owó ilẹ̀ fún ìjọba àmọ́ wọn kò wá kó ilẹ̀ náà mọ́. Bí àwọn bá fi le pa oṣù kan jẹ, wọn yóò wá ti ilé náà ni.
Esther Owobayi náà ṣe àlàyé pé ẹ̀ẹ̀kan lóṣù ni wọ́n ń wá kó ilẹ̀ àdúgbò rẹ̀ báyìí n ígbà mìíràn oṣù méjì àmọ́ èyí kò dí owó wọn lọ́wọ́.
Funmilayo náà dá síi pé àwọn àjọ LAWMA náà ń hu ìwà ta ni yóò mú mi? wọn yóò há ìwé owó ilẹ̀ àmọ́ wọn kò ní wákó ilẹ̀ bí àwọn kò bá sì sanwo kíá ni wọn yóò wá ti ilé náà.
Wọ́n rọ ìjọba láti ṣe àtúnṣe sí èyí nítorí pé ó le fa àjàkálẹ̀ ààrùn.
iroyin okere:
Ọmọ orílẹ̀-ède Nàìjíríà kan tó lọ kẹ́kọ̀ọ́gboyè ní ilẹ̀ UK ti kú sí ọ̀hún báyìí o.
Ìlera Hammed dẹnukọlẹ̀ lẹ́ẹ̀kan náà látàrí ààrùn jẹjẹrẹ tó ti kọ́lé sínú àgọ́ ara rẹ̀.
Àwọn èèyàn ti ń dá owó ìrànwọ́ fún ní àpò Gofundme tí Mariam Ajibola ṣí fún un kí ó fi wo ààrùn náà àmọ́ ní báyìí, Marian ti kéde pé àwọn yóò fi owó náà ṣètò ìsìnkú rẹ̀ ni.
Ọmọ bíbí ìlú Ayete ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ni Hammed, ẹni ọdún mẹ́rìndínlógójì ni pẹ̀lú. Ó ti kẹ́kọ̀ọ́jáde ìwé gíga ìpele kìíní ní Nàìjíríà kó tó lọ sí UK lọ ka ìpele kejì.
Inú ọdún yìí náà ni wọ́n ríi pé ó ti ní ààrùn jẹjẹrẹ àmọ́ ó fi orí tìí pé kí òun ó kẹ́kọ̀ọ́ náà parí kí ó tó darí wálé.
Hammed ni àbígbẹ́yìn nínú ọmọ mẹ́rin ó sì jẹ́ ọlọ́yàyà ọmọ.
Àwọn tó ṣètò Gofundme náà fún un ṣe àlàyé pé ìlera rẹ̀ burú síi lẹ́nu lọ́lọ́ yìí àwọn sì gbìyànjú àti gbé e wálé kí ó le lo àwọn ọjọ́ rẹ̀ yòókù pẹ̀lú àwọn ẹbí rẹ̀ àmọ́ àwọn dọ́kítà ní kò ní okun àtirin ìrìn àjò.
Wọn kò le gbé òkú Hammed wálé fún ọ̀pọ̀ ìdí, wọ́n nílò ẹgbẹ̀rún márùn-ún owó dọ́là láti sin òkú rẹ̀ sí UK, ní báyìí, wọ́n ti rí owó tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́fà dọ́là.
Eyi ni akojo awon iroyin to gbode lose yii, e ma rin jinna.




