Ayẹyẹ ìwúyè parí ìdárò nígbà tí iná gbé àwọn èèyàn mẹ́ta pa. Agbègbè Idimu ní Alimosho, Èkó ni èyí ti wáyé lọ́jọ́ kọkànlá, oṣù Bélú.
Bàbá kan ní òpópónà Anjorin ni ó ń wúyè tó sì pe àwọn èèyàn jọ, nígbà tí ayẹyẹ ń lọ lọ́wọ́ ni ọkọ̀ ajáyanrìn kan fẹ́ kọjà lọ sí ilé tí wọ́n ń kọ́ lọ́wọ́ ní òpin òpópónà náà, ọ̀kan nínú àwọn agbòòrùn òde tí wọ́n ta náà dí ọ̀nà tí ọkọ̀ agbéyanrìn yìí le gbà kọjá, wọ́n gbìyànjú láti gbé agbòòrùn náà ni iná bá gbé wọn pa.
Ọmọ ẹ̀kọ́ṣẹ́ awakọ̀ náà àti àwọn mẹ́ta mìíràn tí wọ́n wá sí òde ni wọ́n jọ gbé agbòòrùn náà kúrò lọ́nà, nígbà tí wọ́n máà gbé e kalẹ̀, orí wáyà iná ni wọ́n gbé e lé, èyí ló fà á tí iná fi gbé wọn.
Àwọn èèyàn ò tètè mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ àfi ìgbà tí wọ́n ṣubú sílẹ̀.
Femi Ajiboye; ọ̀kan lára àwọn àlejò òde náà ṣe àlàyé pé ìgbìyànjú àti la ọ̀nà tí ọkọ̀ agbéyanrìn náà le gbà kọjá síbi tó ń lọ ló ṣekú pa wọ́n, kò sí ẹni tó mọ̀ pé wáyà iná wà nílẹ̀ ní ìhòòhò, orí rẹ̀ tí wọ́n gbé irin agbòòrùn òde náà lé ni iná fi gbé wọn tó sì gbé wọn pa.
Ẹ̀sẹ̀kẹsẹ̀ ni àríyá ìdùnú di òde ìbànújé́, olórin pa ìlù lójú ẹsẹ̀, ojú agbo dàrú, wọ́n ṣe aájò àwọn tó ṣe àgbákò iná náà.
Olajide náà sọ̀rọ̀, ó wí pé wọ́n kó àwọn mẹ́rin náà lọ sí ilé ìwòsàn àmọ́ ọmọ iṣẹ́ awakọ̀ náà kú nígbà tí àwọ mẹ́ta yòókù ń gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó ní àwọn kò gbọ́ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Lónìí yìí kan náà ni adájọ́ gbé ìdájọ́ kalẹ̀ lórí ẹ̀sùn Nnamdi Kanu báyìí pé:
ILÉ ẸJỌ́ TI DÁ Ẹ̀WỌ̀N GBÉRE FÚN NNAMDI KANU.
Ilé ẹjọ́ gíga ìjọba tó fìkàlẹ̀ sí Abuja ti dá ẹ̀wọ̀n gbére fún ajìjàǹgbara fún ìdásílẹ̀ orílẹ̀-ède Biafra; Nnamdi Kanu lọ́jọ́bọ, oṣù Bélú.
Adájọ́ Justin James Omotosho wí pé Nnamdi Kanu jẹ̀bi gbogbo ẹ̀sùn oníkókó méje tí ìjọba fi kàn án lórí ìgbésùnmọ̀mí àti ìfẹ̀míṣòfò. Ẹjọ́ ikú ni adájọ́ ní ó tọ́ síi àmọ́ ó wò ó ṣe fún un ni ó ṣe dá ẹ̀wọ̀n gbére fún un.
Ayẹyẹ ni àwọn èèyàn yìí lọ tí wọ́n fi ṣe àgbákò iná ọba tó sẹkú pa wọ̀n.
ILÉ ÌTURA EBUNLOMO TI JÓNÁ, AJÉ O!
Ilé ìtura Ebunlomo tó wà ní Ilorin tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Kwara ti jóná kan éérú lọ́jọ́ ìṣẹ́gun.
Nǹkan bíi aago márùn-ún ìdájí ni iná náà bẹ̀rẹ̀ tó sì ràn mọ́ gbogbo yàrá mẹ́tàlélógún ilé ìtura náà. Àwọn panápaná ìpínlẹ̀ náà ló kojú iná náà.
Hassan Adekunle; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ Kwara ṣe àlàyé pé à kiwọn tètè kojú iná náà kó má baà ràn mọ́ àwọn ilé tó yíi ká.
Ìwádìí fi hàn pé iná náà sẹ́yọ nígbà tí àwọn wáyà iná kanra wọn ẹ̀ka ọtí mímu ilé ìtura náà tó sì ṣe bẹ́ẹ̀ ràn mọ́ gbogbo ilé náà.
Adarí ilé iṣẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ náà; Ọmọọba Falade John rọ àwọn onílé ìtura láti máa mójútó gbogbo ohun tó bá le fa ìjàm̀bá iná.
ILÉ ÌTURA EBUNLOMO TI JÓNÁ, AJÉ O!
Ilé ìtura Ebunlomo tó wà ní Ilorin tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Kwara ti jóná kan éérú lọ́jọ́ ìṣẹ́gun.
Nǹkan bíi aago márùn-ún ìdájí ni iná náà bẹ̀rẹ̀ tó sì ràn mọ́ gbogbo yàrá mẹ́tàlélógún ilé ìtura náà. Àwọn panápaná ìpínlẹ̀ náà ló kojú iná náà.
Hassan Adekunle; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ Kwara ṣe àlàyé pé àwọn tètè kojú iná náà kó má baà ràn mọ́ àwọn ilé tó yíi ká.
Ìwádìí fi hàn pé iná náà sẹ́yọ nígbà tí àwọn wáyà iná kanra wọn ẹ̀ka ọtí mímu ilé ìtura náà tó sì ṣe bẹ́ẹ̀ ràn mọ́ gbogbo ilé náà.
Adarí ilé iṣẹ́ panápaná ìpínlẹ̀ náà; Ọmọọba Falade John rọ àwọn onílé ìtura láti máa mójútó gbogbo ohun tó bá le fa ìjàm̀bá iná.
Lórí ikú Mohbad
MO NÍ FỌ́NRÁN BÍ WỌ́N ṢE PA MOHBAD – YOMI FABIYI.
Òṣèrékùnrin ilẹ̀ wa; Yomi Fabiyi ti ju àdó ọ̀rọ̀ sílẹ̀ lórí ikú tó pa Ilerioluwa Aloba tí orúkọ ìtàgé rẹ̀ ń jẹ́ Mohbad.
Ààrẹ Bola Ahmed Tinubu ni Fabiyi darí ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí pé kí ó dá sí, ó ní òun ní fọ́nrán bí wọ́n ṣe pa Mohbad lọ́wọ́, ó ní àwọn kan ló fi fọ́nrán náà ṣọwọ́ sí òun láti fi gba owó.
Àwọn ọlọ́pàá ẹ̀ka FCID Abuja ti ṣe àtúnyẹ̀wò ìwé ẹjọ́ náà wọ́n sì ti ṣe ìdámọ̀ àwọn afurasí lórí ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tẹ̀síwájú pé Wunmi; ìyàwó Mohbad ti farahàn ní Abuja pẹ̀lú àwọn afurasí kan, wọ́n ń lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọlọ́pàá láti bo ẹjọ́ náà mọ́lẹ̀ wọ́n sì tún ń gbìyànjú àti da ẹjọ́ náà lé òun lórí. Kódà, àwọn ọlọ́pàá kan ti ń dúnkokò mọ́ mi nítorí ẹ̀rí tó wà lọ́wọ́ mi- Yomi Fabiyi.
GÉŃDÉ ỌKÙNRIN MÁRÙN-ÚN ṢE ÌYÁ KAN NÍṢEKÚṢE NÍ ÌPÍNLẸ̀ IMO.
Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Imo ti tẹ awọn ọkùnrin márùn-ún kan tí wọ́n ṣe ìyá ìyá kan ẹni ọdún márùndínlọ́gọ́ta níṣekúṣe.
Ndidiamaka Agu ni orúkọ ìyá yìí, agbègbè Emekuku ní Owerri ni ilé rẹ̀ wà. Agbẹnusó fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Imo; Henry Okoye ló sọ ọ̀rọ̀ di mímọ̀. Ó wí pé kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà ti pàṣẹ kí wọn ó wádìí ọ̀rọ̀ dé délẹ̀délẹ̀.
Àwọn tí ọwọ́ tẹ̀ náà ni Onyekachi Njoku, Chiazor Osuji, Chukwuma Iwuala, Eugene Njoku àti Njoku Emmanuel, ọmọ ìlú Uboegbelu ni gbogbo wọn.
Lọ́jọ́ náà, àwọn márùn-ún pẹ̀lú ẹjìkẹfà wọn lọ ká ìyá yìí mọ́lé láti jà á lólè, ibi tí wọ́n ti ń gbìyànjú àti já ilẹ̀kùn rẹ̀ wọlé ni ìyá náà ti jadé sí wọn láti kojú wọn, wọ́n nawọ́ gán ìyá yìí wọ́n sì lùú ní àlùbámi.
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Imo bu ẹnu àtẹ́ lu ìwà náà, ó pàṣẹ kí àwọn ọlọ́pàá ó parí ìwádìí náà kí wọ́n sì fi ojú ba ilé ẹjọ́.




