Abdullahi Abass yóò lo gbogbo ìṣẹ̀mí rẹ̀ yòókù lọ́gbà ẹ̀wọ̀n lórí ẹ̀sùn pé ó fipá bá ọmọdékùnrin kan tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lájọṣepọ̀.
Ẹni ọdún mọ́kàndínlógún ni Abdullahi Abass, iṣẹ́ olùkọ́ ló ń ṣe nílé ìwé aládàáni kan ní agbègbè Kwali.
A gbọ́ pé lọ́jọ́ kọkàndínlógún, oṣù Ẹrẹ́nà, lẹ́yìn tí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà jáde ilé ìwé, Abdullahi rán akẹ́kọ̀ọ́ kan kí ó lọ pe ọmọkùnrin ọmọ ọdún mẹ́sàn-án náà wá, ó tan ọmọ náà lọ sí kọ̀rọ̀ ó sì fipá bá a lò láti ihò ìdí.
Ọmọ yìí sọ fún ìyá rẹ̀ wọ́n sì fi ọlọ́pàá gbé e. ẹ̀sùn oníkókó méjì ni ìjọba fi kan Abdullahi; ìfipábánilò àti ìṣenimọ́kumọ̀ku nípa ti ìbálòpọ̀.
Ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Ọ̀wàrà ni Abdullahi farahàn nílé ẹjọ́ gíga Abuja níwájú Adájọ́ M. Osho-Adebiyi, lẹ́yìn gbogbo atótónu àti àwíjàre, adájọ́ wí pé Abdullahi jẹ̀bi àwọn ẹ̀sùn náà ó sì dá ẹ̀wọ̀n gbére fún un.
Bákan náà ni Pásítọ̀ Aka-Bashorun Olawale ń jẹ́jọ́ lórí ìṣenimọ́kumọ̀ku:
Pásítọ̀ Aka-Bashorun Olawale; ẹni tó tún jẹ́ agbẹjọ́rò ti balẹ̀ síwájú adájọ́ Hakeem Oshodi ti ilé ẹjọ́ gíga Ikeja lórí ẹ̀sùn pé ó fi ọwọ́ tẹ ọmú ọmọdébìnrin ọmọ ọdún mẹ́rìnlá kan.
Ìròyìn fi yé wa pé Pásítọ̀ Olawale jẹ́ pásítọ́ ní ìjọ ìràpadà, ẹ̀sùn oníkókó kan tí ìjọba fi kàn án náà ni pé ó fi ọwọ́ tẹ ọmú ọmọdébìnrin ọmọ ọdún mẹ́rìnlá kan ní agbègbè Iwaya, ìpínlẹ̀ Èkó.
Agbẹjọ́rò ìjọba; Funmilola Aluko wí pé ohun tí pásítọ̀ Olawale ṣe yìí tako òfin ipínlẹ̀ Èkó àmọ́ agbẹjọ́rò Olawale wí pé Olawale ko jẹ̀bi ẹ̀sùn náà. Morenikeji Oyekunle rọ ilé ẹjọ́ láti gba onídùúró Olawale nítorí pé kò le sá lọ àti wí pé pásítọ̀ ni.
Agbẹjọ́rò fún ìjọba; Funmilola Aluko tako ẹ̀bẹ̀ Morenikeji ó sì rọ ilé ẹjọ́ láti wo ọ̀rọ̀ náà dáadáa.
Adajo Hakeem Oshodi gba onídùúró Olawale pẹ̀lú àṣẹ pé ó gbọ́dọ̀ yọjú ní gbogbo ìgbẹ́jọ́ tió yóò wáyé.
Àlàyé tí ọmọdébìnrin ìgbà náà; ẹni tó ti pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n nísìn yìí ṣe ni pé lọ́dún 2010 nígbà tí òun wà ní ọmọ ọdún mẹ́jọ ni bàbá òun mú òun lọ gbé ní ilé pásítọ̀ Olawale kí òun le tẹ̀síwájú nínú ẹ̀kọ́ kí òun sì le máa kópa nínú ẹgbẹ́ akọrin ìjọ. Ó wí pé bí òun ṣe dé ibẹ̀́ ni Olawale ti ń ṣe òun mọ́kumọ̀ku, yóò fi ọwọ́ tẹ gbogbo ọmú rẹ̀ yóò sì tún lù ú lálùbami bí ó bá fìdí rẹ́mi nílé ìwé.
Ó ní òun padà sá kúrò nílé Olawale lọ́dún náà lọ́hùn-ún tí òun sì ṣe àlàyé fún ìyá òun.
Lọ́dún 2023 tí òun gbọ́ pé Olawale ṣe irú èyí fún ọmọdébìnrin mìíràn ni òun pe ẹjọ́ náà. Ó wí pé ẹlẹ́rìí òun ni olùkọ́ òun nígbà náà; Arábìnrin Akingbeoyewa nítorí pé òun sọ fún un nígbà náà.
Adájọ́ Oshodi pàṣẹ kí Olawale ó san ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta náírà fún ọmọbìnrin náà ṣáájú ìgbẹ́jọ́ tó ń bọ̀. Ó sún ìgbẹ́jọ́ sí ọjọ́ kẹsàn-án, oṣù Ọ̀pẹ.
Bàbá ẹni ọdún méjìdínláàdọ́ta kan tí wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Emmanuel George ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá lẹ́yìn tó fi ipá gba ìbálé ọmọbìnrin ọmọ ọdún méjìlá kan.
A gbọ́ pé nínú keke maruwa tí bàbá yìí ń w ni ó ti já ìbálé ọmọ náà.
Ọjọ́ kẹfà, oṣù Ọwẹ́wẹ̀ yìí ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹ̀ ní agbègbè Mini Orlu ní Portharcourt tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Rivers.
Ọmọbìnrin yìí ni ẹ̀gbọ́n rẹ̀ tó wá lo ìsinmi lọ́dọ̀ rẹ̀ rán níṣẹ́ nígbà tí Emmanuel fi ipá wọ́ ọ sínú keke rẹ̀, ó fi aṣọ díi lẹ́nu ó tún so ọwọ́ rẹ̀ sẹ́yìn kó tó fi ipá já ìbálé rẹ̀, lẹ́yìn náà ni ó sálọ.
Ọmọ yìí délé ròyìn fún ẹ̀gbọ́n rẹ̀, wọ́n gbé e lọ sí ilé ìwòsàn wọ́n sì fi tó àwọn ọlọ́pàá létí.
Ìtọpinpin awọn ọlọ́pàá ni wọ́n fi lọ gbé Emmanuel níbi tó lọ farasin sí, kò tilẹ̀ jiyàn, pẹ̀lú sùúrù ló fi jẹ́wọ́ pé òun bá ọmọ náà lò lóòótọ́.
Grace Iringe-Koko; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Rivers ló sọ ọ̀rọ̀ yìí di mímọ̀ ó sì ṣe ìkìlọ̀ fún àwọn òbí láti mójútó àwọn ọmọ wọn.
Èyí kìí ṣe ìgbà àkọ́kọ́ tí a ó mú ìròyìn wá nípa ìfipábánilò, lára àwọn èyí tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn rèé.
Aṣọ́gbà ilé ìwé alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ kan tó wà ní Ìbàdàn tíí ṣe olú ìlú ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá lẹ́yìn tó fipá bá ọmọ ọdún mẹ́rin tó jẹ́ ọmọ ilé ìwé náà lò.
Josiah Ayomide ni orúkọ aṣọ́gbà yìí, ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gbọ̀n ni pẹ̀lú.
Ìròyìn fi yé wa pé lọ́jọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n, oṣù Ògún tó kọjá yìí ni Josiah ki ọmọ náà mọ́lẹ̀ tó sì fipá já ìbálé rẹ̀.
Ọmọ yìí sọ fún ẹ̀gbọ́n rẹ̀ pé ojú ara ń dun òun, nígbà tí wọ́n tẹ̀ ẹ́ nínú ló ṣe àlàyé pé aṣọ́gbà ilé ìwé bọ́ pátá òun lọ́jọ́ kan tó sì ki nǹkan bọ̀ ìdí rẹ̀.
Àyẹ̀wò nílé ìwòsàn Eleyele fi hàn pé ìbálé ọmọ náà ti já, ojú ara rẹ̀ sì tún dégbò.
Josiah náà kò jiyàn lágọ̀ọ́ ọlọ́pàá, ó jẹ́wọ́ pé lóòótọ́ ni òun fipá bá ọmọ náà lò.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé Josiah yóò fi ojú ba ilé-ẹjọ́ láìpẹ́.
Adewale Osifeso; ẹni tó jẹ́ alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ lọ fi ọ̀rọ̀ yìí léde.
Olajobi Taiwo náà ti wà ní àhámọ́ àwọn ọlọ́pàá fún ẹ̀sùn ìfipábánilò. Ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún ni Olajobi nígbà tí ọmọbìnrin náà jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀dógún.
Ìyá rẹ̀ fẹ́ nà án ló ṣe sá kúrò nílé, ọwọ́ Olajobi àti ọ̀rẹ́ rẹ̀ ló kó sí, wọ́n tàn án wọlé wọ́n sì fi ipá báa ní àjọṣepọ̀. Agbègbè Oke ila ní Ado Ekiti ni èyí ti ṣẹ̀.
Alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkìtì; Sunday Abutu wí pé ọwọ́ àwọn ti tó Olajobi o lórí ẹ̀sùn pé ó fi ipá bá ọmọdébìnrin náà lò. Wọ́n ní àwọn ti fi ọ̀rọ̀ náà ṣọwọ́ sí ẹ̀ka tó kàn gbọ̀ngbọ̀n.




