Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ti tẹ ọkùnrin kan tó ṣekú pa ọlọ́kadà ẹni ọdún mẹ́tàléláàdọ́ta kan tó sì tún gbé ọ̀kadà rẹ̀ sá lọ.
Friday Orumgbe ni orúkọ ọlọ́kadà yìí, agbègbè Agbor ní ìjọba ìbílẹ̀ Gúúsù Ika, ìpínlẹ̀ Delta ló ti ṣe àgbákò ikú òjijì náà.
Ìròyìn fi yé wa pé ọjọ́ keje, oṣù Ọ̀wàrà ni àwọn ẹbí Friday kò ti ríi mọ́ tí wọ́n sì fi tó àwọn ọlọ́pàá létí. Ìwádìí bẹ̀rẹ̀ wọ́n sì mú Musa Buhari; ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n, wọ́n bá ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ Friday lọ́wọ́ rẹ̀.
Musa jẹ́wọ́ pé òun àti Manu Usman ni àwọn gun ọ̀kadà Friday bíi èrò tí àwọn sì tàn án lọ sínú igbó kan ní Powerline, Oki ní Agbor, ibẹ̀ ni wọ́n ti ṣá a ní ọkọ́ títí tó fi kú tí wọ́n sì gbé ọ̀kadà rẹ̀ sá lọ.
Wọ́n bá òkú Friday níbẹ̀ lóòótó tó ti ń jẹ̀ra, àwọn ẹbí rẹ̀ ṣe ìdámọ̀ òkú náà. Manu Usman ti fẹṣẹ̀ fẹ́ẹ báyìí àwọn ọlọ́pàá ṣì ń wá a.
Agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Delta; Bright Edafe ló fi ọ̀rọ̀ yìí léde.
Ọ̀sẹ̀ tó lọ yìí náà ni Mamuda gún ọlọ́kadà lọ́bẹ tó sì gbé ọ̀kadà rẹ̀ lọ.
Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Bauchi tit ẹ ọmọkùnrin ẹni ọgbọ̀n ọdún kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mamuda Zakari Yau lórí ẹ̀sùn ìpànìyàn àti i-digunjalè.
Àlàyé tí a rí gbà láti ẹnu alukoro fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà nip é Mamuda fẹ́ ṣe ìgbéyàwó ó sì nílò owó fún ètò ìgbéyàwó náà. Èyí ló mú un lọ dá Zango Saidawa; ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n lọ́nà, ó gún un lọ́bẹ pa ó sì gbé ọ̀kadà rẹ̀ sá lọ.
Mamuda jẹ́wọ́ pé òun gún Zango lọ́bẹ lóòótọ́ àmọ́ òun kò lérò láti pa á, ó ní òun ṣe èyí láti rí owó fẹ́ ìyàwó kẹta.
Lórí ìpànìyàn yìí kan náà.
Ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ ni Gafar àti Hammed kó tó di pé abo dá ìjà sílẹ̀ láàrin wọ́n. A gbọ́ pé àwọn méjéèjì nífẹ̀ẹ́ obìnrin kan náà wọn kò sì ṣetán àti yọ̀ǹda rẹ̀.
Ẹni ọdún mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n ni Hammed Usman Tunde nígbà tí Gafar jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlélógún. Ọmọ ìlú Ilorin ni àwọn méjéèjì.
Ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà, àwọn méjéèjì pàdé ní ìsọ̀ onírèké lọ́jà Gboro, Ilorin. Èdè àìyedè ni wọ́n kọ́ fi bẹ̀rẹ̀ àgi bó ṣe di ìjàkadì, ẹ̀ẹ̀kan náà ni Gafar fa ọ̀bẹ yó tó sì fi gún Hammed láyà, lẹ́yìn náà ló sá lọ.
Àwọn èèyàn ṣe aájò Hammed dé ilé ìwòsàn aládàáni kan ní Gboro àmọ́ ó ti kú kí wọ́n tó dé ibẹ̀.
Títí di àsìkò yìí, kò sí ẹni tó mọ ibi tí Gafar wà bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ ti sá kúrò nílé.
Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ mímọ̀ láti ẹnu agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Kwara; Adetoun Ejire-Aderemi. Ó wí pé àwọn gba ìpè pàjáwìrì náà ní aago méjì ọ̀sán lọ́jọ́rú, nígbà tí wọn dé ibẹ̀, ẹ̀jẹ Hammed ni wọ́n bá nílẹ̀ tí àwọn èèyàn sì ti gbé e lọ sí ilé ìwòsàn. Àwọn ọlọ́pàá ta mọ́ra lọ sílé Gafar àmọ́ wọn kò bá ẹyẹ, tọdé tàgbà ilé náà tin a pápá bora kódà wọn kò dúró kó ẹrù.
Kọmiṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ náà; Adekimi Ojo bá àwọn ẹbí Hammed kẹ́dùn ó sì kí àwọn ará ọjà Gboro kú ìbọ̀wọ̀ fún òfin tí wọn kò dáná sun Gafar náà.
Ni ipinle Eko bakan naa, Àṣìta ìbọn pa oníkẹ̀kẹ́ kan.
Arákùnrin kan tó ń wa kẹ̀kẹ́ maruwa ni àṣìta ìbọn ti pa sí iwájú ilé ọtí tó ti lọ ṣe fàájì lẹ́yìn iṣẹ́ ní agbègbè Badore, Ajah ní ìpínlẹ̀ Èkó.
A gbọ́ pé lọ́jọ́ kejìlá, oṣù Ọ̀wàrà, ọkùnrin yìí ṣíwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ lọ sí ilé ọtí kan ní Badore, ó jáde sịta láti ra omi nítorí omi inú ilé ọtí náà wọ́n ju ti ìta lọ, omi náà ló ń mu lọ́wọ́ tí ọta ìbọn fi bàá tó sì pa á lẹ́sẹ̀kẹṣẹ̀.
Àwọn ará àdúgbò náà ṣe àlàyé pé àwọn ikọ̀ ẹgbẹ́ òkùnkùn kan ló gbé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wọ àdúgbò tí wọ́n wá ṣe ìkọlù sí ikọ̀ alátakò wọn, inú ọkọ̀ náà ni wọ́n wà tí wọ́n ti ń yin ìbọn lákọlákọ síta, ọ̀kan lára àwọn ọta tí wọ́n yìn náà ló pa onímaruwa yìí.
Abimbola Adebisi; ẹni tó jẹ́ agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Èkó fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ náà múlẹ̀ pé àwọn ọlọ́pàá bá òkú ọkùnrin náà nílẹ̀ láàárọ̀ ọjọ́ kejì, wọ́n gbé e lọ sí ilé ìgbókùúsí, àwọn e.bí rẹ̀ ti lọ gbé òkú rẹ̀ fún ìsinmi ìkẹyìn.
Wọ́n tún pa èèyàn ní ìpínlẹ̀ Anambra:
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Anambra kọ̀ láti gbọ́ ti àwọn òbí ọmọ kan tó ṣàdédé kú tí wọ́n sì ní àwọ́n kò fẹ́ wádìí ikú rẹ̀ nítorí pé ọmọ líle ni ọmọ náà. Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá yarí pé dandan ni kí àwọn ó ṣe ìwádìí ikú tó pa ọmọ náà gan-an.
Ọmọkunrin, ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún ni ọmọ náà, ìdájí ọjọ́ karùn-ún, oṣù Ọ̀wàrà ni wọ́n bá òkú rẹ̀ nínú ọgbà ilé kan Umuzocha, ìjọba ìbílẹ̀ Gúúsù Awka.
Àwọn òbí rẹ̀ kọ ìwé sí kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá pé àwọn kò fẹ́ wádìí ikú rẹ̀ nítorí pé ọmọ líle ni ọmọ náà.
Kọmíṣọ́nà ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Anambra kọ jálẹ̀ ó sì pàṣẹ kí àwọn ọlọ́pàá ó wádìí jinlẹ̀ lórí ikú Chikamso Ejiofor.
Ẹni tí wọn kò pa pa ara rẹ̀:
Ọmọdébìnrin kan tí kò tíì bàlágà lábẹ́ òfin ti pa ara rẹ̀ lẹ́yìn tí bàbá rẹ̀ fipá fi fún ọ̀rẹ́ rẹ̀ níyàwó.
A gbọ́ pé ọmọ yìí kọ̀ fún bàbá rẹ̀ pé òun kò fẹ́ ọ̀rẹ́ bàbá rẹ̀ lọ́kọ àti pé ìwé ni òun fẹ́ kà, bàbá rẹ̀ kọ̀ jálẹ̀ ó sì ṣe ìgbéyàwó tìpátìkúùkú fún un, nígbà tí ìyàwó dé ilé ọkọ rẹ̀ ìyẹn ilé ọ̀rẹ́ bàbá rẹ̀ lálẹ́, ó gbé òògùn jẹ ó sì kú.
Agbègbè Gubio ní ìpínlẹ̀ Borno ni èyí ti ṣẹlẹ̀. Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ní àwọn ti bẹ̀rẹ̀ ìwádìí lórí rẹ̀.




