Ìyá kan àti ọmọ rẹ̀ ti gbẹ́mìí mìn lẹ́yìn tí wọ́n jẹ àkàrà òyìnbó ayẹyẹ ọjọ́ ìbí kan ní orílẹ̀-ède Brazil.
Ana Maria de Jesus ni orúkọ obìnrin yìí, Castilho ni orúkọ ọmọ rẹ̀. A gbọ́ pé mọ̀lẹ́bí wọn kan ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí àmọ́ Ana kò ráyè lọ. Ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà ni àbúrò Ana tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Patricia mú ègé àkàrà oyìnbó wá fún ẹ̀gbọ́n rẹ̀; Ana ní ilé.
Ana àti àwọn ọmọ́ rẹ̀ méjì; Castilho àti Larissa ni wọ́n jẹ àkàrà òyìnbó náà, kò pẹ́ ni inú bẹ̀rẹ̀ sí run wọ́n tí àárẹ̀ sì mú wọn, ilé ìwòsàn Heliopolis ni wọ́n gbé wọn lọ.
Ana àti Castilho padà kú sílé ìwòsàn àmọ́ Larissa yè. Àyẹ̀wò àwọn dọ́kítà fi hàn pé wọ́n jẹ àwọn kẹ́mikà apakòkòrò tí wọ́n fi ń ṣe ọṣẹ.
Ẹ̀rọ akáwòrán ilé Ana gbé Patricia nígbà tó gbé àkàrà òyìnbó náà wá fún wọn ní èyí tó sọ ọ́ di afurasí. Yàtọ̀ sí fọ́nrán yìí, àyẹ̀wò ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ rẹ̀ ò, wọ́n bá àwọn ìbéèrè tó ti bèèrè lórí GOOGLE bíi ‘ṣé ọṣe le pa èèyàn? Ṣé ìpakòkòrò le pa èèyàn? Ìgbà wò ni ẹni tó bá jẹ ipakòkòrò máa kú? Àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.
Bákan náà ni àyẹ̀wò àpò owó Ana fi hàn pé ó ti tari ọ̀pọ̀ owó sí Patricia àti ọkọ rẹ̀; Leonardo ní èyí tó yá wọn àmọ́ tí kò dá ọ̀kankan padà.
Àwọn ọlọ́pàá fura pé Patricia àti ọkọ rẹ̀ kò fẹ́ dá àwọn owó náà padà ni wọ́n ṣe pa Ana àti ọmọ rẹ̀.
ỌWỌ́ ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ TẸ IKỌ̀ AFỌMỌṢÒWÒ NÍ ÌPÍNLẸ̀ RIVERS.
Ọwọ́ àwọn ọlọ́pàá ti tẹ ikọ̀ afọmọṣòwò kan ní ìpínlẹ̀ Rivers, ohun tí wọ́n máa ń ṣe náà ni pé wọn yóò rọ àwọn ọmọdé tó bá róyún he àti àti aláboyún tí wọn kò ní olùrànlọ́wọ́ láti ta ọmọ náà fún wọn.
Blessing Jack ni olórí ikọ̀ yìí, ó ti ṣe ẹ̀wọ̀n ní ìpínlẹ̀ Cross-River lórí ẹ̀sùn kan náà.
Ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Rivers ni ó sọ èyí di mímọ̀ láti ẹnu agbẹnusọ wọn; Grace Iringe-Koko pé àwọn mú Blessing; ẹni ọdún mẹ́rìnléláàdọ́ta ní ọjọ́ kẹsàn-án, oṣù kẹwàá, ní Igwuruta nítòsí Port Harcourt lẹ́yìn ìtanilólobó àwọn tó fura síi.
Mímú tí wọ́n mú Blessing ni àwọn ọlọ́pàá fi tọpinpin àwọn mẹ́ta tó jẹ́ ẹmẹ̀wàá rẹ̀, ọ̀pọ̀ ọmọ ọwọ́ ni wọ́n bá ní ibùdó wọn nígbà tí wọ́n ya bò wọ́n.
Bákan náà ni pé Blessing ń ṣiṣẹ́ ní ìfọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú dọ́kítà ọkùnrin kan tí yóò fi ayédèrú àwòrán oyún tan àwọn aláboyún ilé ìwòsàn rẹ̀ pé ọmọ inú wọn kò dá pé, lẹ́yìn tí wọ́n bá bímọ tán ni yóò wí fún wọn pé ọmọ náà ti kú tí yóò sì tà á ní mílíọ́nù méjì fún Blessing.
Ọdún mẹ́ta ni Blessing ti lò lẹ́wọ̀n lórí ọ̀ràn yìí ní ìpínlẹ̀ Cross-River, bó ṣe jáde lẹ́wọ̀n ló tẹ̀síwájú ní ìpínlẹ̀ Rivers.
KÓ Ọ̀RỌ̀ NÁÀ JẸ PADÀ – UMAHI SỌ FÚN MAKINDE.
Mínísítà fún iṣẹ́; David Umahi ti fèsì sí ọ̀rọ̀ tí Gómìnà ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́; Seyi Makinde pé kí ó dá ọ̀rọ̀ tó sọ nípa rẹ̀ padà sí ẹnu rẹ̀.
Ó wí pé ó ju ẹnu rẹ̀ lọ láti sọ pé òun ń pòòyì ẹnu nígbà tí wọ́n bèèrè iye tí wọ́n fi ṣe títì ọlọ́dà Èkó sí Calabar.
Ohun tó fa èyí ni ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò tí Umahi ṣe lórí ìkànnì ẹ̀rọ amóhùnmáwòrán Arise níbi tí òun àti olóòtú ti ta kàǹgbà lórí iye tí wọ́n fi ṣe títì ọlọ́dà Èkó sí Calabar.
Makinde, nígbà tí ó ń sọ̀rọ̀ fi ọ̀rọ̀ náà ṣẹ̀fẹ̀ pé kò yẹ kó mínísítà Umahi ó máa pòòyì ẹnu nígbà tí wọ́n bèèrè iye tí wọ́n ná lórí titi náà.
Umahi ti wá fèsì pé ọmọ ìyá ni òun àti Makinde nínú ìṣèlú, kò yẹ kí ó ṣẹnu sọ̀rọ̀ sí òun bẹ́ẹ̀ yẹn bó bá sì dá a lójú, kó wá fún ìdíje.
ÀWỌN ỌLỌ́PÀÁ HISBAH MÚ ÀWỌN TÍ WỌ́N ṢE ÌGBÉYÀWÓ LÁÌ GBA ÀṢẸ.
Àwọn ọlọ́pàá Hisbah ti lọ kó wọn níbi tí wọ́n ti ń ṣe ìgbéyàwó ní Kano. Tọkọtaya àti àwọn ọ̀dọ́ márùn-ún ni wọ́n kó ní ibẹ̀, ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n náà ni pé wọn kò gba àṣẹ lọ́wọ́ àwọn òbí ọmọbìnrin náà.
Igbákejì aláṣẹ àjọ Hisbah; Dọ́kítà Mujahideen Aminudeen ló sọ ọ̀rọ̀ yìí di mímọ̀ láàárọ̀ òní, ọjọ́ Ajé.
Ó wí pé ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá náírà ni wọ́n san ní owó orí ìyàwó náà ní èyí tó lòdì í òfin ẹ̀sìn ìsìláàmù.
Aminudeen rọ àwọn òbí láti tẹ̀lé àlàkalẹ̀ òfin ẹ̀sìn náà nínú ètò ìgbéyàwó àwọn ọmọ wọn.
INÁ GBÉ AKẸ́KỌ̀Ọ́ MÉJÌ PA NÍ ANAMBRA.
Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ méjí kan pàdé ikú òjijì nígbà tí wọ́n yà fún òjò. Àlàyé tí a rí gbà ni pé àwọn ọmọ náà ń lọ sí ilé ìwé láàárọ̀ ọjọ́ náà nígbà tí òjò bẹ̀rẹ̀ sí ní rọ̀, wọ́n yà fún òjò náà sí abẹ́ ìsọ̀ kan níbi tí ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn àti akẹ́kọ̀ọ́ ẹgbẹ́ wọn fara pamọ́ sí, kò sí ẹni tó mọ bí wọ́n ṣe fi ara gbé wáyà iná ní ìsọ̀ náà tí wọ́n sì kú lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, àwọn yòókù sáré jáde tìbẹ̀rùbojo.
Àwọn òṣiṣẹ́ aláàbò ló gbé òkú àwọn ọmọ náà jáde, ẹni tó ni ìsọ̀ náà kò tíì dé lásìkò ìṣẹ̀lẹ̀ náà.
Agbègbè Nnewi ní ìpínlẹ̀ Anambra ni èyí ti ṣẹ̀.
Ẹ ṣe adura fún Mínísítà fún ètò ìṣùná ilẹ̀ wa.
Wọ́n ti gbé e ní dìgbàdìgbà lọ sí òkè òkun báyìí nítorí àìsàn rọpárọsẹ̀.
Ẹ má rìn jìnnà o!



