Àjọ tó ń mójútó oúnjẹ àti òògùn; NAFDAC ti gbé àwọn ilé ìtajà kan tì pa lórí ẹ̀sùn pé wọ́n ń ta àwọn oúnjẹ àti òògùn tó lòdi sí òfin ilẹ̀ wa.
Méjì ni àwọn ilé ìtajà ìgbàlódé yi-í, ọ̀kan wà ní opópónà Mike Akhigbe nígbà tí èkejì wà ní òpópónà Ebitu Ukiwe, Abuja.
Àwọn oúnjẹ tí wọ́n ṣe àpèjúwe wọn ní ède ṣainíísì ni wọ́n ń tà ní àwọn ilé ìtajà yìí àti àwọn ìpara amáradán to le fa ìpalára lọ́jọ́ iwájú ni wọ́n ń tà ní àwọn ilé ìtajà yìí.
Àjọ NAFDAC wí pé òfin ni kí wọn ó ṣe àlàyé oúnjẹ sí ara páálí rẹ̀ lédè gẹ́ẹ̀sì kí àwọn ọmọ Nàìjíríà ó le mọ irú oúnjẹ tí wọ́n ń rà jẹ ní pàtó.
Bákan náà ni pé àwọn ìpara àti ọṣẹ aṣaralóge tí wọ́n ń tà nílé ìtajà náà kò nií ìforúkọsílẹ̀ ó sì tún ní àwọn èròjà tó le pani lára lọ́jọ́ iwájú.
Ilé ìtajà ọṣẹ àti ìpara báyìí mẹ́jọ ni wọ́n gbé tì pa ní ọjà Wuse, ọjà tí iye rẹ̀ ń lọ bíi àádọ́jọ mílíọ́nù náírà ni wọ́n gbẹ́sẹ̀ lé.
Bákan náà ni àwọn ilé ìtajà yìí ń ta àwọn òògùn yọ̀dí, yọmú, ayọ́ràá, alekó àti àwọn òògùn mìíràn bẹ́ẹ̀ tó ṣe pé àìlera ni yóò fà lọ́jọ́ iwájú.
Àjọ NAFDAC wí pé àwọn kò ní gbà fún ilé ìtajà kankan láti mú ìpalára ọjọ́ iwájú bá àwọn èèyàn.
Nínú oṣù Ọwẹ́wẹ̀ ni àwọn ìgbìmọ̀ kan ṣe àbẹ̀wò ọlọ́fìn-íntótó sí àwọn ilé ìtajà ìgbàlódé kiri ìpínlẹ̀ Èkó, àbábọ̀ wọn fi hàn pé iwọ ni ọ̀pọ̀ àwọn ilé ìtajà náà ń fún àwọn èèyàn jẹ.
Báyìí ni ìròyìn náà ṣe lọ:
Àwọn ilé ìtajà ńláńlá káàkiri ìpínlẹ̀ Èkó ń ta àwọn ọjà tí gbèdéke ọjọ́ wọn ti kọjá fún àwọn oníbàárà, ohun jíjẹ ló pọ̀ nínú àwọn nǹkan yìí ní èyí tó mú ìpalára bá ìlera àwọn
Àwọn tí wọ́n ṣe àgbákò àwọn oúnjẹ yìí ṣe àlàyé ohun tí ojú wọn rí fún àwọn akọ̀ròyìn, wọ́n ṣe àlàyé pé àwọn ilé ìtajà yìí yóò kó àwọn ọjà náà sí apá kan pé àwọn ń ṣe ètò ẹdínwó, ẹ̀dínwó yìí kò ní jẹ́ kí àwọn èèyàn ó yẹ ọjà náà wò tàbí wo gbèdéke rẹ̀ tí wọn yóò fi rà á, ìgbà tí wọ́n bá dé ilé tàbí tí inú bá bẹ̀rẹ̀ sí ní run wọ́n ni wọ́n tó máa ń mọ̀ pé gbèdéke ọjọ́ ọjà náà ti ré kọjá.
Díẹ̀ ló kù kí Daniel Olanrewaju ó pàdánù àwọn ọmọ méjì nígbà tó fún wọn ní ketchup jẹ láìmọ̀ pé gbèdéke ọjọ́ rẹ̀ ti kọjá láti ọ̀sẹ̀ mẹ́ta sẹ́yìn.
Daniel ṣe àlàyé pé òun yà sí ilé ìtajà kan tó gbajúmọ̀ ní Ikeja òun sì ra ketchup náà fún akeem ọmọ òun, nígbà tó dé ilé, ó dín iṣu fún àwọn ọmọ rẹ̀ mẹ́tẹ́ẹ̀ta ó sì bu ketchup náà síi fún wọn.
Àkọ́bí rẹ̀ tu oúnjẹ náà dànù pé ó ti kan àmọ́ Daniel kò kọbi ara síi, ó rò pé ọmọ náà kò fẹ́ jẹun ni.
Inú rírun ló jí àwọn ọmọ méjì tó jẹ oúnjẹ náà láàárọ̀ ọjọ́ kejì, ìgbà náà ni Daniel yẹ ketchup náà wò tó sì ríi pé gbèdéke ọjọ́ rẹ̀ ti kọjá láti ọ̀sẹ̀ mẹ́ta sẹ́yìn!
Dìgbàdìgbà ló di àwọn ọmọ náà dé ilé ìwòsàn, fún ìtọ́jú.
Ìrírí Daniel rèé gẹ́gẹ́ bó ṣe ṣe àlàyé, ó wí pé òun rò pé àìtà ọjà ló máa ń mú àwọn ilé ìtajà ṣe ètò ẹdínwó ni, òun kò mọ̀ pé ọjà tó le mú ìpalára bá ìlera àwọn èèyàn ni wọ́n ń tà ní gbàǹjo,
Daniel gba àwọn èèyàn lámọ̀ràn pé kí wọn ó máa yẹ ohun tí wọ́n bá rà wò fínífíní.
Temitope Ogunsanya náà ṣe àlàyé ohun tí ojú rẹ̀ rí nílé ìtajà ìgbàlódé kan tó wà ní Ijegun, ó ṣe àlàyé pé òun bá ìyàwó òun ra ìpekeré inú agolo (Pringles) ní ilé ìtajà ìgbàlódé kan tó gbajúmọ̀ dáadáa.
Nígbà tí ó fẹ́ sọ agolo ìpekeré náà nù ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì ló ṣe àkíyèsí gbèdéke ọjọ́ tí wọ́n kọ sí ara rẹ̀ tó sì ríi pé ó ti kọjá láti oṣù kan sẹ́yìn.
Àyà rẹ̀ já nítorí pé ìyàwó rẹ̀ kò tíì jí láàárọ̀ ọjọ́ náà, ó sáré wọ ìyẹ̀wù láti jíi, ọkàn rẹ̀ balẹ̀ nígbà tí ìyàwó rẹ̀ jí pẹ̀lú àlàáfíà.
Temitope ní òun kò le rò ó pé ilé ìtajà náà le ta irú ọjà bẹ́ẹ̀ nítorí pé ilé ìtajà náà lórúkọ káàkiri ìpínlẹ̀ Èkó.
Àlàyé àwọn èèyàn yìí ló ta àwọn ikọ̀ dìde láti lọ ṣe àbẹ̀wò sí àwọn ilé ìtajà káàkiri, àwọn ọjà tí gbèdéke ọjọ́ wọn ti ré kọjá ni wọ́n tò sí orí atẹ ẹ̀dínwó lóòótọ́.
Àwọn ohun jíjẹ bíi Bisikí, tíì, mílíkì, ìpàdánù àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ ló wọ́pọ̀ nínú àwọn ọjà yìí.
Àwọn ilé ìtajà ìgbàlódé tó wà ní Lekki, Abúlé Ẹ̀gbá, Ishaga àti Ọgbà ni àwọn ikọ̀ yìí ṣe àbẹ̀wò sí.
Nílé ìtajà Renne tó wà ní Lekki, gbogbo àwọn ọjà tó wà ní orí àtẹ ẹ̀dínwó ni gbèdéke ọjọ́ wọn ti ré kọjá.
Wọ́n ta Chicco D’oro ní ẹgbẹ̀rún márùún náírà dípò ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá náírà dín igba tí wọ́n ń tà á, wọ́n ta Bristol Decaf náà ní ẹgbẹ̀rún márùún náírà dípò ẹgbẹ̀rún méje, àwọn èèyàn ń ti ara wọn láti ra àwọn ọjà yìí láìmọ̀ pé gbèdéke ọjọ́ rẹ̀ ti ré kọjá.
Bákan náà lọmọ ṣorí nílé ìtajà Medzie tó wà ní Abúlé Ẹ̀gbá, White Dats àti Pune cocoa tí gbèdéke ọjọ́ wọn ti ré kọjá ni wọ́n tò sí orí igbá.
Ilé ìtajà Everbest tó wà ní Iju-Ishaga ló burú jù, àwọn ọjà tó ti ré kọjá láti inú oṣù kẹrin ọdún ni wọ́n ń tà fún àwọn èèyàn ní ẹ̀dínwó.
Ketchup, mílíkì Dano, ìfọyín, tíì lóríṣiríṣi ni wọ́n ń tà fún àwọn èèyàn tí kò fura.
Nílé ìtajà So-Rite tó wà ní Ishaga náà, tó fi dé orí bisiikí ni ọjọ́ wọn ti ré kọjá.
Ikọ̀ yìí dé ilé ìtajà Market Square tó wà ní Lekki, gbogbo àwọn ọtí ẹlẹ́rìnròdò tí wọ́n ń tà níbẹ̀ ni gbèdéke ọjọ́ wọn ti ré kọjá. Ọtí ẹlẹ́rìnròdò Schweppes, Brand Rubicon àti àwọn ohun mímu mìíràn ni gbèdéke ọjọ́ wọn ti ré kọjá.
Gbogbo àwọn ilé ìtajà ìgbàlódé tí àwọn ikọ̀ yìí lọ kò yàtọ̀, gbogbo ọjà tí wọ́n dínwó rẹ̀ ni gbèdéke ọjọ́ wọn ti ré kọjá.
Ikọ̀ yìí ṣe àkíyèsí pé ẹ̀dínwó yìí ni kò jẹ́ kí àwọn èèyàn ó yẹ àwọn ọjà náà wò tí wọ́n fi ń rà á , wọ́n ní bóyá nítorí bí gbogbo nǹkan ṣe gbowó lérí ló fàá.
Ikọ̀ yìí ti fi àbájáde wọn ṣọwọ́ sí àjọ NAFDAC, èsì tí wọ́n fọ̀ náà ni pé àwọn kò le dé gbogbo ilé ìtajà tán, àwọn ilé ìtajà yìí kò tíì fi ojú winá òfin títí di àsìkò yìí.




