Àwọn ọ̀dọ́ Onoli ní ìjọba ìbílẹ̀ Awgu, ìpínlẹ̀ Enugu ti fara ya lórí ikú ọ̀kan lára wọn tí wọ́n fura pé Fulani darandaran ló pa á.
Onochukwu Ogbagi ni orúkọ ẹni tó kú yìí, ẹni ọgbọ̀n ọdún sì ni pẹ̀lú. A gbọ́ pé ọjọ́ Ẹtì ni àwọn Fulani darandaran náà tún ṣe ìkọlù sí abúlé Obuovia tí wọ́n sì pa Ogbagi nípakúpa.
Ìkọlù àwọn darandaran yìí ti lé àwọn ará abúlé náà kúrò lóko, ìbẹ̀rùbojo ni ọ́n ń fi jáde kúrò nílé.
Mọ̀lẹ́bí Onochukwu kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Sampson Okolie bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ pé lóòótọ́ ni àwọn Fulani ṣekú pa Onochukwu, wọ́n tilẹ̀ ṣe aájò rẹ̀ dé ilé ìwòsàn ìjọba àmọ́ ẹ̀pa kò bá oró mọ́.
Ó wí pé Ogbagi lọ sí oko rẹ̀ ní ojú ọ̀nà Enugu sí PortHarcourt tó wà ní òdi ìpínlẹ̀ Enugu àti Abia lọ́jọ́ Àbámẹ́ta náà, àwọn Fulani dá a lọ́nà wọ́n sì pa á nípakúpa.
Ààrẹ Ugwuleshi; Ọ̀gbẹ́ni Aron Chidi Osu ṣe àlàyé pé àwọn ti fi ìṣẹ̀lẹ̀ náà tó ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá létí àti wí pé irú ìṣẹ̀lẹ̀ báyìí kìí ṣe ìròyìn mọ́ ní agbègbè náà.
Ọ̀gbẹ́ni Osu rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ìjọba ìpínlẹ̀ Enugu láti wá ojútùú sí ọ̀rọ̀ àwọn darandaran tí wọ́n ń ṣe ìkọlù náà. Ó wí pé ọ̀rọ̀ náà le débi wí pé awọn kò le lọ sí oko mọ́.
Gbogbo ìgbìyànjú láti bá agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Enugu; Daniel Ndukwe sọ̀rọ̀ kò so èso rere látàrí pé kò gbé aago rẹ̀ bẹ́ẹ̀ sì ni kò fèsì sí àtẹ̀jíṣẹ́.
Ọ̀rọ̀ àwọn Fulani darandaran yìí kìí ṣe ìròyìn mọ́ ní orílẹ̀-èdè wa.
Ìpínlẹ̀ Borno ò gbẹ́yìn:
Àwọn ará abulé Kwaple ní ìjọba ìbílẹ̀ Chibok ìpínlẹ̀ Borno pé jọ láti sin òkú àwọn èèyàn tí àwọn agbésùnmọ̀mí pa, ibẹ̀ ni wọ́n wà tí wọ́n tún fi y abò wọ́n, èèyàn mẹ́ẹ̀dógún ni wọ́n pa nígbà tí wọ́n jí ọ̀pọ̀lọpọ̀ gbé sá lọ.
Alága ìjọba ìbílẹ̀ Chibok; Modu Mustapha fi ìdí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí múlẹ̀ fún àwọn akọ̀ròyìn pé èèyàn mẹ́ẹ̀dógún mìíràn ni wọ́n pa níbi tí wọ́n ti ń sin òkú àwọn ti wọ́n ti pa tẹ́lẹ̀.
Lẹ́yìn náà ni wọ́n dáná sun ilé ìjọsìn EYN àti ilé márùn-ún.
Gbogbo akotiyan láti bá agbẹnusọ fún ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Borno; Nahum Daso sọ̀rọ̀ kò yọrí sí rere lásìkò tí a kọ ìròyìn yìí.
Bí a kò bá gbàgbé, ìjọba ìbílẹ̀ Chibok yìí ni àwọn agbésùnmọ̀mí ti kó ogúnlọ́gọ̀ àwọn akẹ́kọ̀ọ́bìnrin lọ́dún 2014 tí kò sì sí àbọ̀ kankan lórí wọn di àsìkò yìí.
Kò fẹ́rẹ̀ sí ibi tó fara rọ lásìkò yìí ní àríwá ilẹ̀ wa, ojoojumọ́ ni àwọn agbésùnmọ̀mí ń ṣe ìkọlù sí wọn.
Kò yọ wọ́n sílẹ̀ ní ìpínlẹ̀ Adamawa:
Alága ìjọba ìbílẹ̀ Hong ní ìpínlẹ̀ Adamawa; Usman Wa’anganda bá àwọn akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lórí àwọn ìkọlù tó ti wáyé ní agbègbè rẹ̀ láàrin ọ̀sẹ̀ méjì síra. Ó wí pé àwọn èèyàn mẹ́tàdínlógun ni àwọn agbésùnmọ̀mí ti pa lápapọ̀ láàrín ọ̀sẹ̀ méjì síra.
Nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀, Usman wí pé àwọn ọdẹ mẹ́wàá ni wọ́n pa lọ́jọ́ Àbámẹ́ta ní abúlé Kopre. Nǹkan bí aago mẹ́rin ìrọ̀lẹ́ ní ọjọ́ Àbámẹ́ta, ọjọ́ kẹrìnlélọgún, oṣù Igbe yìí ni ìkọlù náà wáyé.
Yàtọ̀ sí àwọn tí wọ́n pa yìí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ilé ni wọ́n dáná sun tí àwọn èèyàn sì wà nínú ìbẹ̀rùbojo. Usman ní òun gan-an ò le fi ojú ba oorun láti ìgbà yìí.
Ó wí pé àwọn agbésùnmọ̀mí máa ń wọ abúlé Kopre lóòrèkóòrè nítorí pé ó pààlà pẹ̀lú igbó Sambisa ní èyí tó mú un rọrùn fún wọn láti wọlé jáde.
Usman tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé àwọn ọdẹ ìbílẹ̀ nìkan ni àwọn ní ní aláàbò, kò sí ológun kankan ní ìtòsí abúlé náà, àwọn ọlọ́pàá tó súnmọ́ àwọn kìí dáhùn bí àwọn bá ránṣẹ́ pè wọ́n. Ó ní ó bani lọ́kàn jẹ́ gidi. Usman rọ ìjọba ìpínlẹ̀ Adamawa láti da àwọn ọmọ ológun sí abúlé náà kí àwọn ó le padà sí oko.
Abúlé Kopre ni ìlú akọ̀wé ìjọba àpapọ̀ tẹ́lẹ̀rí; Mustapha. Àwọn ológun a máa dáàbò bo abúlé náà láti ibùdó Garaha tí kò jìnnà sí Kopre àmọ́ lọ́gán tí Mustapha kúrò nípò ni wọ́n kó gbogbo àwọn ọmọ ológun náà kúrò tí ibùdó náà sì ṣófo.
Àwọn ará abúlé Kopre ra ọwọ́ ẹ̀bẹ̀ sí ìjọba láti gbà wọ́n kalẹ̀ lọ́wọ́ àwọn agbésùnmọ̀mí tó ń fi ojoojúmọ́ pa wọ́n bíi adìyẹ. Wọ́n ní inú fu àyà fu ni àwọn wà nítorí pé ìgbàkúùgbà ni wọ́n le ṣe ìkọlù sí àwọn.
Ipa àwọn ológun:
Ilé iṣẹ́ ológun ilẹ̀ yìí, ẹ̀ka àwọn jagunjagun ojú òfurufú ti kéde pé àwọn ti pa ọlọ́wọ́ ọ̀tún Bello Turji àti àwọn ẹmẹ̀wá rẹ̀ nínú ìkọlù tí àwọn ṣe sí ibùdó wọn.
Bello Turji ni ògbólògbó agbésùnmọ̀mí tó ń da ìpínlẹ̀ Sokoto, Zamfara àti Kastina láàmú, gbogbo àwọn ìkọlù tó nípọn tó ń wáyé ní Sokoto àti àwọn ìlú tó yíi ká kò ṣẹ̀yìn rẹ̀, ó ti pẹ́ tí àwọn ológun ti ń lépa Bello Turji tí wọn kò ríi mú.
Àmọ́ báyìí, ilé iṣẹ́ ológun wí pé àwọn ti pa ọlọ́wọ́ ọ̀tún rẹ̀ tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Shaudo Alku pẹ̀lú àwọn ikọ̀ rẹ̀. Ìbùdó àwọn agbésùnmọ̀mí tó wà ní ìtòsí ilé ìwé ìjọba alákọ̀ọ́bẹ̀rẹ̀ Tunfa tó wà ní ìjọba ìbílẹ̀ Sokoto ni wọ́n ti ṣe ìkọlù sí wọn.
Shaudo Alku wá sí Sokoto láti ilẹ̀ Nìjéè wá ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn lọ́gàálọ́gàá agbésùnmọ̀mí pẹ̀lú àṣe Bello Turji. Shaudo ni ó máa ń kó àwọn ohun ìjà olóró wọlé fún Bello láti ilẹ̀ òkèrè.
Ipa ààrẹ lórí ètò ààbò:
Ètò ààbò orílẹ̀-ède wa Nàìjíríà tó mẹ́hẹ ti gba oorun lójú ààrẹ wa; Bola Ahmed Tinubu.
Ọjọ́bọ, ọjọ́ kẹsàn-án, oṣù Ọ̀wàrà ni ààrẹ yóò ṣe ìpàdé pẹ̀lú àwọn tọ́rọ̀ náà kàn lórí bí ètò ààbò ó fi padà sípò.
Gbogbo bí ìlú ó ṣe tubà tùṣẹ ni ààrẹ àti ìgbìmọ̀ náà ó jíròrò lé lórí, ká fi ọkàn balẹ̀ ló kù.



